M’Cheyne Bible Reading Plan
Àwọn ọmọ Dafidi
3 (A)Àwọn wọ̀nyí sì ni ọmọ Dafidi tí a bí fún un ní Hebroni:
Àkọ́bí sì ni Amnoni ọmọ Ahinoamu ti Jesreeli;
èkejì sì ni Daniẹli ọmọ Abigaili ará Karmeli;
2 Ẹ̀kẹta sì ni Absalomu ọmọ Maaka ọmọbìnrin Talmai ọba Geṣuri bí fún un;
ẹ̀kẹrin sì ni Adonijah ọmọ Haggiti;
3 Ẹ̀karùnún ni Ṣefatia láti ọ̀dọ̀ Abitali;
àti ẹ̀kẹfà, Itreamu, láti ọ̀dọ̀ Egla aya rẹ̀.
4 (B)Àwọn mẹ́fà wọ̀nyí ni a bí fún Dafidi ni Hebroni, níbi tí ó ti jẹ ọba fún ọdún méje àti oṣù mẹ́fà.
Dafidi sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n (33). 5 Wọ̀nyí ni ọmọ wẹ́wẹ́ tí a bí fún un ní Jerusalẹmu:
Ṣimea, Ṣobabu, Natani àti Solomoni. Àwọn mẹ́rin wọ̀nyí sì ni a bí láti ọ̀dọ̀ Bati-Ṣua ọmọbìnrin Ammieli.
6 Ibhari sì wà pẹ̀lú, Eliṣama, Elifeleti, 7 Noga, Nefegi, Jafia, 8 Eliṣama, Eliada àti Elifeleti mẹ́sàn-án ni wọ́n.
9 Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Dafidi yàtọ̀ sí àwọn ọmọ tí àlè bí fún un. Tamari sì ni arábìnrin wọn.
Àwọn ọba Juda
10 Ọmọ Solomoni ni Rehoboamu,
Abijah ọmọ rẹ̀,
Asa ọmọ rẹ̀,
Jehoṣafati ọmọ rẹ̀,
11 Jehoramu ọmọ rẹ̀,
Ahasiah ọmọ rẹ̀,
Joaṣi ọmọ rẹ̀,
12 Amasiah ọmọ rẹ̀,
Asariah ọmọ rẹ̀,
Jotamu ọmọ rẹ̀,
13 Ahasi ọmọ rẹ̀,
Hesekiah ọmọ rẹ̀,
Manase ọmọ rẹ̀,
14 Amoni ọmọ rẹ̀,
Josiah ọmọ rẹ̀.
15 Àwọn ọmọ Josiah:
Àkọ́bí ọmọ rẹ̀ ni Johanani,
èkejì ọmọ rẹ̀ ni Jehoiakimu,
ẹ̀kẹta ọmọ rẹ̀ ni Sedekiah,
ẹ̀kẹrin ọmọ rẹ̀ ni Ṣallumu.
16 Àwọn ìran ọmọ Jehoiakimu:
Jekoniah ọmọ rẹ̀,
àti Sedekiah.
Ìdílé ọba lẹ́yìn ìgbèkùn
17 Àwọn ọmọ Jekoniah tí a mú ní ìgbèkùn:
Ṣealitieli ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, 18 Malkiramu, Pedaiah, Ṣenasari, Jekamiah, Hoṣama àti Nedabiah.
19 Àwọn ọmọ Pedaiah:
Serubbabeli àti Ṣimei.
Àwọn ọmọ Serubbabeli:
Meṣullamu àti Hananiah. Ṣelomiti ni arábìnrin wọn. 20 Àwọn márùn-ún mìíràn sì tún wà: Haṣuba, Oheli, Berekiah, Hasadiah àti Jusabhesedi.
21 Àwọn ọmọ Hananiah:
Pelatiah àti Jeṣaiah, àti àwọn ọmọ Refaiah, ti Arnani, ti Ọbadiah àti ti Ṣekaniah.
22 Àwọn ọmọ Ṣekaniah:
Ṣemaiah àti àwọn ọmọ rẹ̀: Hattusi, Igali, Bariah, Neariah àti Ṣafati, mẹ́fà ni gbogbo wọn.
23 Àwọn ọmọ Neariah:
Elioenai; Hesekiah, àti Asrikamu, mẹ́ta ni gbogbo wọn.
24 Àwọn ọmọ Elioenai:
Hodafiah, Eliaṣibu, Pelaiah, Akkubu, Johanani, Delaiah àti Anani, méje sì ni gbogbo wọn.
Ìran Juda
4 Àwọn ọmọ Juda:
Peresi, Hesroni, Karmi, Huri àti Ṣobali.
2 Reaiah ọmọ Ṣobali ni baba Jahati, àti Jahati baba Ahumai àti Lahadi. Àwọn wọ̀nyí ni ẹ̀yà ará Sorati.
3 Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Etamu:
Jesreeli, Iṣima, Idbaṣi, orúkọ arábìnrin wọn sì ni Haseleponi 4 Penueli sì ni baba Gedori, àti Eseri baba Huṣa.
Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Huri, àkọ́bí Efrata àti baba Bẹtilẹhẹmu.
5 Aṣihuri baba Tekoa sì ní aya méjì, Hela àti Naara.
6 Naara sì bí Ahussamu, Heferi Temeni àti Haaṣtari. Àwọn wọ̀nyí sì ni àwọn ọmọ Naara.
7 Àwọn ọmọ Hela:
Sereti Sohari, Etani, 8 Àti Kosi ẹni tí ó jẹ́ baba Anubu àti Sobeba àti ti àwọn ẹ̀yà Aharheli ọmọ Harumu.
9 Jabesi sì ní ọlá ju àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin lọ. Ìyá rẹ̀ sì sọ ọ́ ní Jabesi wí pé, “Mo bí i nínú ìpọ́njú.” 10 Jabesi sì kígbe sókè sí Ọlọ́run Israẹli wí pé, “Háà, Ìwọ yóò bùkún fún, ìwọ yóò sì mú agbègbè mi tóbi! Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ kí ó wà pẹ̀lú mi kí o sì pa mi mọ́ kúrò nínú ibi; kí èmi kí ó le ní ìdáǹdè kúrò nínú ìrora.” Ọlọ́run sì gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ rẹ̀.
11 Kelubu arákùnrin Ṣuha, sì jẹ́ baba Mehiri, ẹni tí ó jẹ́ baba Eṣtoni. 12 Eṣtoni sì jẹ́ baba Beti-Rafa, Pasea àti Tehina ti baba ìlú Nahaṣi. Àwọn wọ̀nyí ni ọkùnrin Reka.
13 Àwọn ọmọ Kenasi:
Otnieli àti Seraiah.
Àwọn ọmọ Otnieli:
Hatati àti Meonotai. 14 Meonotai sì ni baba Ofira.
Seraiah sì jẹ́ baba Joabu,
baba Geharaṣinu. A pè báyìí nítorí àwọn ènìyàn àwọn oníṣọ̀nà ní ìwọ̀n.
15 Àwọn ọmọ Kalebu ọmọ Jefunne:
Iru, Ela, àti Naamu.
Àwọn ọmọ Ela:
Kenasi.
16 Àwọn ọmọ Jehaleeli:
Sifi, àti Sifa, Tiria àti Asareeli.
17 Àwọn ọmọ Esra:
Jeteri, Meredi, Eferi àti Jaloni.
Ọ̀kan lára àwọn aya Meredi sì bí Miriamu, Ṣammai àti Iṣba baba Eṣitemoa.
18 Aya rẹ̀ láti ẹ̀yà Juda sì bí Jaredi baba Gedori, àti Heberi baba Soko àti Jekutieli baba Sanoa. Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ ọmọbìnrin Farao Bitia, ẹni ti Meredi ti fẹ́.
19 Àwọn ọmọ aya Hodiah arábìnrin Nahamu:
Baba Keila ará Garimu, àti Eṣitemoa àwọn ará Maakati.
20 Àwọn ọmọ Ṣimoni:
Amnoni, Rina, Beni-Hanani àti Tiloni.
Àwọn ọmọ Iṣi:
Soheti àti Beni-Soheti.
21 Àwọn ọmọ Ṣela ọmọ Juda:
Eri baba Leka, Lada baba Meraṣa àti àwọn ìdílé ilé àwọn tí ń hun aṣọ oníṣẹ́ ní Beti-Aṣibea.
22 Jokimu, ọkùnrin Koṣeba, àti Joaṣi àti Sarafi, olórí ní Moabu àti Jaṣubi Lehemu. (Àkọsílẹ̀ yìí sì wà láti ìgbà àtijọ́). 23 Àwọn sì ni amọ̀kòkò tí ń gbé ní Netaimu àti Gedera; wọ́n sì dúró níbẹ̀ wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ fún ọba.
Simeoni
24 (C)Àwọn Ọmọ Simeoni:
Nemueli, Jamini, Jaribi, Sera àti Saulu;
25 Ṣallumu sì jẹ́ ọmọ Saulu, Mibsamu ọmọ rẹ̀ Miṣima ọmọ rẹ̀.
26 Àwọn ọmọ Miṣima:
Hamueli ọmọ rẹ̀ Sakkuri ọmọ rẹ̀ àti Ṣimei ọmọ rẹ̀.
27 Ṣimei sì ní ọmọkùnrin mẹ́rìn-dínlógún àti ọmọbìnrin mẹ́fà, ṣùgbọ́n àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin kò ní ọmọ púpọ̀; Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìdílé wọn kò sì pọ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn Juda. 28 (D)Wọ́n sì ń gbé ní Beerṣeba, Molada, Hasari-Ṣuali, 29 Àti ní Biliha, àti ní Esemu, àti ní Toladi, 30 Betueli, Horma, Siklagi, 31 Beti-Markaboti Hormah; Hasari Susimu, Beti-Biri àti Ṣaraimi. Àwọn wọ̀nyí ni ìlú wọn títí di ìgbà ọba Dafidi, 32 agbègbè ìlú wọn ni Etamu, Aini, Rimoni, Tokeni, Aṣani àwọn ìlú márùn-ún, 33 àti gbogbo ìletò wọn, tí ó wà yí ìlú náà ká, dé Baali. Àwọn wọ̀nyí ni ibùgbé wọn.
Àti ìtàn ìdílé wọ́n.
34 Meṣobabu àti Jamleki,
Josa ọmọ Amasiah, 35 Joeli,
Jehu ọmọ Josibiah, ọmọ Seraiah, ọmọ Asieli,
36 àti pẹ̀lú Elioenai, Jaakoba, Jeṣohaiah,
Asaiah, Adieli, Jesimieli, Benaiah,
37 àti Sisa ọmọ Ṣifi ọmọ Alloni, ọmọ Jedaiah, ọmọ Ṣimri ọmọ Ṣemaiah.
38 Àwọn ọkùnrin tí a dárúkọ lókè yìí àwọn ni ìjòyè ìdílé wọn.
Àwọn ìdílé sì pọ̀ sí i gidigidi, 39 Wọ́n sì lọ sí ojú ọ̀nà Gedori. Lọ títí dé ìlà-oòrùn àfonífojì láti wá koríko fún àwọn agbo ẹran wọn 40 Wọ́n sì rí koríko tútù tí ó dára ilẹ̀ náà gbòòrò ó sì ní àlàáfíà ó sì gbé jẹ́. Àwọn ọmọ Hamu ni ó ti ń gbé ibẹ̀ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀.
41 Àwọn ọkùnrin tí a kọ orúkọ rẹ̀ sókè, dé ní ọjọ́ Hesekiah ọba Juda. Wọ́n sì kọlu àwọn ará Hamu ní àgọ́ wọn àti pẹ̀lú àwọn ará Mehuni tí a rí níbẹ̀ tí ó sì pa wọ́n run pátápátá títí di òní yìí. Wọ́n sì ń gbé ní ipò wọn, nítorí pé koríko ń bẹ níbẹ̀ fún agbo ẹran wọn. 42 Ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta nínú àwọn ará Simeoni, lábẹ́ ìdarí pẹ̀lú Pelatiah, Neariah, Refaiah àti Usieli, àwọn ọmọ Iṣi, gbógun sí àwọn òkè ìlú ti Seiri. 43 Wọ́n sì pa àwọn ará Amaleki tí ó kù, àwọn tí ó ti sálà, wọ́n sì ti ń gbé ibẹ̀ títí di òní yìí.
Ìsìn nínú àgọ́ ayé yìí
9 (A)Bẹ́ẹ̀ ni májẹ̀mú àkọ́kọ́ ní ìlànà fún ìsìn àti ibi mímọ́ ti ayé yìí. 2 (B)A gbé àgọ́ kan dìde. Nínú yàrá rẹ̀ àkọ́kọ́ ni a ti rí ọ̀pá fìtílà, tábìlì, àti àkàrà ìfihàn. Èyí tí a ń pè ní ibi mímọ́. 3 (C)Àti lẹ́yìn aṣọ ìkélé kejì, òun ni àgọ́ tí à ń pè ní ibi mímọ́ jùlọ; 4 (D)tí ó ní àwo tùràrí wúrà, àti àpótí ẹ̀rí tí a fi wúrà bò yíká, nínú èyí tí ìkòkò wúrà tí ó ní manna gbé wà, àti ọ̀pá Aaroni tí o rúdí, àti àwọn wàláà májẹ̀mú; 5 àti lórí àpótí ni àwọn kérúbù ògo ti i ṣíji bo ìtẹ́ àánú; èyí tí a kò lè sọ̀rọ̀ rẹ̀ nísinsin yìí lọ́kọ̀ọ̀kan.
6 Ǹjẹ́ nígbà tí a ti ṣe ètò nǹkan wọ̀nyí báyìí, àwọn àlùfáà a máa lọ nígbàkúgbà sínú àgọ́ èkínní, wọn a máa ṣe iṣẹ́ ìsìn. 7 (E)Ṣùgbọ́n sínú èkejì ni olórí àlùfáà nìkan máa ń lọ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo lọ́dún, fún ara rẹ̀, àti fún ìṣìnà àwọn ènìyàn. 8 Ẹ̀mí mímọ́ ń tọ́ka èyí pé a kò ì tí ì ṣí ọ̀nà ibi mímọ́ sílẹ̀ níwọ̀n ìgbà tí àgọ́ èkínní bá sì dúró, 9 (Èyí tí i ṣe àpẹẹrẹ fún ìgbà ìsinsin yìí). Gẹ́gẹ́ bí ètò yìí, a ń mú ẹ̀bùn àti ẹbọ wá, tí kò lè mú ẹ̀rí ọkàn olùsìn di pípé, 10 Èyí sì wà nínú ohun jíjẹ àti ohun mímu àti onírúurú ìwẹ̀, tí í ṣe ìlànà ti ara nìkan tí a fi lélẹ̀ títí fi di ìgbà àtúnṣe.
Ẹ̀jẹ̀ ti Kristi
11 Ṣùgbọ́n nígbà tí Kristi dé bí olórí àlùfáà àwọn ohun rere tí ń bọ̀, nípasẹ̀ àgọ́ tí o tóbi ti ó sì pé ju ti ìṣáájú, (èyí tí a kò fi ọwọ́ dá, èyí yìí ni, tí kì í ṣe ti ẹ̀dá yìí), 12 Bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́ àti ọmọ màlúù, ṣùgbọ́n nípa ẹ̀jẹ̀ òun tìkára rẹ̀, o wọ ibi mímọ́ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, lẹ́yìn tí ó ti rí ìdáǹdè àìnípẹ̀kun gbà fún wa. 13 (F)Nítorí bí ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́ àti ti akọ màlúù àti eérú ẹgbọrọ abo màlúù tí a fi wọ́n àwọn tí a ti sọ di aláìmọ́ ba ń sọ ni di mímọ́ fún ìwẹ̀nùmọ́ ara: 14 mélòó mélòó ni ẹ̀jẹ̀ Kristi, ẹni, nípa Ẹ̀mí ayérayé, tí ó fi ara rẹ̀ rú ẹbọ sí Ọlọ́run láìní àbàwọ́n, yóò wẹ èérí ọkàn yín nù kúrò nínú òkú iṣẹ́ láti sin Ọlọ́run alààyè?
15 Àti nítorí èyí ni ó ṣe jẹ́ alárinà májẹ̀mú tuntun pé bí ikú ti ń bẹ fún ìdáǹdè àwọn ìrékọjá ti o tí wà lábẹ́ májẹ̀mú ìṣáájú, kí àwọn tí a ti pè lè rí ìlérí ogún àìnípẹ̀kun gbà.
16 Nítorí níbi tí ìwé ogún bá gbé wà, ikú ẹni tí o ṣe é kò lè ṣe àìsí pẹ̀lú; 17 nítorí ìwé ogún ní agbára lẹ́yìn ìgbà tí ènìyàn bá kú: Nítorí kò ní agbára rárá nígbà tí ẹni tí o ṣè e bá ń bẹ láààyè. 18 Nítorí náà ni a kò ṣe ya májẹ̀mú ìṣáájú pàápàá sí mímọ́ láìsí ẹ̀jẹ̀. 19 (G)Nítorí nígbà tí Mose ti sọ gbogbo àṣẹ nípa ti òfin fún gbogbo àwọn ènìyàn, ó mú ẹ̀jẹ̀ ọmọ màlúù àti ti ewúrẹ́, pẹ̀lú omi, àti òwú òdòdó, àti ewé hísópù ó sì fi wọ́n àti ìwé pàápàá àti gbogbo ènìyàn. 20 Wí pé, “Èyí ní ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú tí Ọlọ́run pàṣẹ fún yín.” 21 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ó sì fi ẹ̀jẹ̀ wọ́n àgọ́, àti gbogbo ohun èlò ìsìn. 22 Ó sì fẹ́rẹ̀ jẹ́ ohun gbogbo ni a fi ẹ̀jẹ̀ wẹ̀nù gẹ́gẹ́ bí òfin; àti pé láìsí ìtàjẹ̀ sílẹ̀ kò sí ìdáríjì.
23 Nítorí náà a kò lè ṣàì fi ìwọ̀nyí wé àwọn àpẹẹrẹ ohun tí ń bẹ lọ́run mọ́; ṣùgbọ́n ó yẹ kí a fi ẹbọ tí ó sàn ju ìwọ̀nyí lọ wẹ àwọn ohun ọ̀run pàápàá mọ́; ṣùgbọ́n ó yẹ kí a fi ẹbọ tí ó sàn ju ìwọ̀nyí lọ wẹ àwọn ohun ọ̀run pàápàá mọ́. 24 Nítorí Kristi kò wọ ibi mímọ́ tí a fi ọwọ́ ṣe lọ tí i ṣe àpẹẹrẹ ti òtítọ́; ṣùgbọ́n ó lọ sí ọ̀run pàápàá, nísinsin yìí láti farahàn ní iwájú Ọlọ́run fún wa: 25 Kì í sí i ṣe pé kí ó lè máa fi ara rẹ̀ rú ẹbọ nígbàkúgbà, bí olórí àlùfáà tí máa ń wọ inú ibi mímọ́ lọ lọ́dọọdún ti òun pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ ti kì í ṣe tirẹ̀; 26 bí bẹ́ẹ̀ bá ni òun ìbá tí máa jìyà nígbàkúgbà láti ìpìlẹ̀ ayé: Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ni ó fi ara hàn lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo lópin ayé láti mu ẹ̀ṣẹ̀ kúrò nípa ẹbọ ara rẹ̀. 27 Níwọ́n bí a sì ti fi lélẹ̀ fún gbogbo ènìyàn láti kú lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, ṣùgbọ́n lẹ́yìn èyí ìdájọ́: 28 Bẹ́ẹ̀ ni Kristi pẹ̀lú lẹ́yìn tí a ti fi rú ẹbọ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láti ru ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀, yóò farahàn ní ìgbà kejì láìsí ẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn tí n wo ọ̀nà rẹ̀ fún ìgbàlà.
Ẹ̀rí jíjẹ́ nípa àwọn ọmọ Israẹli
3 Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run ti sọ nípa rẹ̀, ẹ̀yin ènìyàn Israẹli nípa àwọn ìdílé tí mo mú jáde láti Ejibiti:
2 “Ìwọ nìkan ni ẹni tí mo yàn
nínú gbogbo àwọn ìran ayé yìí;
nígbà náà èmi ó jẹ ọ́ ní yà
fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ.”
3 Ẹni méjì ha à le rìn pọ̀
láìjẹ́ pé wọ́n ti pinnu láti ṣe bẹ?
4 Ǹjẹ́ Kìnnìún yóò ha bú ramúramù nínú igbó,
bí kò bá ní ohun ọdẹ?
Ọmọ kìnnìún yóò ha ké jáde nínú ìhó rẹ̀
bí kò bá rí ohun kan mú?
5 Ǹjẹ́ ẹyẹ ṣubú sínú okùn ọdẹ lórí ilẹ̀
nígbà tí a kò dẹ okùn ọdẹ fún un?
Okùn ọdẹ ha lè hù jáde lórí ilẹ̀
nígbà tí kò sí ohun tí yóò mú?
6 Nígbà tí ìpè bá dún ní ìlú,
àwọn ènìyàn kò ha bẹ̀rù?
Tí ewu bá wa lórí ìlú
kò ha ṣe Olúwa ni ó fà á?
7 (A)Nítòótọ́ Olúwa Olódùmarè kò ṣe ohun kan
láìfi èrò rẹ̀ hàn
fun àwọn wòlíì ìránṣẹ́ rẹ̀.
8 Kìnnìún ti bú ramúramù
ta ni kì yóò bẹ̀rù?
Olúwa Olódùmarè ti sọ̀rọ̀
ta ni le ṣe àìsọ àsọtẹ́lẹ̀?
9 Ẹ kéde ní ààfin Aṣdodu
àti ní ààfin ní ilẹ̀ Ejibiti.
“Ẹ kó ara yín jọ sí orí òkè ńlá Samaria;
Kí ẹ sì wo ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ńlá láàrín rẹ̀
àti ìnilára láàrín àwọn ènìyàn rẹ.”
10 “Wọn kò mọ bí wọ́n ṣe ń ṣe rere,” ni Olúwa wí,
“àwọn ẹni tí ó gba àwọn ìwà ipá àti olè sí ààfin rẹ̀.”
11 Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí:
“Àwọn ọ̀tá yóò pa ilẹ̀ náà run;
yóò wó ibi gíga yín palẹ̀
a ó sì ba ààfin rẹ̀ jẹ́.”
12 Èyí ni ohun tí Olúwa wí:
“Bí olusọ-àgùntan ti ń gbà itan méjì
kúrò ní ẹnu kìnnìún tàbí ẹ̀là etí kan
bẹ́ẹ̀ ni a ó mú àwọn ọmọ Israẹli,
tí ń gbé Samaria kúrò
ní igun ibùsùn wọn
ní orí àga ìrọ̀gbọ̀kú wọn ní Damasku.”
13 “Gbọ́ èyí kí o sì jẹ́rìí nípa ilé Jakọbu,” ni Olúwa wí, Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun.
14 “Ní ọjọ́ tí mo fìyà jẹ Israẹli lórí ẹ̀ṣẹ̀ wọn,
Èmi yóò pa pẹpẹ Beteli run;
ìwo pẹpẹ ni a ó ké kúrò
yóò sì wó lulẹ̀.
15 Èmi yóò wó ilé òtútù
lulẹ̀ pẹ̀lú ilé ooru;
ilé tí a fi eyín erin ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ yóò ṣègbé
a ó sì pa ilé ńlá náà run,”
ni Olúwa wí.
146 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
Fi ìyìn fún Olúwa, ìwọ ọkàn mi.
2 Èmi yóò yin Olúwa ní gbogbo ayé mi;
Èmi yóò kọrin ìyìn sí Ọlọ́run, níwọ̀n ìgbà tí mo bá wà láààyè.
3 Ẹ má ṣe ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú àwọn ọmọ-aládé,
àní, ọmọ ènìyàn,
lọ́wọ́ ẹni tí kò sí ìrànlọ́wọ́.
4 Ẹ̀mí rẹ jáde lọ, ó padà sí erùpẹ̀:
Ní ọjọ́ náà gan, èrò wọn yóò di òfo:
5 Ìbùkún ni fún ẹni tí
Ọlọ́run Jakọbu ń ṣe ìrànlọ́wọ́ rẹ̀
tí ìrètí rẹ̀ wà nínú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀.
6 Ẹni tí ó dá ọ̀run àti ayé,
òkun àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú wọn,
ẹni tí ó pa òtítọ́ mọ́ títí ayé.
7 Ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ àwọn tí a ni lára
tí ó fi oúnjẹ fún àwọn tí ebi ń pa
Olúwa, tú àwọn oǹdè sílẹ̀ (ẹlẹ́wọ̀n)
8 Olúwa mú àwọn afọ́jú ríran,
Olúwa, gbé àwọn tí a rẹ̀ sílẹ̀ ga,
Olúwa fẹ́ràn àwọn olódodo.
9 Olúwa ń dá ààbò bo àwọn àlejò
ó sì ń dá àwọn aláìní baba àti opó sí
ṣùgbọ́n ó ba ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú jẹ́.
10 Olúwa jẹ ọba títí láé;
Ọlọ́run rẹ, ìwọ Sioni, àti fún gbogbo ìran.
Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
147 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
Nítorí ohun rere ni láti máa kọrin ìyìn sí Ọlọ́run wa,
ó yẹ láti kọrin ìyìn sí i!
2 Olúwa kọ́ Jerusalẹmu;
Ó kó àwọn Israẹli tí a lé sọnù jọ.
3 Ó wo àwọn tí ọkàn wọ́n bàjẹ́ sàn
ó sì di ọgbẹ́ wọ́n.
4 Ó ka iye àwọn ìràwọ̀
ó sì pe ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní orúkọ
5 Títóbi ni Olúwa wa ó sì pọ̀ ní agbára
òye rẹ̀ kò sì ní òpin.
6 Olúwa wa pẹ̀lú àwọn onírẹ̀lẹ̀
bẹ́ẹ̀ ni ó rẹ̀ àwọn ènìyàn búburú sílẹ̀.
7 Fi ọpẹ́ kọrin sí Olúwa
fi ohun èlò orin olókùn yin Ọlọ́run.
8 Ó fi ìkùùkuu bo àwọ̀ sánmọ̀
ó rọ òjò sí orílẹ̀ ayé
ó mú kí koríko hù lórí àwọn òkè
9 Ó pèsè oúnjẹ fún àwọn ẹranko
àti fún àwọn ọmọ ẹyẹ ìwò ní ìgbà tí wọ́n bá ń ké.
10 Òun kò ní inú dídùn nínú agbára ẹṣin
bẹ́ẹ̀ ni Òun kò ní ayọ̀ sí ẹ̀ṣẹ̀ ọkùnrin
11 Olúwa ni ayọ̀ nínú àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,
sí àwọn tí ó ní ìrètí nínú àánú rẹ̀.
12 Yin Olúwa, ìwọ Jerusalẹmu
yin Ọlọ́run rẹ, ìwọ Sioni.
13 Nítorí tí ó ti mú ọ̀pá ìdábùú ibodè rẹ̀ lágbára;
Òun sì ti bùkún fún àwọn ọmọ rẹ̀ nínú rẹ
14 Òun jẹ́ kí àlàáfíà wà ní àwọn ẹnu ibodè rẹ̀
òun sì fi jéró dáradára tẹ́ ọ lọ́rùn.
15 Òun sì rán àṣẹ rẹ̀ sí ayé
ọ̀rọ̀ rẹ̀ sáré tete.
16 Ó fi yìnyín fún ni bi irun àgùntàn
ó sì fọ́n ìrì dídì ká bí eérú
17 Ó rọ òjò yìnyín rẹ̀ bí òkúta wẹ́wẹ́
ta ni ó lè dúró níwájú òtútù rẹ̀
18 Ó rán ọ̀rọ̀ rẹ̀ jáde ó sì mú wọn yọ̀
ó mú kí afẹ́fẹ́ rẹ̀ fẹ́
ó sì mú odò rẹ̀ sàn.
19 Ó sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ di mí mọ̀ fún Jakọbu
àwọn òfin àti ìlànà rẹ̀ fún Israẹli
20 Òun kó tí ṣe irú èyí sí orílẹ̀-èdè kan rí, Bí ó ṣe ti ìdájọ́ rẹ̀
wọn ko mọ òfin rẹ̀.
Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.