Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Saamu. Fún ọpẹ́
100 Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Olúwa, gbogbo ayé
2 Ẹ fi ayọ̀ sin Olúwa:
Ẹ wá síwájú rẹ̀ pẹ̀lú orin dídùn
3 Olúwa Ọlọ́run ni ó dá wa,
kí ẹ̀yin kí ó mọ̀ pé
tirẹ̀ ni àwa; Àwa ní ènìyàn rẹ̀
àti àgùntàn pápá rẹ̀.
4 Ẹ lọ sí ẹnu-ọ̀nà rẹ̀ pẹ̀lú ọpẹ́
àti sí àgbàlá rẹ̀ pẹ̀lú ìyìn;
ẹ fi ọpẹ́ àti ìyìn fún orúkọ rẹ̀.
5 Nítorí tí Olúwa pọ̀ ní oore
ìfẹ́ rẹ̀ sì wà títí láé;
àti òtítọ́ rẹ̀ láti ìran de ìran.
25 “ ‘Èmi yóò dá májẹ̀mú àlàáfíà pẹ̀lú wọn, èmi yóò sì gba ilẹ̀ náà kúrò lọ́wọ́ ẹranko búburú, kí wọn kí o lè gbé ní aṣálẹ̀, kí àgùntàn sì gbé ní inú igbó ní àìléwu. 26 Èmi yóò bùkún wọn àti ibi agbègbè ti ó yí òkè mi ká. Èmi yóò rán ọ̀wààrà òjò ni àkókò; òjò ìbùkún yóò sì wà. 27 Àwọn igi igbó yóò mú èso wọn jáde, ilẹ̀ yóò sì mu irúgbìn jáde; A yóò sì dá ààbò bo àwọn ènìyàn ní ilẹ̀ náà. Wọn yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa, nígbà tí mo bá já àwọn ohun tí ó ṣe okùnfà àjàgà, tí mo sì gbà wọ́n kúrò lọ́wọ́ àwọn tí ó fi wọ́n ṣe ẹrú. 28 Àwọn orílẹ̀-èdè kì yóò lè kó wọn ní ẹrú mọ́, àwọn ẹranko búburú kì yóò lè pa wọn mọ́. Wọn yóò gbé ni àìléwu, kò sì ṣí ẹni kankan tí yóò le dẹ́rùbà wọ́n. 29 Èmi yóò pèsè ilẹ̀ ti o ní oríyìn fún èso rẹ̀ fún wọn, wọn kì yóò sì jìyà nípasẹ̀ ìyàn mọ́ ni ilẹ̀ náà tàbí ru ẹ̀gàn àwọn orílẹ̀-èdè. 30 Nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé, èmi ni Olúwa Ọlọ́run wọn, èmi wà pẹ̀lú wọn àti pé, àwọn ilé Israẹli jẹ́ ènìyàn mi, ni Olúwa Olódùmarè wí. 31 Ìwọ àgùntàn mi, àgùntàn pápá mi; ni ènìyàn, èmi sì ni Ọlọ́run rẹ; ni Olúwa Olódùmarè wí.’ ”
Ìyá Jesu àti àwọn arákùnrin rẹ̀
46 (A)(B) Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún àwọn ènìyàn, wò ó, ìyá rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ dúró lóde, wọ́n fẹ́ bá a sọ̀rọ̀. 47 Nígbà náà ni ẹnìkan wí fún un pé, “Ìyá rẹ àti àwọn arákùnrin rẹ ń dúró dè ọ́ lóde wọ́n ń fẹ́ bá ọ sọ̀rọ̀.”
48 Ó sì fún ni èsì pé, “Ta ni ìyá mi? Ta ni àwọn arákùnrin mi?” 49 Ó nawọ́ sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó wí pé, “Wò ó, ìyá mi àti àwọn arákùnrin mi ni wọ̀nyí.” 50 (C)Nítorí náà, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe ìfẹ́ Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run, ni arákùnrin mi àti arábìnrin mi àti ìyá mi.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.