Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

M’Cheyne Bible Reading Plan

The classic M'Cheyne plan--read the Old Testament, New Testament, and Psalms or Gospels every day.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
2 Kronika 16

Ìgbẹ̀yìn ọdún asà

16 Ní ọdún kẹrìn-dínlógójì ìjọba Asa, Baaṣa ọba Israẹli gòkè wá sí Juda ó sì kọlu Rama, láti ma bá a jẹ́ kí ẹnikẹ́ni lè jáde tàbí wọlé tọ Asa ọba Juda lọ.

Nígbà náà ni Asa mú wúrà àti fàdákà jáde nínú ilé ìṣúra ilé Olúwa àti ààfin ọba ó sì ránṣẹ́ sí Beni-Hadadi ọba Siria, ẹni tí ń gbé ní Damasku, ó wí pé, “Májẹ̀mú kan wà láàrín èmi àti ìrẹ, bí ó ti wà láàrín baba mi àti baba rẹ. Ẹ wò ó, mo fi wúrà àti fàdákà ránṣẹ́ sí ọ; lọ, ba májẹ̀mú tí o bá Baaṣa ọba Israẹli dá jẹ́, kí ó lè lọ kúrò ní ọ̀dọ̀ mi.”

Beni-Hadadi sì gbọ́ ti Asa ọba, ó sì rán àwọn olórí ogun rẹ̀ lọ sí àwọn ìlú Israẹli, wọ́n sì kọlu Ijoni, Dani, Abeli-Maimu, àti gbogbo ìlú ìṣúra Naftali. Nígbà tí Baaṣa gbọ́ èyí, ó sì dá kíkọ́ Rama dúró, ó sì dá iṣẹ́ rẹ̀ dúró. Nígbà náà ní ọba Asa kó gbogbo àwọn ènìyàn Juda jọ, wọ́n sì kó òkúta àti igi Rama lọ èyí ti Baaṣa ń fi kọ́lé; ó sì fi kọ́ Geba àti Mispa.

Ní àkókò náà wòlíì Hanani wá sí ọ̀dọ̀ Asa ọba Juda, ó sì wí fún un pé, “nítorí tí ìwọ gbẹ́kẹ̀lé ọba Siria, ìwọ kò sì gbẹ́kẹ̀lé Olúwa Ọlọ́run rẹ, nítorí náà ni ogún ọba Siria ṣe bọ́ kúrò lọ́wọ́ rẹ. Àwa kì í ṣe ará Etiopia àti àwọn ará Libia àwọn alágbára ogun pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ kẹ̀kẹ́ àti àwọn ẹlẹ́ṣin? Síbẹ̀ nígbà tí ìwọ bá gbẹ́kẹ̀lé Olúwa yóò sì fi wọ́n lé ọwọ́ rẹ. Nítorí ojú Olúwa yí gbogbo ayé ká láti fi agbára fún àwọn ẹni tí ó ní ọkàn pípé sí i. Ìwọ ti ṣe ohun aṣiwèrè, láti ìsinsin yìí lọ, ìwọ yóò wà lójú ogun.”

10 Asa sì bínú pẹ̀lú sí wòlíì nítorí èyí, ó sì mú un bínú gidigidi tí ó sì fi mú un sínú túbú. Ní àkókò náà Asa sì ni díẹ̀ nínú àwọn ènìyàn náà lára.

11 Àwọn iṣẹ́ ìjọba Asa, láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin, ni akọ sínú ìwé ọba Juda àti Israẹli. 12 (A)Ní ọdún kọkàn-dínlógójì ìjọba rẹ̀, Asa sì ṣe àìsàn pẹ̀lú ààrùn nínú ẹsẹ̀ rẹ̀. Bi ó tilẹ̀ jẹ pé ààrùn rẹ̀ lágbára, síbẹ̀ kódà nínú àìsàn rẹ̀ kò wá ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ Olúwa, ṣùgbọ́n lọ́dọ̀ àwọn oníṣègùn nìkan. 13 Nígbà náà tí ó pé ọdún kọ́kànlélógójì rẹ̀, Asa kú, ó sì sùn pẹ̀lú àwọn ìjọba baba rẹ̀, 14 Wọ́n sì sin ín sínú isà òkú tí ó ti gbẹ́ jáde fún ara rẹ̀ ní ìlú Dafidi. Wọ́n sì tẹ sí orí àkéte tí ó fi òórùn dídùn kún, àti onírúurú tùràrí tí a fi ọgbọ́n pèsè, wọ́n sì da iná ńlá nítorí rẹ̀.

Ìfihàn 5

Ìwé àti Ọ̀dọ́-àgùntàn

(A)Mo sì rí i ni ọwọ́ ọ̀tún ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ náà, ìwé kan ti a kọ nínú àti lẹ́yìn, ti a sì fi èdìdì méje dí. Mó sì rí angẹli alágbára kan, ó ń fi ohùn rara kéde pé, “Ta ni ó yẹ láti ṣí ìwé náà, àti láti tu èdìdì rẹ̀?” Kò sì ṣí ẹni kan ní ọ̀run, tàbí lórí ilẹ̀ ayé, tàbí nísàlẹ̀ ilẹ̀, tí ó le ṣí ìwé náà, tàbí ti o lè wo inú rẹ̀. Èmi sì sọkún gidigidi, nítorí tí a kò ri ẹnìkan tí o yẹ láti sí i àti láti ka ìwé náà, tàbí láti wo inú rẹ̀. (B)Ọ̀kan nínú àwọn àgbà náà sì wí fún mi pé, “Má ṣe sọkún: kíyèsi i, kìnnìún ẹ̀yà Juda, Gbòǹgbò Dafidi, tí borí láti ṣí ìwé náà, àti láti tú èdìdì rẹ̀ méjèèje.”

(C)Mo sì rí Ọ̀dọ́-Àgùntàn ni àárín ìtẹ́ náà, àti àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà, àti ni àárín àwọn àgbà náà, Ọ̀dọ́-àgùntàn kan dúró bí èyí tí a ti pa, ó ní ìwo méje àti ojú méje, tí o jẹ́ Ẹ̀mí méje tí Ọlọ́run, tí a rán jáde lọ sì orí ilẹ̀ ayé gbogbo. Ó sì wá, o sì gbà á ìwé náà ni ọwọ́ ọ̀tún ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ náà. (D)Nígbà tí ó sì gba ìwé náà, àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà, àti àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún náà wólẹ̀ níwájú Ọ̀dọ́-àgùntàn náà, olúkúlùkù wọn mú ohun èlò orin olókùn kan lọ́wọ́, àti ago wúrà tí ó kún fún tùràrí tí i ṣe àdúrà àwọn ènìyàn mímọ́. (E)Wọn sì ń kọ orin tuntun kan, wí pé:

“Ìwọ ní o yẹ láti gba ìwé náà,
    àti láti ṣí èdìdì rẹ̀:
nítorí tí a tí pa ọ,
    ìwọ sì tí fi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ṣe ìràpadà ènìyàn sí Ọlọ́run láti inú ẹ̀yà gbogbo,
    àti èdè gbogbo, àti inú ènìyàn gbogbo, àti orílẹ̀-èdè gbogbo wá:
10 (F)Ìwọ sì tí ṣe wọ́n ni ọba àti àlùfáà sì Ọlọ́run wá:
    wọ́n sì ń jẹ ọba lórí ilẹ̀ ayé.”

11 (G)Èmi sì wò, mo sì gbọ́ ohùn àwọn angẹli púpọ̀ yí ìtẹ́ náà ká, àti yí àwọn ẹ̀dá alààyè náà àti àwọn àgbà náà ká: Iye wọn sì jẹ́ ẹgbàárùn-ún ọ̀nà ẹgbàárùn-ún àti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọ̀nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún. 12 Wọn ń wí lóhùn rara pé:

“Yíyẹ ni Ọ̀dọ́-àgùntàn náà tí a tí pa,
láti gba agbára,
àti ọ̀rọ̀ àti ọgbọ́n, àti ipá, àti ọlá,
àti ògo, àti ìbùkún.”

13 Gbogbo ẹ̀dá tí o sì ń bẹ ni ọ̀run, àti lórí ilẹ̀ ayé, àti nísàlẹ̀ ilẹ̀ àti irú àwọn tí ń bẹ nínú Òkun, àti gbogbo àwọn tí ń bẹ nínú wọn, ni mo gbọ́ tí ń wí pé,

“Kí a fi ìbùkún àti ọlá, àti ògo, àti agbára,
fún Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ àti fún Ọ̀dọ́-àgùntàn
        náà láé àti láéláé.”

14 Àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà wí pé, “Àmín!” Àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún náà wólẹ̀, wọn sì foríbalẹ̀ fún ẹni tí ń bẹ láààyè láé àti láéláé.

Sekariah 1

Ìpè láti padà sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run

Ní oṣù kẹjọ ọdún kejì ọba Dariusi, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ wòlíì Sekariah ọmọ Berekiah, ọmọ Iddo pé:

Olúwa ti bínú sí àwọn baba ńlá yín. Nítorí náà sọ fún àwọn ènìyàn: Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: ‘Ẹ padà sí Ọ̀dọ̀ mi,’ Báyìí ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, ‘èmi náà yóò sì padà sí ọ̀dọ̀ yín,’ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. Ẹ má dàbí àwọn baba yín, àwọn tí àwọn wòlíì ìṣáájú ti ké sí wí pé: Báyìí ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: ‘Ẹ yípadà nísinsin yìí kúrò ní ọ̀nà búburú yín,’ àti kúrò nínú ìwà búburú yín; ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò fetí sí ti èmi, ni Olúwa wí. Àwọn baba yín, níbo ni wọ́n wà? Àti àwọn wòlíì, wọ́n ha wà títí ayé? Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ mi àti ìlànà mi, ti mo pa ní àṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ mi wòlíì, kò ha tún bá àwọn baba yín?

“Wọ́n sì padà wọ́n wí pé, ‘Gẹ́gẹ́ bí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti rò láti ṣe sí wa, gẹ́gẹ́ bi ọ̀nà wa, àti gẹ́gẹ́ bí ìṣe wa, bẹ́ẹ̀ ní o ti ṣe sí wa.’ ”

Ènìyàn láàrín àwọn igi miritili

Ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kọkànlá, tí ó jẹ́, oṣù Sebati, ní ọdún kejì Dariusi, ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ wòlíì Sekariah, ọmọ Bẹrẹkiah ọmọ Iddo wá, pé.

Mo rí ìran kan ni òru, si wò ó, ọkùnrin kan ń gun ẹṣin pupa kan, òun sì dúró láàrín àwọn igi maritili tí ó wà ní ibi òòji; lẹ́yìn rẹ̀ sì ni ẹṣin pupa, adíkálà, àti funfun gbé wà.

Nígbà náà ni mo wí pé, “Kí ni wọ̀nyí olúwa mi?”

Angẹli tí ń ba mi sọ̀rọ̀ sì wí fún mi pé, “Èmi ó fi ohun tí àwọn wọ̀nyí jẹ́ hàn ọ́.”

10 Ọkùnrin tí ó dúró láàrín àwọn igi maritili sì dáhùn ó sì wí pé, “Wọ̀nyí ní àwọn tí Olúwa ti rán láti máa rìn sókè sódò ni ayé.”

11 Wọ́n si dá angẹli Olúwa tí ó dúró láàrín àwọn igi maritili náà lóhùn pé, “Àwa ti rìn sókè sódò já ayé, àwa sí ti rí i pé gbogbo ayé wà ní ìsinmi àti àlàáfíà.”

12 Nígbà náà ni angẹli Olúwa náà dáhùn ó sì wí pé, “Olúwa àwọn ọmọ-ogun, yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ kì yóò fi ṣàánú fún Jerusalẹmu, àti fún àwọn ìlú ńlá Juda, ti ìwọ ti bínú sí ni àádọ́rin ọdún wọ̀nyí?” 13 Olúwa sì fi ọ̀rọ̀ rere àti ọ̀rọ̀ ìtùnú dá angẹli tí ń bá mi sọ̀rọ̀ lóhùn.

14 Angẹli ti ń bá mi sọ̀rọ̀ sì wí fún mi pé, “Ìwọ kígbe wí pé: Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: ‘Èmi ń fi ìjowú ńlá jowú fún Jerusalẹmu àti fún Sioni. 15 Èmi sì bínú púpọ̀púpọ̀ si àwọn orílẹ̀-èdè tí ó rò wí pé òun ní ààbò. Nítorí nígbà tí mo bínú díẹ̀, wọ́n ran ìparun lọ́wọ́ láti tẹ̀síwájú.’

16 “Nítorí náà, báyìí ni Olúwa wí: ‘Mo padà tọ Jerusalẹmu wá pẹ̀lú àánú; ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, a ó kọ́ ilé mi sínú rẹ̀, a o sí ta okùn ìwọ̀n kan jáde sórí Jerusalẹmu.’

17 “Máa ké síbẹ̀ pé: Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: ‘A o máa fi ìre kún ìlú ńlá mi síbẹ̀; Olúwa yóò sì máa tu Sioni nínú síbẹ̀, yóò sì yan Jerusalẹmu síbẹ̀.’ ”

Ìwo mẹ́rin àti alágbẹ̀dẹ mẹ́rin

18 Mo si gbé ojú sókè, mo sì rí, sì kíyèsi i, ìwo mẹ́rin. 19 Mo sì sọ fún angẹli tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ pé, “Kí ni nǹkan wọ̀nyí?”

Ó si dà mí lóhùn pé, “Àwọn ìwo wọ̀nyí ni ó tí tú Juda, Israẹli, àti Jerusalẹmu ká.”

20 Olúwa sì fi alágbẹ̀dẹ mẹ́rin kan hàn mí. 21 Nígbà náà ni mo wí pé, “Kí ni àwọn wọ̀nyí wá ṣe?”

O sì sọ wí pé, “Àwọn wọ̀nyí ni ìwo tí ó ti tú Juda ká, tó bẹ́ẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò fi gbé orí rẹ̀ sókè? Ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí wá láti dẹ́rùbà wọ́n, láti lé ìwo àwọn orílẹ̀-èdè jáde, ti wọ́n gbé ìwo wọn sórí ilẹ̀ Juda láti tú ènìyàn rẹ̀ ká.”

Johanu 4

Jesu sọ̀rọ̀ pẹ̀lú obìnrin ara Samaria

(A)Àwọn Farisi sì gbọ́ pé, Jesu ni, ó sì ń ṣe ìtẹ̀bọmi fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn púpọ̀ ju Johanu lọ, Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Jesu tìkára rẹ̀ kò ṣe ìtẹ̀bọmi bí kò ṣe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, Ó fi Judea sílẹ̀, ó sì tún lọ sí Galili.

(B)Òun sì ní láti kọjá láàrín Samaria. (C)Nígbà náà ni ó dé ìlú Samaria kan, tí a ń pè ní Sikari, tí ó súnmọ́ etí ilẹ̀ oko tí Jakọbu ti fi fún Josẹfu, ọmọ rẹ̀. Kànga Jakọbu sì wà níbẹ̀. Nítorí pé ó rẹ Jesu nítorí ìrìn rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó jókòó létí kànga: ó sì jẹ́ ìwọ̀n wákàtí kẹfà ọjọ́.

Obìnrin kan, ará Samaria sì wá láti fà omi: Jesu wí fún un pé ṣe ìwọ yóò fún mi ni omi mu. Nítorí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ti lọ sí ìlú láti lọ ra oúnjẹ.

(D)Obìnrin ará Samaria náà sọ fún un pé, “Júù ni ìwọ, obìnrin ará Samaria ni èmi. Èétirí tí ìwọ ń béèrè ohun mímu lọ́wọ́ mi?” (Nítorí tí àwọn Júù kì í bá àwọn ará Samaria ṣe pọ̀.)

10 (E)Jesu dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Ìbá ṣe pé ìwọ mọ ẹ̀bùn Ọlọ́run, àti ẹni tí ó wí fún ọ pé, Fún mi ni omi mu, ìwọ ìbá sì ti béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, òun ìbá ti fi omi ìyè fún ọ.”

11 Obìnrin náà wí fún un pé, “Alàgbà, ìwọ kò ní igbá-ìfami tí ìwọ ó fi fà omi, bẹ́ẹ̀ ni kànga náà jì: Níbo ni ìwọ ó ti rí omi ìyè náà? 12 Ìwọ pọ̀ ju Jakọbu baba wa lọ bí, ẹni tí ó fún wa ní kànga náà, tí òun tìkára rẹ̀ si mu nínú rẹ̀, àti àwọn ọmọ rẹ̀, àti àwọn ẹran ọ̀sìn rẹ̀?”

13 Jesu dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá mu nínú omi yìí, òǹgbẹ yóò sì tún gbẹ ẹ́: 14 (F)Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá mu nínú omi tí èmi ó fi fún un, òǹgbẹ kì yóò gbẹ ẹ́ mọ́ láé; ṣùgbọ́n omi tí èmi ó fi fún un yóò di kànga omi nínú rẹ̀, tí yóò máa sun si ìyè àìnípẹ̀kun.”

15 (G)Obìnrin náà sì wí fún u pé, “Alàgbà, fún mi ní omi yìí, kí òǹgbẹ kí ó má ṣe gbẹ mí, kí èmi kí ó má sì wá fa omi níbí mọ́.”

16 Jesu wí fún un pé, “Lọ pe ọkọ rẹ, kí ó sì padà wá sí ìhín yìí.”

17 Obìnrin náà dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Èmi kò ní ọkọ.”

Jesu wí fún un pé, “Ìwọ́ dáhùn dáradára pé, èmi kò ní ọkọ: 18 (H)Nítorí tí ìwọ ti ní ọkọ márùn-ún rí; ọkùnrin tí ìwọ sì ní báyìí kì í ṣe ọkọ rẹ. Ohun tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ tán yìí, òtítọ́ ni.”

19 Obìnrin náà wí fún un pé, “Alàgbà, mo wòye pé, wòlíì ni ìwọ ń ṣe. 20 (I)Àwọn baba wa sìn lórí òkè yìí; ẹ̀yin sì wí pé, Jerusalẹmu ni ibi tí ó yẹ tí à bá ti máa sìn.”

21 (J)Jesu wí fún un pé, “Gbà mí gbọ́ obìnrin yìí, àkókò náà ń bọ̀, nígbà tí kì yóò ṣe lórí òkè yìí tàbí ní Jerusalẹmu ni ẹ̀yin ó máa sin Baba. 22 (K)Ẹ̀yin ń sin ohun tí ẹ̀yin kò mọ̀: àwa ń sin ohun tí àwa mọ̀: nítorí ìgbàlà ti ọ̀dọ̀ àwọn Júù wá. 23 Ṣùgbọ́n àkókò ń bọ̀, ó sì dé tán nísinsin yìí, nígbà tí àwọn olùsìn tòótọ́ yóò máa sin Baba ní Ẹ̀mí àti ní òtítọ́: nítorí irú wọn ni Baba ń wá kí ó máa sin òun. 24 (L)Ẹ̀mí ni Ọlọ́run: àwọn ẹni tí ń sìn ín kò lè ṣe aláìsìn ín ní Ẹ̀mí àti ní òtítọ́.”

25 Obìnrin náà wí fún un pé, mo mọ̀ pé, “Messia ń bọ̀ wá, tí a ń pè ní Kristi: Nígbà tí Òun bá dé, yóò sọ ohun gbogbo fún wa.”

26 (M)Jesu sọ ọ́ di mí mọ̀ fún un pé, “Èmi ẹni tí ń bá ọ sọ̀rọ̀ yìí ni Òun.”

Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn pẹ̀lú Jesu

27 Lákokò yí ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ dé, ẹnu sì yà wọ́n pé ó ń bá obìnrin sọ̀rọ̀: ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan tí ó wí pé, “Kí ni ìwọ ń wá?” tàbí “Èéṣe tí ìwọ fi ń bá a sọ̀rọ̀?”

28 Nígbà náà ni obìnrin náà fi ládugbó rẹ̀ sílẹ̀, ó sì mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n lọ sí ìlú, ó sì wí fún àwọn ènìyàn pé, 29 (N)“Ẹ wá wò ọkùnrin kan, ẹni tí ó sọ ohun gbogbo tí mo ti ṣe rí fún mi: èyí ha lè jẹ́ Kristi náà?” 30 Nígbà náà ni wọ́n ti ìlú jáde, wọ́n sì tọ̀ ọ́ wá.

31 Láàrín èyí, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ń rọ̀ ọ́ wí pé, “Rabbi, jẹun.”

32 (O)Ṣùgbọ́n ó wí fún wọn pé, “Èmi ní oúnjẹ láti jẹ, tí ẹ̀yin kò mọ̀.”

33 Nítorí náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ń bi ara wọn lérè wí pé, “Ẹnìkan mú oúnjẹ fún un wá láti jẹ bí?”

34 (P)Jesu wí fún wọn pé, “Oúnjẹ mi ni láti ṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi, àti láti parí iṣẹ́ rẹ̀. 35 (Q)Ẹ̀yin kò ha wí pé, ‘Ó ku oṣù mẹ́rin, ìkórè yóò sì dé?’ Wò ó, mo wí fún un yín, Ẹ ṣí ojú yín sókè, kí ẹ sì wo oko; nítorí tí wọn ti pọ́n fún ìkórè. 36 Kódà báyìí, ẹni tí ó ń kórè ń gba owó ọ̀yà rẹ̀, ó si ń kó èso jọ sí ìyè àìnípẹ̀kun: kí ẹni tí ó ń fúnrúgbìn àti ẹni tí ń kórè lè jọ máa yọ̀ pọ̀. 37 (R)Nítorí nínú èyí ni ọ̀rọ̀ náà fi jẹ́ òtítọ́: Ẹnìkan ni ó fúnrúgbìn, ẹlòmíràn ni ó sì ń kórè jọ. 38 Mo rán yín lọ kórè ohun tí ẹ kò ṣiṣẹ́ fún. Àwọn ẹlòmíràn ti ṣiṣẹ́, ẹ̀yin sì kórè èrè làálàá wọn.”

Ọ̀pọ̀ ara Samaria gbàgbọ́

39 Ọ̀pọ̀ àwọn ará Samaria láti ìlú náà wá sì gbà á gbọ́ nítorí ìjẹ́rìí obìnrin náà pé, “Ó sọ gbogbo ohun tí mo ti ṣe fún mi.” 40 Nítorí náà, nígbà tí àwọn ará Samaria wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n rọ̀ ọ́ pé, kí ó wà pẹ̀lú wọn: ó sì dúró fún ọjọ́ méjì. 41 Àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì gbàgbọ́ sí i nítorí ọ̀rọ̀ rẹ̀.

42 (S)Wọ́n sì wí fún obìnrin náà pé, “Kì í ṣe nítorí ọ̀rọ̀ rẹ nìkan ni àwa ṣe gbàgbọ́: nítorí tí àwa tìkára wa ti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, àwa sì mọ̀ pé, nítòótọ́ èyí ni Kristi náà, Olùgbàlà aráyé.”

Jesu wo ọmọkùnrin ọlọ́lá san

43 Lẹ́yìn ọjọ́ méjì ó sì ti ibẹ̀ kúrò, ó lọ sí Galili. 44 (T)Nítorí Jesu tìkára rẹ̀ ti jẹ́rìí wí pé, Wòlíì kì í ní ọlá ní ilẹ̀ òun tìkára rẹ̀. 45 Nítorí náà nígbà tí ó dé Galili, àwọn ará Galili gbà á, nítorí ti wọ́n ti rí ohun gbogbo tí ó ṣe ní Jerusalẹmu nígbà àjọ ìrékọjá; nítorí àwọn tìkára wọn lọ sí àjọ pẹ̀lú.

46 (U)Bẹ́ẹ̀ ni Jesu tún wá sí Kana ti Galili, níbi tí ó gbé sọ omi di wáìnì. Ọkùnrin ọlọ́lá kan sì wá, ẹni tí ara ọmọ rẹ̀ kò dá ní Kapernaumu. 47 Nígbà tí ó gbọ́ pé Jesu ti Judea wá sí Galili, ó tọ̀ ọ́ wá, ó sì ń bẹ̀ ẹ́, kí ó lè sọ̀kalẹ̀ wá kí ó mú ọmọ òun láradá: nítorí tí ó wà ní ojú ikú.

48 (V)Nígbà náà ni Jesu wí fún un pé, “Bí kò ṣe pé ẹ̀yin bá rí ààmì àti iṣẹ́ ìyanu, ẹ̀yin kì yóò gbàgbọ́ láé.”

49 Ọkùnrin ọlọ́lá náà wí fún un pé, “Olúwa, sọ̀kalẹ̀ wá kí ọmọ mi tó kú.”

50 Jesu wí fún un pé, “Máa bá ọ̀nà rẹ lọ; ọmọ rẹ yóò yè.”

Ọkùnrin náà sì gba ọ̀rọ̀ Jesu gbọ́, ó sì kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. 51 Bí ó sì ti ń sọ̀kalẹ̀ lọ, àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pàdé rẹ̀, wọ́n sì wí fún un pé, ọmọ rẹ ti yè. 52 Nígbà náà ni ó béèrè wákàtí tí ara rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í yá lọ́wọ́ wọn, wọ́n sì wí fún un pé, “Ní àná, ní wákàtí keje ni ibà náà fi í sílẹ̀.”

53 (W)Bẹ́ẹ̀ ni baba náà mọ̀ pé ní wákàtí kan náà ni, nínú èyí tí Jesu wí fún un pé “Ọmọ rẹ̀ yè.” Òun tìkára rẹ̀ sì gbàgbọ́, àti gbogbo ilé rẹ̀.

54 (X)Èyí ni iṣẹ́ ààmì kejì tí Jesu ṣe nígbà tí ó ti Judea jáde wá sí Galili.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.