Book of Common Prayer
Fún adarí orin. Tí ohùn “Lílì ti Májẹ̀mú.” Ti Safu. Saamu.
80 Gbọ́ tiwa, ìwọ olùṣọ́-àgùntàn Israẹli;
ìwọ tí ó darí Josẹfu bí ọ̀wọ́ ẹran;
ìwọ tí o jókòó lórí ìtẹ́ láàrín Kérúbù, tàn jáde
2 Níwájú Efraimu, Benjamini àti Manase.
Ru agbára rẹ̀ sókè;
wá fún ìgbàlà wa.
3 Mú wa padà bọ̀ sípò, ìwọ Ọlọ́run;
jẹ́ kí ojú rẹ kí ó tan ìmọ́lẹ̀ sí wa,
kí a bá à lè gbà wá là.
4 Olúwa Ọlọ́run alágbára,
ìbínú rẹ̀ yóò ti pẹ́ tó
sí àdúrà àwọn ènìyàn rẹ?
5 Ìwọ ti fi oúnjẹ bọ́ wọn
ìwọ ti mú wọn wa ẹkún mu ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́
6 Ìwọ sọ wá di ẹlẹ́yà fún àwọn aládùúgbò wa,
àwọn ọ̀tá wa sì ń yọ̀ wá.
7 Tún wa yípadà, ìwọ, Ọlọ́run alágbára;
jẹ́ kí ojú rẹ tàn sí wa,
kí a ba à lè gbà wá là.
8 Ìwọ mú àjàrà jáde láti Ejibiti;
ìwọ lé àwọn kèfèrí jáde, o sì gbìn ín.
9 Ìwọ ṣí ààyè sílẹ̀ fún un,
ìwọ sì mu ta gbòǹgbò jinlẹ̀
ó sì kún ilẹ̀ náà.
10 A bò àwọn òkè mọ́lẹ̀ òkè pẹ̀lú òjìji rẹ̀,
ẹ̀ka rẹ̀ dàbí kedari Ọlọ́run.
11 O yọ ẹ̀ka rẹ̀ sínú Òkun,
ọwọ́ rẹ̀ sí odò ńlá nì.
12 Èéṣe tí ìwọ fi wó odi rẹ̀
tí àwọn ènìyàn tí ó ń kọjá fi ń ṣa èso rẹ̀?
13 Ìmàdò láti inú igbó ń bá a jẹ́
àti ẹranko igbó ń jẹ ẹ́ run.
14 Yípadà sí wa, àwa ń bẹ̀ ọ́, Ọlọ́run alágbára!
Bojú wolẹ̀ láti ọ̀run kí o sì wò ó!
Kí o sì bẹ àjàrà yìí wò,
15 Gbòǹgbò èyí tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ ti gbìn,
àti ẹ̀ka tí ìwọ ti mú lágbára fún ara rẹ.
16 A gé àjàrà rẹ lulẹ̀, a ti fi iná sun ún;
ní ìfibú, àwọn ènìyàn rẹ̀ ń ṣègbé.
17 Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ kí ó wà lára ọkùnrin tí ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ,
ọmọ ènìyàn tí ìwọ tí gbé kalẹ̀ fún ara rẹ.
18 Nígbà náà àwa kí yóò yípadà kúrò lọ́dọ̀ rẹ;
mú wa yè, àwa o sì máa pe orúkọ rẹ.
19 Tún wa yípadà, Olúwa Ọlọ́run alágbára;
kí ojú rẹ̀ kí ó tan ìmọ́lẹ̀ sí wa,
kí á ba à lè gbà wá là.
Fún adarí orin. Fún Jedutuni. Ti Asafu. Saamu.
77 Mó kígbe sí Ọlọ́run fún ìrànlọ́wọ́;
mo kígbe sí Ọlọ́run láti gbọ́ tèmi.
2 Nígbà tí mo wà nínú ìpọ́njú,
mo wá Olúwa;
ní òru ni mo na ọwọ́ mi jáde ní àìkáárẹ̀
ọkàn mí sì kọ̀ láti tù ú nínú.
3 Èmi rántí rẹ, Ọlọ́run,
mo sì kẹ́dùn;
mo ṣe àròyé, ẹ̀mí mi sì rẹ̀wẹ̀sì. Sela.
4 Ìwọ kò fẹ́ kí èmi fi ojú ba oorun,
mo dààmú tó bẹ́ẹ̀ tí ń kò le sọ̀rọ̀.
5 Mo ronú nípa ọjọ́ ìgbàanì;
ọdún pípẹ́ sẹ́yìn;
6 Mo rántí orin mi ní òru.
Èmi ń bá àyà mi sọ̀rọ̀,
ọkàn mi sì ń ṣe àwárí jọjọ.
7 “Olúwa yóò ha kọ̀ títí láé?
Ki yóò ha ṣe ojúrere rẹ̀ mọ́?
8 Ṣe ìfẹ́ rẹ̀ àti àánú rẹ̀ ti kú lọ láéláé?
Ìlérí rẹ̀ ha kùnà títí ayé?
9 Ọlọ́run ha gbàgbé láti máa ṣàánú?
Ní ìbínú rẹ̀, ó ha sé ojúrere rẹ̀ mọ́?” Sela.
10 Èmi wí pé, “Èyí ní ẹ̀dùn ọkàn mi,
pé ọwọ́ ọ̀tún Ọ̀gá-ògo jùlọ ti yípadà”.
11 Èmi ó rántí iṣẹ́ Olúwa:
bẹ́ẹ̀ ni, èmi ó rántí iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ ọjọ́ pípẹ́.
12 Èmi ṣàṣàrò lórí iṣẹ́ rẹ gbogbo
pẹ̀lú, ènìyàn sì máa sọ̀rọ̀ gbogbo iṣẹ́ agbára rẹ.
13 Ọlọ́run, Ọ̀nà rẹ jẹ́ mímọ́.
Ọlọ́run wo ni ó sì tóbi bí Ọlọ́run wa?
14 Ìwọ ni Ọlọ́run tó ń ṣe ìyanu;
ìwọ fi agbára rẹ hàn nínú àwọn ènìyàn.
15 Pẹ̀lú ọwọ́ agbára rẹ ni ìwọ ra àwọn ènìyàn padà,
àwọn ọmọ Jakọbu àti Josẹfu. Sela.
16 Nígbà tí àwọn omi rí Ọlọ́run,
nígbà tí àwọn omi rí ọ,
ẹ̀rù bà wọ́n,
nítòótọ́ ara ibú kò balẹ̀.
17 Àwọn ojú ọ̀run tú omi sílẹ̀,
àwọsánmọ̀ fi àrá dáhùn;
ọfà rẹ̀ ń tàn sẹ́yìn àti síwájú
18 Àrá rẹ̀ ni a gbọ́ nínú ìjì,
ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀ sí gbogbo ayé;
ayé bẹ̀rù, wọ́n sì wárìrì.
19 Ipa rẹ̀ gba Òkun, ọ̀nà rẹ̀ ń bẹ nínú Òkun,
Ọ̀nà la omi alágbára kọjá ipa rẹ̀ ń bẹ nínú líla omi alágbára kọjá,
nítòótọ́ a kò rí ojú ẹsẹ̀ rẹ̀.
20 Ó tọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́ ẹran
nípa ọwọ́ Mose àti Aaroni.
Saamu ti Asafu.
79 Ọlọ́run, àwọn orílẹ̀-èdè ti wá ilẹ̀ ìní rẹ;
wọ́n ti ba tẹmpili mímọ́ rẹ jẹ́,
wọn di Jerusalẹmu kù sí òkìtì àlàpà.
2 Wọn ti fi ara òkú àwọn ìránṣẹ́ rẹ
fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run ní oúnjẹ,
ẹran-ara àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ fún ẹranko ilẹ̀.
3 Wọ́n tu ẹ̀jẹ̀ jáde gẹ́gẹ́ bí omi
yí Jerusalẹmu ká,
kò sì ṣí àwọn tí yóò sìn wọ́n.
4 Àwa di ohun ẹ̀gàn sí àwọn tí ó yí wa ká,
àbùkù àti ìfiṣe ẹlẹ́yà sí àwọn tí ó yí wa ká.
5 Nígbà wo, Olúwa? Ní ìwọ ó máa bínú títí láé?
Yóò ti pẹ́ tó ti owú rẹ yóò ha jò bí iná?
6 Tú ìbínú rẹ jáde sí orílẹ̀-èdè
tí kò ní ìmọ̀ rẹ,
lórí àwọn ìjọba
tí kò pe orúkọ rẹ;
7 Nítorí wọ́n ti run Jakọbu
wọ́n sì sọ ibùgbé rẹ di ahoro.
8 Má ṣe ka ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba wa sí wa lọ́rùn
jẹ́ kí àánú rẹ wá kánkán láti bá wa,
nítorí tí a rẹ̀ wá sílẹ̀ gidigidi.
9 Ràn wá lọ́wọ́, Ọlọ́run Olùgbàlà wa,
fún ògo orúkọ rẹ;
gbà wá kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì
nítorí orúkọ rẹ.
10 Àwọn orílẹ̀-èdè yóò máa wí pé,
“Níbo ni Ọlọ́run wọn wà?”
Ní ojú wa, kí a mọ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè
kí ó sì gbẹ̀san àwọn ẹ̀jẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ tí a tú jáde.
11 Jẹ́ kí ìmí ẹ̀dùn oǹdè náà wá síwájú rẹ,
gẹ́gẹ́ bí títóbi agbára rẹ
ìwọ ṣe ìtọ́jú àwọn ti a dá lẹ́bi ikú.
12 San án padà sí àyà àwọn aládùúgbò wa nígbà méje
nípa ẹ̀gàn tí wọn ti gàn ọ́ Olúwa.
13 Nígbà náà àwa ènìyàn rẹ,
àti àgùntàn pápá rẹ,
yóò fi ọpẹ́ fún ọ títí láé;
láti ìran dé ìran
ni àwa ó fi ìyìn rẹ hàn.
35 (A)“ ‘Bí arákùnrin yín kan bá tálákà tí kò sì le è pèsè fún àìní ara rẹ̀: ẹ pèsè fún un bí ẹ ti ń ṣe fún àwọn àlejò tàbí àwọn tí ẹ gbà sílé: kí ó ba à le è máa gbé láàrín yín. 36 (B)Ẹ kò gbọdọ̀ gba èlé kankan lọ́wọ́ rẹ̀: ẹ bẹ̀rù Olúwa kí arákùnrin yín le è máa gbé láàrín yín. 37 Ẹ má ṣe gba èlé lórí owó tí ẹ yá a bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ jẹ èrè lórí oúnjẹ tí ẹ tà fún un. 38 Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín tí ó mú yín jáde láti ilẹ̀ Ejibiti láti fún yín ní ilẹ̀ Kenaani àti láti jẹ́ Ọlọ́run yín.
39 (C)“ ‘Bí arákùnrin yín kan bá tálákà dé bi pé ó ta ara rẹ̀ fún ọ bí ẹrú. Má ṣe lò ó bí ẹrú. 40 Jẹ́ kí ó wà lọ́dọ̀ rẹ bí alágbàṣe tàbí àlejò láàrín yín: kí ó máa ṣiṣẹ́ sìn ọ́ títí di ọdún ìdásílẹ̀. 41 Nígbà náà ni kí ó yọ̀ǹda òun àti àwọn ọmọ rẹ̀, kí wọ́n padà sí ìdílé wọn àti sí ilẹ̀ ìní baba wọn. 42 Torí pé ìránṣẹ́ mi ni àwọn ará Israẹli jẹ́. Ẹni tí mo mú jáde láti ilẹ̀ Ejibiti wá, torí èyí ẹ kò gbọdọ̀ tà wọ́n lẹ́rú. 43 Ẹ má ṣe rorò mọ́ wọn: ṣùgbọ́n ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run yín.
44 “ ‘Àwọn ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin yín lè jẹ́ láti orílẹ̀-èdè tí ó yí yín ká: Ẹ lè ra àwọn ẹrú wọ̀nyí lọ́wọ́ wọn. 45 Bákan náà, ẹ sì le è ra àwọn àlejò tí ń gbé láàrín yín, àti àwọn ìdílé wọn tí a bí sáàrín yín. Wọn yóò sì di ohun ìní yín. 46 Ẹ lè fi wọ́n sílẹ̀ bí ogún fún àwọn ọmọ yín; Wọ́n sì lè sọ wọ́n di ẹrú títí láé. Ṣùgbọ́n ẹ kò gbọdọ̀ rorò mọ́ ọmọ Israẹli kankan.
47 “ ‘Bí àlejò kan láàrín yín tàbí ẹni tí ń gbé àárín yín fún ìgbà díẹ̀ bá lọ́rọ̀ tí ọmọ Israẹli sì tálákà dé bi pé ó ta ara rẹ̀ lẹ́rú fún àlejò tàbí ìdílé àlejò náà. 48 Ó lẹ́tọ̀ọ́ si ki a rà á padà lẹ́yìn ìgbà tí ó ti ta ara rẹ̀. Ọ̀kan nínú ìbátan rẹ̀ le è rà á padà. 49 Àbúrò baba rẹ̀ ọkùnrin tàbí àbúrò rẹ̀ obìnrin tàbí ẹnikẹ́ni tí ó bá a tan nínú ìdílé rẹ̀ le è rà á padà: Bí ó bá sì ti là (Lówólọ́wọ́) ó lè ra ara rẹ̀ padà. 50 Kí òun àti olówó rẹ̀ ka iye ọdún tí ó ta ara rẹ̀ títí dé ọdún ìdásílẹ̀ kí iye owó ìdásílẹ̀ rẹ̀ jẹ́ iye tí wọ́n ń san lórí alágbàṣe fún iye ọdún náà. 51 Bí iye ọdún rẹ̀ tí ó ṣẹ́kù bá pọ̀, kí iye owó fún ìràpadà rẹ̀ pọ̀. 52 Bí ó bá sì ṣe pé kìkì ọdún díẹ̀ ni ó kù títí di ọdún jubili, kí ó ṣe ìṣirò rẹ̀, kí ó sì san owó náà bí iye ìṣirò rẹ̀ padà. 53 Bí ẹ ti ń ṣe sí i lọ́dọọdún, ẹ rí i dájú pé olówó rẹ̀ kò korò mọ́ ọ.
54 “ ‘Bí a kò bá rà á padà nínú gbogbo ọ̀nà wọ̀nyí, kí ẹ tú òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ sílẹ̀ ní ọdún ìdásílẹ̀. 55 Nítorí pé ìránṣẹ́ ni àwọn ọmọ Israẹli jẹ́ fún mi. Ìránṣẹ́ mi ni wọ́n, tí mo mú jáde láti Ejibiti wá. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.
9 (A)Nítorí ìdí èyí, láti ọjọ́ tí a ti gbọ́ nípa yín, a kò sinmi láti máa gbàdúrà fún yin, tí a sì ń gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fi ìmọ̀ ìfẹ́ rẹ̀ kún yín nípasẹ̀ ọgbọ́n àti òye gbogbo tí ń ṣe ti Ẹ̀mí. 10 Àwa sì ń gbàdúrà yìí kí ẹ lè gbé irú ìgbé ayé tó yẹ fún Olúwa kí ẹ sì máa wu ú ní gbogbo ọ̀nà, kí ẹ sì máa so èso rere gbogbo, kí ẹ sì máa dàgbà nínú ìmọ̀ Ọlọ́run, 11 pé kí a lè fi ipa gbogbo sọ yín di alágbára gẹ́gẹ́ bí agbára rẹ̀ àti ògo rẹ̀, kí ó lè ṣe é ṣe fún un yín láti máa tẹ̀síwájú nínú sùúrù àti ìpamọ́ra pẹ̀lú ayọ̀. 12 Kí a máa dúpẹ́ nígbà gbogbo lọ́wọ́ Baba, ẹni tí ó kà yín láti jẹ́ alábápín nínú ogún àwọn ẹni mímọ́ nínú ìjọba ìmọ́lẹ̀. 13 (B)Nítorí tí ó ti já wa gbà kúrò nínú agbára òkùnkùn ó sì mú wa wá sí ìjọba Ọmọ tí ó fẹ́ràn. 14 Nínú ẹni tí a ní ìràpadà, àti ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀.
Òwe afúnrúgbìn
13 (A)Ní ọjọ́ kan náà, Jesu kúrò ní ilé, ó jókòó sí etí Òkun. 2 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn péjọ sọ́dọ̀ rẹ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi bọ́ sínú ọkọ̀ ojú omi, ó jókòó, gbogbo ènìyàn sì dúró létí Òkun. 3 Nígbà náà ni ó fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ òwe bá wọn sọ̀rọ̀, wí pé: “Àgbẹ̀ kan jáde lọ gbin irúgbìn sínú oko rẹ̀. 4 Bí ó sì ti gbin irúgbìn náà, díẹ̀ bọ́ sí ẹ̀bá ọ̀nà, àwọn ẹyẹ sì wá, wọ́n sì jẹ ẹ́. 5 Díẹ̀ bọ́ sórí ilẹ̀ orí àpáta, níbi ti kò sí erùpẹ̀ púpọ̀. Àwọn irúgbìn náà sì dàgbàsókè kíákíá, nítorí erùpẹ̀ kò pọ̀ lórí wọn. 6 Ṣùgbọ́n nígbà tí oòrùn gòkè, oòrùn gbígbóná jó wọn, gbogbo wọn sì rọ, wọ́n kú nítorí wọn kò ni gbòǹgbò. 7 Àwọn irúgbìn mìíràn bọ́ sí àárín ẹ̀gún, ẹ̀gún sì dàgbà, ó sì fún wọn pa. 8 Ṣùgbọ́n díẹ̀ tó bọ́ sórí ilẹ̀ rere, ó sì so èso, òmíràn ọgọ́ọ̀rún, òmíràn ọgọ́tọ̀ọ̀ta, òmíràn ọgbọọgbọ̀n, ni ìlọ́po èyí ti ó gbìn. 9 Ẹni tí ó bá létí, kí ó gbọ́.”
10 (B)Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọ́n bí i pé, “Èéṣe tí ìwọ ń fi òwe bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀?”
11 Ó sì da wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin ni a ti fi fún láti mọ ohun ìjìnlẹ̀ ìjọba ọ̀run, ṣùgbọ́n kì í ṣe fún wọn. 12 Ẹnikẹ́ni tí ó ní, òun ni a ó fún sí i, yóò sì ní lọ́pọ̀lọpọ̀. Ṣùgbọ́n lọ́wọ́ ẹni tí kò ní, ni a ó ti gbà èyí kékeré tí ó ní náà. 13 Ìdí nìyìí tí mo fi ń fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀:
“Ní ti rí rí, wọn kò rí;
ní ti gbígbọ́ wọn kò gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò sì yé wọn.
14 (C)Sí ara wọn ni a ti mú àsọtẹ́lẹ̀ wòlíì Isaiah ṣẹ:
“ ‘Ní gbígbọ́ ẹ̀yin yóò gbọ́ ṣùgbọ́n kì yóò sì yé yín;
ní rí rí ẹ̀yin yóò rí, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kì yóò sì mòye.
15 Nítorí àyà àwọn ènìyàn yìí sébọ́
etí wọn sì wúwo láti gbọ́
ojú wọn ni wọ́n sì dì
nítorí kí àwọn má ba à fi ojú wọn rí
kí wọ́n má ba à fi etí wọn gbọ́
kí wọn má ba à fi àyà wọn mọ̀ òye,
kí wọn má ba à yípadà, kí èmi ba à le mú wọn láradá.’
16 (D)Ṣùgbọ́n ìbùkún ni fún ojú yín, nítorí wọ́n ríran, àti fún etí yín, nítorí ti wọ́n gbọ́.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.