M’Cheyne Bible Reading Plan
Àwọn èrò Dafidi lórí ilé Olúwa
28 Dafidi pe gbogbo àwọn oníṣẹ́ ti Israẹli láti péjọ ní Jerusalẹmu: Àwọn ìjòyè lórí àwọn ẹ̀yà, àwọn alákòóso ìpín nínú iṣẹ́ bí ọba, àwọn alákòóso ẹgbẹgbẹ̀rún àti àwọn alákòóso ọ̀rọ̀ọ̀rún àti àwọn oníṣẹ́ tí ó wà ní ìdí bíbojútó gbogbo àwọn ẹrù àti ohun ọ̀sìn tí ó jẹ́ ti ọba àti àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú ààfin àwọn oníṣẹ́ ààfin, àwọn ọkùnrin alágbára àti gbogbo àwọn ògbójú jagunjagun lápapọ̀.
2 Ọba Dafidi dìde dúró ní ẹsẹ̀ rẹ̀, o sì wí pé “Fetísílẹ̀ sí mi, ẹ̀yin ará mi àti ẹ̀yin ènìyàn mi. Èmi ní o ni lọ́kàn mi láti kọ́ ilé gẹ́gẹ́ bí ibi ìsinmi fún àpótí ẹ̀rí tí Olúwa fún àpótí ìtìsẹ̀ Ọlọ́run wa, èmi sì gbèrò láti kọ́ ọ. 3 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run sọ fún mi pé: Ìwọ kò gbọdọ̀ kọ́ ilé fún orúkọ mi, nítorí ìwọ jẹ́ jagunjagun, ìwọ sì ti tàjẹ̀ sílẹ̀”.
4 “Síbẹ̀ Olúwa, Ọlọ́run Israẹli yàn mí láti gbogbo ìdílé láti jẹ́ ọba lórí Israẹli, títí láé. Ó yan Juda gẹ́gẹ́ bí olórí, àti láti ilé Juda, ó yan ìdílé mi, àti láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ baba à mí, ó tẹ́ Ẹ lọ́rùn láti fi mí ṣe ọba lórí gbogbo Israẹli. 5 Nínú gbogbo àwọn ọmọ mi pẹ̀lú Olúwa ti fún mi ní púpọ̀, ó ti yan ọmọ mi Solomoni láti jókòó lórí ìtẹ́ ìjọba ti Olúwa lórí Israẹli. 6 Ó wí fún mi pé, Solomoni ọmọ rẹ ni ẹni tí yóò kọ́ ilé mi àti àwọn ààfin mi, Nítorí tí èmi ti yàn án láti ṣe ọmọ mi èmi yóò sì jẹ́ baba a rẹ̀. 7 Èmi yóò fi ìdí ìjọba rẹ̀ kalẹ̀ títí láé tí kò bá kọ̀ láti gbé àṣẹ àti òfin mi jáde, gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe é ní àsìkò yìí.
8 “Bẹ́ẹ̀ ni, nísinsin yìí, èmi pàṣẹ fún ọ ní ojú gbogbo Israẹli àti ní ti ìpéjọpọ̀ tí Olúwa, àti ní etí ìgbọ́ Ọlọ́run wa: Ṣọ́ra kó o sì tẹ̀lé gbogbo òfin Olúwa Ọlọ́run rẹ kí ìwọ kí ó le jogún ilẹ̀ dáradára yìí, kí o sì mú un lọ síwájú gẹ́gẹ́ bí ogún rẹ fún àwọn ìran ọmọ rẹ títí láé.
9 “Àti ìwọ, ọmọ mi Solomoni, rántí Ọlọ́run baba à rẹ, kí o sì sìn ín pẹ̀lú tọkàntọkàn pẹ̀lú ìfọkànsí pẹ̀lú ọkàn tí ó pé, nítorí Olúwa ṣàwárí gbogbo ọkàn ó sì mọ gbogbo èrò. Tí ìwọ bá wá a, ìwọ yóò rí i; ṣùgbọ́n tí ìwọ bá kọ̀ ọ́ sílẹ̀, òun yóò kọ̀ ọ́ títí láé. 10 Gbèrò báyìí nítorí tí Olúwa ti yàn ọ́ láti kọ́ ilé Olúwa gẹ́gẹ́ bí ilé tí a yà sí mímọ́ fún Olúwa. Jẹ́ alágbára kí ó sì ṣe iṣẹ́ náà.”
11 Nígbà náà ni Dafidi fi àpẹẹrẹ fún Solomoni ọmọ rẹ̀ ti ìloro àti ti ilé Olúwa náà, kíkọ́ ọ rẹ̀, àti ti ibi ìṣúra rẹ̀, àti ti iyàrá òkè rẹ̀, àti ti ìyẹ̀wù rẹ̀ àti ti ibùjókòó àánú. 12 Ó fún un ní àwọn ètò gbogbo èyí tí ẹ̀mí ti fi sí ọkàn rẹ̀ fún ti ààfin ilé Olúwa àti gbogbo yàrá tí ó yíká fún ìṣúra ilé Ọlọ́run àti fún ìṣúra fún ohun yíyà sọ́tọ̀. 13 Ó fún un ní àwọn ìlànà fún ìpín ti àwọn àlùfáà àti àwọn ará Lefi àti fún gbogbo iṣẹ́ ìsìn nínú ilé Olúwa àti fún gbogbo ohun èlò tí wọn ó lò nínú ìsìn rẹ̀. 14 Ó yàn ìwọ̀n wúrà fún gbogbo ohun èlò wúrà tí a ó lò níbi oríṣìí ìsìn, àti ìwọ̀n fàdákà fún gbogbo ohun èlò fàdákà tí a ó lò fún oríṣìí ìsìn: 15 Ìwọ̀n wúrà fún ìdúró fìtílà àti fìtílà wọn, fún ìwọ̀n fún ọ̀kọ̀ọ̀kan ìdúró fìtílà àti fìtílà wọn; àti ìwọ̀n fàdákà ìdúró fìtílà fàdákà àti àwọn fìtílà rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìlò ti gbogbo ìdúró fìtílà. 16 Ìwọ̀n ti wúrà fun tábìlì, tábìlì fún àkàrà tí a yà sọ́tọ̀; ìwọ̀n fàdákà fún àwọn tábìlì fàdákà; 17 Ìwọ̀n kìkì wúrà fún àwọn àmúga ìjẹun, àwọn ìbùwọ́n ọpọ́n àti àwọn ìkòkò ìpọnmi; ìwọ̀n wúrà fún gbogbo àwopọ̀kọ́ fàdákà; 18 Àti ìwọ̀n ìdá wúrà fún Pẹpẹ tùràrí ó fún un ní ètò fún kẹ̀kẹ́, ìyẹn ni pé àwọn ìdúró kérúbù wúrà tí wọ́n tan iye wọn ká, wọ́n sì bo àpótí ẹ̀rí Olúwa.
19 “Gbogbo èyí,” ni Dafidi wí pé, “Èmi ní kíkọ sílẹ̀ láti ọwọ́ Olúwa sórí mi, ó sì fún mí ní ìmọ̀ nínú gbogbo iṣẹ́ ètò yìí.”
20 Dafidi tún sọ fún Solomoni ọmọ rẹ̀ pé, “Jẹ́ alágbára kí o sì gbóyà, kí o sì ṣe iṣẹ́ náà. Má ṣe bẹ̀rù tàbí dààmú, nítorí Olúwa Ọlọ́run, Ọlọ́run mi, wà pẹ̀lú rẹ. Òun kì yóò sì jọ ọ kule tàbí kọ Ọ sílẹ̀ títí gbogbo iṣẹ́ fún ìsìn ní ti ilé Olúwa yóò fi parí. 21 Ìpín àwọn àlùfáà àti àwọn ará Lefi ti ṣetán fún gbogbo iṣẹ́ ilé Olúwa. Gbogbo ọkùnrin tí ó ní ìfẹ́ sí i tí ó sì ní òye oríṣìíríṣìí iṣẹ́. Yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ náà. Àwọn ìjòyè àti gbogbo àwọn ènìyàn yóò gbọ́rọ̀ sí gbogbo àṣẹ rẹ.”
Àwọn olùkọ́ni èké àti ìparun wọn
2 (A)Ṣùgbọ́n àwọn wòlíì èké wà láàrín àwọn ènìyàn náà pẹ̀lú, gẹ́gẹ́ bí àwọn olùkọ́ni èké yóò ti wà láàrín yín. Wọn yóò yọ́ kẹ́lẹ́ mú ẹ̀kọ́ òdì àti ègbé tọ̀ yín wa, àní tí yóò sẹ́ Olúwa tí ó rà wọ́n padà, wọ́n ó sì mú ìparun ti o yára kánkán wá sórí ara wọn. 2 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni yóò si máa tẹ̀lé ọ̀nà ìtìjú wọn, tí wọn yóò sì mú kí ọ̀nà òtítọ́ di ìsọ̀rọ̀-òdì sí. 3 Nínú ìwà wọ̀bìà wọn, àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ òdì wọ̀nyí yóò máa rẹ́ ẹ yín jẹ nípa ìtàn asán. Ìdájọ́ ẹni tí kò falẹ̀ láti ìgbà yìí wá àti ìparun wọn tí kò sí tòògbé.
4 Nítorí pé bi Ọlọ́run kò bá dá àwọn angẹli si nígbà tí wọn ṣẹ̀, ṣùgbọ́n ti ó sọ wọ́n sí ìsàlẹ̀ ọ̀run àpáàdì tí ó sì fi wọ́n sínú ọ̀gbun òkùnkùn biribiri nínú ìfipamọ́ títí dé ìdájọ́. 5 (B)Bí òun kò si dá ayé ìgbàanì sí, nígbà tí ó mú ìkún omi wá sórí ayé àwọn aláìwà-bí-Ọlọ́run, ṣùgbọ́n ó pa Noa mọ́, oníwàásù òdodo, pẹ̀lú àwọn ọmọ méje mìíràn. 6 (C)Tí ó sọ àwọn ìlú Sodomu àti Gomorra di eérú, nígbà tí ó fi ìparun pátápátá dá wọn lẹ́bi, tí ó fi wọ́n ṣe àpẹẹrẹ fún àwọn tí yóò jẹ́ aláìwà-bí-Ọlọ́run. 7 (D)Tí ó sì yọ Lọti olóòtítọ́ ènìyàn, ẹni tí ìwà ẹ̀gbin àwọn ènìyàn láìlófin bà nínú jẹ́; 8 (nítorí ọkùnrin olóòtítọ́ náà bí ó ti ń gbé àárín wọn, tí ó ń rí, tí ó sì ń gbọ́, lójoojúmọ́ ni ìwà búburú wọn ń bá ọkàn òtítọ́ rẹ̀ jẹ́) 9 Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, Olúwa mọ bí a tí ń yọ àwọn ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run kúrò nínú ìdánwò àti bí a ti ń pa àwọn aláìṣòótọ́ mo fún ọjọ́ ìdájọ́ nígbà tí wọn yóò tẹ̀síwájú nínú ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn. 10 Ṣùgbọ́n pàápàá àwọn tí ó ń tọ ẹran-ara lẹ́yìn nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ìwà èérí, tí wọ́n sì ń gan àwọn ìjòyè.
Àwọn ọ̀dájú àti agbéraga, wọn kò bẹ̀rù láti sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí àwọn ẹni ògo. 11 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn angẹli bí wọ́n ti pọ̀ ní agbára àti ipá tó o nì, wọn kò dá wọ́n lẹ́jọ́ ẹ̀gàn níwájú Olúwa. 12 Ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí, bí ẹranko igbó tí kò ní èrò, ẹranko sá á tí a dá láti máa mú pa, wọ́n ń sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn nínú ọ̀rọ̀ tí kò yé wọn, a ó pa wọn run pátápátá nínú ìbàjẹ́ ara wọn.
13 Wọn yóò gba ibi padà bí ibi tí wọ́n ti ṣe. Òye ìgbafẹ́ tí wọ́n ní láti máa jẹ adùn ayé. Wọ́n jẹ́ àbàwọ́n àti àbùkù, wọ́n ń jayé nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wọn nígbà tí wọ́n bá ń jẹ àsè pẹ̀lú yín. 14 Ojú wọn kún fún panṣágà, wọn kò sì dẹ́kun ẹ̀ṣẹ̀ dídá; wọ́n ń tan àwọn tí ọkàn kò fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ jẹ; àwọn tí wọ́n ní ọkàn tí ó ti yege nínú wọ̀bìà, ọmọ ègún ni wọ́n. 15 (E)Wọ́n kọ ọ̀nà tí ó tọ́ sílẹ̀, wọ́n sì ṣáko lọ, wọ́n tẹ̀lé ọ̀nà Balaamu ọmọ Beori, ẹni tó fẹ́ràn èrè àìṣòdodo. 16 (F)Ṣùgbọ́n a bá a wí nítorí ìrékọjá rẹ̀, odi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ fi ohùn ènìyàn sọ̀rọ̀, ó sì fi òpin sí ìṣiwèrè wòlíì náà.
17 Àwọn wọ̀nyí ni kànga tí kò ní omi, ìkùùkuu tí ẹ̀fúùfù ń gbá kiri; àwọn ẹni tí a pa òkùnkùn biribiri mọ́ dè títí láé. 18 Nítorí ìgbà tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀ ìhàlẹ̀ asán, nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara, wọn a máa tan àwọn tí wọ́n fẹ́rẹ̀ má tí ì bọ́ tán kúrò lọ́wọ́ àwọn tí wọ́n wà nínú ìṣìnà. 19 Wọn a máa ṣe ìlérí òmìnira fún wọn, nígbà tí àwọn pàápàá jẹ́ ẹrú ìdíbàjẹ́; nítorí ènìyàn tí di ẹrú ohunkóhun tí ó bá ṣe ọ̀gá rẹ̀. 20 Lẹ́yìn tí wọ́n bá ti yọ tán kúrò nínú èérí ayé nípa mímọ́ Olúwa àti Olùgbàlà wá Jesu Kristi, bí wọn bá sì tún fi ara kó o, tí a sì ṣẹ́gun wọn, ìgbẹ̀yìn wọn a burú jú ti ìṣáájú lọ. 21 Nítorí ìbá sàn fún wọn, kí wọn má mọ́ ọ̀nà òdodo, jù pé lẹ́yìn tí wọ́n mọ̀ ọ́n tán, kí wọn yípadà kúrò nínú òfin mímọ́ tí a fi fún wọn. 22 (G)Òwe òtítọ́ náà ṣẹ sí wọn lára: “Ajá tún padà sí èébì ara rẹ̀; àti ẹlẹ́dẹ̀ tí a ti wẹ̀mọ́ tún padà ń yíràá nínú ẹrọ̀fọ̀.”
Àsọtẹ́lẹ̀ nípa Olùgbàlà láti Bẹtilẹhẹmu
5 Nísinsin yìí, kó àwọn ọ̀wọ́ ogun rẹ jọ,
ìwọ ìlú ti o ni ọmọ-ogun,
nítorí ó ti fi gbógun dó tì wá.
Wọn yóò fi ọ̀pá lu àwọn alákòóso Israẹli ní ẹ̀rẹ̀kẹ́.
2 “Ṣùgbọ́n ìwọ, Bẹtilẹhẹmu Efrata,
bí ìwọ ti jẹ́ kékeré láàrín àwọn ẹ̀yà Juda,
nínú rẹ ni ẹni tí yóò jẹ́ olórí ní Israẹli
yóò ti jáde tọ̀ mí wá,
ìjáde lọ rẹ̀ sì jẹ́ láti ìgbà àtijọ́,
láti ìgbà láéláé.”
3 Nítorí náà Israẹli yóò di kíkọ̀sílẹ̀ pátápátá
títí di àkókò tí ẹni tí ń rọbí yóò fi bí,
àti àwọn ìyókù arákùnrin rẹ̀ yóò fi padà
láti darapọ̀ mọ́ àwọn Israẹli.
4 Òun yóò sì dúró,
yóò sì máa ṣe olùṣọ́-àgùntàn àwọn agbo ẹran rẹ̀ ní agbára Olúwa,
ní ọláńlá orúkọ Olúwa Ọlọ́run rẹ̀.
Wọn yóò sì wà láìléwu,
nítorí nísinsin yìí ni títóbi rẹ
yóò sì dé òpin ayé.
Ìgbàlà àti ìparun
5 Òun yóò sì jẹ́ àlàáfíà wọn.
Nígbà tí àwọn Asiria bá gbógun sí ilẹ̀ wa
tí wọ́n sì ń yan lórí odi alágbára wa,
nígbà náà ni a ó gbé olùṣọ́-àgùntàn méje dìde sí i,
àti olórí ènìyàn mẹ́jọ.
6 Wọn yóò sì fi idà pa ilẹ̀ Asiria run,
àti ilẹ̀ Nimrodu pẹ̀lú idà tí a fà.
Òun yóò sì gbà wá sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Asiria
nígbà tí wọn bá gbógun ti ilẹ̀ wa
tí wọ́n sì tún yan wọ ẹnu-bodè wa.
7 Ìyókù Jakọbu yóò sì wà
láàrín ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn
bí ìrì láti ọ̀dọ̀ Olúwa wa,
bí ọ̀wààrà òjò lórí koríko,
tí kò gbẹ́kẹ̀lé ènìyàn
tàbí kò dúró de àwọn ọmọ ènìyàn.
8 Ìyókù Jakọbu yóò sì wà láàrín àwọn aláìkọlà
ní àárín àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn,
bí i kìnnìún láàrín àwọn ẹranko inú igbó,
bí i ọmọ kìnnìún láàrín agbo àgùntàn,
èyí tí ó máa ń fà á ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ,
tí ó sì máa ń tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀,
tí kò sì ṣí ẹnìkan tí ó lè gbà á là.
9 A ó gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè ní ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá rẹ̀,
gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ sì ni a ó parun.
10 “Ní ọjọ́ náà,” ni Olúwa wí,
“Èmi yóò pa àwọn ẹṣin rẹ̀ run kúrò láàrín rẹ
èmi yóò sì pa àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ run.
11 Èmi yóò sì pa ilẹ̀ ìlú ńlá rẹ̀ run,
èmi ó sì fa gbogbo ibi gíga rẹ̀ ya.
12 Èmi yóò gé ìwà àjẹ́ kúrò lọ́wọ́ rẹ̀,
ìwọ kì yóò sì ní aláfọ̀ṣẹ mọ́.
13 Èmi yóò pa àwọn ère fínfín rẹ̀ run,
àti ọwọ́n rẹ̀ kúrò láàrín rẹ̀;
ìwọ kì yóò sì le è foríbalẹ̀
fún iṣẹ́ ọwọ́ rẹ mọ́.
14 Èmi yóò fa ère Aṣerah tu kúrò láàrín rẹ̀,
èmi yóò sì pa ìlú ńlá rẹ̀ run.
15 Èmi yóò gbẹ̀san ní ìbínú àti ìrunú
lórí àwọn orílẹ̀-èdè tí kò ti tẹríba fún mi.”
Jesu ní ilé Farisi kan
14 (A)Nígbà tí ó wọ ilé ọ̀kan nínú àwọn olórí Farisi lọ ní ọjọ́ ìsinmi láti jẹun, wọ́n sì ń ṣọ́ ọ. 2 Sì kíyèsi i, ọkùnrin kan tí ó ní ara wíwú níwájú rẹ̀. 3 (B)Jesu sì dáhùn ó wí fún àwọn amòfin àti àwọn Farisi pé, “Ǹjẹ́ ó tọ́ láti mú ni láradá ní ọjọ́ ìsinmi, tàbí kò tọ́?” 4 Wọ́n sì dákẹ́. Ó sì mú un, ó mú un láradá, ó sì jẹ́ kí ó lọ.
5 (C)Ó sì dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Ta ni nínú yín tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tàbí màlúù rẹ̀ yóò bọ́ sínú ihò, tí kì yóò sì fà á sókè lójúkan náà ní ọjọ́ ìsinmi?” 6 Wọn kò sì lè dá a lóhùn mọ́ sí nǹkan wọ̀nyí.
7 Ó sì pa òwe kan fún àwọn tí ó pè é wá jẹun, nígbà tí ó ṣàkíyèsí bí wọ́n ti ń yan ipò ọlá; ó sì wí fún wọn pé: 8 (D)“Nígbà tí ẹnìkan bá pè ọ́ wá sí ibi ìyàwó, má ṣe jókòó ní ipò ọlá; kí ó má ba à jẹ́ pé, a ó pe ẹni tí ó lọ́lá jù ọ́ lọ. 9 Nígbà tí ẹni tí ó pè ọ́ bá dé, a sì wí fún ọ pé, ‘Fún ọkùnrin yìí ní ààyè!’ Ìwọ á sì wá fi ìtìjú mú ipò ẹ̀yìn. 10 Ṣùgbọ́n nígbà tí a bá pè ọ́, lọ kí o sì jókòó ní ipò ẹ̀yìn; nígbà tí ẹni tí ó pè ọ́ bá dé, kí ó lè wí fún ọ pé, ‘Ọ̀rẹ́, bọ́ sókè!’ Nígbà náà ni ìwọ ó ní ìyìn lójú àwọn tí ó bá ọ jókòó ti oúnjẹ. 11 (E)Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga, ni a ó rẹ̀ sílẹ̀; ẹnikẹ́ni tí ó bá sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, ni a ó sì gbéga.”
12 (F)Nígbà náà ni ó sì wí fún alásè tí ó pè é pé, “Nígbà tí ìwọ bá ṣe àsè má ṣe pe àwọn arákùnrin rẹ tàbí àwọn ìbátan rẹ, tàbí àwọn ọlọ́rọ̀ aládùúgbò rẹ̀; nítorí kí wọn má ṣe pè ọ́ padà láti san ẹ̀san padà. 13 (G)Ṣùgbọ́n nígbà tí ìwọ bá ṣe àsè, pe àwọn tálákà, àwọn alábùkún ara, àwọn amúnkùn ún, àti àwọn afọ́jú: 14 Ìwọ ó sì jẹ́ alábùkún fún; nítorí wọn kò ní ohun tí wọn ó fi san án fún ọ: ṣùgbọ́n a ó san án fún ọ ní àjíǹde, àwọn olóòtítọ́.”
Òwe nípa àsè ńlá
15 (H)Nígbà tí ọ̀kan nínú àwọn tí wọ́n jọ jókòó gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, ó wí fún Jesu pé, “Alábùkún ni fún ẹni tí yóò jẹ oúnjẹ àsè ní ìjọba Ọlọ́run!”
16 (I)Jesu dá a lóhùn pé, “Ọkùnrin kan ṣe àsè alẹ́ ńlá, ó sì pe ènìyàn púpọ̀. 17 Ó sì rán ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ ní wákàtí àsè alẹ́ náà láti sọ fún àwọn tí a ti pè pé, ‘Ẹ wá; nítorí ohun gbogbo ṣetán!’
18 “Gbogbo wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àwáwí ohun kan. ‘Èkínní wí fún un pé, mo ra ilẹ̀ kan, mo sì fẹ́ lọ wò ó wò, mo bẹ̀ ọ́ ṣe gáfárà fún mi.’
19 “Èkejì sì wí pé, ‘Mo ra àjàgà màlúù márùn-ún, mo sì ń lọ wò wọ́n wò: mo bẹ̀ ọ́ ṣe gáfárà fún mi.’
20 (J)“Ẹ̀kẹta sì wí pé, ‘Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ gbéyàwó, nítorí náà ni èmi kò fi lè wá.’
21 (K)“Ọmọ ọ̀dọ̀ náà sì padà dé, ó sọ nǹkan wọ̀nyí fún olúwa rẹ̀. Nígbà náà ni baálé ilé bínú, ó wí fún ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé, ‘Jáde lọ sí ìgboro, àti sí òpópó ọ̀nà, kí o sì mú àwọn tálákà, àti àwọn amúnkùn ún, àti àwọn arọ, àti àwọn afọ́jú wá sí ìhín yìí.’
22 “Ọmọ ọ̀dọ̀ náà sì wí pé, ‘Olúwa a ti ṣe bí o ti pàṣẹ, ààyè sì ń bẹ síbẹ̀.’
23 “Olúwa náà sì wí fún ọmọ ọ̀dọ̀ náà pé, ‘Jáde lọ sí òpópó, àti sí ọ̀nà ọgbà, kí o sì rọ̀ wọ́n láti wọlé wá, kí ilé mi lè kún. 24 Nítorí mo wí fún yín, ẹnikẹ́ni nínú àwọn ènìyàn wọ̀nyí tí a ti pè, kì yóò tọ́wò nínú àsè ńlá mi!’ ”
Àmúyẹ láti jẹ ọmọ-ẹ̀yìn
25 Àwọn ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn ń bá a lọ; ó sì yípadà, ó sì wí fún wọn pé, 26 (L)“Bí ẹnìkan bá tọ̀ mí wá, tí kò sì kórìíra baba àti ìyá, àti aya, àti ọmọ, àti arákùnrin, àti arábìnrin, àní àti ọkàn ara rẹ̀ pẹ̀lú, kò lè ṣe ọmọ-ẹ̀yìn mi. 27 (M)Ẹnikẹ́ni tí kò bá ru àgbélébùú rẹ̀, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn, kò lè ṣe ọmọ-ẹ̀yìn mi.
28 “Nítorí ta ni nínú yín tí ń pète láti kọ́ ilé ìṣọ́, tí kì yóò kọ́kọ́ jókòó kí ó ṣírò iye owó rẹ̀, bí òun ní tó tí yóò fi parí rẹ̀. 29 Kí ó má ba à jẹ́ pé nígbà tí ó bá fi ìpìlẹ̀ ilé sọlẹ̀ tan, tí kò lè parí rẹ̀ mọ́, gbogbo àwọn tí ó rí i a bẹ̀rẹ̀ sí í fi í ṣe ẹlẹ́yà. 30 Wí pé, ‘Ọkùnrin yìí bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ilé, kò sì lè parí rẹ̀.’
31 “Tàbí ọba wo ni ó ń lọ bá ọba mìíràn jà, tí kì yóò kọ́kọ́ jókòó, kí ó sì gbèrò bí yóò lè fi ẹgbàárùn-ún pàdé ẹni tí ń mú ẹgbàáwàá bọ̀ wá ko òun lójú? 32 Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, nígbà tí onítọ̀hún bá sì wà ní òkèrè, òun a rán ikọ̀ sí i, a sì bẹ̀rẹ̀ àdéhùn àlàáfíà. 33 (N)Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, ẹnikẹ́ni tí ó wù kí ó ṣe nínú yín, tí kò kọ ohun gbogbo tí ó ní sílẹ̀, kò lè ṣe ọmọ-ẹ̀yìn mi.
34 (O)“Iyọ̀ dára: ṣùgbọ́n bí iyọ̀ bá di òbu, kín ni a ó fi mú un dùn? 35 Kò yẹ fún ilẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò yẹ fún ààtàn; bí kò ṣe pé kí a kó o dànù.
“Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́ kí ó gbọ́.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.