Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 23

Saamu ti Dafidi.

23 Olúwa ni Olùṣọ́ èmi àgùntàn rẹ̀, èmi kì yóò ṣe aláìní.
    (A)Ó mú mi dùbúlẹ̀ sí ibi pápá oko tútù
Ó mú mi lọ sí ibi omi dídákẹ́ rọ́rọ́;
    Ó mú ọkàn mi padà bọ̀ sípò
Ó mú mi lọ sí ọ̀nà òdodo
    nítorí orúkọ rẹ̀.
Bí mo tilẹ̀ ń rìn
    Láàrín àfonífojì òjìji ikú,
èmi kì yóò bẹ̀rù ibi kan;
    nítorí ìwọ wà pẹ̀lú mi;
ọ̀gọ rẹ àti ọ̀pá à rẹ
    wọ́n ń tù mí nínú.

Ìwọ tẹ́ tábìlì oúnjẹ sílẹ̀ níwájú mi
    ní ojú àwọn ọ̀tá à mi;
ìwọ ta òróró sí mi ní orí;
    ago mí sì kún àkúnwọ́sílẹ̀.
Nítòótọ́, ìre àti àánú ni yóò máa tọ̀ mí lẹ́yìn
    ní ọjọ́ ayé è mi gbogbo,
èmi yóò sì máa gbé inú ilé Olúwa
    títí láéláé.

1 Samuẹli 15:10-21

10 Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Samuẹli wá pé: 11 “Èmi káàánú gidigidi pé mo fi Saulu jẹ ọba, nítorí pé ó ti yípadà kúrò lẹ́yìn mi, kò sì pa ọ̀rọ̀ mi mọ́.” Inú Samuẹli sì bàjẹ́ gidigidi, ó sì ké pe Olúwa ní gbogbo òru náà.

12 Ní òwúrọ̀ kùtùkùtù Samuẹli sì dìde láti lọ pàdé Saulu, ṣùgbọ́n wọ́n sọ fún un pé, “Saulu ti wá sí Karmeli. Ó ti kọ́ ibìkan fún ara rẹ̀ níbẹ̀, ó sì ti yípadà, ó sì ti sọ̀kalẹ̀ lọ sí Gilgali.”

13 Nígbà tí Samuẹli sì dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, Saulu sì wí fún un pé, “Olúwa bùkún fún ọ, mo ti ṣe ohun tí Olúwa pàṣẹ.”

14 Ṣùgbọ́n Samuẹli wí pé, “Èwo wá ni igbe àgùntàn tí mo ń gbọ́ ní etí mi? Kí ni igbe màlúù ti mo ń gbọ́ yìí?”

15 Saulu sì dáhùn pé, “Àwọn ọmọ-ogun ní o mú wọn láti Amaleki wá, wọ́n dá àwọn àgùntàn, àti màlúù tí ó dára jùlọ sí láti fi rú ẹbọ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ, ṣùgbọ́n a pa àwọn tókù run pátápátá.”

16 Samuẹli sí wí fún Saulu pé, “Dákẹ́ ná, jẹ́ kí èmi kí ó sọ ohun tí Olúwa wí fún mi ní alẹ́ àná fún ọ.”

Saulu sì wí pé, “Sọ fún mi.”

17 Samuẹli sì wí pé, “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ fi ìgbà kan kéré lójú ara rẹ, ǹjẹ́ ìwọ kò ha di olórí ẹ̀yà Israẹli? Olúwa fi ààmì òróró yàn ọ́ ní ọba lórí Israẹli. 18 Olúwa sì rán ọ níṣẹ́ wí pé, ‘Lọ, kí o sì pa àwọn ènìyàn búburú ará Amaleki run pátápátá; gbóguntì wọ́n títí ìwọ yóò fi run wọ́n.’ 19 Èéṣe tí ìwọ kò fi gbọ́ ti Olúwa? Èéṣe tí ìwọ fi sáré sí ìkógun tí o sì ṣe búburú níwájú Olúwa?”

20 Saulu sì wí fún Samuẹli pé, “Ṣùgbọ́n èmi ti ṣe ìgbọ́ràn sí Olúwa, èmi sì ti lọ ní ọ̀nà tí Olúwa rán mi. Mo sì ti pa àwọn ará Amaleki run pátápátá, mo sì ti mú Agagi ọba wọn padà wá. 21 Àwọn ọmọ-ogun ti mú àgùntàn àti màlúù lára ìkógun èyí tí ó dára láti fi fún Olúwa láti fi rú ẹbọ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ ní Gilgali.”

Efesu 4:25-32

25 (A)Nítorí náà ẹ fi èké ṣíṣe sílẹ̀, ki olúkúlùkù yín kí ó máa ba ọmọnìkejì rẹ̀ sọ òtítọ́, nítorí ẹ̀yà ara ọmọnìkejì wa ni àwa jẹ́. 26 Nínú ìbínú yín, ẹ máa ṣe ṣẹ̀, ẹ má ṣe jẹ́ kí oòrùn wọ̀ bá ìbínú yín: 27 Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe fi ààyè ẹ̀gbẹ́ kan fún Èṣù. 28 Kí ẹni tí ń jalè má ṣe jalè mọ́: ṣùgbọ́n kí ó kúkú máa ṣe làálàá, kí ó máa fi ọwọ́ rẹ̀ ṣiṣẹ́ ohun tí ó dára, kí òun lè ní láti pín fún ẹni tí ó ṣe aláìní.

29 Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ìdíbàjẹ́ kan ti ẹnu yín jáde, ṣùgbọ́n irú èyí tí ó lè ràn ìdàgbàsókè wọn lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí ohun tí wọ́n nílò, kí ó lè máa fi oore-ọ̀fẹ́ fún àwọn tí ń gbọ́. 30 Ẹ má sì ṣe mú Ẹ̀mí Mímọ́ Ọlọ́run bínú, ẹni tí a fi ṣe èdìdì yín dé ọjọ́ ìdáǹdè. 31 Gbogbo ìwà kíkorò àti ìbínú, àti ìrunú, àti ariwo, àti ọ̀rọ̀ búburú ni kí a mú kúrò lọ́dọ̀ yín, pẹ̀lú gbogbo àrankàn: 32 Ẹ máa ṣoore fún ọmọnìkejì yín, ẹ ní ìyọ́nú, ẹ máa dáríjì ara yín, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run nínú Kristi ti dáríjì yín.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.