Add parallel Print Page Options

A fi òróró kun Jesu lára ní Betani

(A)Nígbà tí Jesu wà ní Betani ní ilé ọkùnrin tí à ń pè ní Simoni adẹ́tẹ̀; Bí ó ti ń jẹun, obìnrin kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú alabasita òróró ìkunra iyebíye, ó sì dà á sí i lórí.

Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rí i, inú bí wọn. Wọ́n wí pé, “Irú ìfowóṣòfò wo ni èyí? Èéha ti ṣe, obìnrin yìí ìbá tà á ní owó púpọ̀, kí a sì fi owó náà fún àwọn aláìní.”

10 Jesu ti mọ èrò ọkàn wọn, ó wí pé, “Èéṣe ti ẹ̀yin fi ń dá obìnrin yìí lẹ́bi? Ó ṣe ohun tí ó dára fún mi 11 Ẹ̀yin yóò ní àwọn aláìní láàrín yín nígbà gbogbo, ṣùgbọ́n, ẹ̀yin kò le rí mi nígbà gbogbo. 12 Nípa dída òróró ìkunra yìí sí mi lára, òun ń ṣe èyí fún ìsìnkú mi ni. 13 Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, a ó sì máa ṣe ìrántí rẹ̀ nígbà gbogbo fún ìṣesí rẹ̀ yìí. Níbikíbi tí a bá ti wàásù ìhìnrere yìí ní gbogbo àgbáyé ni a ó ti sọ ìtàn ohun tí obìnrin yìí ṣe.”

Read full chapter

(A)Nígbà tí ó sì wà ní Betani ni ilé Simoni adẹ́tẹ̀ bí ó ti jókòó ti oúnjẹ, obìnrin kan wọlé, ti òun ti alabasita òróró ìkunra olówó iyebíye, ó ṣí ìgò náà, ó sì da òróró náà lé Jesu lórí.

Àwọn kan nínú àwọn tí ó jókòó ti tábìlì kún fún ìbànújẹ́. Wọ́n sì ń bi ara wọn pé, “Nítorí kí ni a ṣe fi òróró yìí ṣòfò? Òun ìbá ta òróró ìkunra yìí ju owó iṣẹ́ ọdún kan lọ, kí ó sì fi owó rẹ̀ ta àwọn tálákà lọ́rẹ.” Báyìí ni wọ́n ń fi ọ̀rọ̀ gún obìnrin náà lára.

Ṣùgbọ́n Jesu wí fún pé, “Ẹ fi í sílẹ̀, kí ni ẹ ń yọ ọ́ lẹ́nu fún ṣé nítorí tí ó ṣe ohun rere sí mi? (B)Nígbà gbogbo ni àwọn tálákà wà ní àárín yín, wọ́n sì ń fẹ́ ìrànlọ́wọ́ yín. Ẹ sì lè ṣe oore fún wọn nígbàkúgbà tí ẹ bá fẹ́. (C)Ó ti ṣe èyí tí ó lè ṣe, o ti fi òróró kùn mí ni ara ní ìmúrasílẹ̀ de ìgbà tí wọn yóò sin òkú mi. Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín, níbikíbi tí wọ́n bá ti wàásù mi, ní gbogbo ayé, wọn kò ní ṣe aláìsọ ohun tí obìnrin yìí ṣe pẹ̀lú ní ìrántí rẹ̀.”

Read full chapter

37 Sì kíyèsi i, obìnrin kan wà ní ìlú náà, ẹni tí i ṣe ẹlẹ́ṣẹ̀, nígbà tí ó mọ̀ pé Jesu jókòó, ó ń jẹun ní ilé Farisi, ó mú ṣágo kékeré alabasita òróró ìkunra wá, 38 Ó sì dúró tì í lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ̀ lẹ́yìn, ó ń sọkún, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí i fi omijé wẹ̀ ẹ́ ní ẹsẹ̀, ó sì ń fi irun orí rẹ nù ún nù, ó sì ń fi ẹnu kò ó ní ẹsẹ̀, ó sì ń fi òróró kùn wọ́n.

Read full chapter