Add parallel Print Page Options

27 Nítorí Ọmọ ènìyàn yóò wá nínú ògo baba rẹ pẹ̀lú àwọn angẹli rẹ̀, nígbà náà ni yóò sì san án fún olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀.

Read full chapter

13 (A)“Nínú ìran mi ní òru mo wò, mo rí ẹnìkan tí ó dúró sí iwájú u mi, ó rí bí Ọmọ ènìyàn, ó ń bọ̀ wá nínú àwọsánmọ̀ ọ̀run, ó ń bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ ẹni ìgbàanì, a sì mú u wá sí iwájú rẹ̀.

Read full chapter

(A)Kíyèsi i, o ń bọ̀ nínú àwọsánmọ̀;
    gbogbo ojú ni yóò sì rí i,
àti àwọn tí ó gún un ní ọ̀kọ̀ pẹ̀lú;
    àti gbogbo orílẹ̀-èdè ayé ni yóò sì máa pohùnréré ẹkún nítorí rẹ̀.
Bẹ́ẹ̀ náà ni! Àmín.

Read full chapter