Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Fún adarí orin. Tí ohùn “Lílì ti Májẹ̀mú.” Ti Safu. Saamu.
80 Gbọ́ tiwa, ìwọ olùṣọ́-àgùntàn Israẹli;
ìwọ tí ó darí Josẹfu bí ọ̀wọ́ ẹran;
ìwọ tí o jókòó lórí ìtẹ́ láàrín Kérúbù, tàn jáde
2 Níwájú Efraimu, Benjamini àti Manase.
Ru agbára rẹ̀ sókè;
wá fún ìgbàlà wa.
3 Mú wa padà bọ̀ sípò, ìwọ Ọlọ́run;
jẹ́ kí ojú rẹ kí ó tan ìmọ́lẹ̀ sí wa,
kí a bá à lè gbà wá là.
4 Olúwa Ọlọ́run alágbára,
ìbínú rẹ̀ yóò ti pẹ́ tó
sí àdúrà àwọn ènìyàn rẹ?
5 Ìwọ ti fi oúnjẹ bọ́ wọn
ìwọ ti mú wọn wa ẹkún mu ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́
6 Ìwọ sọ wá di ẹlẹ́yà fún àwọn aládùúgbò wa,
àwọn ọ̀tá wa sì ń yọ̀ wá.
7 Tún wa yípadà, ìwọ, Ọlọ́run alágbára;
jẹ́ kí ojú rẹ tàn sí wa,
kí a ba à lè gbà wá là.
17 Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ kí ó wà lára ọkùnrin tí ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ,
ọmọ ènìyàn tí ìwọ tí gbé kalẹ̀ fún ara rẹ.
18 Nígbà náà àwa kí yóò yípadà kúrò lọ́dọ̀ rẹ;
mú wa yè, àwa o sì máa pe orúkọ rẹ.
19 Tún wa yípadà, Olúwa Ọlọ́run alágbára;
kí ojú rẹ̀ kí ó tan ìmọ́lẹ̀ sí wa,
kí á ba à lè gbà wá là.
Èrò ènìyàn àti ti Ọlọ́run
2 Ègbé ni fún àwọn tí ń gbèrò àìṣedéédéé
tí wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ ibi lórí ibùsùn wọn!
Nígbà tí ojúmọ́ bá mọ́, wọn yóò gbé e jáde
nítorí ó wà ní agbára wọn láti ṣe é.
2 Wọ́n sì ń ṣe ojúkòkòrò oko, wọ́n sì fi agbára wọn gbà wọ́n,
àti àwọn ilé, wọ́n sì gbà wọ́n.
Wọ́n sì ni ènìyàn àti ilẹ̀ rẹ̀ lára
àní ènìyàn àti ohun ìní rẹ̀.
3 Nítorí náà, Olúwa wí pé:
“Èmi ń gbèrò ibi sí àwọn ìdílé wọ̀nyí,
nínú èyí tí wọn kì yóò le è gba ara wọn là.
Ìwọ kì yóò sì lè máa rìn ní ìgbéraga mọ́,
nítorí yóò jẹ́ àkókò ibi.
4 Ní ọjọ́ náà ni ẹnìkan yóò pa òwe kan sí yín;
wọn yóò sì pohùnréré ẹkún kíkorò pé:
‘Ní kíkó a ti kó wọn tán;
Olúwa ti pín ohun ìní àwọn ènìyàn mi;
Ó ti mú un kúrò lọ́dọ̀ mi!
Ó fi oko wa lé àwọn ọlọ̀tẹ̀ lọ́wọ́.’ ”
5 Nítorí náà, ìwọ kò ní ní ẹnìkankan tí yóò ta okùn nínú ìjọ Olúwa,
tí yóò pín ilẹ̀ nípa ìbò.
Àwọn wòlíì èké
6 “Ẹ má ṣe sọtẹ́lẹ̀,” ni àwọn Wòlíì wọn wí.
“Ẹ má ṣe sọtẹ́lẹ̀ nípa nǹkan wọ̀nyí;
kí ìtìjú má ṣe le bá wa”
7 Ṣé kí á sọ ọ́, ìwọ ilé Jakọbu:
“Ǹjẹ́ ẹ̀mí Olúwa ha ń bínú bí?
Ǹjẹ́ iṣẹ́ rẹ ha nìwọ̀nyí?”
“Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ mi kò ha ń ṣe rere
fún ẹni tí ń rìn déédé bí?
8 Láìpẹ́ àwọn ènìyàn mi dìde
bí ọ̀tá sí mi.
Ìwọ bọ́ aṣọ ọlọ́rọ̀
kúrò lára àwọn tí ń kọjá lọ ní àìléwu,
bí àwọn ẹni tí ó padà bọ̀ láti ojú ogun.
9 Ẹ̀yin sì lé obìnrin àwọn ènìyàn mi
kúrò nínú ilé ayọ̀ wọn,
ẹ̀yin sì ti gba ògo mi,
kúrò lọ́wọ́ àwọn ọmọ wọn láéláé.
10 Ẹ dìde, kí ẹ sì máa lọ!
Nítorí èyí kì í ṣe ibi ìsinmi yín,
nítorí tí a ti sọ ọ́ di àìmọ́
yóò pa yín run,
àní ìparun kíkorò.
11 Tí òpùrọ́ àti ẹlẹ́tàn bá wà tí wọ́n sì wí pé,
‘Èmi yóò sọtẹ́lẹ̀ fún ọ nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ wáìnì àti ọtí líle,’
òun ni yóò tilẹ̀ ṣe wòlíì àwọn ènìyàn wọ̀nyí!
Ìlérí ìgbàlà
12 “Èmi yóò kó gbogbo yín jọ, ìwọ Jakọbu;
Èmi yóò gbá ìyókù Israẹli jọ.
Èmi yóò kó wọn jọ pọ̀ gẹ́gẹ́ bí àgùntàn nínú agbo ẹran,
gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́ ẹran nínú agbo wọn,
ibẹ̀ yóò sì pariwo nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn.
13 Ẹni tí ó ń fọ ọ̀nà yóò lọ sókè níwájú wọn;
wọn yóò fọ láti ẹnu ibodè, wọn yóò sì jáde lọ.
Àwọn ọba wọn yóò sì kọjá lọ níwájú wọn,
Olúwa ni yóò sì ṣe olórí wọn.”
15 (A)“Nítorí náà, nígbà tí ẹ̀yin bá rí ìríra ìsọdahoro, tí a ti ẹnu wòlíì Daniẹli sọ, tí ó bá dúró ní ibi mímọ́, (ẹni tí ó bá kà á, kí òye kí ó yé e). 16 Nítorí náà, jẹ́ kí àwọn tí ó wà ní Judea sálọ sí àwọn orí òkè. 17 Kí ẹni tí ó wà lórí ilé rẹ̀ má ṣe sọ̀kalẹ̀ wá mú ohunkóhun jáde nínú ilé rẹ̀. 18 Kí àwọn tí ó sì wà lóko má ṣe darí wá sí ilé láti mú àwọn aṣọ wọn. 19 Ṣùgbọ́n àánú ṣe mí fún àwọn obìnrin ti ó lóyún, àti fún àwọn tí ó ń fún ọmọ loyan ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì! 20 Ẹ sì máa gbàdúrà kí sísá yín má ṣe jẹ́ ìgbà òtútù, tàbí ọjọ́ ìsinmi. 21 Nítorí ìpọ́njú ńlá yóò wà, irú èyí tí kò tí ì ṣẹlẹ̀ láti ìgbà ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ ayé wá títí di ìsinsin yìí irú rẹ̀ kì yóò sì ṣí.
22 “Lóòótọ́, àfi bí a ké ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì kúrú, gbogbo ẹ̀dá alààyè yóò ṣègbé. Ṣùgbọ́n nítorí ti àwọn àyànfẹ́ ni a ó fi ké ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì kúrú. 23 Nígbà náà, bí ẹnikẹ́ni bá sọ fún yín pé, ‘Wo Kristi náà,’ tàbí pé ó ti farahàn níhìn-ín tàbí lọ́hùn ún, ẹ má ṣe gbà á gbọ́. 24 Nítorí àwọn èké Kristi àti àwọn èké wòlíì yóò dìde. Wọn yóò sì ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ààmì àti ìyanu. Bí ó bá lè ṣe é ṣe wọn yóò tan àwọn àyànfẹ́ Ọlọ́run pàápàá jẹ. 25 Wò ó, mo ti kìlọ̀ fún yín tẹ́lẹ̀.
26 (B)“Nítorí náà, bí ẹnìkan bá sọ fún yín pé, ‘Olùgbàlà ti dé,’ àti pé, ‘Ó wà ní aginjù,’ ẹ má ṣe wàhálà láti lọ wò ó, tàbí tí wọ́n bá ní ó ń fi ara pamọ́ sí iyàrá, ẹ má ṣe gbà wọn gbọ́. 27 Nítorí bí mọ̀nàmọ́ná ti ń tàn láti ìlà-oòrùn títí dé ìwọ̀-oòrùn, bẹ́ẹ̀ ni wíwá Ọmọ Ènìyàn yóò jẹ́. 28 Nítorí ibikíbi tí òkú bá gbé wà, ibẹ̀ ni àwọn ẹyẹ igún ń kójọpọ̀ sí.
29 (C)“Lójúkan náà, lẹ́yìn ìpọ́njú ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì,
“ ‘ni oòrùn yóò ṣókùnkùn,
òṣùpá kì yóò sì fi ìmọ́lẹ̀ rẹ hàn;
àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run yóò já sílẹ̀,
agbára ojú ọ̀run ni a ó mì tìtì.’
30 (D)“Nígbà náà ni ààmì Ọmọ Ènìyàn yóò sì fi ara hàn ní ọ̀run, nígbà náà ni gbogbo ẹ̀yà ayé yóò káàánú, wọn yóò sì rí Ọmọ Ènìyàn tí yóò máa ti ojú ọ̀run bọ̀ ti òun ti ògo àti agbára ńlá. 31 Yóò sì rán àwọn angẹli rẹ̀ jáde pẹ̀lú ohùn ìpè ńlá, wọn yóò sì kó gbogbo àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ láti orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé àti ọ̀run jọ.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.