Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 128

Orin fún ìgòkè.

Ìbẹ̀rù Olúwa dára

128 Ìbùkún ni fún gbogbo ẹni tí ó bẹ̀rù Olúwa:
    tí ó sì ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀
Nítorí tí ìwọ yóò jẹ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ
    ìbùkún ni fún ọ; yóò sì dára fún ọ
Obìnrin rẹ yóò dàbí àjàrà rere
    eléso púpọ̀ ní àárín ilé rẹ;
    àwọn ọmọ rẹ yóò dàbí igi olifi tí ó yí tábìlì rẹ ká.
Kíyèsi i pé, bẹ́ẹ̀ ni a ó bùsi i fún ọkùnrin náà,
    tí ó bẹ̀rù Olúwa.

Olúwa kí ó bùsi i fún ọ láti Sioni wá,
    kí ìwọ kí ó sì máa rí ìre
Jerusalẹmu ní ọjọ́ ayé rẹ gbogbo.
    Bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ kí ó sì máa rí àti ọmọdọ́mọ rẹ.
Láti àlàáfíà lára Israẹli.

Esekiẹli 36:22-32

22 “Nítorí náà, sọ fún ilé Israẹli, ‘Èyí ni Olúwa Olódùmarè wí: Kì í ṣe nítorí rẹ, ìwọ ilé Israẹli, ni èmi yóò ṣe ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí, ṣùgbọ́n nítorí orúkọ mímọ́ mi, èyí ti ìwọ ti sọ di aláìmọ́ ní àárín àwọn orílẹ̀-èdè tí ìwọ ti lọ. 23 Èmi yóò fi jíjẹ́ mímọ́ orúkọ ńlá mi, èyí tí a ti sọ di aláìmọ́ hàn ni àárín àwọn orílẹ̀-èdè, orúkọ tí ìwọ ti sọ di aláìmọ́ ni àárín wọn. Nígbà náà àwọn orílẹ̀-èdè yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa, ni Olúwa Olódùmarè wí, nígbà tí mo bá fi ara mi hàn ni mímọ́ nípasẹ̀ yín ni iwájú wọn.

24 “ ‘Nítorí èmi yóò mú yín jáde kúrò ni àwọn orílẹ̀-èdè náà; Èmi yóò ṣà yín jọ kúrò ní gbogbo àwọn ìlú náà; Èmi yóò sì mú yín padà sí ilẹ̀ ẹ̀yin tìkára yín. 25 Èmi yóò wọ́n omi tó mọ́ sí yín lára ẹ̀yin yóò sì mọ́; Èmi yóò sì fọ̀ yín mọ́ kúrò nínú gbogbo ìwà èérí yin gbogbo àti kúrò nínú gbogbo òrìṣà yin. 26 Èmi yóò fún yín ni ọkàn tuntun, èmi yóò sì fi ẹ̀mí tuntun sínú yín; Èmi yóò sì mú ọkàn òkúta kúrò nínú yín, èmi yóò sì fi ọkàn ẹran fún yín. 27 Èmi yóò fi ẹ̀mí mi sínú yín, èmi yóò sì mú ki ẹ tẹ̀lé àṣẹ mi, kí ẹ sì fiyèsí àti pa òfin mi mọ́. 28 Ẹ̀yin yóò sì máa gbé ilẹ̀ náà tí mo ti fi fún àwọn baba ńlá yín; ẹ̀yin yóò sì jẹ́ ènìyàn mi èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run yín. 29 Èmi yóò sì gbà yín kúrò nínú gbogbo ìwà àìmọ́ yín. Èmi yóò pèsè ọkà, èmi yóò sì mú kí ó pọ̀ yanturu, èmi kì yóò sì mú ìyàn wá sí orí yín. 30 Èmi yóò sọ èso àwọn igi yín àti ohun ọ̀gbìn oko yín di púpọ̀, nítorí kí ẹ̀yin kí ó má ṣe jìyà ìdójútì mọ́ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè náà nítorí ìyàn. 31 (A)Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò rántí àwọn ọ̀nà búburú àti àwọn ìwà ìkà yín, ẹ̀yin yóò sì kórìíra ara yín fún ẹ̀ṣẹ̀ yín, ìwà tí kò bójúmu. 32 Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé ń kò ṣe nǹkan wọ̀nyí nítorí yín, ni Olúwa Olódùmarè wí. Jẹ kí ojú kí ó tì yín, kí ẹ sì gba ẹ̀tẹ́ nítorí ìwà yín ẹ̀yin ilé Israẹli!

Johanu 7:53-8:11

53 Wọ́n sì lọ olúkúlùkù sí ilé rẹ̀. Jesu sì lọ sí orí òkè olifi.

Ó sì tún padà wá sí tẹmpili ní kùtùkùtù òwúrọ̀, gbogbo ènìyàn sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀; ó sì jókòó, ó ń kọ́ wọn. Àwọn akọ̀wé àti àwọn Farisi sì mú obìnrin kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀, tí a mú nínú ṣíṣe panṣágà; wọ́n sì mú un dúró láàrín. Wọ́n sì wí fún un pé, “Olùkọ́, a mú obìnrin yìí nínú ìṣe panṣágà, Ǹjẹ́ nínú òfin, Mose pàṣẹ fún wa láti sọ irú àwọn obìnrin bẹ́ẹ̀ ní òkúta, ṣùgbọ́n ìwọ ha ti wí?” Èyí ni wọ́n wí, láti dán án wò, kí wọn ba à lè rí ẹ̀sùn kan kà sí i lọ́rùn.

Ṣùgbọ́n Jesu bẹ̀rẹ̀ sílẹ̀, ó sì ń fi ìka rẹ̀ kọ̀wé ní ilẹ̀. Nígbà tí wọ́n ń bi í léèrè lemọ́lemọ́, ó gbe orí rẹ sókè, ó sì wí fún wọn pé, “Jẹ́ kí ẹni tí ó wà láìní ẹ̀ṣẹ̀ nínú yín kọ́kọ́ sọ òkúta lù ú.” Ó sì tún bẹ̀rẹ̀ sílẹ̀, ó ń kọ̀wé ní ilẹ̀.

Nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, (tí ẹ̀rí ọkàn wọn sì dá wọn lẹ́bi) wọ́n sì jáde lọ lọ́kọ̀ọ̀kan, bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn àgbà títí dé àwọn tí ó kẹ́yìn; a sì fi Jesu nìkan sílẹ̀, àti obìnrin náà láàrín, níbi tí ó wà. 10 Jesu sì dìde, ó sì wí fún un pé, “Obìnrin yìí, àwọn (olùfisùn rẹ) dà? Kò sí ẹnìkan tí ó dá ọ lẹ́bi?”

11 Ó wí pé, “Kò sí ẹnìkan, Olúwa.”

Jesu wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ ni èmi náà kò dá ọ lẹ́bi: máa lọ, láti ìgbà yìí lọ, má dẹ́ṣẹ̀ mọ́.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.