M’Cheyne Bible Reading Plan
9 (A)Gbogbo Israẹli ni a kọ lẹ́sẹẹsẹ nínú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ àwọn baba ńlá nínú ìwé àwọn ọba Israẹli. Àwọn ènìyàn Juda ni a kó ní ìgbèkùn lọ sí Babeli nítorí àìṣòótọ́ wọn.
Àwọn ènìyàn tí ó wà ní Jerusalẹmu
2 Nísinsin yìí, àwọn tí ó kọ́kọ́ tún tẹ̀dó lórí ohun ìní wọn ní ìlú wọn ni díẹ̀ nínú àwọn ọmọ Israẹli, àwọn àlùfáà, àwọn ará Lefi àti àwọn Ìránṣẹ́ ilé Olúwa.
3 (B)Àwọn tí ó wá láti Juda láti Benjamini àti láti Efraimu àti Manase tí ó ń gbé ní Jerusalẹmu jẹ́:
4 Uttai ọmọ Ammihudu, ọmọ Omri, ọmọ Imri, ọmọ Bani, ìran ọmọ Peresi ọmọ Juda.
5 Àti nínú ará Ṣilo:
Asaiah àkọ́bí àti àwọn ọmọ rẹ̀.
6 Ní ti ará Sera:
Jeueli
Àwọn ènìyàn láti Juda sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ó dín mẹ́wàá (690).
7 Àti nínú àwọn ọmọ Benjamini ni:
Sallu ọmọ Meṣullamu, ọmọ Hodafiah; ọmọ Hasenuah;
8 Ibinaiah ọmọ Jerohamu;
Ela ọmọ Ussi, ọmọ Mikri;
àti Meṣullamu ọmọ Ṣefatia; ọmọ Reueli, ọmọ Ibinijah.
9 Àwọn ènìyàn láti Benjamini gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe kọ ọ́ nínú ìran wọn nínú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn, tí ó jẹ́ ẹgbẹ̀rún ó dín mẹ́rìnlélógójì, (956). Gbogbo àwọn ọkùnrin yí jẹ́ àwọn olórí àwọn ìdílé.
10 Ní ti àwọn àlùfáà:
Jedaiah; Jehoiaribi; Jakini;
11 Asariah ọmọ Hilkiah, ọmọ Meṣullamu, ọmọ Sadoku, ọmọ Meraioti, ọmọ Ahitubu, olórí tí ó ń bojútó ilé Ọlọ́run;
12 Adaiah ọmọ Jerohamu, ọmọ Paṣuri, ọmọ Malkiah;
àti Masai ọmọ Adieli, ọmọ Jahisera, ọmọ Meṣullamu ọmọ Meṣilemiti, ọmọ Immeri
13 Àwọn àlùfáà, tí wọ́n jẹ́ àwọn olórí àwọn ìdílé, tí ó jẹ́ ẹgbẹ̀sán ó dín méjì (1,760). Wọ́n jẹ́ alágbára ọkùnrin, tí wọ́n lè dúró fún iṣẹ́ ìránṣẹ́ nínú ilé Ọlọ́run.
14 Ní ti àwọn ará Lefi:
Ṣemaiah ọmọ Haṣubu, ọmọ Asrikamu, ọmọ Haṣabiah ará Merari;
15 Bakibakari, Hereṣi, Galali àti Mattaniah, ọmọ Mika, ọmọ Sikri, ọmọ Asafu;
16 Ọbadiah ọmọ Ṣemaiah, ọmọ Galali, ọmọ Jedutuni;
àti Berekiah ọmọ Asa, ọmọ Elkana, Tí ó ń gbé nínú àwọn ìlú àwọn ará Netofa.
17 Àwọn olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà:
Ṣallumu, Akkubu, Talmoni, Ahimani àti arákùnrin wọn, Ṣalumu olóyè wọn, 18 ti wà ní ipò ìdúró ní ẹnu-ọ̀nà ọba ní apá ìhà ìlà-oòrùn títí di àkókò yí. Wọ̀nyí ni àwọn olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà tí ó jẹ́ ti ìpàgọ́ àwọn ará Lefi.
19 Ṣallumu ọmọ Kore ọmọ Ebiasafi, ọmọ Kora, àti àwọn olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà ẹlẹgbẹ́ rẹ̀. Láti ìdílé rẹ̀ (àwọn ará Korati) ni ó dúró fún ṣíṣọ́ ìloro ẹnu-ọ̀nà àgọ́ gẹ́gẹ́ bí baba wọn ti ń dúró fún ṣíṣọ́ àbáwọlé ibùgbé Olúwa.
20 Ní ìgbà àkọ́kọ́ Finehasi ọmọ Eleasari jẹ́ olórí fún àwọn olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà, Olúwa sì wà pẹ̀lú rẹ̀.
21 Sekariah, ọmọ Meṣelemiah jẹ́ olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà ní àbáwọlé sí àgọ́ ibi ìpàdé.
22 Gbogbo rẹ̀ lápapọ̀, àwọn tí a yàn láti jẹ́ olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà ní àwọn ìloro jẹ́ igba ó-lé-méjìlá (212). A ka àwọn wọ̀nyí nípa ìdílé ní ìletò wọn.
Àwọn olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà ni a ti yàn sí ipò láti ọ̀dọ̀ Dafidi àti Samuẹli, aríran, nítorí òtítọ́ wọn. 23 Àwọn àti àwọn ọmọ wọn ni ó wà fún ṣíṣọ́ ẹnu-ọ̀nà ilé Olúwa ilé tí a pè ní àgọ́. 24 Àwọn olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà wà ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin: ìlà-oòrùn, ìwọ̀-oòrùn àríwá àti gúúsù. 25 Àwọn arákùnrin wọn ní àwọn ìletò wọn ní láti wá ní àkókò dé àkókò láti pín iṣẹ́ ìsìn wọn fún àkókò ọjọ́ méje. 26 Ṣùgbọ́n àwọn olórí alábojútó ẹnu-ọ̀nà mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí wọ́n jẹ́ ará Lefi ni a yàn fún àwọn iyàrá àti àwọn àpótí ìṣúra ní ilé Ọlọ́run. 27 Wọ́n á lo gbogbo òru ní dídúró yí ilé Ọlọ́run ká, nítorí wọ́n ní láti ṣọ́ ọ; Wọ́n sì ní àṣẹ sí kọ́kọ́rọ́ fún ṣíṣí i ní àràárọ̀.
28 Díẹ̀ wà ní ìdí ohun èlò tí à ń lò fún ìsìn ilé Ọlọ́run; wọn a máa kà á nígbà tí wọ́n gbé e wọlé àti nígbà tí a kó wọn jáde. 29 Àwọn mìíràn ni a yàn láti bojútó ohun èlò àti gbogbo ohun èlò ilé tí a yà sọ́tọ̀ fún Ọlọ́run, àti ìyẹ̀fun àti ọtí èso àjàrà àti òróró náà, tùràrí àti tùràrí olóòórùn dídùn. 30 Ṣùgbọ́n díẹ̀ nínú àwọn àlùfáà ni ó ń bojútó pípò tùràrí olóòórùn dídùn papọ̀. 31 Ará Lefi tí a sọ ní Mattitiah àkọ́bí ọmọkùnrin Ṣallumu ará Kora ni a yàn, tí ń ṣe alábojútó ohun tí a dín. 32 Àti nínú àwọn arákùnrin wọn, nínú àwọn ọmọ Kohati tó ń ṣe ìtọ́jú àkàrà ìfihàn, láti máa pèsè rẹ̀ ní ọjọọjọ́ ìsinmi.
33 Àwọn tí wọ́n jẹ́ ọkùnrin, olórí àwọn ìdílé Lefi dúró nínú àgọ́ ilé Olúwa, wọn kò sì ṣe lára iṣẹ́ ìsìn yòókù nítorí wọ́n ń ṣe iṣẹ́ náà lọ́sàn, lóru.
34 Gbogbo wọ̀nyí jẹ́ olórí àwọn Lefi, olóyè gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe kọ lẹ́sẹẹsẹ sínú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn, wọ́n sì ń gbé ní Jerusalẹmu.
Ìdílé àti Ìrandíran Saulu
35 Jeieli baba Gibeoni ń gbé ní Gibeoni.
Orúkọ ìyàwó rẹ̀ a máa jẹ́ Maaka, 36 Pẹ̀lú àkọ́bí ọmọkùnrin rẹ̀ jẹ́ Abdoni, tí wọ̀nyí sì ń tẹ̀lé Suri, Kiṣi, Baali, Neri, Nadabu. 37 Gedori, Ahio, Sekariah àti Mikiloti. 38 Mikiloti jẹ́ baba Ṣimeamu, àwọn náà ń gbé ní ẹ̀bá ìbátan wọn ní Jerusalẹmu.
39 Neri jẹ́ baba Kiṣi, Kiṣi baba a Saulu, àti Saulu baba a Jonatani, àti Malikiṣua, Abinadabu àti Eṣi-Baali.
40 Ọmọ Jonatani:
Meribu-Baali, tí ó jẹ́ baba Mika:
41 Àwọn ọmọ Mika:
Pitoni. Meleki, Tarea àti Ahasi.
42 Ahasi jẹ́ baba Jada, Jada jẹ́ baba Alemeti, Asmafeti, Simri, sì Simri jẹ́ baba Mosa. 43 Mosa jẹ́ baba Binea; Refaiah jẹ́ ọmọ rẹ̀, Eleasa ọmọ rẹ̀ àti Aseli ọmọ rẹ̀.
44 Aseli ní ọmọ mẹ́fà, pẹ̀lú wọ̀nyí ni orúkọ wọn:
Asrikamu, Bokeru, Iṣmaeli Ṣeariah, Ọbadiah àti Hanani, gbogbo wọ̀nyí ni ọmọ Aseli.
Saulu gba ẹ̀mí ara rẹ̀
10 (C)Nísinsin yìí, àwọn ará Filistini dojú ìjà kọ Israẹli, Àwọn ará Israẹli sì sálọ kúrò níwájú wọn, a sì pa ọ̀pọ̀ wọn sí orí òkè Gilboa. 2 Àwọn ará Filistini sí lépa Saulu gidigidi àti àwọn ọmọ rẹ̀. Wọ́n sì pa àwọn ọmọ rẹ̀. Jonatani, Abinadabu àti Malikiṣua. 3 Ogun náà sí gbóná janjan fún Saulu, nígbà tí àwọn tafàtafà sì lé e bá, wọ́n sì ṣá a lọ́gbẹ́.
4 Saulu sì sọ fún ẹni tí ó gbé ìhámọ́ra rẹ̀ pé, Fa idà rẹ yọ, kí o sì fi gún mi, kí àwọn aláìkọlà wọ̀nyí má wá láti bú mi.
Ṣùgbọ́n ẹni tí ó ń gbé ìhámọ́ra rẹ̀ ń bẹ̀rù, kò sì le ṣe é; Bẹ́ẹ̀ ni Saulu mú idà tirẹ̀ ó sì ṣubú lé e. 5 Nígbà tí agbé-ìhámọ́ra rí pé Saulu ti kú, òhun pẹ̀lú ṣubú lórí idà tirẹ̀, ó sì kú. 6 Bẹ́ẹ̀ ni Saulu àti ọmọ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta kú, gbogbo ilé rẹ̀ sì kú ṣọ̀kan, lọ́jọ́ kan náà.
7 Nígbà tí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ rí wí pé àwọn ọmọ-ogun ti sálọ àti pé Saulu àti àwọn ọmọ rẹ̀ ti kú wọ́n kọ àwọn ìlú wọn sílẹ̀, wọ́n sì sálọ. Àwọn ará Filistini wá, wọ́n sì jókòó nínú wọn.
8 Ní ọjọ́ kejì, Nígbà tí àwọn ará Filistini wá láti kó òkú, wọ́n rí Saulu àti àwọn ọmọ rẹ̀ tí wọ́n ṣubú sórí òkè Gilboa. 9 Wọ́n bọ́ ní aṣọ, wọ́n sì gbé orí rẹ̀ àti ìhámọ́ra rẹ̀, wọ́n sì rán ìránṣẹ́ lọ káàkiri ilẹ̀ àwọn ará Filistini láti kéde ìròyìn náà láàrín àwọn òrìṣà wọn àti àwọn ènìyàn wọn. 10 Wọ́n gbé ìhámọ́ra rẹ̀ sí inú ilé tí wọ́n kọ́ fún òrìṣà wọn, wọ́n sì fi orí rẹ̀ kọ́ sí inú ilé Dagoni.
11 Nígbà tí gbogbo àwọn olùgbé Jabesi—Gileadi gbọ́ gbogbo ohun tí àwọn ará Filistini ṣe fún Saulu, 12 Gbogbo àwọn akọni ọkùnrin wọn lọ láti mú àwọn ará Saulu àti àwọn ọmọ rẹ̀, wọ́n sì kó wọn wá sí Jabesi. Nígbà náà, wọ́n sin egungun wọn sábẹ́ igi óákù ní Jabesi, wọ́n sì gbààwẹ̀ fún ọjọ́ méje.
13 Saulu kú nítorí kò ṣe òtítọ́ sí Olúwa: Kò pa ọ̀rọ̀ Olúwa mọ́ pẹ̀lú, ó tọ abókùúsọ̀rọ̀ lọ fún ìtọ́sọ́nà. 14 Kò sì béèrè lọ́wọ́ Olúwa, bẹ́ẹ̀ ni Olúwa pa á, Ó sì yí ìjọba náà padà sọ́dọ̀ Dafidi ọmọ Jese.
Ìbáwí àwọn ọmọ Ọlọ́run
12 Nítorí náà bí a ti fi ìkùùkuu àwọsánmọ̀ tí o kún fún àwọn ẹlẹ́rìí tó báyìí yí wa ká, ẹ jẹ́ kí a pa ohun ìdíwọ́ gbogbo tì sí apá kan, àti ẹ̀ṣẹ̀ tí o rọrùn láti di mọ́ wa, kí a sì máa fi sùúrù súré ìje tí a gbé ka iwájú wa, 2 (A)Kí a máa wo Jesu Olùpilẹ̀ṣẹ̀ àti aláṣepé ìgbàgbọ́ wa; ẹni nítorí ayọ̀ tí a gbé ka iwájú rẹ, tí o faradà àgbélébùú láìka ìtìjú sí, tí ó sì jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọlọ́run. 3 Máa ro ti ẹni tí ó faradà irú ìṣọ̀rọ̀-òdì yìí láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ si ara rẹ̀, kí ẹ má ba á rẹ̀wẹ̀sì ni ọkàn yín, kí àárẹ̀ si mu yín.
4 Ẹ̀yin kò sá à tí ì kọ ojú ìjà si ẹ̀ṣẹ̀ títí dé títa ẹ̀jẹ̀ yín sílẹ̀ nínú ìjàkadì yín. 5 (B)Ẹ̀yin sì ti gbàgbé ọ̀rọ̀ ìyànjú tí ó n ba yin sọ̀rọ̀ bí ọmọ pé,
“Ọmọ mi, ma ṣe aláìnání ìbáwí Olúwa,
kí o má sì ṣe rẹ̀wẹ̀sì nígbà tí a bá ń ti ọwọ́ rẹ̀ ba ọ wí:
6 Nítorí pé ẹni ti Olúwa fẹ́, òun ni i bá wí,
a sì máa na olúkúlùkù ọmọ tí òun tẹ́wọ́gbà.”
7 Ẹ máa ní sùúrù lábẹ́ ìbáwí: Ọlọ́run bá wa lò bí ọmọ ni; nítorí pé ọmọ wo ni ń bẹ ti baba kì í bá wí? 8 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin ba wà láìsí ìbáwí, nínú èyí tí gbogbo ènìyàn ti jẹ alábápín, ǹjẹ́ ọmọ àlè ni yín, ẹ kì í sì ṣe ọmọ. 9 Pẹ̀lúpẹ̀lú àwa ni baba wa nípa ti ara tí o ń tọ́ wa, àwa sì ń bu ọlá fún wọn: kò ha yẹ kí a kúkú tẹríba fún Baba àwọn ẹ̀mí, kí a sì yè? 10 Nítorí wọ́n tọ́ wa fún ọjọ́ díẹ̀ bí o bá ti dára lójú wọn; ṣùgbọ́n òun (tọ́ wa) fún èrè wa, kí àwa lè ṣe alábápín ìwà mímọ́ rẹ̀. 11 Gbogbo ìbáwí kò dàbí ohun ayọ̀ nísinsin yìí bí kò ṣe ìbànújẹ́; ṣùgbọ́n níkẹyìn yóò so èso àlàáfíà fún àwọn tí a tọ́ nípa rẹ̀, àní èso òdodo.
12 (C)Nítorí náà, ẹ na ọwọ́ tí ó rọ, àti eékún àìlera; 13 (D)“Kí ẹ sì ṣe ipa ọ̀nà tí ó tọ́ fún ẹsẹ̀ yin,” kí èyí tí ó rọ má bá a kúrò lórí ike ṣùgbọ́n kí a kúkú wò ó sàn.
Ìkìlọ̀ lòdì sí kíkọ Ọlọ́run
14 Ẹ máa lépa àlàáfíà pẹ̀lú ènìyàn gbogbo, àti ìwà mímọ́, láìsí èyí yìí kò sí ẹni tí yóò rí Olúwa: 15 (E)Ẹ máa kíyèsára kí ẹnikẹ́ni má ṣe kùnà oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run; kí “gbòǹgbò ìkorò” kan máa ba hù sókè kí ó sì yọ yín lẹ́nu, ọ̀pọ̀lọpọ̀ a sì ti ipa rẹ̀ di àìmọ́. 16 (F)Kí o má bá à si àgbèrè kan tàbí aláìwà-bí-Ọlọ́run bi Esau, ẹni tí o tìtorí òkèlè oúnjẹ kan ta ogún ìbí rẹ̀. 17 (G)Nítorí ẹ̀yin mọ pé lẹ́yìn náà, nígbà tí ó fẹ́ láti jogún ìbùkún náà, a kọ̀ ọ́, nítorí kò ri ààyè ìrònúpìwàdà, bí o tilẹ̀ jẹ́ pé ó fi omijé wa a gidigidi.
18 (H)Nítorí ẹ̀yin kò wá òkè tí a lè fi ọwọ́ kàn, àti ti iná ti ń jó, àti ti ìṣúdudu àti òkùnkùn, àti ìjì. 19 Àti ìró ìpè, àti ohùn ọ̀rọ̀, èyí tí àwọn tí o gbọ́ bẹ̀bẹ̀ pé, kí a má ṣe sọ ọ̀rọ̀ sí i fún wọn mọ́: 20 (I)Nítorí pé wọn kò lè gba ohun tí ó paláṣẹ, “Bí o tilẹ̀ jẹ ẹranko ni ó fi ara kan òkè náà, a ó sọ ọ́ ni òkúta.” 21 (J)Ìran náà sì lẹ́rù to bẹ́ẹ̀ tí Mose wí pé, “Ẹ̀rù ba mi gidigidi mo sì wárìrì.”
22 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin wá sí òkè Sioni, àti sí ìlú Ọlọ́run alààyè, ti Jerusalẹmu ti ọ̀run, àti si ẹgbẹ́ àwọn angẹli àìníye, 23 Si àjọ ńlá tí ìjọ àkọ́bí tí a ti kọ orúkọ wọn ni ọ̀run, àti sọ́dọ̀ Ọlọ́run onídàájọ́ gbogbo ènìyàn, àti sọ́dọ̀ àwọn ẹ̀mí olóòtítọ́ ènìyàn tí a ṣe ni àṣepé, o 24 (K)Àti sọ́dọ̀ Jesu alárinà májẹ̀mú tuntun, àti si ibi ẹ̀jẹ̀ ìbùwọ́n ni, ti ń sọ̀rọ̀ ohun tí ó dára ju ti Abeli lọ.
25 (L)Kíyèsi i, kí ẹ má ṣe kọ̀ ẹni tí ń kìlọ̀. Nítorí bí àwọn wọ̀nyí kò bá bọ́ nígbà tí wọn kọ̀ ẹni ti ń kìlọ̀ ni ayé, mélòó mélòó ni àwa kì yóò bọ́, bí àwa ba pẹ̀hìndà sí ẹni tí ń kìlọ̀ láti ọ̀run wá: 26 (M)Ohùn ẹni tí ó mi ayé nígbà náà: ṣùgbọ́n nísinsin yìí o ti ṣe ìlérí, wí pé, “Lẹ́ẹ̀kan sí i èmi ki yóò mi kìkì ayé nìkan, ṣùgbọ́n ọ̀run pẹ̀lú.” 27 Àti ọ̀rọ̀ yìí, “Lẹ́ẹ̀kan sí i,” ìtumọ̀ rẹ̀ ni, mímú àwọn ohun wọ̀nyí ti a ń mì kúrò, bí ohun tí a ti dá, kí àwọn ohun tí a kò lè mì lè wà síbẹ̀.
28 Nítorí náà bí àwa tí ń gbà ilẹ̀ ọba ti a kò lè mì, ẹ jẹ́ kí a dá ọpẹ́ nípa èyí ti a fi lè máa sin Ọlọ́run ni ìtẹ́wọ́gbà pẹ̀lú ọ̀wọ̀ àti ìbẹ̀rù rẹ̀. 29 (N)Nítorí pé, “Ọlọ́run wa, iná ti ń jó ni run ni.”
Ègbé ni fún àwọn tí ara rọ̀
6 Ègbé ni fún ẹ̀yin tí ará rọ̀ ní Sioni
àti ẹ̀yin tí ẹ wà ní abẹ́ ààbò ní òkè Samaria
àti ẹ̀yin olókìkí orílẹ̀-èdè
tí ẹ̀yin ènìyàn Israẹli máa ń tọ̀ ọ́ wá
2 Ẹ lọ Kalne kí ẹ lọ wò ó
kí ẹ sí tí ibẹ̀ lọ sí Hamati ìlú ńlá a nì.
Kí ẹ sì tún sọ̀kalẹ̀ lọ Gati ní ilẹ̀ Filistini
Ǹjẹ́ wọ́n ha dára ju ìpínlẹ̀ yín méjèèjì lọ?
Ǹjẹ́ a ha rí ilẹ̀ tó tóbi ju tiyín lọ bí?
3 Ẹ̀yin sún ọjọ́ ibi síwájú,
ẹ sì mú ìjọba òǹrorò súnmọ́ tòsí
4 Ẹ̀yin sùn lé ibùsùn tí a fi eyín erin ṣe
ẹ sì tẹ́ ara sílẹ̀ ni orí àwọn ibùsùn
ẹyin pa èyí tí o dára nínú àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn yín jẹ
ẹ sì ń pa àwọn ọ̀dọ́ màlúù láàrín agbo wọn jẹ
5 Ẹ̀yin ń lo ohun èlò orin bí i Dafidi
ẹ sì ń ṣe àwọn àpilẹ̀rọ àwọn ohun èlò orin
6 Ẹ̀yin mu wáìnì ẹ̀kún ọpọ́n kan
àti ìkunra tí o dára jùlọ
ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò káàánú ilé Josẹfu tí ó di ahoro
7 Nítorí náà, àwọn ni yóò lọ sí ìgbèkùn
pẹ̀lú àwọn tí ó ti kó lọ sí ìgbèkùn
àsè àwọn tí ń ṣe àṣelékè ni a ó mú kúrò.
Olúwa Kórìíra Ìgbéraga Ọmọ Israẹli
8 Olúwa Olódùmarè ti búra fúnrarẹ̀, Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun sì ti wí pé:
“Mo kórìíra ìgbéraga Jakọbu
n kò sì ní inú dídùn sí odi alágbára rẹ̀
Èmi yóò sì fa ìlú náà lé wọn lọ́wọ́
àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀.”
9 Bí Ọkùnrin mẹ́wàá bá ṣẹ́kù nínú ilé kan, àwọn náà yóò kú 10 Bí ẹbí tí ó yẹ kí ó gbé òkú wọn jáde fún sínsin bá wọlé, bí o ba sì béèrè pé ǹjẹ́ ẹnìkan wa tí ó fi ara pamọ́ níbẹ̀, “Ǹjẹ́ ẹnìkankan wà lọ́dọ̀ yín?” tí ó bá sì dáhùn wí pé, “Rárá,” nígbà náà ni yóò wí pé, “Pa ẹnu rẹ mọ́ àwa kò gbọdọ̀ dárúkọ Olúwa.”
11 Nítorí Olúwa tí pa àṣẹ náà,
Òun yóò sì wó ilé ńlá náà lulẹ̀ túútúú
Àti àwọn ilé kéékèèkéé sí wẹ́wẹ́.
12 Ǹjẹ́ ẹṣin a máa sáré lórí àpáta bí?
Ǹjẹ́ ènìyàn a máa fi akọ màlúù kọ ilẹ̀ níbẹ̀?
Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti yí òtítọ́ padà sí májèlé
ẹ sì ti sọ èso òdodo di ìkorò.
13 Ẹ̀yin yọ̀ torí ìṣẹ́gun lórí Lo-Debari
Ẹ̀yin sì wí pé, “Ṣé kì í ṣe agbára wa ni àwa fi gba Karnaimu?”
14 Nítorí Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun wí pé,
“Èmi yóò gbé orílẹ̀-èdè kan dìde sí ọ ìwọ Israẹli,
wọn yóò pọ́n yín lójú ní gbogbo ọ̀nà,
láti Lebo-Hamati, títí dé pẹ̀tẹ́lẹ̀ Arabah.”
Maria bẹ Elisabeti wò
39 Ní àkókò náà ni Maria sì dìde, ó lọ kánkán sí ilẹ̀ òkè, sí ìlú kan ní Judea; 40 Ó sì wọ ilé Sekariah lọ ó sì kí Elisabeti. 41 Ó sì ṣe, nígbà tí Elisabeti gbọ́ kíkí Maria, ọlẹ̀ sọ nínú rẹ̀; Elisabeti sì kún fún Ẹ̀mí mímọ́; 42 (A)Ó sì ké ní ohùn rara, ó sì wí pé, “Alábùkún fún ni ìwọ nínú àwọn obìnrin, alábùkún fún sì ni ọmọ tí ìwọ yóò bí. 43 Èéṣe tí èmi fi rí irú ojúrere yìí, tí ìyá Olúwa mi ìbá fi tọ̀ mí wá? 44 Sá wò ó, bí ohùn kíkí rẹ ti bọ́ sí mi ní etí, ọlẹ̀ sọ nínú mi fún ayọ̀. 45 Alábùkún fún sì ni ẹni tí ó gbàgbọ́: nítorí nǹkan wọ̀nyí tí a ti sọ fún un láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá yóò ṣẹ.”
Orin Maria
46 Maria sì dáhùn, ó ní:
“Ọkàn mi yin Olúwa lógo,
47 Ẹ̀mí mi sì yọ̀ sí Ọlọ́run Olùgbàlà mi.
48 Nítorí tí ó ṣíjú wo ìwà ìrẹ̀lẹ̀
ọmọbìnrin ọ̀dọ̀ rẹ̀: Sá wò ó.
Láti ìsinsin yìí lọ gbogbo ìran ènìyàn ni yóò máa pè mí ní alábùkún fún.
49 Nítorí ẹni tí ó ní agbára ti ṣe ohun tí ó tóbi fún mi;
Mímọ́ sì ni orúkọ rẹ̀.
50 Àánú rẹ̀ sì ń bẹ fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀
láti ìrandíran.
51 Ó ti fi agbára hàn ní apá rẹ̀;
o ti tú àwọn onígbèéraga ká ní ìrònú ọkàn wọn.
52 Ó ti mú àwọn alágbára kúrò lórí ìtẹ́ wọn,
o sì gbé àwọn onírẹ̀lẹ̀ lékè.
53 Ó ti fi ohun tí ó dára kún àwọn tí ebi ń pa
ó sì rán àwọn ọlọ́rọ̀ padà ní òfo.
54 Ó ti ran Israẹli ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ lọ́wọ́,
Ní ìrántí àánú rẹ̀;
55 (B)sí Abrahamu àti àwọn ìran rẹ̀ láéláé, baba wa,
àti bí ó ti sọ fún àwọn baba wa.”
56 Maria sì jókòó tì Elisabeti níwọ̀n oṣù mẹ́ta, ó sì padà lọ sí ilé rẹ̀.
Ìbí Johanu onítẹ̀bọmi
57 Nígbà tí ọjọ́ Elisabeti pé tí yóò bí; ó sì bí ọmọkùnrin kan. 58 Àwọn aládùúgbò, àti àwọn ìbátan rẹ̀ gbọ́ bí Olúwa ti fi àánú ńlá hàn fún un, wọ́n sì bá a yọ̀.
59 (C)Ó sì ṣe, ní ọjọ́ kẹjọ wọ́n wá láti kọ ọmọ náà nílà; wọ́n sì fẹ́ sọ orúkọ rẹ̀ ní Sekariah, gẹ́gẹ́ bí orúkọ baba rẹ̀. 60 Ìyá rẹ̀ sì dáhùn, ó ní, “Bẹ́ẹ̀ kọ́! Johanu ni a ó pè é.”
61 Wọ́n sì wí fún un pé, “Kò sí ọ̀kan nínú àwọn ará rẹ̀ tí à ń pè ní orúkọ yìí.”
62 Wọ́n sì ṣe àpẹẹrẹ sí baba rẹ̀, bí ó ti ń fẹ́ kí a pè é. 63 Ó sì béèrè fún wàláà, ó sì kọ ọ wí pé, “Johanu ni orúkọ rẹ̀.” Ẹnu sì ya gbogbo wọn. 64 Ẹnu rẹ̀ sì ṣí lọ́gán, okùn ahọ́n rẹ̀ sì tú, ó sì sọ̀rọ̀, ó sì ń yin Ọlọ́run. 65 Ẹ̀rù sì ba gbogbo àwọn tí ń bẹ ní agbègbè wọn: a sì ròyìn gbogbo nǹkan wọ̀nyí ká gbogbo ilẹ̀ òkè Judea. 66 Ó sì jẹ́ ohun ìyanu fún gbogbo àwọn tí ó gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n sì tò ó sínú ọkàn wọn, wọ́n ń wí pé, “Irú-ọmọ kín ni èyí yóò jẹ́?” Nítorí tí ọwọ́ Olúwa wà pẹ̀lú rẹ̀.
Orin Ṣakariah
67 Sekariah baba rẹ̀ sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, ó sì sọtẹ́lẹ̀, ó ní:
68 “Olùbùkún ni Olúwa Ọlọ́run Israẹli;
nítorí tí ó ti bojú wò, tí ó sì ti dá àwọn ènìyàn rẹ̀ nídè,
69 Ó sì ti gbé ìwo ìgbàlà sókè fún wa
ní ilé Dafidi ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀;
70 (bí ó ti sọtẹ́lẹ̀ láti ẹnu àwọn wòlíì rẹ̀ mímọ́ tipẹ́tipẹ́),
71 Pé, a ó gbà wá là lọ́wọ́
àwọn ọ̀tá wa àti lọ́wọ́ àwọn tí ó kórìíra wá.
72 Láti ṣe àánú tí ó ṣèlérí fún àwọn baba wa,
àti láti rántí májẹ̀mú rẹ̀ mímọ́,
73 ìbúra tí ó ti bú fún Abrahamu baba wa,
74 láti gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa,
kí àwa kí ó lè máa sìn láìfòyà,
75 ni ìwà mímọ́ àti ní òdodo níwájú rẹ̀, ní ọjọ́ ayé wa gbogbo.
76 (D)“Àti ìwọ, ọmọ mi, wòlíì Ọ̀gá-ògo jùlọ ni a ó máa pè ọ́:
nítorí ìwọ ni yóò ṣáájú Olúwa láti tún ọ̀nà rẹ̀ ṣe;
77 (E)láti fi ìmọ̀ ìgbàlà fún àwọn ènìyàn rẹ̀
fún ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ wọn,
78 (F)nítorí ìyọ́nú Ọlọ́run wà;
nípa èyí tí ìlà-oòrùn láti òkè wá bojú wò wá,
79 (G)Láti fi ìmọ́lẹ̀ fún àwọn tí ó jókòó ní
òkùnkùn àti ní òjìji ikú,
àti láti fi ẹsẹ̀ wa lé ọ̀nà àlàáfíà.”
80 (H)Ọmọ náà sì dàgbà, ó sì le ní ọkàn, ó sì ń gbé ní ijù títí ó fi di ọjọ́ ìfihàn rẹ̀ fún Israẹli.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.