M’Cheyne Bible Reading Plan
Dafidi di ọba lórí Israẹli
11 (A)Gbogbo àwọn Israẹli kó ara wọn jọ pọ̀ sí ọ̀dọ̀ Dafidi ní Hebroni, wọ́n sì wí pé, “Ẹran-ara rẹ àti ẹ̀jẹ̀ rẹ ni àwa í ṣe. 2 Ní àtijọ́, kódà nígbà tí Saulu jẹ ọba, ìwọ ni ẹni tí ó darí Israẹli ní ojú ogun wọn. Olúwa Ọlọ́run rẹ sì wí fún ọ pé, ‘Ìwọ yóò sì jẹ́ olùṣọ́ Israẹli ènìyàn mi, ìwọ yóò sì jẹ́ olórí fún wọn.’ ”
3 Nígbà tí gbogbo àwọn ìjòyè Israẹli tí wọ́n ti wá sọ́dọ̀ ọba Dafidi ni Hebroni. Ó sì ṣe májẹ̀mú pẹ̀lú wọn ní Hebroni níwájú Olúwa, wọ́n sì fi òróró yan Dafidi ní ọba lórí Israẹli, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa láti ọwọ́ Samuẹli.
Dafidi borí Jerusalẹmu
4 (B)Dafidi àti gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jáde lọ sí Jerusalẹmu (tí ṣe Jebusi). Àwọn Jebusi ara ilẹ̀ náà ń gbé níbẹ̀. 5 Àwọn ará ìlú Jebusi sì wí fún Dafidi pé, “Ìwọ kò sì gbọdọ̀ wọ ìhín yìí wá.” Ṣùgbọ́n Dafidi kó ìlú odi Sioni—èyí tí í ṣe ìlú Dafidi.
6 Dafidi ti wí pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá tètè kọlu àwọn ará Jebusi ni yóò di olórí àti balógun.” Joabu ọmọ Seruiah sì kọ́kọ́ gòkè lọ, bẹ́ẹ̀ ni ó sì gba olórí.
7 Dafidi sì ń gbé inú ìlú odi, nítorí náà ni wọ́n fi ń pè é ni ìlú Dafidi. 8 Ó sì kọ́ àwọn ìlú náà yíkákiri; láti Millo yíkákiri; Joabu sì tún ìyókù àwọn ìlú náà ṣe. 9 Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi ń ga, ó sì pọ̀ sí i, nítorí pé Olúwa àwọn ọmọ-ogun wà pẹ̀lú rẹ̀.
Dafidi alágbára ọkùnrin
10 (C)Àwọn wọ̀nyí sì ni ìjòyè alágbára ọkùnrin Dafidi, àwọn pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n sì fún ìjọba rẹ̀ ní àtìlẹ́yìn tó lágbára láti mú un tàn káàkiri gbogbo ilẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti ṣèlérí: 11 Èyí sì ni iye àwọn akọni ọkùnrin Dafidi:
Jaṣobeamu ọmọ Hakumoni, òun sì ni olórí nínú àwọn ìjòyè, ó sì gbé ọ̀kọ̀ rẹ̀ sókè lórí àwọn ọ̀ọ́dúnrún ènìyàn, àwọn ẹni tí ó pa ní ogun ẹ̀ẹ̀kan.
12 Lẹ́yìn rẹ̀ sì ni Eleasari ọmọ Dodo àwọn ará Ahohi, ọ̀kan lára àwọn mẹ́ta ọkùnrin alágbára. 13 Ó sì wà pẹ̀lú Dafidi ní Pasi-Dammimu nígbà tí àwọn ará Filistini kó ara wọn jọ láti jagun, níbi tí ilẹ̀ kan wà tí ó kún fún ọkà barle. Àwọn ènìyàn sì sálọ kúrò níwájú Filistini. 14 Ṣùgbọ́n wọ́n mú ìdúró wọn ní àárín pápá náà. Wọ́n sì gbà a wọ́n sì gún àwọn ará Filistini mọ́lẹ̀, Olúwa sì mú ìgbàlà ńlá fún wọn.
15 Mẹ́ta nínú àwọn ọgbọ̀n ìjòyè sọ̀kalẹ̀ tọ́ Dafidi wá lọ sí orí àpáta nínú ihò Adullamu; Nígbà tí àwọn ẹgbẹ́ Filistini sì dúró ní Àfonífojì ní orí òkè Refaimu. 16 Ní àsìkò náà Dafidi sì ń bẹ nínú ìlú odi, ẹgbẹ́ ogun àwọn ará Filistini sì ń bẹ ní Bẹtilẹhẹmu. 17 Dafidi sí pòǹgbẹ fún omi ó sì wí pé, Háà, ẹnìkan yóò ha bu omi láti inú kànga ní ẹ̀gbẹ́ ẹnu-bodè Bẹtilẹhẹmu fún un mu? 18 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn mẹ́ta náà sì là láti ogun ará Filistini, ó sì fa omi jáde láti inú kànga ní ẹ̀gbẹ́ ẹnu-bodè Bẹtilẹhẹmu ó sì gbé padà tọ Dafidi wá. Ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti mu ú: dípò, ó sì tú jáde níwájú Olúwa. 19 “Kí Ọlọ́run dẹ́kun kí èmi ó má ṣe ṣe èyí!” ó wí pé. “Ṣé kí èmi kí ó mú ẹ̀jẹ̀ ọkùnrin yí ẹni tí ó fi ẹ̀mí rẹ̀ wéwu?” Nítorí wọ́n fi ẹ̀mí wọn wéwu láti mú padà wá, Dafidi kò ní mu ú.
Nǹkan wọ̀nyí ni àwọn akọni mẹ́ta ọkùnrin náà ṣe ohun ìyanu ńlá.
20 Abiṣai arákùnrin Joabu ìjòyè àwọn mẹ́ta. Ó sì gbé ọ̀kọ̀ rẹ̀ sókè lórí àwọn ọ̀ọ́dúnrún àwọn ènìyàn, àwọn ẹni tí ó pa, bẹ́ẹ̀ ni ó sì di olókìkí gẹ́gẹ́ bí àwọn mẹ́ta. 21 Ó sì gba ìlọ́po ọlá lórí àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ó sì di olórí wọn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò ka kún ara wọn.
22 Benaiah ọmọ Jehoiada ó sì jẹ́ akọni oníjà láti Kabṣeeli, ẹni tí ó ṣe iṣẹ́ agbára ńlá. Ó sì pa àwọn ọmọ Arieli méjì ti Moabu, ó sì tún sọ̀kalẹ̀ lọ sí inú ihò lákokò sno (yìnyín dídì), ó sì pa kìnnìún kan 23 Ó sì pa ara Ejibiti ẹni tí ó ga ní ìwọ̀n ẹsẹ̀ méje àti ààbọ̀ ṣùgbọ́n àwọn ará Ejibiti wọn ní ọ̀kọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdábùú igi ahunṣọ àti ọ̀pá ní ọwọ́ rẹ̀, Benaiah sọ̀kalẹ̀ lórí rẹ̀ pẹ̀lú kùmọ̀. Ó sì gba ọ̀kọ̀ náà láti ọwọ́ ará Ejibiti ó sì pa á pẹ̀lú ọ̀kọ̀ rẹ̀. 24 Nǹkan wọ̀nyí sì ní ìwà akin Benaiah ọmọ Jehoiada; ohun náà pẹ̀lú sì di olókìkí gẹ́gẹ́ bí àwọn akọni ọkùnrin mẹ́ta. 25 Ó sì ní ọlá púpọ̀ ju àwọn ọgbọ̀n lọ, ṣùgbọ́n a kò kà á láàrín àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Dafidi sì fi sí ìkáwọ́ àwọn ẹ̀ṣọ́.
26 Àwọn akọni ọkùnrin náà nìyí:
Asaheli arákùnrin Joabu,
Elhanani ọmọ Dodo láti Bẹtilẹhẹmu,
27 Ṣamotu ará Harori,
Helesi ará Peloni
28 Ira ọmọ Ikẹsi láti Tekoa,
Abieseri láti Anatoti,
29 Sibekai ará Huṣati,
láti ará Ahohi
30 Maharai ará Netofa,
Heledi ọmọ Baanah ará Netofa,
31 Itai ọmọ Ribai láti Gibeah ní Benjamini,
Benaiah ará Piratoni,
32 Hurai láti Àfonífojì Gaaṣi,
Abieli ará Arbati,
33 Asmafeti ará Bahurimu
Eliaba ará Ṣaalboni
34 Àwọn ọmọ Haṣemu ará Gisoni
Jonatani ọmọ Ṣage ará Harari.
35 Ahiamu ọmọ Sakari ará Harari,
Elifali ọmọ Uri
36 Heferi ará Mekerati,
Ahijah ará Peloni,
37 Hesro ará Karmeli
Naarai ọmọ Esbai,
38 Joeli arákùnrin Natani
Mibari ọmọ Hagari,
39 Seleki ará Ammoni,
Naharai ará Beroti ẹni tí ó jẹ́ ẹni tí n ru ìhámọ́ra Joabu ọmọ Seruiah.
40 Ira ará Itri,
Garebu ará Itri,
41 Uriah ará Hiti
Sabadi ọmọ Ahlai.
42 Adina ọmọ Ṣina ará Reubeni, ẹni tí ó jẹ́ ìjòyè ará Reubeni, àti pẹ̀lú ọgbọ́n rẹ̀.
43 Hanani ọmọ Maaka.
Jehoṣafati ará Mitini.
44 Ussia ará Asiterati,
Ṣama àti Jeieli àwọn ọmọ Hotami ará Aroeri,
45 Jediaeli ọmọ Ṣimri,
àti arákùnrin Joha ará Tisi
46 Elieli ará Mahafi
Jeribai àti Joṣafia àwọn ọmọ Elnaamu,
Itimah ará Moabu,
47 Elieli, Obedi àti Jaasieli ará Mesoba.
Àwọn ọ̀gágun tí ó dúró ti Dafidi
12 Àwọn wọ̀nyí ni ọkùnrin tí ó wá sí ọ̀dọ̀ Dafidi ní Siklagi, nígbà tí ó sá kúrò níwájú Saulu ọmọ Kiṣi (Wọ́n wà lára àwọn jagunjagun ẹni tí ó ràn án lọ́wọ́ láti ibi ìjà. 2 Wọ́n sì mú wọn pẹ̀lú ìtẹríba wọ́n sì lágbára láti ta ọfà tàbí láti ta kànnàkànnà òkúta ní ọwọ́ òsì tàbí ní ọwọ́ ọ̀tún, wọ́n sì jẹ́ ìbátan ọkùnrin Saulu láti ẹ̀yà Benjamini):
3 Ahieseri Olórí wọn àti Joaṣi àwọn ọmọ Ṣemaah ará Gibeah:
Jeṣieli àti Peleti ọmọ Asmafeti,
Beraka, Jehu ará Anatoti. 4 Àti Iṣmaiah ará Gibeoni, ọkùnrin alágbára kan lára àwọn ọgbọ̀n ẹni tí ó jẹ́ olórí nínú àwọn ọgbọ̀n;
Jeremiah, Jahasieli, Johanani, Josabadi ará Gedera, 5 Elusai, Jerimoti, Bealiah, Ṣemariah àti Ṣefatia ará Harufiti;
6 Elkana, Iṣiah, Asareeli, Joeseri àti Jaṣobeamu ará Kora;
7 Àti Joela, àti Sebadiah àwọn ọmọ Jerohamu láti Gedori.
8 Díẹ̀ lára àwọn ará Gadi yà sọ́dọ̀ Dafidi ní ibi gíga ní aginjù. Wọ́n sì jẹ́ onígboyà ológun tí ó múra fún ogun tí ó sì lágbára láti di asà àti ẹṣin mú. Ojú wọn sì dàbí ojú kìnnìún, wọ́n sì yára bí àgbọ̀nrín lórí àwọn òkè.
9 Eseri sì jẹ́ ìjòyè,
Ọbadiah sì jẹ́ igbákejì akọgun, Eliabu ẹlẹ́kẹta,
10 Miṣimana ẹlẹ́kẹrin, Jeremiah ẹlẹ́karùnún
11 Attai ẹlẹ́kẹfà, Elieli èkeje,
12 Johanani ẹlẹ́kẹjọ Elsabadi ẹlẹ́kẹsànán
13 Jeremiah ẹlẹ́kẹwàá àti Makbannai ẹlẹ́kọkànlá.
14 Àwọn ará Gadi wọ́n sì jẹ́ olórí ogun; ẹni tí ó kéré jù sì jẹ́ àpapọ̀ ọgọ́rùn-ún, àti fún ẹni tí ó pọ̀jù fún ẹgbẹ̀rún. 15 Àwọn ni ẹni tí ó rékọjá Jordani ní oṣù àkọ́kọ́ nígbà tí ó kún bo gbogbo bèbè rẹ̀, wọ́n sì lé gbogbo àwọn tí ó ń gbé nínú Àfonífojì, lọ sí ìlà-oòrùn àti níhà ìwọ̀-oòrùn.
16 Ìyókù ará Benjamini àti àwọn díẹ̀ ọkùnrin láti Juda lọ sí ọ̀dọ̀ Dafidi ní ibi gíga. 17 Dafidi sì lọ láti lọ pàdé wọn ó sì wí fún wọn pé, “Tí ẹ bá wá sọ́dọ̀ mi lálàáfíà, láti ràn mí lọ́wọ́ mo ṣetán láti mú un yín wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú mi ṣùgbọ́n tí ẹ bá wá láti dá mi sí fún àwọn ọ̀tá mi nígbà tí ọwọ́ mi bá mọ́ kúrò nínú ìwà agbára, kí Ọlọ́run àwọn baba wa kí ó sì ri kí ó sì ṣe ìdájọ́.”
18 Nígbà náà Ẹ̀mí Mímọ́ wa sórí Amasai ìjòyè àwọn ọgbọ̀n, ó sì wí pé:
“Tìrẹ ni àwa ń ṣe, ìwọ Dafidi!
Àwa pẹ̀lú rẹ, ìwọ ọmọ Jese!
Àlàáfíà, àlàáfíà fún ọ,
àti àlàáfíà fún àwọn tí ó ràn ó lọ́wọ́,
nítorí Ọlọ́run rẹ̀ yóò ràn ọ́ lọ́wọ́.”
Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi sì gbà wọ́n ó sì mú wọn jẹ olórí ẹgbẹ́ ogun.
19 Díẹ̀ nínú àwọn ọkùnrin Manase sì yà sí ọ̀dọ̀ Dafidi nígbà tí ó lọ pẹ̀lú àwọn ará Filistini láti bá Saulu jà. (Òun àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ wọn kò sì ran ará Filistini lọ́wọ́ nítorí, lẹ́yìn tiwọn sọ̀rọ̀ papọ̀, àwọn olórí wọn rán wọn jáde, wọ́n sì wí pé, “Yóò jẹ́ ìparun fún wa tí ó bá padà tọ ọ̀gá rẹ̀ Saulu lọ.”) 20 Nígbà tí Dafidi lọ sí Siklagi, àwọn wọ̀nyí ni ọkùnrin ti Manase ẹni tí ó sì yà sọ́dọ̀ rẹ̀. Adina, Josabadi, Jediaeli, Mikaeli, Josabadi, Elihu àti Siletai, àwọn olórí ìrẹ́pọ̀ ti ẹgbẹgbẹ̀rún ní Manase. 21 Wọ́n sì ran Dafidi lọ́wọ́ lórí ẹgbẹ́ ogun náà, nítorí gbogbo wọn ni akọni ènìyàn àwọn sì tún ni olórí nínú àwọn ọmọ-ogun rẹ̀. 22 Ọjọ́ dé ọjọ́ ni àwọn ọkùnrin wá láti ran Dafidi lọ́wọ́, títí tí ó fi ní àwọn ológun ńlá, bí ogun Ọlọ́run.
Àwọn tókù darapọ̀ pẹ̀lú Dafidi ní Hebroni
23 Àwọn wọ̀nyí sì ni iye ọkùnrin tí ó ti di ìhámọ́ra fún ogun àwọn ẹni tí ó wá sọ́dọ̀ Dafidi ní Hebroni láti yí ìjọba Dafidi padà sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ:
24 Ọkùnrin Juda, tí o ń gbé asà àti ọ̀kọ̀, ẹgbàáta lé lọ́gọ́rin (6,080) tí ó ti di ìhámọ́ra fún ogun;
25 Àwọn ọkùnrin Simeoni, akọni tó mú fún ogun sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin ó-lé-ọgọ́rùn-ún (7,100);
26 Àwọn ọkùnrin Lefi ẹgbàajì ó le ẹgbẹ̀ta (4,600), 27 Pẹ̀lú Jehoiada, olórí ìdílé Aaroni pẹ̀lú ẹgbẹ̀ẹ́dógún ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ènìyàn (3,700), 28 Àti Sadoku akọni ọ̀dọ́mọkùnrin, pẹ̀lú àwọn (22) méjìlélógún ìjòyè láti ọ̀dọ̀ àwọn ìdílé rẹ̀;
29 Àwọn arákùnrin Benjamini ìbátan ọkùnrin Saulu ẹgbẹ̀ẹ́dógún (3,000), ọ̀pọ̀ nínú àwọn ẹni tí ó si kù ní olóòtítọ́ sí ilé Saulu títí di ìgbà náà;
30 àwọn arákùnrin Efraimu, ògbójú akọni, ènìyàn Ọlọ́run ni wọ́n nílé baba wọn ẹgbàáwàá ó le ẹgbẹ̀rin (20,800).
31 Àwọn ọkùnrin nínú ààbọ̀ ẹ̀yà Manase, tí a yàn nípa orúkọ láti wá àti láti yan Dafidi gẹ́gẹ́ bí ọba, ẹgbàásàn án (18,000).
32 Àti ní ti àwọn ọmọ Isakari, àwọn ẹni tí ó ní òye àkókò, láti mọ ohun tí Israẹli ìbá máa ṣe; olórí wọn jẹ́ ìgbà (200); àti gbogbo àwọn ìbátan wọn ń bẹ ní ìkáwọ́ wọn.
33 Àwọn ọkùnrin Sebuluni, àti àwọn jagunjagun tí ó ti nípa ogun múra fún ogun pẹ̀lú oríṣìíríṣìí ohun èlò ìjà, láti ran Dafidi lọ́wọ́ pẹ̀lú àwọn tí kò fi iyèméjì ṣe ìjólóòótọ́ wọn jẹ́ ẹgbàá-mẹ́dọ́gbọ̀n (50,000).
34 Àwọn ọkùnrin Naftali, ẹgbẹ̀rún (1,000) ìjòyè àpapọ̀ pẹ̀lú ẹgbàá-méjì-dínlógún (36,000). Ọkùnrin tí wọ́n gbé asà àti ọ̀kọ̀ wọn.
35 Àwọn ọkùnrin Dani, tí wọ́n ṣetán fún ogun ẹgbàá-mẹ́tàlá (28,600)
36 Àwọn ọkùnrin Aṣeri, àwọn tí ó ti ní ìmọ̀ ogun múra fún ogun ọ̀kẹ́ méjì (40,000).
37 Láti ìlà-oòrùn Jordani, ọkùnrin Reubeni, Gadi, àti ìdajì ẹ̀yà Manase, dìmọ́ra pẹ̀lú gbogbo onírúurú ohun èlò ìjà ọ̀kẹ́ mẹ́fà (120,000).
38 Gbogbo èyí ni àwọn ọkùnrin ológun tí ó fi ara wọn fún ogun láti ṣe iṣẹ́ fún nínú ẹgbẹ́.
Wọ́n wá sí Hebroni tí ó kún fún ìpinnu láti fi Dafidi jẹ́ ọba lórí gbogbo Israẹli. Gbogbo àwọn ìyókù lára àwọn ọmọ Israẹli sì jẹ́ onínú kan láti fi Dafidi jẹ ọba 39 Àwọn ọkùnrin náà lo ọjọ́ mẹ́ta níbẹ̀ pẹ̀lú Dafidi, wọ́n jẹ, wọ́n sì ń mu, nítorí ìdílé wọn ti pèsè oúnjẹ fún wọn. 40 Àwọn aládùúgbò láti ọ̀nà jíjìn gẹ́gẹ́ bí Isakari, Sebuluni àti Naftali gbé oúnjẹ wá lórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, lórí Ràkunmí, àti lórí ìbáaka àti lórí màlúù, àní oúnjẹ ti ìyẹ̀fun, èso àjàrà gbígbẹ, èso ọ̀pọ̀tọ́, àkàrà dídùn, ọtí wáìnì, òróró, màlúù àti àgùntàn, nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ayọ̀ wà ní Israẹli.
Ìparí àwọn ọ̀rọ̀ ìyànjú náà
13 Kí ìfẹ́ ará kí o wà títí. 2 (A)Ẹ má ṣe gbàgbé láti máa ṣe àlejò; nítorí pé nípa bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlòmíràn ṣe àwọn angẹli ní àlejò láìmọ̀. 3 Ẹ máa rántí àwọn òǹdè bí ẹni tí a dè pẹ̀lú wọn, àti àwọn tí a ń pọn lójú bí ẹ̀yin tìkára yín pẹ̀lú tí ń bẹ nínú ara.
4 Kí ìgbéyàwó lọ́lá láàrín gbogbo ènìyàn, kí àkéte si jẹ́ aláìléèérí: Nítorí àwọn àgbèrè àti àwọn panṣágà ni Ọlọ́run yóò dá lẹ́jọ́. 5 (B)Kí ọkàn yín má ṣe fà sí ìfẹ́ owó, ki ohun tí ẹ ní tó yin; nítorí òun tìkára rẹ̀ ti wí pé,
“Èmi kò jẹ́ fi ọ́ sílẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ni èmi kò jẹ́ kọ̀ ọ́ sílẹ̀.”
6 (C)Nítorí náà ni àwa ṣe ń fi ìgboyà wí pé,
“Olúwa ni olùrànlọ́wọ́ mi, èmi kì yóò bẹ̀rù;
kín ni ènìyàn lè ṣe sí mi?”
7 Ẹ máa rántí àwọn tiwọn jẹ́ aṣáájú yín, tiwọn ti sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún yín; kí ẹ máa ro òpin ìwà ayé wọn, kí ẹ sì máa ṣe àfarawé ìgbàgbọ́ wọn. 8 Jesu Kristi ọ̀kan náà ni lánàá, àti lónìí, àti títí láé.
9 Ẹ má ṣe jẹ́ kí a fi onírúurú àti àjèjì ẹ̀kọ́ gbá yin kiri. Nítorí ó dára kí a mú yin lọ́kàn le nípa oore-ọ̀fẹ́, kì í ṣe nípa oúnjẹ nínú èyí tí àwọn tí ó ti rìn nínú wọn kò ní èrè. 10 Àwa ní pẹpẹ kan, níbi èyí tí àwọn ti ń sin àgọ́ kò ni agbára láti máa jẹ.
11 (D)Nítorí nígbà tí olórí àlùfáà bá mú ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹran wá si ibi mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ìrúbọ ẹ̀ṣẹ̀, òkú àwọn ẹran náà ni a o sun lẹ́yìn ibùdó. 12 Nítorí náà Jesu pẹ̀lú, kí ó lè fi ẹ̀jẹ̀ ara rẹ̀ sọ àwọn ènìyàn di mímọ́, ó jìyà lẹ́yìn ibodè. 13 Nítorí náà ẹ jẹ́ kí a jáde tọ̀ ọ́ lọ lẹ́yìn ibùdó, kí a máa ru ẹ̀gàn rẹ̀. 14 Nítorí pé àwa kò ní ìlú tí o wa títí níhìn-ín, ṣùgbọ́n àwa ń wá èyí tí ń bọ.
15 (E)Ǹjẹ́ nípasẹ̀ rẹ̀, ẹ jẹ́ kí a máa rú ẹbọ ìyìn si Ọlọ́run nígbà gbogbo, èyí yìí ni èso ètè wa, tí ń jẹ́wọ́ orúkọ rẹ̀. 16 Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe gbàgbé láti máa ṣoore àti láti máa pín fun ni nítorí irú ẹbọ wọ̀nyí ni inú Ọlọ́run dùn sí jọjọ.
17 Ẹ máa gbọ́ ti àwọn tí ń ṣe olórí yín, kí ẹ sì máa tẹríba fún wọ́n: Nítorí wọn ń ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ nítorí ọkàn yín, bí àwọn ti yóò ṣe ìṣirò, kí wọn lè fi ayọ̀ ṣe èyí, kì í ṣe pẹ̀lú ìbànújẹ́, nítorí èyí yìí yóò jẹ àìlérè fún yín.
18 Ẹ máa gbàdúrà fún wa: nítorí àwa gbàgbọ́ pé àwa ni ẹ̀rí ọkàn rere, a sì ń fẹ́ láti máa hùwà títọ́ nínú ohun gbogbo. 19 Ṣùgbọ́n èmi ń bẹ̀ yín gidigidi sí i láti máa ṣe èyí, kí a ba lè tètè fi mi fún yín padà.
20 (F)Ǹjẹ́ Ọlọ́run àlàáfíà, ẹni tí o tún mu olùṣọ́-àgùntàn ńlá ti àwọn àgùntàn, ti inú òkú wá, nípa ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú ayérayé, àní Olúwa wa Jesu. 21 Kí ó mú yín pé nínú iṣẹ́ rere gbogbo láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀, kí ó máa ṣiṣẹ́ ohun tí i ṣe ìtẹ́wọ́gbà níwájú rẹ̀ nínú yín nípasẹ̀ Jesu Kristi; ẹni tí ògo wà fún láé àti láéláé. Àmín.
22 Èmi sì ń bẹ̀ yín ará, ẹ gbà ọ̀rọ̀ ìyànjú mi; nítorí ìwé kúkúrú ni mo kọ sí yín.
23 Ẹ mọ pé a sá titu Timotiu arákùnrin wa sílẹ̀; bí ó ba tètè dé, èmí pẹ̀lú rẹ̀ yóò rí yín, àti gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́.
24 Ẹ ki gbogbo àwọn tí ń ṣe olórí yín, àti gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́.
Àwọn tí o ti Itali wá ki yín.
25 Kí oore-ọ̀fẹ́ wà pẹ̀lú gbogbo yín.
Eṣú, iná àti ìwọ̀n okùn
7 Èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè fihàn mí: Ó pèsè ọwọ́ eṣú lẹ́yìn ìgbà tí a kórè ìpín ọba, ní ìgbà ti èso ẹ̀ẹ̀kejì ń jáde bọ̀. 2 Nígbà tí wọ́n jẹ koríko ilẹ̀ náà mọ́ féfé nígbà náà ni mo gbé ohùn mi sókè pé, “Olúwa Olódùmarè, mo bẹ̀ ọ́, dáríjì! Báwo ni Jakọbu yóò ha ṣe lè dìde? Òun kéré jọjọ!”
3 Olúwa ronúpìwàdà nípa èyí.
“Èyí kò ni ṣẹlẹ̀,” ni Olúwa wí.
4 Èyí ni ohun ti Olúwa Olódùmarè fihàn mí: Olúwa Olódùmarè ń pè fún ìdájọ́ pẹ̀lú iná; ó jó ọ̀gbun ńlá rún, ó sì jẹ ilẹ̀ run. 5 Nígbà náà ni mo gbé ohùn mi sókè pé, “Olúwa Olódùmarè jọ̀wọ́ má ṣe ṣe é! Báwo ni Jakọbu yóò ha ṣe lè dìde? Òun kéré jọjọ!”
6 Olúwa ronúpìwàdà nípa èyí.
“Èyí náà kò ní ṣẹlẹ̀,” ni Olúwa Olódùmarè wí.
7 Èyí ni ohun tí ó fihàn mí: Olúwa dúró ní ẹ̀gbẹ́ odi ti a fi okùn ìwọ̀n mọ́, ti òun ti okùn ìwọ̀n tí ó rún ni ọwọ́ rẹ̀. 8 Olúwa sì bi mi pé, “Amosi, kí ni ìwọ rí?”
Mo dáhùn pé, “Okùn ìwọ̀n.”
Nígbà náà ni Olúwa wí pé, “Wò ó, Èmí ń gbé okùn ìwọ̀n kalẹ̀ láàrín àwọn Israẹli ènìyàn mi; Èmi kì yóò sì tún kọjá lọ́dọ̀ wọn mọ́.
9 “Ibi gíga Isaaki wọ̀n-ọn-nì yóò sì di ahoro
àti ibi mímọ Israẹli wọ̀n-ọn-nì yóò di ahoro.
Èmi yóò sì fi idà dìde sí ilé Jeroboamu.”
Amosi àti Amasiah
10 Nígbà náà Amasiah àlùfáà Beteli ránṣẹ́ sí Jeroboamu ọba Israẹli, wí pé: “Amosi ti dìde láti dìtẹ̀ sí ọ ni àárín gbùngbùn Israẹli. Ilẹ̀ kò sì le gba gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀. 11 Nítorí èyí ni ohun ti Amosi ń sọ:
“ ‘Jeroboamu yóò ti ipa idà kú,
Lóòtítọ́ Israẹli yóò lọ sí ìgbèkùn,
jìnnà kúrò ní ilẹ̀ ìní wọn.’ ”
12 Nígbà náà ni Amasiah sọ fún Amosi pé, “Lọ jáde, ìwọ aríran! Padà sí ilẹ̀ àwọn Juda. Kí o máa jẹun rẹ níbẹ̀, kí o sì máa sọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ níbẹ̀. 13 Má ṣe sọtẹ́lẹ̀ mọ ni Beteli nítorí ibi mímọ́ ọba ni àti ibi tẹmpili ìjọba rẹ̀.”
14 Amosi dá Amasiah lóhùn pé, “Èmi kì í ṣe wòlíì tàbí àwọn ọmọ wòlíì, ṣùgbọ́n mo jẹ́ olùṣọ́-àgùntàn, mo sì ń ṣe ìtọ́jú igi ọ̀pọ̀tọ́ sikamore. 15 Ṣùgbọ́n Olúwa mu mi bí mo ti ń tọ́ agbo ẹran lẹ́yìn, ó sì wí fun mi pé, ‘Lọ sọtẹ́lẹ̀ fun àwọn Israẹli ènìyàn mi.’ 16 Nítorí náà nísinsin yìí, gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa. Ìwọ wí pé,
“ ‘Má ṣe sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí Israẹli
Má sì ṣe wàásù sí ilé Isaaki.’
17 “Nítorí náà, èyí ni ohun ti Olúwa wí:
“ ‘Ìyàwó rẹ yóò di panṣágà ni ìlú,
àwọn ọmọ ọkùnrin àti obìnrin rẹ yóò ti ipa idà ṣubú.
A ó fi okùn wọn ilẹ̀ rẹ, a ó sì pín in
àti ìwọ pẹ̀lú yóò kú ni ilẹ̀ àìmọ́.
Israẹli yóò sì lọ sí ìgbèkùn,
kúrò ní ilẹ̀ ìní wọn.’ ”
Ìbí Jesu
2 (A)Ó sì ṣe ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, àṣẹ ti ọ̀dọ̀ Kesari Augustu jáde wá pé, kí a kọ orúkọ gbogbo ayé sínú ìwé. 2 (Èyí ni ìkọ sínú ìwé èkínní tí a ṣe nígbà tí Kirene fi jẹ baálẹ̀ Siria.) 3 Gbogbo àwọn ènìyàn sì lọ láti kọ orúkọ wọn sínú ìwé, olúkúlùkù sí ìlú ara rẹ̀.
4 (B)Josẹfu pẹ̀lú sì gòkè láti Nasareti ni Galili, sí ìlú Dafidi ní Judea, tí à ń pè ní Bẹtilẹhẹmu; nítorí ti ìran àti ìdílé Dafidi ní í ṣe, 5 láti kọ orúkọ rẹ̀, pẹ̀lú Maria aya rẹ̀ àfẹ́sọ́nà, tí oyún rẹ̀ ti tó bí. 6 Ó sì ṣe, nígbà tí wọ́n wà níbẹ̀, ọjọ́ rẹ̀ pé tí òun yóò bí. 7 Ó sì bí àkọ́bí rẹ̀ ọmọkùnrin, ó sì fi ọ̀já wé e, ó sì tẹ́ ẹ sínú ibùjẹ ẹran; nítorí tí ààyè kò sí fún wọn nínú ilé èrò.
Àwọn olùṣọ́-àgùntàn àti àwọn angẹli
8 Àwọn olùṣọ́-àgùntàn ń bẹ tí wọ́n ń gbé ní ìlú náà, wọ́n ń ṣọ́ agbo àgùntàn wọn ní òru ní pápá tí wọ́n ń gbé. 9 (C)Angẹli Olúwa sì yọ sí wọn, ògo Olúwa sì ràn yí wọn ká: ẹ̀rù sì bà wọ́n gidigidi. 10 Angẹli náà sì wí fún wọn pé, Má bẹ̀rù: sá wò ó, mo mú ìhìnrere ayọ̀ ńlá fún yín wá, tí yóò ṣe ti ènìyàn gbogbo. 11 (D)Nítorí a ti bí Olùgbàlà fún yín lónìí ní ìlú Dafidi, tí í ṣe Kristi Olúwa. 12 (E)Èyí ni yóò sì ṣe ààmì fún yín; ẹ̀yin yóò rí ọmọ ọwọ́ tí a fi ọ̀já wé, ó dùbúlẹ̀ ní ibùjẹ ẹran.
13 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ogun ọ̀run sì darapọ̀ mọ́ angẹli náà ní òjijì, wọ́n ń yin Ọlọ́run, wí pé,
14 (F)“Ògo ni fún Ọlọ́run lókè ọ̀run,
Àti ní ayé Àlàáfíà, ìfẹ́ inú rere sí ènìyàn.”
15 Ó sì ṣe, nígbà tí àwọn angẹli náà padà kúrò lọ́dọ̀ wọn lọ sí ọ̀run, àwọn olùṣọ́-àgùntàn náà bá ara wọn sọ pé, “Ẹ jẹ́ kí á lọ tààrà sí Bẹtilẹhẹmu, kí á lè rí ohun tí ó ṣẹ̀, tí Olúwa fihàn fún wa.”
16 Wọ́n sì wá lọ́gán, wọ́n sì rí Maria àti Josẹfu, àti ọmọ ọwọ́ náà, ó dùbúlẹ̀ nínú ibùjẹ ẹran. 17 Nígbà tí wọ́n sì ti rí i, wọ́n sọ ohun tí a ti wí fún wọn nípa ti ọmọ yìí. 18 Ẹnu sì ya gbogbo àwọn tí ó gbọ́ sí nǹkan wọ̀nyí tí a ti wí fún wọn láti ọ̀dọ̀ àwọn olùṣọ́-àgùntàn wá. 19 (G)Ṣùgbọ́n Maria pa gbogbo nǹkan wọ̀nyí mọ́, ó ń rò wọ́n nínú ọkàn rẹ̀. 20 Àwọn olùṣọ́-àgùntàn sì padà lọ, wọ́n ń fi ògo fún Ọlọ́run, wọ́n sì yìn ín, nítorí ohun gbogbo tí wọ́n ti gbọ́ àti tí wọ́n ti rí, bí a ti wí i fún wọn.
A gbé Jesu kalẹ̀ nínú Tẹmpili
21 (H)Nígbà tí ọjọ́ mẹ́jọ sì pé láti kọ ọmọ náà nílà, wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Jesu, bí a ti sọ ọ́ tẹ́lẹ̀ láti ọ̀dọ̀ angẹli náà wá kí á tó lóyún rẹ̀.
22 (I)Nígbà tí ọjọ́ ìwẹ̀nù Maria sì pé gẹ́gẹ́ bí òfin Mose, Josẹfu àti Maria gbé Jesu wá sí Jerusalẹmu láti fi í fún Olúwa 23 (J)(bí a ti kọ ọ́ sínú òfin Olúwa pé, “Gbogbo ọmọ ọkùnrin tí ó ṣe àkọ́bí, òun ni a ó pè ní mímọ́ fún Olúwa”), 24 àti láti rú ẹbọ gẹ́gẹ́ bí èyí tí a wí nínú òfin Olúwa: “Àdàbà méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì.”
25 (K)Sì kíyèsi i, ọkùnrin kan wà ní Jerusalẹmu, orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Simeoni; ọkùnrin náà sì ṣe olóòtítọ́ àti olùfọkànsìn, ó ń retí ìtùnú Israẹli: Ẹ̀mí mímọ́ sì bà lé e. 26 A sì ti fihàn án láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ náà wá pé, òun kì yóò rí ikú, kí ó tó rí Kristi Olúwa. 27 Ó sì ti ipa Ẹ̀mí wá sínú tẹmpili: nígbà tí àwọn òbí rẹ̀ sì gbé Jesu wá, láti ṣe fún un bí ìṣe òfin, 28 Nígbà náà ni Simeoni gbé e ní apá rẹ̀, ó fi ìbùkún fún Ọlọ́run, ó ní:
29 “Olúwa Olódùmarè, nígbà yìí ni ó tó jọ̀wọ́ ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ lọ́wọ́ lọ,
ní Àlàáfíà, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ:
30 (L)Nítorí tí ojú mi ti rí ìgbàlà rẹ ná,
31 Tí ìwọ ti pèsè sílẹ̀ níwájú ènìyàn gbogbo;
32 (M)ìmọ́lẹ̀ láti mọ́ sí àwọn aláìkọlà,
àti ògo Israẹli ènìyàn rẹ̀.”
33 Ẹnu sì ya Josẹfu àti ìyá rẹ̀ sí nǹkan tí a ń sọ sí i wọ̀nyí. 34 Simeoni sì súre fún wọn, ó sì wí fún Maria ìyá rẹ̀ pé: “Kíyèsi i, a gbé ọmọ yìí kalẹ̀ fún ìṣubú àti ìdìde ọ̀pọ̀ ènìyàn ní Israẹli; àti fún ààmì tí a ń sọ̀rọ̀-òdì sí; 35 (Idà yóò sì gún ìwọ náà ní ọkàn pẹ̀lú) kí á lè fi ìrònú ọ̀pọ̀ ọkàn hàn.”
36 (N)Ẹnìkan sì ń bẹ, Anna wòlíì, ọmọbìnrin Penueli, nínú ẹ̀yà Aṣeri: ọjọ́ ogbó rẹ̀ pọ̀, ó ti bá ọkọ gbé ní ọdún méje láti ìgbà wúńdíá rẹ̀ wá; 37 Ó sì ṣe opó títí ó fi di ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́rin, ẹni tí kò kúrò ní tẹmpili, ṣùgbọ́n ó ń fi àwẹ̀ àti àdúrà sin Ọlọ́run lọ́sàn án àti lóru. 38 Ó sì wólẹ̀ ní àkókò náà, ó sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run pẹ̀lú, ó sì sọ̀rọ̀ rẹ̀ fún gbogbo àwọn tí ó ń retí ìdáǹdè Jerusalẹmu.
39 Nígbà tí wọ́n sì ti ṣe nǹkan gbogbo tán gẹ́gẹ́ bí òfin Olúwa, wọ́n padà lọ sí Galili, sí Nasareti ìlú wọn. 40 (O)Ọmọ náà sì ń dàgbà, ó sì ń lágbára, ó sì kún fún ọgbọ́n: oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run sì ń bẹ lára rẹ̀.
Ọ̀dọ́mọkùnrin Jesu ni tẹmpili
41 (P)Àwọn òbí rẹ̀ a sì máa lọ sí Jerusalẹmu ní ọdọọdún sí àjọ ìrékọjá. 42 Nígbà tí ó sì di ọmọ ọdún méjìlá, wọ́n gòkè lọ sí Jerusalẹmu gẹ́gẹ́ bí ìṣe àjọ náà. 43 Nígbà tí ọjọ́ wọn sì pé bí wọ́n ti ń padà bọ̀, ọmọ náà, Jesu dúró lẹ́yìn ní Jerusalẹmu; Josẹfu àti ìyá rẹ̀ kò mọ̀. 44 Ṣùgbọ́n wọ́n ṣe bí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ èrò, wọ́n rin ìrìn ọjọ́ kan; wọ́n wá a kiri nínú àwọn ará àti àwọn ojúlùmọ̀ wọn. 45 Nígbà tí wọn kò sì rí i, wọ́n padà sí Jerusalẹmu, wọ́n ń wá a kiri. 46 Ó sì ṣe, lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta wọ́n rí i nínú tẹmpili ó jókòó ní àárín àwọn olùkọ́ni, ó ń gbọ́ tiwọn, ó sì ń bi wọ́n léèrè. 47 Ẹnu sì ya gbogbo àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ fún òye àti ìdáhùn rẹ̀. 48 (Q)Nígbà tí wọ́n sì rí i, háà ṣe wọ́n: ìyá rẹ̀ sì bi í pé, “Ọmọ, èéṣe tí ìwọ fi ṣe wá bẹ́ẹ̀? Sá wò ó, baba rẹ̀ àti èmi ti ń fi ìbànújẹ́ wá ọ kiri.”
49 Ó sì dáhùn wí fún wọn pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń wá mi kiri, ẹ̀yin kò mọ̀ pé èmi kò lè ṣàìmá wà níbi iṣẹ́ Baba mi?” 50 Ọ̀rọ̀ tí o sọ kò sì yé wọn.
51 (R)Ó sì bá wọn sọ̀kalẹ̀ lọ sí Nasareti, sì fi ara balẹ̀ fún wọn: ṣùgbọ́n ìyá rẹ̀ pa gbogbo nǹkan wọ̀nyí mọ́ nínú ọkàn rẹ̀. 52 (S)Jesu sì ń pọ̀ ní ọgbọ́n, sì ń dàgbà, ó sì wà ní ojúrere ní ọ̀dọ̀ Ọlọ́run àti ènìyàn.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.