Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Isaiah 64:1-9

64 Ìwọ ìbá fa ọ̀run ya kí o sì sọ̀kalẹ̀ wá,
    tí àwọn òkè ńlá yóò fi wárìrì níwájú rẹ!
Gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí iná mú ẹ̀ka igi jó
    tí ó sì mú kí omi ó hó,
sọ̀kalẹ̀ wá kí orúkọ rẹ le di mí mọ̀ fún àwọn ọ̀tá rẹ
    kí o sì jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè kí ó wárìrì níwájú rẹ!
Nítorí nígbà tí o bá ṣe àwọn ohun ẹ̀rù tí àwa kò nírètí,
    o sọ̀kalẹ̀ wá, àwọn òkè ńlá sì wárìrì níwájú rẹ̀.
(A)Láti ìgbà àtijọ́ kò sí ẹni tí ó gbọ́ rí
    kò sí etí kan tí ó gbọ́ ọ,
kò sí ojú tí ó tí ì rí Ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn rẹ,
    tí ó máa ń ṣe nǹkan lórúkọ àwọn tí ó dúró dè é.
Ìwọ a máa wá fún ìrànlọ́wọ́ àwọn tí wọn
    ń fi ayọ̀ ṣe ohun tó tọ́,
tí ó rántí ọ̀nà rẹ.
    Ṣùgbọ́n nígbà tí a bẹ̀rẹ̀ sí dẹ́ṣẹ̀ sí wọn,
inú bí ọ.
    Báwo ni a ó ṣe gbà wá là?
Gbogbo wa ti dàbí ẹnìkan tí ó jẹ́ aláìmọ́,
    gbogbo òdodo wa sì dàbí èkísà ẹlẹ́gbin;
gbogbo wa kákò bí ewé,
    àti bí afẹ́fẹ́, ẹ̀ṣẹ̀ wa ti gbá wa lọ kúrò.
Ẹnikẹ́ni kò pe orúkọ rẹ
    tàbí kí ó gbìyànjú láti dì ẹ́ mú;
nítorí ìwọ ti fi ojú rẹ pamọ́ fún wa
    ó sì jẹ́ kí àwa ṣòfò dànù nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.

Síbẹ̀síbẹ̀, Olúwa, ìwọ ni Baba wa.
    Àwa ni amọ̀, ìwọ ni amọ̀kòkò;
    gbogbo wa jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.
Má ṣe bínú kọjá ààlà, ìwọ Olúwa:
    Má ṣe rántí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa títí láé.
Jọ̀wọ́, bojú wò wá, ni a gbàdúrà,
    nítorí ènìyàn rẹ ni gbogbo wa.

Saamu 80:1-7

Fún adarí orin. Tí ohùn “Lílì ti Májẹ̀mú.” Ti Safu. Saamu.

80 Gbọ́ tiwa, ìwọ olùṣọ́-àgùntàn Israẹli;
    ìwọ tí ó darí Josẹfu bí ọ̀wọ́ ẹran;
    ìwọ tí o jókòó lórí ìtẹ́ láàrín Kérúbù, tàn jáde
Níwájú Efraimu, Benjamini àti Manase.
    Ru agbára rẹ̀ sókè;
wá fún ìgbàlà wa.

Mú wa padà bọ̀ sípò, ìwọ Ọlọ́run;
    jẹ́ kí ojú rẹ kí ó tan ìmọ́lẹ̀ sí wa,
kí a bá à lè gbà wá là.

Olúwa Ọlọ́run alágbára,
    ìbínú rẹ̀ yóò ti pẹ́ tó
    sí àdúrà àwọn ènìyàn rẹ?
Ìwọ ti fi oúnjẹ bọ́ wọn
    ìwọ ti mú wọn wa ẹkún mu ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́
Ìwọ sọ wá di ẹlẹ́yà fún àwọn aládùúgbò wa,
    àwọn ọ̀tá wa sì ń yọ̀ wá.

Tún wa yípadà, ìwọ, Ọlọ́run alágbára;
    jẹ́ kí ojú rẹ tàn sí wa,
    kí a ba à lè gbà wá là.

Saamu 80:17-19

17 Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ kí ó wà lára ọkùnrin tí ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ,
    ọmọ ènìyàn tí ìwọ tí gbé kalẹ̀ fún ara rẹ.
18 Nígbà náà àwa kí yóò yípadà kúrò lọ́dọ̀ rẹ;
    mú wa yè, àwa o sì máa pe orúkọ rẹ.

19 Tún wa yípadà, Olúwa Ọlọ́run alágbára;
    kí ojú rẹ̀ kí ó tan ìmọ́lẹ̀ sí wa,
    kí á ba à lè gbà wá là.

1 Kọrinti 1:3-9

(A)Oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà fún yín láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa àti Olúwa wa tí í ṣe Jesu Kristi.

Ìdúpẹ́

(B)Nígbà gbogbo ni mo ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ tó fi fún un yín nínú Kristi Jesu. Nítorí nínú rẹ̀ ni a ti sọ yín di ọlọ́rọ̀ nínú ọ̀rọ̀ sísọ yín gbogbo àti nínú ìmọ̀ yín gbogbo. Nítorí ẹ̀rí wa nínú Kristi ni a ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ nínú yín. Nítorí náà ẹ̀yin kò ṣe aláìní nínú èyíkéyìí ẹ̀bùn ẹ̀mí, bí ẹ̀yin ṣe ń retí ìfarahàn Olúwa wa Jesu Kristi. (C)Òun yóò sì mú yín dúró títí dé òpin, kí ẹ̀yin kí ó lè jẹ́ aláìlábùkù ní ọjọ́ Olúwa wa Jesu Kristi. (D)Ọlọ́run, nípasẹ̀ ẹni ti a pè yín sínú ìdàpọ̀ pẹ̀lú Ọmọ rẹ̀ Jesu Kristi Olúwa wa, jẹ́ Olóòtítọ́.

Marku 13:24-37

24 “Ṣùgbọ́n ni ọjọ́ wọ̀nyí lẹ́yìn ìpọ́njú tí mo sọ yìí,

“ ‘oòrùn yóò ṣókùnkùn,
    òṣùpá kò ní tan ìmọ́lẹ̀ rẹ̀.
25 Àwọn ìràwọ̀ pẹ̀lú yóò já lulẹ̀ láti ojú ọ̀run,
    àti agbára tí ń bẹ ní ọ̀run ni a ó sì mì tìtì.’

26 (A)“Nígbà náà ni gbogbo ayé yóò sì rí i tí Èmi Ọmọ Ènìyàn yóò máa bọ̀ wá láti inú àwọsánmọ̀ pẹ̀lú agbára àti ògo ńlá. 27 Nígbà náà ni yóò sì rán àwọn angẹli rẹ̀ láti kó àwọn àyànfẹ́ ní gbogbo ayé jọ láti orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé láti ìkangun ayé títí dé ìkangun ọ̀run.

28 “Nísinsin yìí, ẹ kọ́ òwe lára igi ọ̀pọ̀tọ́, nígbà tí ẹ̀ka rẹ bá ń yọ tuntun, tí ó bá sì ń rú ewé, èyí fihàn pé àkókò ẹ̀rùn ti dé. 29 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, nígbà tí ẹ ba ri àwọn ohun wọ̀nyí ti n ṣẹlẹ̀, kí ẹ mọ̀ pé ó súnmọ́ etílé tán, bi ìgbà tí ó wà lẹ́yìn ìlẹ̀kùn. 30 (B)Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín, ìran yìí kì yóò rékọjá títí a ó fi mú gbogbo nǹkan wọ̀nyí ṣẹ 31 (C)Ọ̀run àti ayé yóò kọjá lọ, ṣùgbọ́n àwọn ọ̀rọ̀ mi dúró dájú títí ayé àìnípẹ̀kun.

Ọjọ́ àti wákàtí tí a kò mọ̀

32 (D)“Ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó mọ ọjọ́ tàbí wákàtí tí nǹkan wọ̀nyí yóò ṣẹlẹ̀. Àwọn angẹli ọ̀run pàápàá kò mọ̀. Àní, èmi pẹ̀lú kò mọ̀ ọ́n, bí kò ṣe baba nìkan. 33 (E)Ẹ máa ṣọ́ra, ẹ dúró wámú, kí ẹ sì máa gbàdúrà: nítorí ẹ̀yin kò mọ ìgbà tí àkókò ná yóò dé. 34 (F)Ó dà bí ọkùnrin kan tí ó lọ sí ìrìnàjò tí ó jìnnà rere: Ẹni tí ó fi ilé rẹ̀ sílẹ̀, tí ó sì fi àṣẹ fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀, àti iṣẹ́ tí ẹnìkọ̀ọ̀kan yóò ṣe, ó sì fi àṣẹ fún ẹni tó dúró lẹ́nu-ọ̀nà láti máa ṣọ́nà.

35 (G)“Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ẹ̀yin pẹ̀lú ní láti máa fi ìrètí ṣọ́nà, nítorí pé ẹ kò mọ àkókò tí baálé ilé yóò dé. Bóyá ní ìrọ̀lẹ́ ni o, tàbí ní ọ̀gànjọ́ òru, tàbí nígbà tí àkùkọ máa ń kọ, tàbí ní òwúrọ̀. 36 Àti wí pé nígbà tí ó bá dé lójijì, kó má ṣe bá yín lójú oorun. 37 Ohun tí mo wí fún un yín, mo wí fun gbogbo ènìyàn: ‘Ẹ máa ṣọ́nà!’ ”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.