Add parallel Print Page Options

Ìpohùnréré ẹkún fún Ejibiti

30 Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá: wí pé: “Ọmọ ènìyàn, sọtẹ́lẹ̀ kí o sì wí pé: ‘Báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí:

“ ‘Hu, kí o sì wí pé,
    “Ó ṣe fún ọjọ́ náà!”
Nítorí ọjọ́ náà súnmọ́ tòsí
    àní ọjọ́ Olúwa súnmọ́ tòsí
Ọjọ́ tí ọjọ́ ìkùùkuu ṣú dúdú,
    àsìkò ìparun fún àwọn kèfèrí.
Idà yóò wá sórí Ejibiti
    ìrora ńlá yóò sì wá sórí Kuṣi
Nígbà tí àwọn tí a pa yóò ṣubú ní Ejibiti
    wọn yóò kò ọrọ̀ rẹ̀ lọ
    ìpìlẹ̀ rẹ̀ yóò sì wó lulẹ̀.

Kuṣi àti Puti, Libia, Ludi àti gbogbo Arabia, Kubu àti àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà tí ó mulẹ̀ yóò ṣubú nípa idà pẹ̀lú Ejibiti.

Read full chapter

32 “ ‘Ìwọ alágbèrè aya! Ìwọ fẹ́ràn ọkùnrin àjèjì ju ọkọ rẹ lọ! 33 Àwọn ọkùnrin máa ń sanwó fún àwọn panṣágà ni ṣùgbọ́n ìwọ lo tún ń sanwó fun wọn, tí ó tún ń fún àwọn olólùfẹ́ rẹ lẹ́bùn àti owó ẹ̀yìn kí wọn bá à le máa wá ọ wá láti gbogbo agbègbè fún àgbèrè ṣíṣe.

Read full chapter

(A)Ó sì ṣe ní ọjọ́ kejì Mose wọ inú àgọ́ ẹ̀rí lọ, ó sì rí ọ̀pá Aaroni, tí ó dúró fún ẹ̀yà Lefi, kì í ṣe wí pé ó hù nìkan Ṣùgbọ́n ó rúwé, ó yọ ìtànná, ó sì so èso almondi. Nígbà náà ni Mose kó gbogbo àwọn ọ̀pá jáde láti iwájú Olúwa wá fún àwọn ọmọ Israẹli. Wọ́n wò wọ́n, ẹnìkọ̀ọ̀kan sì mú ọ̀pá tirẹ̀.

10 Olúwa sọ fún Mose pé, “Mú ọ̀pá Aaroni padà wá síwájú ẹ̀rí, láti fi pamọ́ gẹ́gẹ́ bí ààmì fún àwọn ọlọ̀tẹ̀. Èyí ó sì mú òpin bá kíkùn sínú wọn sí mi, kí wọn kí ó má ba à kú.”

Read full chapter