Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
95 Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a kọ orin ayọ̀ sí Olúwa
Ẹ jẹ́ kí a kígbe sókè sí àpáta ìgbàlà wa.
2 Ẹ jẹ́ kí a wá sí iwájú rẹ̀ pẹ̀lú ọpẹ́
kí a sì pòkìkí rẹ̀ pẹ̀lú ohun èlò
orin àti ìyìn.
3 Nítorí Olúwa Ọlọ́run títóbi ni,
ọba tí ó tóbi ju gbogbo òrìṣà lọ.
4 Ní ọwọ́ rẹ̀ ni ọ̀gbun ilẹ̀ wà,
ṣóńṣó orí òkè tirẹ̀ ní ṣe.
5 Tirẹ̀ ni Òkun, nítorí òun ni ó dá a
àti ọwọ́ rẹ̀ ni ó fi dá ìyàngbẹ ilẹ̀.
6 Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a foríbalẹ̀ kí a sìn ín,
Ẹ jẹ́ kí a kúnlẹ̀ níwájú
Olúwa ẹni tí ó dá wa;
7 (A)Nítorí òun ni Ọlọ́run wa
àwa sì ni ènìyàn pápá rẹ̀,
àti ọ̀wọ́ ẹran ni abẹ́ ìpamọ́ rẹ̀.
Lónìí tí ìwọ bá gbọ́ ohùn rẹ̀,
8 “Ẹ má ṣe sé ọkàn yín le gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ṣe ní Meriba,
àti bí ẹ ti ṣe ní ọjọ́ náà ní Massa ní aginjù,
9 Nígbà tí àwọn baba yín dán mi wò
tí wọn wádìí mi,
tí wọn sì rí iṣẹ́ mi
10 Fún ogójì ọdún ni èmi fi bínú sí ìran náà;
mo wí pé, ‘Wọ́n jẹ́ ènìyàn tí ọkàn wọn ṣáko lọ
wọn kò sì mọ ọ̀nà mi.’
11 Nítorí náà ni mo kéde ìbúra nínú ìbínú mi
‘Wọn kì yóò wọ ibi ìsinmi mi.’ ”
27 Síbẹ̀síbẹ̀ àwọn ènìyàn kan jáde lọ ní ọjọ́ keje láti kó o, ṣùgbọ́n wọn kò ri nǹkan kan kó. 28 Olúwa sì sọ fún Mose pé, “Yóò ti pẹ́ tó ti ẹ ó kọ̀ láti pa àṣẹ mi àti ìlànà mi mọ́? 29 Wò ó? Olúwa ti fún un yín ni ọjọ́ ìsinmi, nítorí náà, ni ọjọ́ kẹfà, ó fún un yín ni oúnjẹ ọjọ́ méjì; kí ẹnìkọ̀ọ̀kan dúró ni ibi tí ó gbé wà; kí ẹ má ṣe kúrò ni ibi tí ẹ wà ni ọjọ́ keje.” 30 Nítorí náà, àwọn ènìyàn sinmi ní ọjọ́ keje.
31 (A)Àwọn ènìyàn Israẹli sì pe oúnjẹ náà ní manna. Ó funfun bí irúgbìn korianderi, ó sì dùn bí àkàrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ ti a fi oyin ṣe. 32 Mose wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa pàṣẹ: ‘Ẹ mú òṣùwọ̀n omeri manna kí ẹ sì pa á mọ́ de àwọn ìran ti ń bọ̀, kí wọn kí ó lè rí oúnjẹ ti èmi fi fún un yín jẹ ní ijù, nígbà tí mo mú un yín jáde ni ilẹ̀ Ejibiti.’ ”
33 Nígbà náà ni Mose sọ fún Aaroni pe, “Mú ìkòkò kan, kí o sì kó manna tí ó kún òṣùwọ̀n omeri kan sí inú rẹ̀, kí o sì gbé e kalẹ̀ ni iwájú Olúwa láti tọ́jú rẹ̀ pamọ́ de àwọn ìran ti ń bọ̀.”
34 Bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose, Aaroni gbé manna sí iwájú ẹ̀rí láti pa á mọ́. 35 Àwọn ará Israẹli jẹ manna fún ogójì ọdún títí wọ́n fi dé ilẹ̀ Kenaani ni ibi ti èso ti wà fún wọn láti jẹ; Wọ́n jẹ manna títí tí wọ́n fi dé ilẹ̀ agbègbè Kenaani.
Jesu sọ̀rọ̀ pẹ̀lú obìnrin ara Samaria
4 (A)Àwọn Farisi sì gbọ́ pé, Jesu ni, ó sì ń ṣe ìtẹ̀bọmi fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn púpọ̀ ju Johanu lọ, 2 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Jesu tìkára rẹ̀ kò ṣe ìtẹ̀bọmi bí kò ṣe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, 3 Ó fi Judea sílẹ̀, ó sì tún lọ sí Galili.
4 (B)Òun sì ní láti kọjá láàrín Samaria. 5 (C)Nígbà náà ni ó dé ìlú Samaria kan, tí a ń pè ní Sikari, tí ó súnmọ́ etí ilẹ̀ oko tí Jakọbu ti fi fún Josẹfu, ọmọ rẹ̀. 6 Kànga Jakọbu sì wà níbẹ̀. Nítorí pé ó rẹ Jesu nítorí ìrìn rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó jókòó létí kànga: ó sì jẹ́ ìwọ̀n wákàtí kẹfà ọjọ́.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.