Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Eksodu 17:1-7

Omi láti inú àpáta

17 (A)Gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli si gbéra láti jáde kúrò láti aginjù Sini wọ́n ń lọ láti ibi kan de ibi kan gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ. Wọ́n pàgọ́ sí Refidimu, ṣùgbọ́n kò sí omi fún àwọn ènìyàn láti mú. Àwọn ènìyàn sì sọ̀ fún Mose, wọ́n wí pé, “Fún wa ni omi mu.”

Mose dá wọn lóhùn wí pé, “Èéṣe ti ẹ̀yin fi ń bá mi jà? Èéṣe ti ẹ̀yin fi ń dán Olúwa wò?”

(B)Ṣùgbọ́n òǹgbẹ ń gbẹ àwọn ènìyàn, wọ́n sì ń kùn sí Mose, wọ́n wí pé, “Èéṣe tí ìwọ fi mú wa jáde kúrò ní Ejibiti láti mú kí òǹgbẹ pa àwa, àwọn ọmọ wa àti ohun ọ̀sìn wa ku fún òǹgbẹ.”

Nígbà náà ni Mose gbé ohùn rẹ̀ sókè sí Olúwa pé; “Kí ni kí èmi kí ó ṣe fún àwọn ènìyàn yìí? Wọ́n múra tan láti sọ mi ni òkúta.”

Olúwa sì dá Mose lóhùn pé, “Máa lọ síwájú àwọn ènìyàn, mú nínú àwọn àgbàgbà Israẹli pẹ̀lú rẹ, mú ọ̀pá tí ìwọ fi lu odò Naili lọ́wọ́ kí ó sì máa lọ. Èmi yóò dúró ni ibẹ̀ dè ọ ni orí àpáta ni Horebu. Ìwọ ó sì lu àpáta, omi yóò sì jáde nínú rẹ̀ fún àwọn ènìyàn láti mu.” Mose sì ṣe bẹ́ẹ̀ ni iwájú àwọn àgbàgbà Israẹli. Ó sì sọ orúkọ ibẹ̀ ni Massa (ìdánwò) àti Meriba (kíkùn) nítorí àwọn ọmọ Israẹli sọ̀, wọ́n sì dán Olúwa wò, wọ́n wí pé, “Ǹjẹ́ Olúwa ń bẹ láàrín wa tàbí kò sí?”

Saamu 95

95 Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a kọ orin ayọ̀ sí Olúwa
    Ẹ jẹ́ kí a kígbe sókè sí àpáta ìgbàlà wa.
Ẹ jẹ́ kí a wá sí iwájú rẹ̀ pẹ̀lú ọpẹ́
    kí a sì pòkìkí rẹ̀ pẹ̀lú ohun èlò
    orin àti ìyìn.

Nítorí Olúwa Ọlọ́run títóbi ni,
    ọba tí ó tóbi ju gbogbo òrìṣà lọ.
Ní ọwọ́ rẹ̀ ni ọ̀gbun ilẹ̀ wà,
    ṣóńṣó orí òkè tirẹ̀ ní ṣe.
Tirẹ̀ ni Òkun, nítorí òun ni ó dá a
    àti ọwọ́ rẹ̀ ni ó fi dá ìyàngbẹ ilẹ̀.

Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a foríbalẹ̀ kí a sìn ín,
    Ẹ jẹ́ kí a kúnlẹ̀ níwájú
Olúwa ẹni tí ó dá wa;
(A)Nítorí òun ni Ọlọ́run wa
    àwa sì ni ènìyàn pápá rẹ̀,
àti ọ̀wọ́ ẹran ni abẹ́ ìpamọ́ rẹ̀.

    Lónìí tí ìwọ bá gbọ́ ohùn rẹ̀,
“Ẹ má ṣe sé ọkàn yín le gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ṣe ní Meriba,
    àti bí ẹ ti ṣe ní ọjọ́ náà ní Massa ní aginjù,
Nígbà tí àwọn baba yín dán mi wò
    tí wọn wádìí mi,
tí wọn sì rí iṣẹ́ mi
10 Fún ogójì ọdún ni èmi fi bínú sí ìran náà;
    mo wí pé, ‘Wọ́n jẹ́ ènìyàn tí ọkàn wọn ṣáko lọ
    wọn kò sì mọ ọ̀nà mi.’
11 Nítorí náà ni mo kéde ìbúra nínú ìbínú mi
    ‘Wọn kì yóò wọ ibi ìsinmi mi.’ ”

Romu 5:1-11

Àlàáfíà àti ayọ̀

(A)Nítorí náà, níwọ̀n ìgbà tí a ti dá wa láre nípa ìgbàgbọ́, àwa ní àlàáfíà lọ́dọ̀ Ọlọ́run nípasẹ̀ Olúwa wa Jesu Kristi. (B)Nípasẹ̀ ẹni tí àwa sì ti rí ọ̀nà gbà nípa ìgbàgbọ́ sí inú oore-ọ̀fẹ́ yìí nínú èyí tí àwa gbé dúró. Àwa sì ń yọ̀ nínú ìrètí ògo Ọlọ́run. (C)Kì í sì ṣe bẹ́ẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n àwa tún ń ṣògo nínú ìjìyà pẹ̀lú: bí a ti mọ̀ pé ìjìyà ń ṣiṣẹ́ sùúrù; àti pé sùúrù ń ṣiṣẹ́ ìwà rere; àti pé ìwà rere ń ṣiṣẹ́ ìrètí: (D)Ìrètí kì í sì í dójúti ni nítorí a ti dá ìfẹ́ Ọlọ́run sí wa lọ́kàn láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ tí a fi fún wa.

Nítorí ìgbà tí àwa jẹ́ aláìlera, ní àkókò tí ó yẹ, Kristi kú fún àwa aláìwà-bí-Ọlọ́run. Nítorí ó ṣọ̀wọ́n kí ẹnìkan tó kú fún olódodo: ṣùgbọ́n fún ènìyàn rere bóyá ẹlòmíràn tilẹ̀ lè dábàá láti kú. (E)Ṣùgbọ́n Ọlọ́run fi ìfẹ́ òun pàápàá sí wa hàn nínú èyí pé, nígbà tí àwa jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, Kristi kú fún wa.

(F)Mélòó mélòó sì ni tí a dá wa láre nísinsin yìí nípa ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ni a ó gbà wá là kúrò nínú ìbínú nípasẹ̀ rẹ̀. 10 (G)Ǹjẹ́, nígbà tí àwa wà ní ọ̀tá, a mú wa, ba Ọlọ́run làjà nípa ikú Ọmọ rẹ̀, mélòó mélòó, nígbà tí a là wá ní ìjà tan, ni a ó gbà wá là nípa ìyè rẹ̀. 11 (H)Kì sì í ṣe bẹ́ẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n àwa ń ṣògo nínú Ọlọ́run nípa Olúwa wa Jesu Kristi, nípasẹ̀ ẹni tí àwa ti rí ìlàjà gbà nísinsin yìí.

Johanu 4:5-42

(A)Nígbà náà ni ó dé ìlú Samaria kan, tí a ń pè ní Sikari, tí ó súnmọ́ etí ilẹ̀ oko tí Jakọbu ti fi fún Josẹfu, ọmọ rẹ̀. Kànga Jakọbu sì wà níbẹ̀. Nítorí pé ó rẹ Jesu nítorí ìrìn rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó jókòó létí kànga: ó sì jẹ́ ìwọ̀n wákàtí kẹfà ọjọ́.

Obìnrin kan, ará Samaria sì wá láti fà omi: Jesu wí fún un pé ṣe ìwọ yóò fún mi ni omi mu. Nítorí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ti lọ sí ìlú láti lọ ra oúnjẹ.

(B)Obìnrin ará Samaria náà sọ fún un pé, “Júù ni ìwọ, obìnrin ará Samaria ni èmi. Èétirí tí ìwọ ń béèrè ohun mímu lọ́wọ́ mi?” (Nítorí tí àwọn Júù kì í bá àwọn ará Samaria ṣe pọ̀.)

10 (C)Jesu dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Ìbá ṣe pé ìwọ mọ ẹ̀bùn Ọlọ́run, àti ẹni tí ó wí fún ọ pé, Fún mi ni omi mu, ìwọ ìbá sì ti béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, òun ìbá ti fi omi ìyè fún ọ.”

11 Obìnrin náà wí fún un pé, “Alàgbà, ìwọ kò ní igbá-ìfami tí ìwọ ó fi fà omi, bẹ́ẹ̀ ni kànga náà jì: Níbo ni ìwọ ó ti rí omi ìyè náà? 12 Ìwọ pọ̀ ju Jakọbu baba wa lọ bí, ẹni tí ó fún wa ní kànga náà, tí òun tìkára rẹ̀ si mu nínú rẹ̀, àti àwọn ọmọ rẹ̀, àti àwọn ẹran ọ̀sìn rẹ̀?”

13 Jesu dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá mu nínú omi yìí, òǹgbẹ yóò sì tún gbẹ ẹ́: 14 (D)Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá mu nínú omi tí èmi ó fi fún un, òǹgbẹ kì yóò gbẹ ẹ́ mọ́ láé; ṣùgbọ́n omi tí èmi ó fi fún un yóò di kànga omi nínú rẹ̀, tí yóò máa sun si ìyè àìnípẹ̀kun.”

15 (E)Obìnrin náà sì wí fún u pé, “Alàgbà, fún mi ní omi yìí, kí òǹgbẹ kí ó má ṣe gbẹ mí, kí èmi kí ó má sì wá fa omi níbí mọ́.”

16 Jesu wí fún un pé, “Lọ pe ọkọ rẹ, kí ó sì padà wá sí ìhín yìí.”

17 Obìnrin náà dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Èmi kò ní ọkọ.”

Jesu wí fún un pé, “Ìwọ́ dáhùn dáradára pé, èmi kò ní ọkọ: 18 (F)Nítorí tí ìwọ ti ní ọkọ márùn-ún rí; ọkùnrin tí ìwọ sì ní báyìí kì í ṣe ọkọ rẹ. Ohun tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ tán yìí, òtítọ́ ni.”

19 Obìnrin náà wí fún un pé, “Alàgbà, mo wòye pé, wòlíì ni ìwọ ń ṣe. 20 (G)Àwọn baba wa sìn lórí òkè yìí; ẹ̀yin sì wí pé, Jerusalẹmu ni ibi tí ó yẹ tí à bá ti máa sìn.”

21 (H)Jesu wí fún un pé, “Gbà mí gbọ́ obìnrin yìí, àkókò náà ń bọ̀, nígbà tí kì yóò ṣe lórí òkè yìí tàbí ní Jerusalẹmu ni ẹ̀yin ó máa sin Baba. 22 (I)Ẹ̀yin ń sin ohun tí ẹ̀yin kò mọ̀: àwa ń sin ohun tí àwa mọ̀: nítorí ìgbàlà ti ọ̀dọ̀ àwọn Júù wá. 23 Ṣùgbọ́n àkókò ń bọ̀, ó sì dé tán nísinsin yìí, nígbà tí àwọn olùsìn tòótọ́ yóò máa sin Baba ní Ẹ̀mí àti ní òtítọ́: nítorí irú wọn ni Baba ń wá kí ó máa sin òun. 24 (J)Ẹ̀mí ni Ọlọ́run: àwọn ẹni tí ń sìn ín kò lè ṣe aláìsìn ín ní Ẹ̀mí àti ní òtítọ́.”

25 Obìnrin náà wí fún un pé, mo mọ̀ pé, “Messia ń bọ̀ wá, tí a ń pè ní Kristi: Nígbà tí Òun bá dé, yóò sọ ohun gbogbo fún wa.”

26 (K)Jesu sọ ọ́ di mí mọ̀ fún un pé, “Èmi ẹni tí ń bá ọ sọ̀rọ̀ yìí ni Òun.”

Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn pẹ̀lú Jesu

27 Lákokò yí ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ dé, ẹnu sì yà wọ́n pé ó ń bá obìnrin sọ̀rọ̀: ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan tí ó wí pé, “Kí ni ìwọ ń wá?” tàbí “Èéṣe tí ìwọ fi ń bá a sọ̀rọ̀?”

28 Nígbà náà ni obìnrin náà fi ládugbó rẹ̀ sílẹ̀, ó sì mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n lọ sí ìlú, ó sì wí fún àwọn ènìyàn pé, 29 (L)“Ẹ wá wò ọkùnrin kan, ẹni tí ó sọ ohun gbogbo tí mo ti ṣe rí fún mi: èyí ha lè jẹ́ Kristi náà?” 30 Nígbà náà ni wọ́n ti ìlú jáde, wọ́n sì tọ̀ ọ́ wá.

31 Láàrín èyí, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ń rọ̀ ọ́ wí pé, “Rabbi, jẹun.”

32 (M)Ṣùgbọ́n ó wí fún wọn pé, “Èmi ní oúnjẹ láti jẹ, tí ẹ̀yin kò mọ̀.”

33 Nítorí náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ń bi ara wọn lérè wí pé, “Ẹnìkan mú oúnjẹ fún un wá láti jẹ bí?”

34 (N)Jesu wí fún wọn pé, “Oúnjẹ mi ni láti ṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi, àti láti parí iṣẹ́ rẹ̀. 35 (O)Ẹ̀yin kò ha wí pé, ‘Ó ku oṣù mẹ́rin, ìkórè yóò sì dé?’ Wò ó, mo wí fún un yín, Ẹ ṣí ojú yín sókè, kí ẹ sì wo oko; nítorí tí wọn ti pọ́n fún ìkórè. 36 Kódà báyìí, ẹni tí ó ń kórè ń gba owó ọ̀yà rẹ̀, ó si ń kó èso jọ sí ìyè àìnípẹ̀kun: kí ẹni tí ó ń fúnrúgbìn àti ẹni tí ń kórè lè jọ máa yọ̀ pọ̀. 37 (P)Nítorí nínú èyí ni ọ̀rọ̀ náà fi jẹ́ òtítọ́: Ẹnìkan ni ó fúnrúgbìn, ẹlòmíràn ni ó sì ń kórè jọ. 38 Mo rán yín lọ kórè ohun tí ẹ kò ṣiṣẹ́ fún. Àwọn ẹlòmíràn ti ṣiṣẹ́, ẹ̀yin sì kórè èrè làálàá wọn.”

Ọ̀pọ̀ ara Samaria gbàgbọ́

39 Ọ̀pọ̀ àwọn ará Samaria láti ìlú náà wá sì gbà á gbọ́ nítorí ìjẹ́rìí obìnrin náà pé, “Ó sọ gbogbo ohun tí mo ti ṣe fún mi.” 40 Nítorí náà, nígbà tí àwọn ará Samaria wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n rọ̀ ọ́ pé, kí ó wà pẹ̀lú wọn: ó sì dúró fún ọjọ́ méjì. 41 Àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì gbàgbọ́ sí i nítorí ọ̀rọ̀ rẹ̀.

42 (Q)Wọ́n sì wí fún obìnrin náà pé, “Kì í ṣe nítorí ọ̀rọ̀ rẹ nìkan ni àwa ṣe gbàgbọ́: nítorí tí àwa tìkára wa ti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, àwa sì mọ̀ pé, nítòótọ́ èyí ni Kristi náà, Olùgbàlà aráyé.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.