Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Àfonífojì àwọn egungun gbígbẹ
37 Ọwọ́ Olúwa wà lára mi, ó sì mú mi jáde pẹ̀lú ẹ̀mí Olúwa, ó mú kí ń wà ní àárín àfonífojì; ti o kún fún àwọn egungun. 2 Ó mú mi lọ síwájú àti sẹ́yìn láàrín wọn, èmi sì rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn egungun ní orí ilẹ̀ àfonífojì, àwọn egungun tí ó gbẹ gan. 3 Olúwa sì bi mí léèrè, “Ọmọ ènìyàn, ǹjẹ́ àwọn egungun wọ̀nyí lè yípadà di àwọn ènìyàn bí?”
Èmi sì wí pé, “Ìwọ Olúwa Olódùmarè, ìwọ nìkan ni o lè dáhùn sí ìbéèrè yìí.”
4 Nígbà náà ni ó wí fún mi pé, “Sọtẹ́lẹ̀ sí àwọn egungun kí ó sì sọ fún wọn pé, ‘Ẹ̀yin egungun gbígbẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa! 5 (A)Èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí fún àwọn egungun wọ̀nyí: Èmi yóò mú kí èémí wọ inú yín ẹ̀yin yóò sì wá di ààyè. 6 Èmi yóò so iṣan ara mọ́ ọn yín, èmi yóò sì mú kí ẹran-ara wá sí ara yín, èmi yóò sì fi awọ ara bò yín: Èmi yóò sì fi èémí sínú yín, ẹ̀yin yóò sì wà ní ààyè. Nígbà náà ẹ̀yin yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa.’ ”
7 Nítorí náà ni mo ṣe sọtẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí a ti pa á láṣẹ fún mi. Bí mo sì ti ń sọtẹ́lẹ̀, ariwo wá, ìró tí ó kígbe sókè, àwọn egungun sì wà papọ̀, egungun sí egungun. 8 Mo wò ó, iṣan ara àti ẹran-ara farahàn lára wọn, awọ ara sì bò wọ́n, ṣùgbọ́n kò sí èémí nínú wọn.
9 Lẹ́yìn náà ni ó sọ fún mi pé, “Sọtẹ́lẹ̀ sí èémí; sọtẹ́lẹ̀, ọmọ ènìyàn, kí ó sì sọ fún un pé, ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: wá láti atẹ́gùn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, ìwọ èémí, kí ó sì mí èémí sínú àwọn tí a pa wọ̀nyí, kí wọn kí ó lè wà ní ààyè.’ ” 10 Nítorí náà, mo sọtẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe pa á láṣẹ fún mi, èémí sì wọ inú wọn; Wọ́n di alààyè, wọ́n sì dìde dúró lórí ẹsẹ̀ wọn—pẹ̀lú ìhámọ́ra tí ó pọ̀.
11 Lẹ́yìn náà ó sọ fún mi: “Ọmọ ènìyàn, àwọn egungun wọ̀nyí ni gbogbo ìdílé Israẹli. Wọ́n sọ wí pé, ‘Egungun wa ti gbẹ ìrètí wa sì ti lọ; a ti gé wa kúrò.’ 12 Nítorí náà sọtẹ́lẹ̀, kí o sì sọ fun wọn pé, ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè sọ: Ẹ̀yin ènìyàn mi, Èmi yóò ṣí àwọn ibojì yín, èmi yóò sì mú yín wá si ilẹ̀ Israẹli. 13 Ẹ̀yin o sì mọ̀ èmi ni Olúwa, nígbà tí èmi bá ti ṣí ibojì yín, ẹ̀yin ènìyàn mi, ti èmi bá si mú un yín dìde kúrò nínú ibojì yín 14 (B)Èmi yóò fi èémí mi sínú yín, ẹ̀yin yóò sì yè, èmi yóò sì mú kí ẹ fi lélẹ̀ ní ilẹ̀ ẹ̀yin tìkára yín. Nígbà náà ẹ̀yin yóò mọ̀ pé Olúwa ti sọ̀rọ̀, èmi sì ti ṣe ni Olúwa wí.’ ”
Orin fún ìgòkè.
130 Láti inú ibú wá ni
èmi ń ké pè é ọ́ Olúwa
2 Olúwa, gbóhùn mi,
jẹ́ kí etí rẹ kí o tẹ́ sílẹ̀ sí ohùn ẹ̀bẹ̀ mi.
3 (A)Olúwa, ìbá ṣe pé kí ìwọ máa sàmì ẹ̀ṣẹ̀,
Olúwa, tá ni ìbá dúró.
4 Nítorí ìdáríjì wà lọ́dọ̀ rẹ,
kí a lè máa bẹ̀rù rẹ.
5 Èmi dúró de Olúwa, ọkàn mi dúró,
àti nínú ọ̀rọ̀ rẹ ni èmi ń ṣe ìrètí
6 Ọkàn mi dúró de Olúwa,
ju àwọn tí ń ṣọ́nà òwúrọ̀ lọ,
àní ju àwọn tí ń ṣọ́nà òwúrọ̀ lọ.
7 Israẹli, ìwọ ní ìrètí ní ti Olúwa:
nítorí pé lọ́dọ̀ Olúwa ni àánú wà,
àti lọ́dọ̀ rẹ̀ ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdáǹdè wà.
8 Òun ó sì dá Israẹli ní ìdè
kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ gbogbo.
6 (A)Nítorí èrò ti ara ikú ni; ṣùgbọ́n èrò ti ẹ̀mí ni ìyè àti àlàáfíà. 7 Nítorí èrò ti ara ọ̀tá ni sí Ọlọ́run, nítorí kì í tẹríba fún òfin Ọlọ́run, òun kò tilẹ̀ le ṣe e. 8 (B)Ìdí nìyìí tí àwọn tí ó wà lábẹ́ àkóso ara ẹ̀ṣẹ̀, kò le è tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn.
9 (C)Ṣùgbọ́n ẹyin kò sí nínú ti ara, bí kò ṣe nínú ti Ẹ̀mí, bí ó bá ṣe pé Ẹ̀mí Ọlọ́run ń gbé inú yín, Ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni kò bá ní Ẹ̀mí Kristi, òun kò sí nínú ẹni tirẹ̀. 10 (D)Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Kristi ń gbé inú yín síbẹ̀síbẹ̀, ara yín jẹ́ òkú nítorí ẹ̀ṣẹ̀; ṣùgbọ́n ẹ̀mí mímọ́ tí ń gbé inú yín yóò fún yín ní ìyè, nítorí ó ti fún un yín ní òdodo. 11 (E)Àti pé, bí ẹ̀mí Ọlọ́run, ẹni tí ó jí Jesu kúrò nínú òkú bá ń gbé inú yín, ẹni tí ó jí Kristi Jesu dìde kúrò nínú òkú, yóò fi ẹ̀mí rẹ̀ tí ń gbé inú yín sọ ara kíkú yín di ààyè pẹ̀lú.
Ikú Lasaru
11 (A)Ara ọkùnrin kan kò sì dá, Lasaru, ará Betani, tí í ṣe ìlú Maria àti Marta arábìnrin rẹ̀. 2 (B)Maria náà ni ẹni tí ó fi òróró ìkunra kun Olúwa, tí ó sì fi irun orí rẹ̀ nù ún, arákùnrin rẹ̀ ni Lasaru í ṣe, ara ẹni tí kò dá. 3 Nítorí náà, àwọn arábìnrin rẹ̀ ránṣẹ́ sí i, wí pé, “Olúwa, wò ó, ara ẹni tí ìwọ fẹ́ràn kò dá.”
4 (C)Nígbà tí Jesu sì gbọ́, ó wí pé, “Àìsàn yìí kì í ṣe sí ikú, ṣùgbọ́n fún Ògo Ọlọ́run, kí a lè yin Ọmọ Ọlọ́run lógo nípasẹ̀ rẹ̀.” 5 Jesu sì fẹ́ràn Marta, àti arábìnrin rẹ̀ àti Lasaru. 6 Nítorí náà, nígbà tí ó ti gbọ́ pé, ara rẹ̀ kò dá, ó gbé ọjọ́ méjì sí i níbìkan náà tí ó gbé wà. 7 Ǹjẹ́ lẹ́yìn èyí ni ó wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ jẹ́ kí a tún padà lọ sí Judea.”
8 (D)Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì wí fún un pé, “Rabbi, ní àìpẹ́ yìí ni àwọn Júù ń wá ọ̀nà láti sọ ọ́ ní òkúta; ìwọ sì tún padà lọ síbẹ̀?”
9 (E)Jesu dáhùn pé, “Wákàtí méjìlá kọ́ ni ó bẹ nínú ọ̀sán kan bí? Bí ẹnìkan bá rìn ní ọ̀sán, kì yóò kọsẹ̀, nítorí tí ó rí ìmọ́lẹ̀ ayé yìí. 10 Ṣùgbọ́n bí ẹnìkan bá rìn ní òru, yóò kọsẹ̀, nítorí tí kò sí ìmọ́lẹ̀ nínú rẹ̀.”
11 (F)Nǹkan wọ̀nyí ni ó sọ: lẹ́yìn èyí nì ó sì wí fún wọn pé, “Lasaru ọ̀rẹ́ wa sùn; ṣùgbọ́n èmi ń lọ kí èmi kí ó lè jí i dìde nínú orun rẹ̀.”
12 Nítorí náà àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wí fún un pé, “Olúwa, bí ó bá ṣe pé ó sùn, yóò sàn.” 13 Ṣùgbọ́n Jesu ń sọ ti ikú rẹ̀: ṣùgbọ́n wọ́n rò pé, ó ń sọ ti orun sísùn.
14 Nígbà náà ni Jesu wí fún wọn gbangba pé, “Lasaru ti kú. 15 Èmi sì yọ̀ nítorí yín, tí èmi kò sí níbẹ̀. Kí ẹ le gbàgbọ́; ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí a lọ sọ́dọ̀ rẹ̀.”
16 (G)Nítorí náà Tomasi, ẹni tí à ń pè ní Didimu, wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ẹgbẹ́ rẹ̀ pé, “Ẹ jẹ́ kí àwa náà lọ, kí a lè bá a kú pẹ̀lú.”
Jesu tu àwọn arábìnrin rẹ̀ nínú
17 Nítorí náà nígbà tí Jesu dé, ó rí i pé a ti tẹ́ ẹ sínú ibojì ní ọjọ́ mẹ́rin ná, 18 Ǹjẹ́ Betani súnmọ́ Jerusalẹmu tó ibùsọ̀ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún: 19 (H)Ọ̀pọ̀ nínú àwọn Júù sì wá sọ́dọ̀ Marta àti Maria láti tù wọ́n nínú nítorí ti arákùnrin wọn. 20 Nítorí náà, nígbà tí Marta gbọ́ pé Jesu ń bọ̀ wá, ó jáde lọ pàdé rẹ̀: ṣùgbọ́n Maria jókòó nínú ilé.
21 Nígbà náà, ni Marta wí fún Jesu pé, “Olúwa, ìbá ṣe pé ìwọ ti wà níhìn-ín, arákùnrin mi kì bá kú. 22 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí náà, mo mọ̀ pé, ohunkóhun tí ìwọ bá béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, Ọlọ́run yóò fi fún ọ.”
23 Jesu wí fún un pé, “Arákùnrin rẹ yóò jíǹde.”
24 (I)Marta wí fún un pé, “Mo mọ̀ pé yóò jíǹde ní àjíǹde ìkẹyìn.”
25 (J)Jesu wí fún un pé, “Èmi ni àjíǹde àti ìyè: ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́, bí ó tilẹ̀ kú, yóò yè: 26 (K)Ẹnikẹ́ni tí ó ń bẹ láààyè, tí ó sì gbà mí gbọ́, kì yóò kú láéláé ìwọ gbà èyí gbọ́?”
27 (L)Ó wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa: èmi gbàgbọ́ pé, ìwọ ni Kristi náà Ọmọ Ọlọ́run, ẹni tí ń bọ̀ wá sí ayé.”
28 Nígbà tí ó sì ti wí èyí tan, ó lọ, ó sì pe Maria arábìnrin rẹ̀ sẹ́yìn wí pé, “Olùkọ́ dé, ó sì ń pè ọ́.” 29 Nígbà tí ó gbọ́, ó dìde lọ́gán, ó sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀. 30 Jesu kò tí ì wọ ìlú, ṣùgbọ́n ó wà ní ibi kan náà tí Marta ti pàdé rẹ̀. 31 Nígbà tí àwọn Júù tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ nínú ilé, tí wọ́n ń tù ú nínú rí Maria tí ó dìde kánkán, tí ó sì jáde, wọ́n tẹ̀lé, wọ́n ṣe bí ó ń lọ sí ibojì láti sọkún níbẹ̀.
32 (M)Nígbà tí Maria sì dé ibi tí Jesu wà, tí ó sì rí i, ó wólẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ̀, ó wí fún un pé, “Olúwa, ìbá ṣe pé ìwọ ti wà níhìn-ín, arákùnrin mi kì bá kú.”
33 Nígbà tí Jesu rí i, tí ó ń sọkún, àti àwọn Júù tí ó bá a wá ń sọkún pẹ̀lú rẹ̀, ó kérora nínú ẹ̀mí, inú rẹ̀ sì bàjẹ́. 34 Ó sì wí pé, “Níbo ni ẹ̀yin gbé tẹ́ ẹ sí?”
Wọ́n sì wí fún un pé, “Olúwa, wá wò ó.”
35 (N)Jesu sọkún.
36 Nítorí náà àwọn Júù wí pé, “Sá wò ó bí ó ti fẹ́ràn rẹ̀ tó!”
37 (O)Àwọn kan nínú wọn sì wí pé, “Ọkùnrin yìí, ẹni tí ó la ojú afọ́jú, kò lè ṣe é kí ọkùnrin yìí má kú bí?”
Jesu jí òkú Lasaru dìde
38 (P)Nígbà náà ni Jesu tún kérora nínú ara rẹ̀, ó wá sí ibojì, ó sì jẹ́ ihò, a sì gbé òkúta lé ẹnu rẹ̀. 39 Jesu wí pé, “Ẹ gbé òkúta náà kúrò!”
Marta, arábìnrin ẹni tí ó kú náà wí fún un pé, “Olúwa, ó ti ń rùn nísinsin yìí: nítorí pé ó di ọjọ́ kẹrin tí ó tí kú.”
40 Jesu wí fún un pé, “Èmi kò ti wí fún ọ pé, bí ìwọ bá gbàgbọ́, ìwọ yóò rí ògo Ọlọ́run?”
41 (Q)Nígbà náà ni wọ́n gbé òkúta náà kúrò (níbi tí a tẹ́ ẹ sí). Jesu sì gbé ojú rẹ̀ sókè, ó sì wí pé, “Baba, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ nítorí tí ìwọ gbọ́ tèmi. 42 (R)Èmi sì ti mọ̀ pé, ìwọ a máa gbọ́ ti èmi nígbà gbogbo: ṣùgbọ́n nítorí ìjọ ènìyàn tí ó dúró yìí ni mo ṣe wí i, kí wọn ba à lè gbàgbọ́ pé ìwọ ni ó rán mi.”
43 Nígbà tí ó sì wí bẹ́ẹ̀ tan, ó kígbe lóhùn rara pé, “Lasaru, jáde wá.” 44 (S)Ẹni tí ó kú náà sì jáde wá, tí a fi aṣọ òkú dì tọwọ́ tẹsẹ̀ a sì fi gèlè dì í lójú.
Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ tú u, ẹ sì jẹ́ kí ó máa lọ!”
Àwọn alábojútó pinnu láti pa Jesu
45 Nítorí náà ni ọ̀pọ̀ àwọn Júù tí ó wá sọ́dọ̀ Maria, tí wọ́n rí ohun tí Jesu ṣe, ṣe gbà á gbọ́.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.