Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 100

Saamu. Fún ọpẹ́

100 Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Olúwa, gbogbo ayé
Ẹ fi ayọ̀ sin Olúwa:
    Ẹ wá síwájú rẹ̀ pẹ̀lú orin dídùn
Olúwa Ọlọ́run ni ó dá wa,
    kí ẹ̀yin kí ó mọ̀ pé
tirẹ̀ ni àwa; Àwa ní ènìyàn rẹ̀
    àti àgùntàn pápá rẹ̀.

Ẹ lọ sí ẹnu-ọ̀nà rẹ̀ pẹ̀lú ọpẹ́
    àti sí àgbàlá rẹ̀ pẹ̀lú ìyìn;
    ẹ fi ọpẹ́ àti ìyìn fún orúkọ rẹ̀.
Nítorí tí Olúwa pọ̀ ní oore
    ìfẹ́ rẹ̀ sì wà títí láé;
    àti òtítọ́ rẹ̀ láti ìran de ìran.

Gẹnẹsisi 48:15-22

15 Nígbà náà ni ó súre fún Josẹfu wí pé,

“Ǹjẹ́ kí Ọlọ́run, ẹni tí baba mi
    Abrahamu àti Isaaki rìn níwájú rẹ̀,
Ọlọ́run tí ó ti jẹ́ olùtọ́jú àti aláàbò
    mi ní gbogbo ọjọ́ ayé mi títí di òní,
16 Angẹli tí ó dá mi ní ìdè kúrò lọ́wọ́ gbogbo ewu,
    kí ó súre fún àwọn ọmọkùnrin wọ̀nyí.
Kí a máa fi orúkọ mi pè wọ́n àti orúkọ àwọn baba mi
    Abrahamu àti Isaaki,
kí wọn kí ó sì pọ̀ sí i lọ́pọ̀lọpọ̀
    lórí ilẹ̀ ayé.”

17 Nígbà tí Josẹfu rí i pé baba òun gbé ọwọ́ ọ̀tún lé Efraimu lórí, inú rẹ̀ bàjẹ́, ó sì gbá ọwọ́ baba rẹ̀ mú láti gbé ọwọ́ rẹ̀ kúrò lórí Efraimu lọ sí orí Manase. 18 Josẹfu wí fun pé, “Rárá, baba mi, èyí ni àkọ́bí, orí rẹ̀ ni kí ìwọ kí o gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ lé.”

19 Ṣùgbọ́n baba rẹ̀ kò gbà, ó wí pé, “Mo mọ̀, ọmọ mi, mo mọ̀. Òun náà yóò di orílẹ̀-èdè, òun náà yóò sì di ńlá. Ṣùgbọ́n àbúrò rẹ̀ yóò di ẹni ńlá jù ú lọ, irú-ọmọ rẹ yóò sì di ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè.” 20 (A)Ó súre fún wọn lọ́jọ́ náà pé,

“Ní orúkọ yín ni Israẹli yóò máa súre yìí pé:
    ‘Kí Ọlọ́run ṣe ọ́ bí i ti Efraimu àti Manase.’ ”

Ó sì gbé Efraimu gẹ́gẹ́ bí ẹ̀gbọ́n sí Manase.

21 Nígbà náà ni Israẹli wí fún Josẹfu pé, “Ọjọ́ ikú mi súnmọ́ etílé, ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò wà pẹ̀lú yín, yóò sì mú un yín padà sí ilẹ̀ àwọn baba yín. 22 Pẹ̀lúpẹ̀lú èmi yóò fún ọ ní ìpín kan ju ti àwọn arákùnrin rẹ lọ. Ilẹ̀ tí mo fi idà àti ọ̀kọ̀ mi gbà lọ́wọ́ àwọn ará Amori.”

Ìfihàn 14:1-11

Ọ̀dọ́-àgùntàn àti ọ̀kẹ́ méje ó-lé-ẹgbàajì (144,000)

14 (A)Mo sì wo, si kíyèsi i, Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà dúró lórí Òkè Sioni, àti pẹ̀lú rẹ̀ ọ̀kẹ́ méje ó-lé-ẹgbàajì (144,000) ènìyàn; wọ́n ní orúkọ rẹ̀, àti orúkọ baba rẹ̀ tí a kọ sí iwájú orí wọn. Mo sì gbọ́ ohùn kan láti ọ̀run wá, bí ariwo omi púpọ̀, àti bí sísán àrá ńlá: mo sì gbọ́ àwọn aludùùrù tí wọn ń lu dùùrù. Wọ́n sì ń kọ bí ẹni pé orin tuntun níwájú ìtẹ́ náà, àti níwájú àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin nnì àti àwọn àgbà náà: kò sì ṣí ẹni tí o lè kọ orin náà, bí kò ṣe àwọn ọ̀kẹ́ méje ó-lé-ẹgbàajì ènìyàn, tí a tí rà padà láti inú ayé wá. Àwọn wọ̀nyí ni a kò fi obìnrin sọ di èérí: nítorí tí wọ́n jẹ́ wúńdíá. Àwọn wọ̀nyí ni o ń tọ Ọ̀dọ́-àgùntàn náà lẹ́yìn níbikíbi tí o bá ń lọ. Àwọn wọ̀nyí ni a rà padà láti inú àwọn ènìyàn wá, wọ́n jẹ́ àkọ́so fún Ọlọ́run àti fún Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà. A kò sì rí èké lẹ́nu wọn, wọn jẹ́ aláìlábùkù.

Àwọn angẹli mẹ́ta

Mo sì rí angẹli mìíràn ń fò ní àárín méjì ọ̀run, pẹ̀lú ìhìnrere àìnípẹ̀kun láti wàásù fún àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé, àti fún gbogbo orílẹ̀, àti ẹ̀yà, àti èdè, àti ènìyàn. Ó ń wí ni ohùn rara pé, “Ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run, kí ẹ sì fi ògo fún un, nítorí tí wákàtí ìdájọ́ rẹ̀ dé: ẹ sì foríbalẹ̀ fún ẹni tí o dá ọ̀run, àti ayé, àti Òkun, àti àwọn orísun omi!”

(B)Angẹli mìíràn sì tẹ̀lé e, ó ń wí pé, “o ṣubú, Babeli ńlá ṣubú, èyí ti o tí ń mú gbogbo orílẹ̀-èdè mu nínú ọtí wáìnì àìmọ́ àgbèrè rẹ̀!”

Angẹli mìíràn, ẹ̀kẹta, sì tẹ̀lé wọn, ó ń wí ni ohùn rara pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá ń foríbalẹ̀ fún ẹranko náà àti àwòrán rẹ̀, tí ó sì gba ààmì sí iwájú orí rẹ̀ tàbí sí ọwọ́ rẹ̀. 10 (C)Òun pẹ̀lú yóò mú nínú ọtí wáìnì ìbínú Ọlọ́run, tí a dà ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ sínú ago ìrunú rẹ̀; a ó sì fi iná sulfuru dá a lóró níwájú àwọn angẹli mímọ́, àti níwájú Ọ̀dọ́-àgùntàn: 11 (D)Èéfín ìdálóró wọn ń lọ sókè títí láéláé wọn kò sì ní ìsinmi ni ọ̀sán àti ní òru, àwọn tí ń foríbalẹ̀ fún ẹranko náà àti fún àwòrán rẹ̀, àti ẹnikẹ́ni tí o ba sì gba ààmì orúkọ rẹ̀.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.