Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

M’Cheyne Bible Reading Plan

The classic M'Cheyne plan--read the Old Testament, New Testament, and Psalms or Gospels every day.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
2 Kronika 31

31 Nígbà tí gbogbo nǹkan wọ̀nyí ti dé òpin, àwọn ọmọ Israẹli tí ó wà níbẹ̀ jáde lọ sí àwọn ìlú Juda, wọ́n fọ́ àwọn òkúta ìyàsọ́tọ̀ sí wẹ́wẹ́, wọ́n gé àwọn ère Aṣerah lulẹ̀. Wọ́n ba àwọn ibi gíga jẹ́ àti àwọn pẹpẹ jákèjádò Juda àti Benjamini àti ní Efraimu àti Manase. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti pa gbogbo wọn run, àwọn ọmọ Israẹli padà sí ìlú wọn àti sí nǹkan ìní wọn.

Ìdáwó fún ìjọ́sìn

Hesekiah fi lé àwọn àlùfáà àti àwọn ará Lefi lọ́wọ́ sí àwọn ìpín olúkúlùkù wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí àlùfáà tàbí ará Lefi láti tẹ́ ẹbọ sísun àti ọrẹ ìdàpọ̀, láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ láti fi ọpẹ́ fún àti láti kọ àwọn orin ìyìn ní ẹnu-ọ̀nà ibùgbé Olúwa. Ọba fi sílẹ̀ láti ara ohun ìní rẹ̀ fun ẹbọ sísun àárọ̀ àti ìrọ̀lẹ́ àti fún ẹbọ sísun ní ọjọ́ ìsinmi, òṣùpá tuntun àti ní àjọ̀dún tí a yàn gẹ́gẹ́ bi a ti ṣe kọ ọ́ nínú òfin Olúwa. Ó pàṣẹ fún àwọn ènìyàn tí ń gbé ní Jerusalẹmu láti fi ìpín tí ó yẹ fún àlùfáà fún un àti àwọn ará Lefi, kí wọn kí ó lè fi ara wọn jì fún òfin Olúwa. Ní kété tí àṣẹ náà jáde lọ, àwọn ọmọ Israẹli fi tìfẹ́tìfẹ́ fi àkọ́so ti ọkà wọn, ọtí tuntun, òróró àti oyin àti gbogbo ohun tí pápá mú jáde lélẹ̀. Wọ́n kó ọ̀pọ̀ iye, àti ìdámẹ́wàá gbogbo nǹkan wá. Àwọn ọkùnrin Israẹli àti Juda ti gbe inú àwọn ìlú Juda pẹ̀lú mú ìdámẹ́wàá agbo ẹran àti ohun èlò àti ohun ọ̀sìn àti ìdámẹ́wàá ti àwọn nǹkan mímọ́ tí a ti yà sọ́tọ̀ sí Olúwa Ọlọ́run wọn, wọ́n sì kó wọn jọ ní òkìtì. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ ṣíṣe èyí ní oṣù kẹta, wọ́n sì parí ní oṣù keje. Nígbà tí Hesekiah àti àwọn oníṣẹ́ rẹ̀ wá, tí wọ́n sì rí òkìtì náà, wọ́n yin Olúwa, pẹ̀lú ìbùkún àwọn ènìyàn rẹ̀ Israẹli.

Hesekiah béèrè lọ́wọ́ àwọn àlùfáà àti àwọn ará Lefi nípa òkìtì; 10 àti Asariah olórí àlùfáà ti ìdílé Sadoku sì dáhùn pé, “Ní ìwọ̀n ìgbà tí àwọn ènìyàn ti bẹ̀rẹ̀ sí ní mú ìdáwó wọn wá sí ilé Olúwa àti ní èyí tí yóò tó jẹ àti ọ̀pọ̀ láti tọ́jú pamọ́ nítorí Olúwa ti bùkún àwọn ènìyàn rẹ̀, ó sì ṣẹ́kù lọ́pọ̀lọpọ̀.”

11 Hesekiah pàṣẹ láti tọ́jú àwọn yàrá ìṣúra nínú ilé Olúwa, wọ́n sì ṣe èyí. 12 Nígbà náà wọ́n mú ọrẹ àti ìdámẹ́wàá àti àwọn ẹ̀bùn tí a yà sí mímọ́ wọ ilé náà wá nítòótọ́. Lórí èyí tí Konaniah ọmọ Lefi, ń ṣe olórí, Ṣimei arákùnrin rẹ̀ ni igbákejì rẹ̀. 13 Jehieli, Asasiah, Nahati, Asaheli, Jerimoti, Josabadi, Elieli, Ismakia, Mahati àti Benaiah jẹ́ àwọn alábojútó lábẹ́ Konaniah àti Ṣimei arákùnrin rẹ̀ nípa ipá ọba Hesekiah àti Asariah olórí ti ó wà ní ìkáwọ́ ilé Ọlọ́run.

14 Kore ọmọ Imina ará Lefi Olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà ìlà-oòrùn, wà ní ìkáwọ́ àwọn ọrẹ àtinúwá tí a fi fún Ọlọ́run, o ń pín ìdáwó tí a ṣe fún Olúwa pẹ̀lú àwọn ẹ̀bùn tí a yà sọ́tọ̀ 15 Edeni, Miniamini, Jeṣua, Ṣemaiah, Amariah àti Ṣekaniah ràn án lọ́wọ́ tọkàntọkàn nínú àwọn ìlú àwọn àlùfáà tí ń dáwó fún àwọn àlùfáà ẹlẹgbẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn, àgbà àti kékeré.

16 Ní àfikún, wọ́n pín sí àwọn ọkùnrin àgbà ọdún mẹ́ta tàbí ọ̀pọ̀ tí orúkọ wọn wà nínú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn. Gbogbo àwọn ti yóò wọ ilé Olúwa láti ṣe oríṣìí iṣẹ́ ti a gbà wọ́n fún gẹ́gẹ́ bí ìgbẹ́kẹ̀lé wọn àti ìpín wọn. 17 Wọ́n sì pín àwọn àlùfáà, wọn kọ orúkọ àwọn ìdílé wọn sínú ìtàn ìdílé àti sí àwọn ará Lefi ogún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu àti ìpín wọn. 18 Wọ́n fi gbogbo àwọn ọmọ kéékèèkéé sí i, àwọn ìyàwó, àti àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin gbogbo ará ìlú tí a kọ lẹ́sẹẹsẹ sínú ìtàn ìdílé ti baba ńlá wọn fún ìrántí. Nítorí tí wọ́n ṣe òtítọ́ ní yíya ara wọn sí ọ̀tọ̀.

19 Ní ti àwọn àlùfáà, àwọn ìran ọmọ Aaroni, tí ń gbé ni àwọn ilẹ̀ oko lẹ́bàá àwọn ìlú wọn tàbí ní àwọn ìlú mìíràn. A yan àwọn ọkùnrin pẹ̀lú orúkọ láti pín ìlú fún gbogbo ọkùnrin láàrín wọn àti sí gbogbo àwọn tí a kọ sínú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá àwọn ará Lefi.

20 Èyí ni Hesekiah ṣe jákèjádò Juda, ó sì ṣe ohun tí ó dára àti tí ó tọ́ àti ohun òtítọ́ níwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀. 21 Nínú ohun gbogbo tí ó dáwọ́lé ní ti iṣẹ́ ìsìn nínú ilé Ọlọ́run àti ní ìgbọ́ràn sí òfin àti àwọn àṣẹ. Ó wá Ọlọ́run rẹ̀, ó sì ṣiṣẹ́ tọkàntọkàn. Ó sì ṣe rere.

Ìfihàn 17

Obìnrin àti ẹranko

17 (A)Ọ̀kan nínú àwọn angẹli méje náà tí ó ní ìgò méje wọ̀n-ọn-nì sì wá, ó sì ba mi sọ̀rọ̀ wí pé, “Wá níhìn-ín; èmi ó sì fi ìdájọ́ àgbèrè ńlá ní tí ó jókòó lórí omi púpọ̀ han ọ: (B)Ẹni tí àwọn ọba ayé bá ṣe àgbèrè, tí a sì fi ọtí wáìnì àgbèrè rẹ̀ pa àwọn tí ń gbé inú ayé.”

Ó sì gbé mi nínú ẹ̀mí lọ sí aginjù: mo sì rí obìnrin kan ó jókòó lórí ẹranko aláwọ̀ òdòdó kan tí ó kún fún orúkọ ọ̀rọ̀-òdì, ó ní orí méje àti ìwo mẹ́wàá. (C)A sì fi aṣọ elése àlùkò àti aṣọ òdòdó wọ obìnrin náà, a sì fi wúrà àti òkúta iyebíye àti perli ṣe é ní ọ̀ṣọ́, ó ní ago wúrà kan ní ọwọ́ rẹ̀, tí ó kún fún ìríra àti fún ẹ̀gbin àgbèrè rẹ̀; àti níwájú rẹ̀ ni orúkọ kan tí a kọ:

ohun ìjìnlẹ̀ babeli ńlá

ìyá àwọn panṣágà

àti àwọn ohun ìríra ayé.

Mo sì rí obìnrin náà mu ẹ̀jẹ̀ àwọn ènìyàn mímọ́, àti ẹ̀jẹ̀ àwọn ajẹ́rìí ikú Jesu ní àmuyó.

Nígbà tí mo sì rí i, ẹnu yà mi gidigidi. Angẹli sì wí fún mi pé, “Nítorí kí ni ẹnu ṣe yà ọ́? Èmi ó sọ ti ìjìnlẹ̀ obìnrin náà fún ọ, àti ti ẹranko tí ó gùn, ti ó ní orí méje àti ìwo mẹ́wàá. (D)Ẹranko tí ìwọ ri nì, o ti wà, kò sì ṣí mọ́: Yóò sì ti inú ọ̀gbun gòkè wá, yóò sì lọ sínú ìparun rẹ. Àwọn olùgbé ayé ti a kọ orúkọ wọn sínú ìwé iye láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé, nígbà tí wọn ń wò ẹranko tí o ti wà, tí kò sì ṣí mọ́, tí ó sì ń bọ̀ wá, ẹnu si ya wọn.

“Níhìn-ín ni ìtumọ̀ tí o ní ọgbọ́n wà. Orí méje ni òkè ńlá méje ni, lórí èyí tí obìnrin náà jókòó. 10 Ọba méje sì ní wọn: àwọn márùn-ún ṣubú, ọ̀kan ń bẹ, ọ̀kan ìyókù kò sì tí ì dé; nígbà tí ó bá sì dé, yóò dúró fún ìgbà kúkúrú. 11 Ẹranko tí ó sì ti wà, tí kò sì ṣí, òun náà sì ni ẹ̀kẹjọ, ó sì ti inú àwọn méje náà wá, ó sì lọ sí ìparun.

12 (E)“Ìwo mẹ́wàá tí ìwọ sì rí ni ọba mẹ́wàá ni wọn, tí wọn kò ì ti gba ìjọba; ṣùgbọ́n wọn gba àṣẹ bí ọba pẹ̀lú ẹranko náà fún wákàtí kan. 13 Àwọn wọ̀nyí ní inú kan, wọ́n yóò sì fi agbára àti ọlá wọn fún ẹranko náà. 14 (F)Àwọn wọ̀nyí ni yóò si máa bá Ọ̀dọ́-Àgùntàn jagun, Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà yóò sì ṣẹ́gun wọn: nítorí òun ni Olúwa àwọn Olúwa, àti ọba àwọn ọba: Àwọn tí ó sì wà pẹ̀lú rẹ̀, tí a pè, tí a yàn, tí wọ́n sì jẹ́ olóòtítọ́ yóò sì ṣẹ́gun pẹ̀lú.”

15 Ó sì wí fún mi pé, “Àwọn omi tí ìwọ ti rí ni, níbi tí àgbèrè náà jókòó, àwọn ènìyàn àti ẹ̀yà àti orílẹ̀ àti onírúurú èdè ni wọ́n. 16 Àti ìwo mẹ́wàá tí ìwọ rí, àti ẹranko náà, àwọn wọ̀nyí ni yóò kórìíra àgbèrè náà, wọn ó sì sọ ọ́ di ahoro àti ẹni ìhòhò, wọn ó sì jẹ ẹran-ara rẹ̀, wọn ó sì fi iná sun ún pátápátá. 17 Nítorí Ọlọ́run ti fi sínú ọkàn wọn láti mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ, láti ní inú kan, àti láti fi ìjọba wọn fún ẹranko náà, títí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yóò fi ṣẹ 18 Obìnrin tí ìwọ rí ní ìlú ńlá ni, tí ń jẹ ọba lórí àwọn ọba ilẹ̀ ayé.”

Sekariah 13:2-9

“Yóò sì ṣe ní ọjọ́ náà ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, ni èmi ó gé orúkọ àwọn òrìṣà kúrò ni ilẹ̀ náà, a kì yóò sì rántí wọn mọ́: àti pẹ̀lú èmi ó mú àwọn wòlíì èké àti àwọn ẹ̀mí àìmọ́ kúrò ni ilẹ̀ náà. Yóò sì ṣe, nígbà tí ẹnìkan yóò sọtẹ́lẹ̀ síbẹ̀, ni baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ tí ó bí í yóò wí fún un pé, ‘Ìwọ ki yóò yè: nítorí ìwọ ń sọ ọ̀rọ̀ èké ni orúkọ Olúwa.’ Àti baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ tí o bí í yóò gun un ni àgúnpa nígbà tí ó bá sọtẹ́lẹ̀.

“Yóò sì ṣe ní ọjọ́ náà, ojú yóò tí àwọn wòlíì èké olúkúlùkù nítorí ìran rẹ̀, nígbà tí òun ba tí sọtẹ́lẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò sì wọ aṣọ wòlíì onírun rẹ̀ tí o fi ń tan ní jẹ. Ṣùgbọ́n òun o wí pé, ‘Èmi kí í ṣe wòlíì, àgbẹ̀ ni èmi; nítorí tí a ti fi mí ṣe ìránṣẹ́ láti ìgbà èwe mi wá.’ Ẹnìkan ó sì wí fún un pé, ‘Ọgbẹ́ kín ní wọ̀nyí ni ẹ̀yìn rẹ?’ Òun o sì dáhùn pé, ‘Wọ̀nyí ni ibi tí a ti sá mi ní ilé àwọn ọ̀rẹ́ mi.’

A lu olùṣọ́-àgùntàn, agbo ẹran fọ́nká

(A)“Dìde, ìwọ idà, sí olùṣọ́-àgùntàn mi,
    àti sí ẹni tí í ṣe ẹnìkejì mi,”
    ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí:
“Kọlu Olùṣọ́-àgùntàn,
    àwọn àgùntàn a sì túká:
    èmi o sì yí ọwọ́ mi sí àwọn kéékèèkéé.
Yóò sì ṣe, ni gbogbo ilẹ̀,” ni Olúwa wí,
    “a ó gé apá méjì nínú rẹ̀ kúrò yóò sì kú;
    ṣùgbọ́n apá kẹta yóò kù nínú rẹ̀.
Èmi ó sì mú apá kẹta náà la àárín iná,
    èmi yóò sì yọ́ wọn bí a ti yọ́ fàdákà,
    èmi yóò sì dán wọn wò, bi a tí ń dán wúrà wò:
wọn yóò sì pé orúkọ mi,
    èmi yóò sì dá wọn lóhùn:
èmi yóò wí pé, ‘Àwọn ènìyàn mi ni,’
    àwọn yóò sì wí pé, ‘Olúwa ni Ọlọ́run wa.’ ”

Johanu 16

16 “Nǹkan wọ̀nyí ni mo ti sọ fún yín, kí a má ba à mú yín yapa kúrò. (A)Wọ́n ó yọ yín kúrò nínú Sinagọgu: àní, àkókò ń bọ̀, tí ẹnikẹ́ni tí ó bá pa yín, yóò rò pé òun ń ṣe ìsìn fún Ọlọ́run. Nǹkan wọ̀nyí ni wọ́n ó sì ṣe, nítorí tí wọn kò mọ Baba, wọn kò sì mọ̀ mí. Ṣùgbọ́n nǹkan wọ̀nyí ni mo ti sọ fún yín, pé nígbà tí wákàtí wọn bá dé, kí ẹ lè rántí wọn pé mo ti wí fún yín. Ṣùgbọ́n èmi kò sọ nǹkan wọ̀nyí fún yín láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ wá, nítorí tí mo wà pẹ̀lú yín.

Iṣẹ́ ẹ̀mí mímọ́

(B)“Ṣùgbọ́n nísinsin yìí èmi ń lọ sọ́dọ̀ ẹni tí ó rán mi; kò sì sí ẹnìkan nínú yín tí ó bi mí lérè pé, ‘Níbo ni ìwọ ń lọ?’ Ṣùgbọ́n nítorí mo sọ nǹkan wọ̀nyí fún yín, ìbìnújẹ́ kún ọkàn yín. (C)Ṣùgbọ́n òtítọ́ ni èmi ń sọ fún yín; àǹfààní ni yóò jẹ́ fún yín bí èmi bá lọ: nítorí bí èmi kò bá lọ, Olùtùnú kì yóò tọ̀ yín wá; ṣùgbọ́n bí mo bá lọ, èmi ó rán an sí yín. Nígbà tí òun bá sì dé, yóò fi òye yé aráyé ní ti ẹ̀ṣẹ̀, àti ní ti òdodo, àti ní ti ìdájọ́: (D)ní ti ẹ̀ṣẹ̀, nítorí tí wọn kò gbà mí gbọ́; 10 (E)Ní ti òdodo, nítorí tí èmi ń lọ sọ́dọ̀ Baba, ẹ̀yin kò sì mọ̀ mí; 11 (F)Ní ti ìdájọ́, nítorí tí a ti ṣe ìdájọ́ ọmọ-aládé ayé yìí.

12 “Mo ní ohun púpọ̀ láti sọ fún yín pẹ̀lú, ṣùgbọ́n ẹ kò lè gbà wọ́n nísinsin yìí. 13 Ṣùgbọ́n nígbà tí òun, àní Ẹ̀mí òtítọ́ náà bá dé, yóò tọ́ yín sí ọ̀nà òtítọ́ gbogbo; nítorí kì yóò sọ ti ara rẹ̀; ṣùgbọ́n ohunkóhun tí ó bá gbọ́, òun ni yóò máa sọ: yóò sì sọ ohun tí ń bọ̀ fún yín. 14 (G)Òun ó máa yìn mí lógo: nítorí tí yóò gbà nínú ti èmi, yóò sì máa sọ ọ́ fún yín. 15 Ohun gbogbo tí Baba ní tèmi ni: nítorí èyí ni mo ṣe wí pé, òun ó gba nínú tèmi, yóò sì sọ ọ́ fún yín.

16 (H)“Nígbà díẹ̀, ẹ̀yin kì ó sì rí mi: àti nígbà díẹ̀ si, ẹ ó sì rí mi, nítorí tí èmi ń lọ sọ́dọ̀ Baba.”

Ìbànújẹ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn yóò di ayọ̀

17 Nítorí náà díẹ̀ nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ń bá ara wọn sọ pé, “Kín ni èyí tí o wí fún wa yìí, nígbà díẹ̀, ẹ̀yin ó sì rí mi: àti nígbà díẹ̀ ẹ̀wẹ̀, ẹ̀yin kì yóò rí mi: àti, nítorí tí èmi ń lọ sọ́dọ̀ Baba?” 18 Nítorí náà wọ́n wí pé, kín ni, nígbà díẹ̀? Àwa kò mọ̀ ohun tí ó wí.

19 Jesu sá à ti mọ̀ pé, wọ́n ń fẹ́ láti bi òun léèrè, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ń bi ara yín léèrè ní ti èyí tí mo wí pé, nígbà díẹ̀, ẹ̀yin kì yóò sì rí mi: àti nígbà díẹ̀ si, ẹ̀yin ó sì rí mi? 20 (I)Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín pé, ẹ̀yin yóò máa sọkún ẹ ó sì máa pohùnréré ẹkún, ṣùgbọ́n àwọn aráyé yóò máa yọ̀: ṣùgbọ́n, ìbànújẹ́ yín yóò di ayọ̀. 21 (J)Nígbà tí obìnrin bá ń rọbí, a ní ìbìnújẹ́, nítorí tí wákàtí rẹ̀ dé: ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá ti bí ọmọ náà tán, òun kì í sì í rántí ìrora náà mọ́, fún ayọ̀ nítorí a bí ènìyàn sí ayé. 22 Nítorí náà ẹ̀yin ní ìbànújẹ́ nísinsin yìí: ṣùgbọ́n èmi ó tún rí yín, ọkàn yín yóò sì yọ̀, kò sì sí ẹni tí yóò gba ayọ̀ yín lọ́wọ́ yín. 23 Àti ní ọjọ́ náà ẹ̀yin kì ó bi mí lérè ohunkóhun. Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ohunkóhun tí ẹ̀yin bá béèrè lọ́wọ́ Baba ní orúkọ mi, òhun ó fi fún yín. 24 (K)Títí di ìsinsin yìí ẹ kò tí ì béèrè ohunkóhun ní orúkọ mi: ẹ béèrè, ẹ ó sì rí gbà, kí ayọ̀ yín kí ó lè kún.

25 (L)“Nǹkan wọ̀nyí ni mo fi òwe sọ fún yín: ṣùgbọ́n àkókò dé, nígbà tí èmi kì yóò fi òwe bá yín sọ̀rọ̀ mọ́, ṣùgbọ́n èmi ó sọ nípa ti Baba fún yín gbangba. 26 Ní ọjọ́ náà, ẹ̀yin ó béèrè ní orúkọ mi: èmi kò sì wí fún yín pé, èmi ó béèrè lọ́wọ́ Baba fún yín: 27 Nítorí tí Baba tìkára rẹ̀ fẹ́ràn yín, nítorí tí ẹ̀yin ti fẹ́ràn mi, ẹ sì ti gbàgbọ́ pé, lọ́dọ̀ Ọlọ́run ni èmi ti jáde wá. 28 Mo ti ọ̀dọ̀ Baba jáde wá, mo sì wá sí ayé: àti nísinsin yìí mo fi ayé sílẹ̀, mo sì lọ sọ́dọ̀ Baba.”

29 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wí fún un pé, “Wò ó, nígbà yìí ni ìwọ ń sọ̀rọ̀ gbangba, ìwọ kò sì sọ ohunkóhun ní òwe. 30 Nígbà yìí ni àwa mọ̀ pé, ìwọ mọ̀ ohun gbogbo, ìwọ kò ní kí a bi ọ́ léèrè: nípa èyí ni àwa gbàgbọ́ pé, lọ́dọ̀ Ọlọ́run ni ìwọ ti jáde wá.”

31 Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin gbàgbọ́ wàyí? 32 (M)Kíyèsi i, wákàtí ń bọ̀, àní ó dé tan nísinsin yìí, tí a ó fọ́n yín ká kiri, olúkúlùkù sí ilé rẹ̀; ẹ ó sì fi èmi nìkan sílẹ̀: ṣùgbọ́n kì yóò sì ṣe èmi nìkan, nítorí tí Baba ń bẹ pẹ̀lú mi.

33 (N)“Nǹkan wọ̀nyí ni mo ti sọ fún yín tẹ́lẹ̀, kí ẹ̀yin kí ó lè ní àlàáfíà nínú mi. Nínú ayé, ẹ̀yin ó ní ìpọ́njú; ṣùgbọ́n ẹ tújúká; mo ti ṣẹ́gun ayé.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.