Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 121

Orin fún ìgòkè.

121 Èmi yóò gbé ojú mi sórí òkè wọ̀n-ọn-nì—
    níbo ni ìrànlọ́wọ́ mi yóò ti wá
Ìrànlọ́wọ́ mi tí ọwọ́ Olúwa
    Ẹni tí ó dá ọ̀run òun ayé.

Òun kì yóò jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ kí ó yẹ̀;
    ẹni tí ó pa ọ́ mọ́ kì í tòògbé.
Kíyèsi, ẹni tí ń pa Israẹli mọ́,
    kì í tòògbé bẹ́ẹ̀ ni kì í sùn.

Olúwa ni olùpamọ́ rẹ;
    Olúwa ní òjìji rẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ
Oòrùn kì yóò pa ọ́ ní ìgbà ọ̀sán
    tàbí òṣùpá ní ìgbà òru.

Olúwa yóò pa ọ́ mọ́ kúrò nínú ibi gbogbo
    yóò pa ọkàn rẹ mọ́
Olúwa yóò pa àlọ àti ààbọ̀ rẹ mọ́
    láti ìgbà yìí lọ àti títí láéláé.

Mika 7:18-20

18 Ta ni Ọlọ́run bí rẹ̀,
    ẹni tí ó dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì,
    tí ó sì fojú fo ìrékọjá èyí tókù ìní rẹ̀?
Kì í dúró nínú ìbínú rẹ̀ láéláé
    nítorí òun ní inú dídùn sí àánú.
19 Òun yóò tún padà yọ́nú sí wa;
    òun yóò tẹ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa mọ́lẹ̀,
    yóò sì fa gbogbo àìṣedéédéé wa sínú ibú Òkun.
20 (A)Ìwọ yóò fi òtítọ́ hàn sí Jakọbu
    ìwọ yóò sì fi àánú hàn sí Abrahamu,
bí ìwọ ṣe búra fún àwọn baba wa
    láti ọjọ́ ìgbàanì.

Romu 3:21-31

Ìṣòdodo nípa ìgbàgbọ́

21 (A)Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, a ti fi òdodo Ọlọ́run hàn láìsí òfin, tí a ti ń jẹ́rìí sí nípa òfin àti nípa àwọn wòlíì; 22 (B)Àní òdodo Ọlọ́run nípa ìgbàgbọ́ nínú Jesu Kristi, sí gbogbo ènìyàn àti gbogbo àwọn tí ó gbàgbọ́: nítorí tí kò sí ìyàtọ̀ láàrín Júù àti Helleni. 23 (C)Gbogbo ènìyàn ni ó ṣá ti ṣẹ̀, tí wọ́n sì kùnà ògo Ọlọ́run: 24 (D)Àwọn ẹni tí a ń dá láre lọ́fẹ̀ẹ́ nípa oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀, nípa ìdáǹdè tí ó wà nínú Kristi Jesu: 25 Ẹni tí Ọlọ́run ti gbé kalẹ̀ láti jẹ́ ètùtù nípa ìgbàgbọ́ nípa ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, láti fi òdodo rẹ̀ hàn nítorí ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti kọjá, nínú ìpamọ́ra Ọlọ́run: 26 (E)Láti fi òdodo rẹ̀ hàn ní ìgbà ìsinsin yìí: kí ó lè jẹ́ olódodo àti olùdáláre ẹni tí ó gba Jesu gbọ́.

27 Ọ̀nà ìṣògo dà? A ti mú un kúrò. Nípa òfin wo? Nípa iṣẹ́? Bẹ́ẹ̀ kọ́: Ṣùgbọ́n nípa òfin ìgbàgbọ́. 28 (F)Nítorí náà a parí rẹ̀ sí pé nípa ìgbàgbọ́ ni a ń dá ènìyàn láre láìsí iṣẹ́ òfin. 29 (G)Ọlọ́run àwọn Júù nìkan ha ni bí? Kì í ha ṣe ti àwọn aláìkọlà pẹ̀lú? Bẹ́ẹ̀ ni, ti àwọn aláìkọlà pẹ̀lú: 30 (H)Bí ó ti jẹ́ pé Ọlọ́run kan ni, yóò dá àwọn akọlà láre nípa Ìgbàgbọ́ àti àwọn aláìkọlà nípa ìgbàgbọ́ wọn. 31 (I)Àwa ha ń sọ òfin dasán nípa ìgbàgbọ́ bí? Kí a má rí i: ṣùgbọ́n a ń fi òfin múlẹ̀.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.