Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

M’Cheyne Bible Reading Plan

The classic M'Cheyne plan--read the Old Testament, New Testament, and Psalms or Gospels every day.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
1 Kronika 29

Ẹ̀bùn fún kíkọ́ ilé Olúwa

29 Nígbà náà, ọba Dafidi sọ fún gbogbo àpéjọ pé: “Ọmọ mi Solomoni, èyí tí Ọlọ́run ti yàn, sì kéré ó sì jẹ́ aláìmòye. Iṣẹ́ náà tóbi, nítorí ìkọ́lé bí ti ààfin kì í ṣe fún ènìyàn ṣùgbọ́n fún Olúwa Ọlọ́run. Pẹ̀lú gbogbo ìrànlọ́wọ́ mi èmi ti pèsè fún ilé Ọlọ́run mi wúrà fún iṣẹ́ wúrà, fàdákà fún ti fàdákà, idẹ fún ti idẹ, irin fún ti irin àti igi fún ti igi àti òkúta oníyebíye fún títọ́ rẹ̀, òkúta lóríṣìíríṣìí, àwọ̀ àti oríṣìíríṣìí ẹ̀yà òkúta àti òkúta dáradára kan gbogbo wọ̀nyí ní iye púpọ̀. Yàtọ̀ fún èyí, nínú ìfọkànsìn mi sí ilé Ọlọ́run mi, èmí fi ìṣúra mi tìkára mi ti wúrà àti fàdákà fún ilé Ọlọ́run mi. Jù gbogbo rẹ̀ lọ, èmi ti pèsè fún ilé mímọ́ ti Olúwa yìí: Ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) tálẹ́ǹtì wúrà, ti wúrà ofiri àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (7,000) tálẹ́ǹtì fàdákà dídára, fún bíbo àwọn ògiri ilé náà. Fún iṣẹ́ wúrà àti fàdákà náà, àti fún oríṣìí iṣẹ́ ti ó yẹ ní ṣíṣe nípasẹ̀ àwọn tí ó ní òye oríṣìíríṣìí iṣẹ́. Nísinsin yìí, ta ni ó ní ìfẹ́ sí yíya ará rẹ̀ sọ́tọ̀ lónìí sí Olúwa?”

Nígbà náà àwọn aṣáájú àwọn ìdílé, àwọn ìjòyè àwọn ẹ̀yà Israẹli, àwọn alákòóso ẹgbẹgbẹ̀wàá àti alákòóso ọ̀rọ̀ọ̀rún àti àwọn oníṣẹ́ tí ó wà ní ìdí iṣẹ́ ọba ní ìfẹ́ sí i. Wọ́n fi sílẹ̀ fún iṣẹ́ lórí ilé Ọlọ́run, ẹgbẹ̀rún márùn-ún tálẹ́ǹtì àti ẹgbẹ̀rin mẹ́wàá wúrà, ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá tálẹ́ǹtì fàdákà, ẹgbẹ̀rin méjì-dínlógún tálẹ́ǹtì idẹ àti ọgọ́rin ẹgbẹ̀rin tálẹ́ǹtì irin. Ẹnikẹ́ni tí ó ní òkúta iyebíye fi wọn sí ilé ìṣúra ilé Ọlọ́run ní abẹ́ ìtọ́jú Jehieli ará Gerṣoni. Àwọn ènìyàn láyọ̀ nínú ìṣesí àtọkànwá fi sílẹ̀ àwọn olórí wọn, nítorí tí wọ́n ti fi sílẹ̀ ní ọ̀fẹ́ pẹ̀lú gbogbo ọkàn sí Olúwa. Dafidi ọba pẹ̀lú yọ̀ gidigidi.

Àdúrà Dafidi

10 Dafidi yin Olúwa níwájú gbogbo àwọn tí ó péjọ, wí pé,

“Ìyìn ni fún Ọ, Olúwa,
    Ọlọ́run baba a wa Israẹli,
    láé àti láéláé.
11 Tìrẹ Olúwa ni títóbi àti agbára pẹ̀lú ìyìn
    àti ọláńlá àti dídán,
    nítorí tí gbogbo nǹkan ní ọ̀run àti ayé jẹ́ tìrẹ.
Tìrẹ Olúwa ni ìjọba;
    a gbé ọ ga gẹ́gẹ́ bí orí lórí ohun gbogbo.
12 Ọlá àti ọ̀wọ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Rẹ;
    ìwọ ni alákòóso gbogbo nǹkan.
Ní ọwọ́ rẹ ni ipá àti agbára wà láti gbéga àti
    láti fi agbára fún ohun gbogbo.
13 Nísinsin yìí, Ọlọ́run wa, àwa fi ọpẹ́ fún Ọ,
    a sì fi ìyìn fún orúkọ rẹ̀ tí ó lógo.

14 “Ṣùgbọ́n ta ni èmi, àti ta ni àwọn ènìyàn mi, tí a fi lè ṣe ìrànlọ́wọ́ tinútinú bí irú èyí? Gbogbo nǹkan wá láti ọ̀dọ̀ rẹ ní ti wá, àwa sì ti fífún ọ láti ara ohun tí ó wá láti ọwọ́ rẹ. 15 Àwa jẹ́ àjèjì àti àlejò ní ojú rẹ gẹ́gẹ́ bí baba ńlá a wa, àwọn ọjọ́ wa lórí ilẹ̀ ayé rí bí òjìji láìsí ìrètí. 16 Olúwa Ọlọ́run wa tí fi gbogbo púpọ̀ yìí tí àwa ti pèsè fún kíkọ́ ilé Olúwa fun orúkọ, mímọ́ rẹ̀, ó wá láti ọwọ́ ọ̀ rẹ, gbogbo rẹ̀ sì jẹ́ tirẹ̀. 17 Èmi mọ̀ Ọlọ́run mi, wí pé ìwọ̀ dán ọkàn wò, ó sì tẹ́ ọ lọ́rùn pẹ̀lú òtítọ́ inú. Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni èmi ti fi sílẹ̀ pẹ̀lú tìfẹ́tìfẹ́ pẹ̀lú òtítọ́. Nísinsin yìí èmi ti rí i pẹ̀lú ayọ̀ bí àwọn ènìyàn yìí tí ó wà níbí ti fi fún ọ pẹ̀lú tìfẹ́tìfẹ́. 18 Olúwa Ọlọ́run àwọn baba a wa Abrahamu, Isaaki àti Israẹli pa ìfẹ́ yìí mọ́ nínú ọkàn àwọn ènìyàn rẹ títí láé pẹ̀lú pípa ọkàn mọ́ lóòtítọ́ sí ọ. 19 Àti fún ọmọ mi Solomoni ní ìfọkànsìn tòótọ́ láti pa àṣẹ rẹ mọ́ àwọn ohun tí ó nílò àti òfin àti láti ṣe ohun gbogbo láti kọ́ ààfin bí ti ọba fún èyí tí mo ti pèsè.”

20 Dafidi sì sọ fún gbogbo ìjọ ènìyàn pé, Nísinsin yìí, ẹ fi ìyìn fún Olúwa Ọlọ́run yín. Gbogbo ènìyàn sì fi ìyìn fún Olúwa Ọlọ́run àwọn baba wọn, wọ́n sì tẹ orí wọn ba, wọ́n wólẹ̀ fún Olúwa àti ọba.

A yan Solomoni gẹ́gẹ́ bí ọba

21 Ni ọjọ́ kejì, wọ́n rú ẹbọ sí Olúwa, wọ́n sì rú ẹbọ sísun sí i: ẹgbẹ̀rún kan akọ màlúù, ẹgbẹ̀rin kan àgbò, àti ẹgbẹ̀rin kan akọ ọ̀dọ́-àgùntàn. Lápapọ̀ pẹ̀lú ọrẹ mímu àti àwọn ẹbọ mìíràn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ fún gbogbo Israẹli. 22 Wọ́n jẹ wọ́n sì mu pẹ̀lú ayọ̀ kíkún ní iwájú Olúwa ní ọjọ́ náà.

Nígbà náà wọ́n yan Solomoni ọmọ Dafidi gẹ́gẹ́ bí ọba lẹ́ẹ̀kejì wọ́n fi ààmì òróró yàn án níwájú Olúwa láti ṣe olórí àti Sadoku láti ṣe àlùfáà. 23 (A)Bẹ́ẹ̀ ni Solomoni jókòó lórí ìtẹ́ Olúwa gẹ́gẹ́ bí ọba ní ipò baba a rẹ̀ Dafidi. O ṣe àṣeyọrí, gbogbo Israẹli sì gbọ́rọ̀ sí i lẹ́nu. 24 Gbogbo àwọn ìjòyè àti àwọn ọkùnrin alágbára, pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ ọba Dafidi tẹrí ara wọn ba fún ọba Solomoni.

25 Olúwa gbé Solomoni ga púpọ̀ ní ojú gbogbo Israẹli, ó sì kẹ́ ẹ ní ìkẹ́ ọláńlá, ní irú èyí tí a kò kẹ́ ọba kankan ṣáájú rẹ̀ tí ó jẹ lórí Israẹli.

Ikú Dafidi

26 Dafidi ọmọ Jese jẹ́ ọba lórí gbogbo Israẹli. 27 Ó jẹ ọba lórí Israẹli fún ogójì ọdún; ọdún méje ni ó jẹ ọba ní Hebroni, ó sì jẹ ọba ní ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n ní Jerusalẹmu. 28 Òun sì darúgbó, ó sì kú ikú rere, ó gbádùn ẹ̀mí gígùn, ọlá àti ọrọ̀. Solomoni ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

29 Ní ti ohun tí ó ṣẹlẹ̀ nígbà ìjọba ọba Dafidi, láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin, a kọ wọ́n sínú ìwé ìrántí ti Samuẹli aríran, ìwé ìrántí ti Natani wòlíì àti ìwé ìrántí ti Gadi aríran, 30 lápapọ̀, pẹ̀lú gbogbo ìjọba àti agbára rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìgbà tí ó kọjá lórí rẹ̀, àti lórí Israẹli, àti lórí gbogbo àwọn ìjọba gbogbo ilẹ̀ náà.

2 Peteru 3

Ọjọ́ Olúwa

Olùfẹ́, èyí ni ìwé kejì tí mo ń kọ sí yín, nínú méjèèjì náà ni èmi ń ru èrò inú yín sókè nípa rírán yín létí; kí ẹ̀yin lè máa rántí ọ̀rọ̀ tí a ti ẹnu àwọn wòlíì mímọ́ sọ ṣáájú, àti òfin Olúwa àti Olùgbàlà wa láti ọ̀dọ̀ àwọn aposteli yín.

Kí ẹ kọ́ mọ èyí pé, nígbà ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn ẹlẹ́gàn yóò dé pẹ̀lú ẹ̀gàn wọn. Wọn ó máa rìn nípa ìfẹ́ ara wọn. Wọn ó sì máa wí pé, “Níbo ni ìlérí wíwà rẹ̀ gbé wà? Láti ìgbà tí àwọn baba ti sùn, ohun gbogbo ń lọ bí wọ́n ti wà rí láti ìgbà ọjọ́ yìí wá.” (A)Nítorí èyí ni wọ́n mọ̀ ọ́n mọ̀ ṣe àìfẹ́ ẹ́ mọ̀ pé nípa ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni àwọn ọ̀run ti wà láti ìgbà àtijọ́ àti tí ilẹ̀ yọrí jáde nínú omi, tí ó sì dúró nínú omi. Nípa èyí tí omi bo ayé tí ó wà nígbà náà tí ó sì ṣègbé. Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀run àti ayé, tí ó ń bẹ nísinsin yìí, nípa ọ̀rọ̀ kan náà ni ó ti tò jọ bí ìṣúra fún iná, a pa wọ́n mọ́ de ọjọ́ ìdájọ́ àti ìparun àwọn aláìwà-bí-Ọlọ́run.

(B)Ṣùgbọ́n, olùfẹ́, ẹ má ṣe gbàgbé ohun kan yìí, pé ọjọ́ kan lọ́dọ̀ Olúwa bí ẹgbẹ̀rún ọdún ni ó rí, àti ẹgbẹ̀rún ọdún bí ọjọ́ kan. Olúwa kò fi ìlérí rẹ̀ jáfara, bí àwọn ẹlòmíràn ti ka ìjáfara sí; ṣùgbọ́n ó ń mú sùúrù fún yín nítorí kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni ṣègbé, bí kò ṣe kí gbogbo ènìyàn wá sí ìrònúpìwàdà.

10 Ṣùgbọ́n ọjọ́ Olúwa ń bọ̀ wá bí olè ní òru; nínú èyí tí àwọn ọ̀run yóò kọjá lọ pẹ̀lú ariwo ńlá, àti àwọn ìmọ́lẹ̀ ojú ọ̀run yóò sì ti inú ooru gbígbóná gidigidi di yíyọ́, ayé àti àwọn iṣẹ́ tí ó wà nínú rẹ̀ yóò sì jóná túútúú.

11 Ǹjẹ́ bí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò ti yọ́ bẹ́ẹ̀, irú ènìyàn wo ni ẹ̀yin ìbá jẹ́ nínú ìwà mímọ́ gbogbo àti ìwà-bí-Ọlọ́run. 12 (C)Kí ẹ máa retí, kí ẹ sì máa múra gírí de dídé ọjọ́ Ọlọ́run, nítorí èyí tí àwọn ọ̀run yóò gbiná, tí wọn yóò di yíyọ́, tí àwọn ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ yóò sì ti inú ooru gbígbóná gidigidi di yíyọ́. 13 (D)Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ̀, àwa ń retí àwọn ọ̀run tuntun àti ayé títún nínú èyí tí òdodo ń gbé.

14 Nítorí náà, olùfẹ́, bí ẹ̀yin ti ń retí irú nǹkan wọ̀nyí, ẹ múra gírí, kí a lè bá yín ní àlàáfíà ní àìlábàwọ́n, àti ní àìlábùkù lójú rẹ̀. 15 Kí ẹ sì máa kà á sí pé, sùúrù Olúwa wa ìgbàlà ni; bí Paulu pẹ̀lú arákùnrin wa olùfẹ́, ti kọ̀wé sí yín gẹ́gẹ́ bí ọgbọ́n tí a fi fún un. 16 Bí ó tí ń sọ̀rọ̀ nǹkan wọ̀nyí pẹ̀lú nínú ìwé rẹ̀ gbogbo nínú èyí ti ohun mìíràn sọ̀rọ̀ láti yé ni gbé wà, èyí ti àwọn òpè àti àwọn aláìdúró níbìkan ń lo, bí wọ́n ti ń lo ìwé mímọ́ ìyókù, sí ìparun ara wọn.

17 Nítorí náà ẹ̀yin olùfẹ́, bí ẹ̀yin ti mọ nǹkan wọ̀nyí tẹ́lẹ̀, ẹ máa kíyèsára, kí a má ba à fi ìṣìnà àwọn ènìyàn búburú fà yín lọ, kí ẹ sì ṣubú kúrò ní ìdúró ṣinṣin yín. 18 Ṣùgbọ́n ẹ máa dàgbà nínú oore-ọ̀fẹ́ àti nínú ìmọ̀ Olúwa àti Olùgbàlà wa Jesu Kristi.

Ẹni tí ògo wà fún nísinsin yìí àti títí láé! Àmín.

Mika 6

Ọlọ́run pe Israẹli níjà

Ẹ fi etí sí ohun tí Olúwa wí:

“Dìde dúró, bẹ ẹ̀bẹ̀ fún ẹjọ́ rẹ níwájú òkè ńlá;
    sì jẹ́ kí àwọn òkè kéékèèkéé gbọ́ ohun tí ó fẹ́ wí.

“Gbọ́, ìwọ òkè ńlá, ẹ̀sùn Olúwa;
    gbọ́, ìwọ ìpìlẹ̀ ilé ayérayé.
Nítorí Olúwa ń bá àwọn ènìyàn rẹ̀ wíjọ́;
    òun yóò sì bá Israẹli rojọ́.

“Ẹ̀yin ènìyàn mi, kí ni mo ṣe fún yín?
    Àti nínú kí ni mo ti dá yin lágara? Dá mi lóhùn.
Nítorí èmi mú un yín gòkè láti ilẹ̀ Ejibiti wá,
    mo sì rà yín padà láti ilẹ̀ ẹrú wá.
Mo rán Mose láti darí yín,
    bákan náà mo rán Aaroni àti Miriamu síwájú rẹ̀.
Ìwọ ènìyàn mi,
    rántí ohun tí Balaki ọba Moabu gbèrò
    àti ohun tí Balaamu ọmọ Beori dáhùn.
Rántí ìrìnàjò rẹ̀ láti Ṣittimu dé Gilgali,
    kí ìwọ ba le mọ òdodo Olúwa.”

Kí ni èmi yóò ha mú wá síwájú Olúwa
    tí èmi ó fi tẹ ara mi ba níwájú Ọlọ́run gíga?
Kí èmi ha wá sí iwájú rẹ̀ pẹ̀lú ọrẹ ẹbọ sísun,
    pẹ̀lú ọmọ màlúù ọlọ́dún kan?
Ǹjẹ́ Olúwa yóò ní inú dídùn sí ẹgbẹgbàarùn-ún àgbò,
    tàbí sí ẹgbẹgbàarùn-ún ìṣàn òróró?
Èmi yóò ha fi àkọ́bí mi sílẹ̀ fún ìré-òfin-kọjá mi,
    èso inú ara mi fún ẹ̀ṣẹ̀ ọkàn mi?
Ó ti fihàn ọ́, ìwọ ènìyàn, ohun tí ó dára,
    àti ohun tí Olúwa ń béèrè lọ́wọ́ rẹ?
Bí kò ṣe láti ṣe òtítọ́, kí o sì fẹ́ràn àánú,
    àti kí o rìn ní ìrẹ̀lẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run rẹ̀.

Ẹ̀ṣẹ̀ Israẹli àti ìjìyà wọn

Gbọ́! Ohùn Olúwa kígbe sí ìlú ńlá náà,
    láti jẹ ọlọ́gbọ́n ni láti bẹ̀rù orúkọ rẹ.
    “Ẹ kíyèsi ọ̀pá rẹ̀ gbọ́ ọ̀pá àti Ẹni náà tí ó yàn án
10 Ǹjẹ́ ìṣúra ìwà búburú ha wà
    ní ilé ènìyàn búburú síbẹ̀,
    àti òṣùwọ̀n àìkún tí ó jẹ́ ohun ìbínú?
11 Ǹjẹ́ èmi ha lè kà wọ́n sí mímọ́
    pẹ̀lú òṣùwọ̀n búburú,
    pẹ̀lú àpò òṣùwọ̀n ẹ̀tàn?
12 Àwọn ọlọ́rọ̀ inú rẹ̀ kún fún ìwà ipá;
    àwọn tí ń gbé inú rẹ̀ ti ọ̀rọ̀ èké
    àti ahọ́n wọn ń sọ ẹ̀tàn?
13 Nítorí náà ni èmi yóò ṣe mú ọ ṣàìsàn ní lílù ọ́,
    láti sọ ọ́ dahoro nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ.
14 Ìwọ yóò jẹun ṣùgbọ́n kì yóò yó;
    ìyàn yóò wà láàrín rẹ;
Ìwọ yóò kó pamọ́, ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò lò láìléwu,
    nítorí ohun tí ìwọ kò pamọ́ ni èmi yóò fi fún idà.
15 Ìwọ yóò gbìn ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò kórè
    ìwọ yóò tẹ olifi,
ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò fi òróró rẹ̀ kún ara rẹ;
    ìwọ yóò tẹ èso àjàrà, ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò mu wáìnì.
16 Nítorí tí ìwọ ti pa òfin Omri mọ́,
    àti gbogbo iṣẹ́ ilé Ahabu,
    tí ó sì ti tẹ̀lé ìmọ̀ràn wọn,
nítorí náà ni èmi yóò ṣe mú ọ fún ìparun
    àti àwọn ènìyàn rẹ fún ìfiṣe ẹlẹ́yà;
    ìwọ yóò sì ru ẹ̀gàn àwọn ènìyàn mi.”

Luku 15

Òwe àgùntàn tó sọnù

15 (A)Gbogbo àwọn agbowó òde àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ sì súnmọ́ ọn láti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀. Àti àwọn Farisi àti àwọn akọ̀wé ń kùn pé, “Ọkùnrin yìí ń gba ẹlẹ́ṣẹ̀, ó sì ń bá wọn jẹun.”

Ó sì pa òwe yìí fún wọn, pé, (B)“Ọkùnrin wo ni nínú yín, tí ó ní ọgọ̀rún-ún àgùntàn, bí ó bá sọ ọ̀kan nù nínú wọn, tí kì yóò sì tọ ipasẹ̀ èyí tí ó nù lọ, títí yóò fi rí i? Nígbà tí ó bá sì rí i tán, yóò gbé e lé èjìká rẹ̀ pẹ̀lú ayọ̀. Nígbà tí ó bá sì dé ilé yóò pe àwọn ọ̀rẹ́ àti aládùúgbò rẹ̀ jọ, yóò sì wí fún wọn pé, ‘Ẹ bá mí yọ̀; nítorí tí mo ti rí àgùntàn mi tí ó nù.’ (C)Mo wí fún yín, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ayọ̀ yóò wà ní ọ̀run lórí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tí ó ronúpìwàdà, ju lórí olóòtítọ́ mọ́kàn-dínlọ́gọ́rùn-ún lọ, tí kò nílò ìrònúpìwàdà.

Òwe owó tó sọnù

“Tàbí obìnrin wo ni ó ní owó fàdákà mẹ́wàá bí ó bá sọ ọ̀kan nù, tí kì yóò tan fìtílà, kí ó fi gbá ilé, kí ó sì wá a gidigidi títí yóò fi rí i? Nígbà tí ó sì rí i, ó pe àwọn ọ̀rẹ́ àti àwọn aládùúgbò rẹ̀ jọ, ó wí pé, ‘Ẹ bá mi yọ̀; nítorí mo rí owó fàdákà tí mo ti sọnù.’ 10 Mo wí fún yín, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ayọ̀ ń bẹ níwájú àwọn angẹli Ọlọ́run lórí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tí ó ronúpìwàdà.”

Òwe ọmọ tó sọnù

11 (D)Ó sì wí pé ọkùnrin kan ní ọmọ méjì: 12 (E)“Èyí àbúrò nínú wọn wí fún baba rẹ̀ pé, ‘Baba, fún mi ní ìní tí ó kàn mí.’ Ó sì pín ohun ìní rẹ̀ fún wọn.

13 “Kò sì tó ọjọ́ mélòó kan lẹ́yìn náà, èyí àbúrò kó ohun gbogbo tí ó ní jọ, ó sì mú ọ̀nà àjò rẹ̀ pọ̀n lọ sí ilẹ̀ òkèrè, níbẹ̀ ni ó sì gbé fi ìwà wọ̀bìà ná ohun ìní rẹ̀ ní ìnákúnàá. 14 Nígbà tí ó sì ba gbogbo rẹ̀ jẹ́ tan, ìyàn ńlá wá mú ní ilẹ̀ náà; ó sì bẹ̀rẹ̀ sí di aláìní. 15 Ó sì fi ara rẹ sọfà fun ọ̀kan lára àwọn ọmọ ìlú náà; òun sì rán an lọ sí oko rẹ̀ láti tọ́jú ẹlẹ́dẹ̀. 16 Ayọ̀ ni ìbá fi jẹ oúnjẹ tí àwọn ẹlẹ́dẹ̀ ń jẹ ní àjẹyó: ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni kò sì fi fún un.

17 “Ṣùgbọ́n nígbà tí ojú rẹ̀ wálẹ̀, ó ní ‘Mélòó mélòó àwọn alágbàṣe baba mí ni ó ní oúnjẹ àjẹyó, àti àjẹtì, èmi sì ń kú fún ebi níhìn-ín. 18 Èmi ó dìde, èmi ó sì tọ baba mi lọ, èmi ó sì wí fún un pé: Baba, èmí ti dẹ́ṣẹ̀ sí ọ̀run, àti níwájú rẹ; 19 Èmi kò sì yẹ, ní ẹni tí à bá pè ní ọmọ rẹ mọ́; fi mí ṣe ọ̀kan nínú àwọn alágbàṣe rẹ.’ 20 Ó sì dìde, ó sì tọ baba rẹ̀ lọ.

“Ṣùgbọ́n nígbà tí ó sì wà ní òkèrè, baba rẹ̀ rí i, àánú ṣe é, ó sì súré, ó rọ̀ mọ́ ọn ní ọrùn, ó sì fi ẹnu kò ó ní ẹnu.

21 “Ọmọ náà sì wí fún un pé, Baba, èmi ti dẹ́ṣẹ̀ sí ọ̀run, àti níwájú rẹ, èmi kò yẹ ní ẹni tí à bá pè ní ọmọ rẹ mọ́!

22 (F)“Ṣùgbọ́n baba náà wí fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé, Ẹ mú ààyò aṣọ wá kánkán, kí ẹ sì fi wọ̀ ọ́; ẹ sì fi òrùka bọ̀ ọ́ lọ́wọ́, àti bàtà sí ẹsẹ̀ rẹ̀: 23 Ẹ sì mú ẹgbọrọ màlúù àbọ́pa wá, kí ẹ sì pa á; kí a máa ṣe àríyá: 24 (G)Nítorí ọmọ mi yìí ti kú, ó sì tún yè; ó ti nù, a sì rí i. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àríyá.

25 “Ṣùgbọ́n ọmọ rẹ̀ èyí ẹ̀gbọ́n ti wà ní oko: bí ó sì ti ń bọ̀, tí ó súnmọ́ etí ilé, ó gbọ́ orin àti ijó. 26 Ó sì pe ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ wọn, ó béèrè, kín ni a mọ nǹkan wọ̀nyí sí? 27 Ó sì wí fún un pé, ‘Arákùnrin rẹ dé, baba rẹ sì pa ẹgbọrọ màlúù àbọ́pa, nítorí tí ó rí i padà ní àlàáfíà àti ní ìlera.’

28 “Ó sì bínú, ó sì kọ̀ láti wọlé; baba rẹ̀ sì jáde, ó sì wá í ṣìpẹ̀ fún un. 29 Ó sì dáhùn ó wí fún baba rẹ̀ pé, ‘Wò ó, láti ọdún mélòó wọ̀nyí ni èmi ti ń sìn ọ́, èmi kò sì rú òfin rẹ rí: ìwọ kò sì tí ì fi ọmọ ewúrẹ́ kan fún mi, láti fi bá àwọn ọ̀rẹ́ mi ṣe àríyá: 30 Ṣùgbọ́n nígbà tí ọmọ rẹ yìí dé, ẹni tí ó fi panṣágà fi ọrọ̀ rẹ̀ ṣòfò, ìwọ sì ti pa ẹgbọrọ màlúù àbọ́pa fún un.’

31 “Ó sì wí fún un pé, ‘Ọmọ, nígbà gbogbo ni ìwọ ń bẹ lọ́dọ̀ mi, ohun gbogbo tí mo sì ní, tìrẹ ni. 32 Ó yẹ kí a ṣe àríyá kí a sì yọ̀: nítorí arákùnrin rẹ yìí ti kú, ó sì tún yè; ó ti nù, a sì rí i.’ ”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.