Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Saamu ti Asafu.
79 Ọlọ́run, àwọn orílẹ̀-èdè ti wá ilẹ̀ ìní rẹ;
wọ́n ti ba tẹmpili mímọ́ rẹ jẹ́,
wọn di Jerusalẹmu kù sí òkìtì àlàpà.
2 Wọn ti fi ara òkú àwọn ìránṣẹ́ rẹ
fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run ní oúnjẹ,
ẹran-ara àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ fún ẹranko ilẹ̀.
3 Wọ́n tu ẹ̀jẹ̀ jáde gẹ́gẹ́ bí omi
yí Jerusalẹmu ká,
kò sì ṣí àwọn tí yóò sìn wọ́n.
4 Àwa di ohun ẹ̀gàn sí àwọn tí ó yí wa ká,
àbùkù àti ìfiṣe ẹlẹ́yà sí àwọn tí ó yí wa ká.
5 Nígbà wo, Olúwa? Ní ìwọ ó máa bínú títí láé?
Yóò ti pẹ́ tó ti owú rẹ yóò ha jò bí iná?
6 Tú ìbínú rẹ jáde sí orílẹ̀-èdè
tí kò ní ìmọ̀ rẹ,
lórí àwọn ìjọba
tí kò pe orúkọ rẹ;
7 Nítorí wọ́n ti run Jakọbu
wọ́n sì sọ ibùgbé rẹ di ahoro.
8 Má ṣe ka ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba wa sí wa lọ́rùn
jẹ́ kí àánú rẹ wá kánkán láti bá wa,
nítorí tí a rẹ̀ wá sílẹ̀ gidigidi.
9 Ràn wá lọ́wọ́, Ọlọ́run Olùgbàlà wa,
fún ògo orúkọ rẹ;
gbà wá kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì
nítorí orúkọ rẹ.
10 Àwọn orílẹ̀-èdè yóò máa wí pé,
“Níbo ni Ọlọ́run wọn wà?”
Ní ojú wa, kí a mọ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè
kí ó sì gbẹ̀san àwọn ẹ̀jẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ tí a tú jáde.
11 Jẹ́ kí ìmí ẹ̀dùn oǹdè náà wá síwájú rẹ,
gẹ́gẹ́ bí títóbi agbára rẹ
ìwọ ṣe ìtọ́jú àwọn ti a dá lẹ́bi ikú.
12 San án padà sí àyà àwọn aládùúgbò wa nígbà méje
nípa ẹ̀gàn tí wọn ti gàn ọ́ Olúwa.
13 Nígbà náà àwa ènìyàn rẹ,
àti àgùntàn pápá rẹ,
yóò fi ọpẹ́ fún ọ títí láé;
láti ìran dé ìran
ni àwa ó fi ìyìn rẹ hàn.
Àsọtẹ́lẹ̀ nípa Olùgbàlà láti Bẹtilẹhẹmu
5 Nísinsin yìí, kó àwọn ọ̀wọ́ ogun rẹ jọ,
ìwọ ìlú ti o ni ọmọ-ogun,
nítorí ó ti fi gbógun dó tì wá.
Wọn yóò fi ọ̀pá lu àwọn alákòóso Israẹli ní ẹ̀rẹ̀kẹ́.
2 “Ṣùgbọ́n ìwọ, Bẹtilẹhẹmu Efrata,
bí ìwọ ti jẹ́ kékeré láàrín àwọn ẹ̀yà Juda,
nínú rẹ ni ẹni tí yóò jẹ́ olórí ní Israẹli
yóò ti jáde tọ̀ mí wá,
ìjáde lọ rẹ̀ sì jẹ́ láti ìgbà àtijọ́,
láti ìgbà láéláé.”
3 Nítorí náà Israẹli yóò di kíkọ̀sílẹ̀ pátápátá
títí di àkókò tí ẹni tí ń rọbí yóò fi bí,
àti àwọn ìyókù arákùnrin rẹ̀ yóò fi padà
láti darapọ̀ mọ́ àwọn Israẹli.
4 Òun yóò sì dúró,
yóò sì máa ṣe olùṣọ́-àgùntàn àwọn agbo ẹran rẹ̀ ní agbára Olúwa,
ní ọláńlá orúkọ Olúwa Ọlọ́run rẹ̀.
Wọn yóò sì wà láìléwu,
nítorí nísinsin yìí ni títóbi rẹ
yóò sì dé òpin ayé.
Ìgbàlà àti ìparun
5 Òun yóò sì jẹ́ àlàáfíà wọn.
Nígbà tí àwọn Asiria bá gbógun sí ilẹ̀ wa
tí wọ́n sì ń yan lórí odi alágbára wa,
nígbà náà ni a ó gbé olùṣọ́-àgùntàn méje dìde sí i,
àti olórí ènìyàn mẹ́jọ.
34 (A)“Ṣùgbọ́n ẹ máa kíyèsára yín, kí ọkàn yín má ṣe kún fún wọ̀bìà, àti fún ọtí àmupara, àti fún àníyàn ayé yìí, tí ọjọ́ náà yóò sì fi dé bá yín lójijì bí ìkẹ́kùn. 35 Nítorí bẹ́ẹ̀ ni yóò dé bá gbogbo àwọn tí ń gbé orí gbogbo ilẹ̀ ayé. 36 (B)Ǹjẹ́ kì ẹ máa ṣọ́nà, kí ẹ sì máa gbàdúrà nígbà gbogbo, kí ẹ ba à lè la gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí yóò ṣẹlẹ̀, kí ẹ sì lè dúró níwájú Ọmọ Ènìyàn.”
37 (C)Lọ́sàn án, Jesu a sì máa kọ́ni ní tẹmpili: lóru, a sì máa jáde lọ í wọ̀ ní òkè tí à ń pè ní Òkè Olifi. 38 Gbogbo ènìyàn sì ń tọ̀ ọ́ wá ní tẹmpili ní kùtùkùtù òwúrọ̀, láti gbọ́rọ̀ rẹ̀.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.