Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 32

Ti Dafidi. Maskili.

32 (A)Ìbùkún ni fún àwọn
    tí a dárí ìrékọjá wọn jì,
    tí a sì bo ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́lẹ̀.
Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà
    ẹni tí Ọlọ́run kò ka ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ sí i lọ́rùn
    àti nínú ẹ̀mí ẹni tí kò sí ẹ̀tàn.

Nígbà tí mo dákẹ́,
    egungun mi di gbígbó dànù
    nípa ìkérora mi ní gbogbo ọjọ́.
Nítorí pé ni ọ̀sán àti ní òru
    ọwọ́ rẹ̀ wúwo sí mi lára;
agbára mi gbẹ tán
    gẹ́gẹ́ bí ooru ẹ̀ẹ̀rùn. Sela.

Èmi jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi sí ọ
    àti pé èmi kò sì fi àìṣòdodo mi pamọ́.
Èmi wí pé, “Èmi yóò jẹ́wọ́
    ẹ̀ṣẹ̀ mi fún Olúwa,”
ìwọ sì dárí
    ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí. Sela.

Nítorí náà jẹ́ kí gbogbo àwọn olódodo máa gbà àdúrà sí ọ
    ní ìgbà tí a lè rí ọ;
nítòótọ́ nígbà tí ìṣàn omi ńlá bá ru sókè,
    wọn kì yóò lè dé ọ̀dọ̀ rẹ̀.
Ìwọ ni ibi ìpamọ́ mi;
    ìwọ yóò pa mí mọ́ kúrò nínú ìyọnu;
    ìwọ yóò fi orin ìgbàlà yí mi ka. Sela.

Èmi yóò kọ́ ọ, èmi yóò sì fi ẹsẹ̀ rẹ lé ọ̀nà tí ìwọ yóò rìn
    èmi yóò máa gbà ọ́ ní ìyànjú, èmi yóò sì máa fi ojú mi tọ́ ọ.
Má ṣe dàbí ẹṣin tàbí ìbáaka,
    tí kò ní òye
ẹnu ẹni tí a gbọdọ̀ fi ìjánu bọ̀,
    kí wọn má ba à súnmọ́ ọ.
10 Ọ̀pọ̀ ìkáàánú ní yóò wà fún ènìyàn búburú,
    ṣùgbọ́n ìfẹ́ Olúwa tí ó dúró ṣinṣin
    ni yóò yí àwọn tí ó ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa ká.

11 Ẹ yọ̀ nínú Olúwa, kí ẹ sì ní inú dídùn, ẹ̀yìn olódodo;
    ẹ sì máa kọrin, gbogbo ẹ̀yìn tí àyà yín dúró ṣinṣin.

Eksodu 34:1-9

Òkúta wàláà tuntun

34 Olúwa sọ fún Mose pé, “E gé òkúta wàláà méjì jáde bí i ti àkọ́kọ́, èmi yóò sì kọ àwọn ọ̀rọ̀ ìwé tó wà lára tí àkọ́kọ́ tí ìwọ ti fọ́ sára wọn. Múra ní òwúrọ̀, kí o sì wá sórí òkè Sinai. Kí o fi ara rẹ hàn mí lórí òkè náà. Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ wá pẹ̀lú rẹ tàbí kí a rí wọn lórí òkè náà; bẹ́ẹ̀ ni agbo àgùntàn tàbí ọwọ́ ẹran kó má ṣe jẹ níwájú òkè náà.”

Bẹ́ẹ̀ Mose sì gbẹ́ òkúta wàláà méjì bí ti àkọ́kọ́, ó sì gun orí òkè Sinai lọ ní kùtùkùtù òwúrọ̀, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún un; Ó sì gbé òkúta wàláà méjèèjì náà sí ọwọ́ rẹ̀. Nígbà náà ni Olúwa sọ̀kalẹ̀ nínú àwọsánmọ̀, ó sì dúró níbẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, ó sì pòkìkí orúkọ Olúwa. (A)Ó sì kọjá níwájú Mose, ó sì ń ké pé, “Olúwa, Olúwa, Ọlọ́run aláàánú àti olóore-ọ̀fẹ́, ẹni tí ó lọ́ra láti bínú, tí ó pọ̀ ní ìfẹ́ àti olóòtítọ́, Ẹni tí ó ń pa ìfẹ́ mọ́ fún ẹgbẹ̀rún (1,000), ó sì ń dáríjì àwọn ẹni búburú, àwọn ti ń ṣọ̀tẹ̀ àti ẹlẹ́ṣẹ̀. Síbẹ̀ kì í fi àwọn ẹlẹ́bi sílẹ̀ láìjìyà; Ó ń fi ìyà jẹ ọmọ àti àwọn ọmọ wọn fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba dé ìran kẹta àti ẹ̀kẹrin.”

Mose foríbalẹ̀ lẹ́ẹ̀kan náà ó sì sìn. Ó wí pé, “Olúwa, bí èmi bá rí ojúrere rẹ, nígbà náà jẹ́ kí Olúwa lọ pẹ̀lú wa. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ènìyàn ọlọ́rùn líle ni wọn, dárí búburú àti ẹ̀ṣẹ̀ wa jì, kí o sì gbà wá gẹ́gẹ́ bí ìní rẹ.”

Eksodu 34:27-28

27 Olúwa sì wí fún Mose pé, “Kọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sílẹ̀, nítorí nípa àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni èmi bá ìwọ àti Israẹli dá májẹ̀mú.” 28 Mose wà níbẹ̀ pẹ̀lú Olúwa fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru (40) láìjẹ oúnjẹ tàbí mu omi. Ó sì kọ ọ̀rọ̀ májẹ̀mú náà òfin mẹ́wàá sára wàláà.

Matiu 18:10-14

Òwe àgùntàn tó sọnù

10 (A)“Ẹ rí i pé ẹ kò fi ojú tẹ́ńbẹ́lú ọ̀kan nínú àwọn kéékèèkéé wọ̀nyí. Lóòótọ́ ni mo wí fún yin pé, nígbà gbogbo ni ọ̀run ni àwọn angẹli ń wo ojú Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run. 11 Nítorí náà, Ọmọ ènìyàn wá láti gba àwọn tí ó nù là.

12 (B)“Kí ni ẹ̀yin rò? Bí ọkùnrin kan bá ni ọgọ́rùn-ún àgùntàn, tí ẹyọ kan nínú wọn sì sọnù, ṣé òun kì yóò fi mọ́kàn-dínlọ́gọ́rùn-ún (99) ìyókù sílẹ̀ sórí òkè láti lọ wá ẹyọ kan tó nù náà bí? 13 Ǹjẹ́ bí òun bá sì wá á rí i, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ǹjẹ́ ẹ̀yin kò mọ̀ pé inú rẹ̀ yóò dùn nítorí rẹ̀ ju àwọn mọ́kàn-dínlọ́gọ́rùn-ún tí kò nù lọ? 14 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ni kì í ṣe ìfẹ́ Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run, pé ọ̀kan nínú àwọn kékeré wọ̀nyí kí ó ṣègbé.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.