Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Saamu ti Asafu.
79 Ọlọ́run, àwọn orílẹ̀-èdè ti wá ilẹ̀ ìní rẹ;
wọ́n ti ba tẹmpili mímọ́ rẹ jẹ́,
wọn di Jerusalẹmu kù sí òkìtì àlàpà.
2 Wọn ti fi ara òkú àwọn ìránṣẹ́ rẹ
fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run ní oúnjẹ,
ẹran-ara àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ fún ẹranko ilẹ̀.
3 Wọ́n tu ẹ̀jẹ̀ jáde gẹ́gẹ́ bí omi
yí Jerusalẹmu ká,
kò sì ṣí àwọn tí yóò sìn wọ́n.
4 Àwa di ohun ẹ̀gàn sí àwọn tí ó yí wa ká,
àbùkù àti ìfiṣe ẹlẹ́yà sí àwọn tí ó yí wa ká.
5 Nígbà wo, Olúwa? Ní ìwọ ó máa bínú títí láé?
Yóò ti pẹ́ tó ti owú rẹ yóò ha jò bí iná?
6 Tú ìbínú rẹ jáde sí orílẹ̀-èdè
tí kò ní ìmọ̀ rẹ,
lórí àwọn ìjọba
tí kò pe orúkọ rẹ;
7 Nítorí wọ́n ti run Jakọbu
wọ́n sì sọ ibùgbé rẹ di ahoro.
8 Má ṣe ka ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba wa sí wa lọ́rùn
jẹ́ kí àánú rẹ wá kánkán láti bá wa,
nítorí tí a rẹ̀ wá sílẹ̀ gidigidi.
9 Ràn wá lọ́wọ́, Ọlọ́run Olùgbàlà wa,
fún ògo orúkọ rẹ;
gbà wá kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì
nítorí orúkọ rẹ.
10 Àwọn orílẹ̀-èdè yóò máa wí pé,
“Níbo ni Ọlọ́run wọn wà?”
Ní ojú wa, kí a mọ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè
kí ó sì gbẹ̀san àwọn ẹ̀jẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ tí a tú jáde.
11 Jẹ́ kí ìmí ẹ̀dùn oǹdè náà wá síwájú rẹ,
gẹ́gẹ́ bí títóbi agbára rẹ
ìwọ ṣe ìtọ́jú àwọn ti a dá lẹ́bi ikú.
12 San án padà sí àyà àwọn aládùúgbò wa nígbà méje
nípa ẹ̀gàn tí wọn ti gàn ọ́ Olúwa.
13 Nígbà náà àwa ènìyàn rẹ,
àti àgùntàn pápá rẹ,
yóò fi ọpẹ́ fún ọ títí láé;
láti ìran dé ìran
ni àwa ó fi ìyìn rẹ hàn.
Òkè Olúwa
4 (A)Ní ọjọ́ ìkẹyìn
a ó fi òkè ilé Olúwa lélẹ̀ lórí àwọn òkè ńlá,
a ó sì gbé e ga ju àwọn òkè kéékèèkéé lọ,
àwọn ènìyàn yóò sì máa wọ̀ sínú rẹ̀.
2 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè yóò wá,
wọn yóò sì wí pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á gòkè ńlá Olúwa,
àti sí ilé Ọlọ́run Jakọbu
Òun yóò sì kọ́ wa ní ọ̀nà rẹ̀,
kí àwa kí ó lè rìn ní ọ̀nà rẹ̀.”
Òfin yóò jáde láti Sioni wá,
àti ọ̀rọ̀ Olúwa láti Jerusalẹmu.
3 Òun yóò sì ṣe ìdájọ́ láàrín ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn,
yóò sì parí aáwọ̀ fún orílẹ̀-èdè alágbára jíjìn réré.
Wọn yóò sì fi idà wọn rọ ohun èlò ìtulẹ̀
àti ọ̀kọ̀ wọn di dòjé
orílẹ̀-èdè kì yóò gbé idà sókè sí orílẹ̀-èdè mọ́,
bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò kọ́ ogun jíjà mọ́.
4 (B)Ṣùgbọ́n olúkúlùkù yóò jókòó lábẹ́ àjàrà rẹ̀
àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀,
ẹnìkan kì yóò sì dẹ́rùbà wọ́n,
nítorí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti sọ̀rọ̀.
5 Gbogbo àwọn ènìyàn ń rìn,
olúkúlùkù ni orúkọ ọlọ́run tirẹ̀,
ṣùgbọ́n àwa yóò máa rìn ní orúkọ Olúwa.
Ọlọ́run wa láé àti láéláé.
Angẹli méje pẹ̀lú ìyọnu méje
15 (A)Mo sì rí ààmì mìíràn ní ọ̀run tí ó tóbi tí ó sì ya ni lẹ́nu, àwọn angẹli méje tí ó ni àwọn ìyọnu méje ìkẹyìn, nítorí nínú wọn ni ìbínú Ọlọ́run dé òpin. 2 Mo sì rí bí ẹni pé, Òkun dígí tí o dàpọ̀ pẹ̀lú iná: àwọn tí ó sì dúró lórí Òkun dígí yìí jẹ́ àwọn ti wọ́n ṣẹ́gun ẹranko náà, àti àwòrán rẹ̀, àti ààmì rẹ̀ àti nọ́mbà orúkọ rẹ̀, wọn ní ohun èlò orin Ọlọ́run. 3 (B)Wọ́n sì ń kọ orin ti Mose, ìránṣẹ́ Ọlọ́run, àti orin ti Ọ̀dọ́-Àgùntàn, wí pé:
“Títóbi àti ìyanu ni àwọn iṣẹ́ rẹ,
Olúwa Ọlọ́run Olódùmarè;
òdodo àti òtítọ́ ni ọ̀nà rẹ̀,
ìwọ ọba àwọn orílẹ̀-èdè.
4 (C)Ta ni kì yóò bẹ̀rù, Olúwa,
tí kì yóò sì fi ògo fún orúkọ rẹ̀?
Nítorí ìwọ nìkan ṣoṣo ni mímọ́.
Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ni yóò sì wá,
ti yóò sì foríbalẹ̀ níwájú rẹ,
nítorí a ti fi ìdájọ́ rẹ hàn.”
5 (D)Lẹ́yìn náà mo sì wo, sì kíyèsi i, a ṣí tẹmpili àgọ́ ẹ̀rí ní ọ̀run sílẹ̀; 6 àwọn angẹli méje náà sì ti inú tẹmpili jáde wá, wọ́n ni ìyọnu méje náà, a wọ̀ wọ́n ní aṣọ ọ̀gbọ̀ funfun ti ń dán, a sì fi àmùrè wúrà dìwọ́n ni oókan àyà. 7 Àti ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà fi ìgò wúrà méje fún àwọn angẹli méje náà, tí ó kún fún ìbínú Ọlọ́run, ẹni tí ń bẹ láààyè láé àti láéláé. 8 Tẹmpili náà sì kún fún èéfín láti inú ògo Ọlọ́run àti agbára rẹ̀ wá; ẹnikẹ́ni kò sì lè wọ inú tẹmpili náà lọ títí a fi mú ìyọnu méjèèje àwọn angẹli méje náà ṣẹ.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.