Book of Common Prayer
Òfin Ọlọ́run ní ìrètí
49 Rántí ọ̀rọ̀ rẹ sí ìránṣẹ́ rẹ,
nítorí ìwọ ti fún mi ní ìrètí.
50 Ìtùnú mi nínú ìpọ́njú mi ni èyí:
ìpinnu rẹ pa ayé mi mọ́.
51 Àwọn agbéraga fi mí ṣe ẹlẹ́yà láì dádúró,
ṣùgbọ́n èmi kò padà nínú òfin rẹ.
52 Èmi rántí àwọn òfin rẹ ìgbàanì, Olúwa,
èmi sì rí ìtùnú nínú wọn.
53 Ìbínú dì mímú ṣinṣin nítorí àwọn ẹni búburú,
tí wọ́n ti kọ òfin rẹ sílẹ̀.
54 Òfin rẹ ni ọ̀rọ̀ ìpìlẹ̀ orin mi
níbikíbi tí èmi ń gbé.
55 Ní òru èmi rántí orúkọ rẹ, Olúwa,
èmi yóò sì pa òfin rẹ mọ́
56 nítorí tí mo
gba ẹ̀kọ́ rẹ gbọ́.
Ọlọ́run ni ìpín wa
57 Ìwọ ni ìpín mi, Olúwa:
èmi ti pinnu láti tẹríba sí ọ̀rọ̀ rẹ.
58 Èmi ti wá ojú rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi:
fún mi ní oore-ọ̀fẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ.
59 Èmi ti kíyèsi ọ̀nà mi
èmi sì ti gbé ìgbésẹ̀ mi sí òfin rẹ.
60 Èmi yóò yára, ń kò ni lọ́ra
láti gbọ́rọ̀ sí àṣẹ rẹ.
61 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹni búburú dì mí pẹ̀lú okùn,
èmi kò ní gbàgbé òfin rẹ.
62 Ní àárín ọ̀gànjọ́ òru èmi dìde láti fi ọpẹ́ fún ọ
nítorí òfin òdodo rẹ.
63 Èmi jẹ́ ọ̀rẹ́ sí gbogbo àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ,
sí gbogbo àwọn tí ń tẹ̀lé ẹ̀kọ́ rẹ.
64 Ayé kún fún ìfẹ́ rẹ Olúwa
Kọ́ mi ní òfin rẹ.
Ìpọ́njú mu ni mọ òfin Ọlọ́run
65 Ṣe rere sí ìránṣẹ́ rẹ
gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ, Olúwa.
66 Kọ́ mi ní ìmọ̀ àti ìdájọ́ rere,
nítorí mo gbàgbọ́ nínú àṣẹ rẹ.
67 Kí a tó pọ́n mi lójú èmi ti ṣìnà,
ṣùgbọ́n ni ìsinsin yìí èmi gbọ́rọ̀ sí ọ̀rọ̀ rẹ.
68 Ìwọ dára, ohun tí ìwọ sì ń ṣe rere ni;
kọ́ mi ní ìlànà rẹ.
69 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn agbéraga ti gbìmọ̀ èké sí mí,
èmi pa ẹ̀kọ́ rẹ mọ́ pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi.
70 Ọkàn wọn yigbì kò sì ní àánú,
ṣùgbọ́n èmi ní inú dídùn nínú òfin rẹ.
71 Ó dára fún mi kí a pọ́n mi lójú
nítorí kí èmi lè kọ́ òfin rẹ.
72 Òfin tí ó jáde láti ẹnu rẹ ju iyebíye sí mi lọ
ó ju ẹgbẹ̀rún ẹyọ fàdákà àti wúrà lọ.
Fún adarí orin. Ti àwọn ọmọ Kora. Saamu.
49 Ẹ gbọ́ èyí, gbogbo ènìyàn!
Ẹ fi etí sí i, gbogbo ẹ̀yin aráyé.
2 Àti ẹni tí ó ga àti ẹni tí ó kéré
tálákà àti ọlọ́lá pẹ̀lú!
3 Ẹnu mi yóò sọ̀rọ̀ ọgbọ́n,
èrò láti ọkàn mi yóò mú òye wá
4 Èmi yóò dẹ etí mi sílẹ̀ sí òwe,
èmi yóò ṣí ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ mi sílẹ̀ lójú okùn dùùrù.
5 Èéṣe ti èmi yóò bẹ̀rù nígbà tí ọjọ́ ibi dé?
Nígbà tí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ajinnilẹ́sẹ̀ mi yí mi ká,
6 Àwọn tí o gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ wọn,
tí wọn sì ń ṣe ìlérí ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ wọn.
7 Kò sí ọkùnrin tí ó lè ra ẹ̀mí ẹnìkejì rẹ̀
padà tàbí san owó ìràpadà fún
Ọlọ́run.
8 Nítorí ìràpadà fún ẹni jẹ́ iyebíye
kò sì sí iye owó tó tó fún sísan rẹ̀,
9 Ní ti kí ó máa wà títí ayé
láìrí isà òkú.
10 Nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn rí ọkùnrin ọlọ́gbọ́n tí ó kú,
bẹ́ẹ̀ ni aṣiwèrè àti aláìlọ́gbọ́n pẹ̀lú ṣègbé
wọ́n sì fi ọrọ̀ wọn sílẹ̀ fún ẹlòmíràn.
11 Ibojì wọn ni yóò jẹ́ ilé wọn láéláé,
ibùgbé wọn láti ìrandíran,
wọn sọ orúkọ ilẹ̀ wọn ní orúkọ ara wọn.
12 Ṣùgbọ́n ọkùnrin tí o wà nínú ọlá kò dúró pẹ́
ó sì dàbí ẹranko tí ó ṣègbé.
13 Èyí ni òtítọ́ àwọn ènìyàn tí ó
gbàgbọ́ nínú ara wọn,
àti àwọn tí ń tẹ̀lé wọn,
tí ó gba ọ̀rọ̀ wọn. Sela.
14 Gẹ́gẹ́ bí àgùntàn ni a tẹ́ wọn sínú isà òkú
ikú yóò jẹun lórí wọn;
ẹni tí ó dúró ṣinṣin ni yóò,
jẹ ọba lórí wọn ní òwúrọ̀;
Ẹwà wọn yóò díbàjẹ́,
isà òkú ni ibùgbé ẹwà wọn.
15 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò ra ọkàn mi padà
kúrò nínú isà òkú,
yóò gbé mi lọ sọ́dọ̀ òun fún rara rẹ̀.
16 Má ṣe bẹ̀rù nígbà tí ẹnìkan bá di ọlọ́rọ̀.
Nígbà tí ìyìn ilé rẹ̀ ń pọ̀ sí i.
17 Nítorí kì yóò mú ohun kan lọ nígbà tí ó bá kú,
ògo rẹ̀ kò ní bá a sọ̀kalẹ̀ sí ipò òkú
18 Nígbà tí ó wà láyé, ó súre fún ọkàn ara rẹ̀.
Àwọn ènìyàn yìn ọ́ nígbà tí ìwọ ṣe rere.
19 Òun yóò lọ sí ọ̀dọ̀ ìran àwọn baba rẹ̀
àwọn tí ki yóò ri ìmọ́lẹ̀ ayé.
20 Ọkùnrin tí ó ní ọlá tí kò ní òye dàbí ẹranko tí ó ṣègbé.
Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí mahalati. Maskili ti Dafidi.
53 (A)(B) Aṣiwèrè wí ní ọkàn rẹ̀ pé:
“Ọlọ́run kò sí.”
Wọ́n bàjẹ́, gbogbo ọ̀nà wọn sì burú;
kò sì ṣí ẹnìkan tí ń ṣe rere.
2 Ọlọ́run bojú wo ilẹ̀ láti ọ̀run
sórí àwọn ọmọ ènìyàn,
láti wò bóyá ẹnìkan wà, tí ó ní òye,
tí ó sì ń wá Ọlọ́run.
3 Gbogbo ènìyàn tí ó ti yí padà,
wọ́n ti parapọ̀ di ìbàjẹ́;
kò sí ẹnìkan tí ó ń ṣe rere, kò sí ẹnìkan.
4 Ṣé àwọn oníṣẹ́ búburú kò ní ìmọ̀?
Àwọn ẹni tí ń jẹ ènìyàn mi, bí ẹni jẹun
tí wọn kò sì pe Ọlọ́run?
5 Níbẹ̀ ni ìwọ gbé wà ní ìbẹ̀rù ńlá
níbi tí ẹ̀rù kò gbé sí,
nítorí Ọlọ́run tí fọ́n egungun àwọn tí ó dó tì ọ́ ká;
ìwọ tí dójútì wọ́n, nítorí Ọlọ́run ti kẹ́gàn wọn.
6 Ìgbàlà Israẹli ìbá jáde wá láti Sioni!
Nígbà tí Ọlọ́run bá mú ohun ìní àwọn ènìyàn rẹ̀ padà,
jẹ́ kí Jakọbu yọ̀ kí inú Israẹli sì máa dùn!
Jobu rántí ìbùkún rẹ̀ àtẹ̀yìnwá
29 Pẹ̀lúpẹ̀lú, Jobu sì tún tẹ̀síwájú nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé:
Ọ̀rọ̀ ìbànújẹ́ Jobu
30 “Ṣùgbọ́n nísinsin yìí,
àwọn tí mo gbà ní àbúrò ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà
baba ẹni tí èmi kẹ́gàn
láti tò pẹ̀lú àwọn ajá nínú agbo ẹran mi.
2 Kí ni ìwúlò agbára ọwọ́ wọn sí mi,
níwọ̀n ìgbà tí agbára wọn ti fi wọ́n sílẹ̀?
16 “Àti nísinsin yìí, ayé mi n yòrò lọ díẹ̀díẹ̀;
ọjọ́ ìpọ́njú mi dì mímú.
17 Òru gún mi nínú egungun mi,
èyí tí ó bù mí jẹ kò sì sinmi.
18 Nípa agbára ńlá rẹ̀ Ọlọ́run wà bí aṣọ ìbora fún mi,
ó sì lẹ̀ mọ́ mi ní ara yíká bí aṣọ ìlekè mi.
19 Ọlọ́run ti mú mi lọ sínú ẹrẹ̀,
èmi sì dàbí eruku àti eérú.
20 “Èmi ké pè ọ́ ìwọ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n ìwọ kò dá mi lóhùn;
èmi dìde dúró ìwọ sì wò mí lásán.
21 Ìwọ padà di ẹni ìkà sí mi; ọwọ́
agbára rẹ ni ìwọ fi dè mí ní ọ̀nà.
22 Ìwọ gbé mi sókè sí inú ẹ̀fúùfù, ìwọ mú mi fò lọ,
bẹ́ẹ̀ ni ìwọ sì sọ mí di asán pátápátá.
23 Èmi sá à mọ̀ pé ìwọ yóò mú mi lọ sínú ikú,
sí ilé ìpéjọ tí a yàn fún gbogbo alààyè.
24 “Bí ó ti wù kí ó rí, ẹnìkan kí yóò ha nawọ́ rẹ̀ nígbà ìṣubú rẹ̀,
tàbí kì yóò ké nínú ìparun rẹ̀.
25 Èmi kò ha sọkún bí fún ẹni tí ó wà nínú ìṣòro?
Ọkàn mi kò ha bàjẹ́ fún tálákà bí?
26 Nígbà tí mo fojú ṣọ́nà fún àlàáfíà, ibi sì dé;
nígbà tí mo dúró de ìmọ́lẹ̀, òkùnkùn sì dé.
27 Ikùn mí n ru kò sì sinmi;
Ọjọ́ ìpọ́njú ti dé bá mi.
28 Èmí ń rìn kiri nínú ọ̀fọ̀, ṣùgbọ́n kì í ṣe nínú oòrùn;
èmi dìde dúró ní àwùjọ mo sì kígbe fún ìrànlọ́wọ́.
29 Èmi ti di arákùnrin ìkookò,
èmi di ẹgbẹ́ àwọn ògòǹgò.
30 Àwọ̀ mi di dúdú ní ara mi;
egungun mi sì jórun fún ooru.
31 Ohun èlò orin mi pẹ̀lú sì di ti ọ̀fọ̀,
àti ìpè orin mi sì di ohùn àwọn tí ń sọkún.
19 (A)Àwọn Júù kan sì ti Antioku àti Ikoniomu wá, nígbà tí wọ́n yí àwọn ènìyàn lọ́kàn padà, wọ́n sì sọ Paulu ní òkúta, wọ́n wọ́ ọ kúrò sí ẹ̀yin odi ìlú náà, wọn ṣe bí ó ti kú. 20 Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn dúró ti i yíká, ó dìde ó sì padà wọ inú ìlú náà lọ. Ní ọjọ́ kejì ó bá Barnaba lọ sí Dabe.
Ìpadàbọ̀ sí Antioku ti Siria
21 Nígbà tí wọ́n sì ti wàásù ìhìnrere fún ìlú náà, tí wọ́n sì ni ọmọ-ẹ̀yìn púpọ̀, wọn padà lọ sí Lysra, àti Ikoniomu, àti Antioku, 22 wọn sì ń mú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn lọ́kàn le, wọ́n sì ń gbà wọ́n níyànjú láti dúró nínú ìgbàgbọ́, àti pé nínú ìpọ́njú púpọ̀, ni àwa ó fi wọ ìjọba Ọlọ́run. 23 Nígbà tí wọ́n sì ti yan àwọn alàgbà fún olúkúlùkù ìjọ, tí wọn sì ti fi àwẹ̀ gbàdúrà, wọn fi wọ́n lé Olúwa lọ́wọ, ẹni tí wọn gbàgbọ́. 24 Nígbà tí wọn sí la Pisidia já, wọ́n wá sí pamfilia. 25 Nígbà tí wọn sì ti sọ ọ̀rọ̀ náà ni Perga, wọ́n sọ̀kalẹ̀ lọ sí Atalia:
26 Àti láti ibẹ̀ lọ wọ́n ṣíkọ̀ lọ sí Antioku ní ibi tí a gbé ti fi wọ́n lé oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run lọ́wọ́, fún iṣẹ́ tí wọ́n ṣe parí 27 Nígbà tí wọ́n sì dé, tí wọ́n sì pé ìjọ jọ, wọ́n ròhìn gbogbo ohun tí Ọlọ́run fi wọ́n ṣe, àti bí ó ti ṣí ìlẹ̀kùn ìgbàgbọ́ fún àwọn aláìkọlà. 28 Níbẹ̀ ni wọ́n ń gbé pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ni ọjọ́ púpọ̀.
Ikú Lasaru
11 (A)Ara ọkùnrin kan kò sì dá, Lasaru, ará Betani, tí í ṣe ìlú Maria àti Marta arábìnrin rẹ̀. 2 (B)Maria náà ni ẹni tí ó fi òróró ìkunra kun Olúwa, tí ó sì fi irun orí rẹ̀ nù ún, arákùnrin rẹ̀ ni Lasaru í ṣe, ara ẹni tí kò dá. 3 Nítorí náà, àwọn arábìnrin rẹ̀ ránṣẹ́ sí i, wí pé, “Olúwa, wò ó, ara ẹni tí ìwọ fẹ́ràn kò dá.”
4 (C)Nígbà tí Jesu sì gbọ́, ó wí pé, “Àìsàn yìí kì í ṣe sí ikú, ṣùgbọ́n fún Ògo Ọlọ́run, kí a lè yin Ọmọ Ọlọ́run lógo nípasẹ̀ rẹ̀.” 5 Jesu sì fẹ́ràn Marta, àti arábìnrin rẹ̀ àti Lasaru. 6 Nítorí náà, nígbà tí ó ti gbọ́ pé, ara rẹ̀ kò dá, ó gbé ọjọ́ méjì sí i níbìkan náà tí ó gbé wà. 7 Ǹjẹ́ lẹ́yìn èyí ni ó wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ jẹ́ kí a tún padà lọ sí Judea.”
8 (D)Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì wí fún un pé, “Rabbi, ní àìpẹ́ yìí ni àwọn Júù ń wá ọ̀nà láti sọ ọ́ ní òkúta; ìwọ sì tún padà lọ síbẹ̀?”
9 (E)Jesu dáhùn pé, “Wákàtí méjìlá kọ́ ni ó bẹ nínú ọ̀sán kan bí? Bí ẹnìkan bá rìn ní ọ̀sán, kì yóò kọsẹ̀, nítorí tí ó rí ìmọ́lẹ̀ ayé yìí. 10 Ṣùgbọ́n bí ẹnìkan bá rìn ní òru, yóò kọsẹ̀, nítorí tí kò sí ìmọ́lẹ̀ nínú rẹ̀.”
11 (F)Nǹkan wọ̀nyí ni ó sọ: lẹ́yìn èyí nì ó sì wí fún wọn pé, “Lasaru ọ̀rẹ́ wa sùn; ṣùgbọ́n èmi ń lọ kí èmi kí ó lè jí i dìde nínú orun rẹ̀.”
12 Nítorí náà àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wí fún un pé, “Olúwa, bí ó bá ṣe pé ó sùn, yóò sàn.” 13 Ṣùgbọ́n Jesu ń sọ ti ikú rẹ̀: ṣùgbọ́n wọ́n rò pé, ó ń sọ ti orun sísùn.
14 Nígbà náà ni Jesu wí fún wọn gbangba pé, “Lasaru ti kú. 15 Èmi sì yọ̀ nítorí yín, tí èmi kò sí níbẹ̀. Kí ẹ le gbàgbọ́; ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí a lọ sọ́dọ̀ rẹ̀.”
16 (G)Nítorí náà Tomasi, ẹni tí à ń pè ní Didimu, wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ẹgbẹ́ rẹ̀ pé, “Ẹ jẹ́ kí àwa náà lọ, kí a lè bá a kú pẹ̀lú.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.