Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 20-21

Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi.

20 Olúwa kí ó gbóhùn rẹ ní ọjọ́ ìpọ́njú;
    kí orúkọ Ọlọ́run Jakọbu kí ó dáàbò bò ọ́.
Kí ó rán ìrànlọ́wọ́ sí ọ, láti ibi mímọ́
    kí ó sì tì ọ́ lẹ́yìn láti Sioni wá.
Kí ó sì rántí gbogbo ẹbọ rẹ
    kí ó sì gba ẹbọ sísun rẹ. Sela
Kí ó fi fún ọ gẹ́gẹ́ bi ti èrò ọkàn rẹ
    kí ó sì mú gbogbo ìmọ̀ rẹ ṣẹ.
Àwa yóò hó fún ayọ̀ nígbà tí o bá di aṣẹ́gun
    àwa yóò gbé àsíá wa sókè ní orúkọ Ọlọ́run wa.

Kí Ọlọ́run kí ó mú gbogbo ìbéèrè rẹ̀ ṣẹ.

Nísinsin yìí, èmi mọ̀ wí pé:
    Olúwa pa ẹni ààmì òróró rẹ̀ mọ́.
Yóò gbọ́ láti ọ̀run mímọ́ rẹ̀ wá
    pẹ̀lú agbára ìgbàlà ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀.
Àwọn mìíràn gbẹ́kẹ̀ wọn lé kẹ̀kẹ́, àwọn mìíràn gbẹ́kẹ̀ wọn lé ẹṣin,
    ṣùgbọ́n àwa gbẹ́kẹ̀lé orúkọ Olúwa Ọlọ́run wa.
Wọ́n wólẹ̀, ní eékún, wọ́n sì ṣubú,
    ṣùgbọ́n àwa dìde, a sì dúró ṣinṣin.
Olúwa, fi ìṣẹ́gun fún ọba!
    Dá wa lóhùn nígbà tí a bá ń kígbe pè!

Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi.

21 Háà! Olúwa, ọba yóò yọ̀ nínú agbára rẹ,
    àti ní ìgbàlà rẹ, yóò ti yọ̀ pẹ́ tó!

Nítorí pé ìwọ ti fi ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ fún un,
    bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò sì dùn ún ní ìbéèrè ẹnu rẹ̀. Sela.
Ìwọ ti fi àwọn ìbùkún oore kò ó ni ọ̀nà
    ìwọ fi adé wúrà dé e ní orí.
Ó béèrè fún ìyè, ìwọ sì fi fún un,
    àní ọjọ́ gígùn títí ayérayé.
Ògo rẹ̀ pọ̀ nípasẹ̀ ìṣẹ́gun tí o fi fún un;
    ìwọ sì jẹ́ kí iyì ọláńlá rẹ̀ wà lára rẹ.
Dájúdájú, ìwọ ti fi ìbùkún ayérayé fún un:
    ìwọ sì mú inú rẹ̀ dùn pẹ̀lú ayọ̀ ojú u rẹ̀.
Ọba ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa;
    nípasẹ̀ ìfẹ́ Ọ̀gá-ògo tí kì í kùnà
    kì yóò sípò padà.

Ọwọ́ rẹ yóò wá gbogbo àwọn ọ̀tá a rẹ rí;
    ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò wá àwọn tí o kórìíra rẹ rí.
Nígbà tí ìwọ bá yọ
    ìwọ yóò mú wọn dàbí iná ìléru.
Olúwa yóò gbé wọn mì nínú ìbínú rẹ̀,
    àti pé iná rẹ̀ yóò jó wọn run.
10 Ìwọ yóò pa ìrandíran wọn run kúrò lórí ilẹ̀,
    àti irú-ọmọ wọn kúrò láàrín àwọn ọmọ ènìyàn.
11 Bí o tilẹ̀ jẹ́ wí pé wọ́n ro èrò ibi sí ọ
    wọ́n sì ń pète ìwà ìkà, wọn kì yóò ṣe àṣeyọrí.
12 Nítorí pé ìwọ yóò mú wọn yí ẹ̀yìn wọn padà
    nígbà tí o bá pinnu láti ta wọ́n ní ọfà.

13 Gbígbéga ni ọ́ Olúwa, nínú agbára rẹ;
    a ó kọrin, a ó yín agbára a rẹ̀.

Saamu 110

Ti Dafidi. Saamu.

110 (A)Olúwa sọ fún Olúwa mi pé:

“Ìwọ jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi,
    títí èmi yóò fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ
    di àpótí ìtìsẹ̀ rẹ.”

Olúwa yóò na ọ̀pá agbára rẹ̀
    láti Sioni wá, ìwọ jẹ ọba láàrín àwọn ọ̀tá rẹ.
Àwọn ènìyàn rẹ jẹ́ ọ̀rẹ́ àtinúwá
    ní ọjọ́ ìjáde ogun rẹ, nínú ẹwà mímọ́,
    láti inú òwúrọ̀ wá ìwọ ni ìrì ẹwà rẹ.

(B)Olúwa ti búra,
    kò sì í yí ọkàn padà pé,
“Ìwọ ni àlùfáà,
    ní ipasẹ̀ Melkisedeki.”

Olúwa, ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ ni
    yóò lu àwọn ọba bolẹ̀ ni ọjọ́ ìbínú rẹ̀
Yóò ṣe ìdájọ́ láàrín kèfèrí,
    yóò kún ibùgbé wọn pẹ̀lú òkú ara;
    yóò fọ́n àwọn olórí ká sí orí ilẹ̀ ayé tí ó gbòòrò.
Yóò mu nínú odò ṣíṣàn ní ọ̀nà:
    nítorí náà ni yóò ṣe gbé orí sókè.

Saamu 116-117

116 Èmi fẹ́ràn Olúwa, nítorí ó gbọ́ ohùn mi;
    ó gbọ́ ẹkún mi fún àánú.
Nítorí ó yí etí rẹ̀ padà sí mi,
    èmi yóò máa pè é ni wọ́n ìgbà tí mo wà láààyè.

Okùn ikú yí mi ká,
    ìrora isà òkú wá sórí mi;
    ìyọnu àti ìbànújẹ́ borí mi.
Nígbà náà ni mo ké pe orúkọ Olúwa:
    Olúwa, èmi bẹ̀ ọ́, gba ọkàn mi!”

Olúwa ní oore-ọ̀fẹ́, ó sì ní òdodo;
    Ọlọ́run wa kún fún àánú.
Olúwa pa àwọn ọlọ́kàn fífúyẹ́ mọ́
    nígbà tí mo wà nínú àìní ńlá, ó gbà mí.

Padà, ìwọ ọkàn mi, sí ibi ìsinmi rẹ,
    nítorí Olúwa ṣe dáradára sí ọ.

Nítorí ìwọ, Olúwa, ti gba ọkàn mi
    kúrò lọ́wọ́ ikú,
ojú mi kúrò lọ́wọ́ omijé,
    àti ẹsẹ̀ mi kúrò lọ́wọ́ ìṣubú,
Nítorí èmi yóò máa rìn níwájú Olúwa
    ní ilẹ̀ alààyè.

10 (A)Èmi gbàgbọ́; nítorí náà mo wí pé,
    “èmi rí ìpọ́njú púpọ̀”.
11 Àti nínú ìdààmú mi mo wí pé
    “Èké ni gbogbo ènìyàn”.

12 Kí ni èmi yóò san fún Olúwa
    nítorí gbogbo rere rẹ̀ sí mi?

13 Èmi yóò gbé ago ìgbàlà sókè
    èmi yóò sì máa ké pe orúkọ Olúwa.
14 Èmi yóò mú ìlérí mi ṣẹ sí Olúwa
    ní ojú àwọn ènìyàn rẹ̀.

15 Iyebíye ní ojú Olúwa
    àti ikú àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀.
16 Olúwa, nítòótọ́ ìránṣẹ́ rẹ ni mo jẹ́;
    èmi ni ìránṣẹ́ rẹ, ọmọ ìránṣẹ́bìnrin rẹ;
    ó ti tú mi sílẹ̀ nínú ìdè mi.

17 Èmi yóò rú ẹbọ ọpẹ́ sí ọ
    èmi yóò sì ké pe orúkọ Olúwa
18 Èmi yóò mú ìlérí mi sẹ sí Olúwa
    ní ojú gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀,
19 Nínú àgbàlá ilé Olúwa
    ní àárín rẹ̀, ìwọ Jerusalẹmu.

Ẹ yin Olúwa.
117 (B)Ẹ yin Olúwa, gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀-èdè;
    ẹ pòkìkí rẹ̀, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn.
Nítorí ìfẹ́ ńlá rẹ̀ tí ó ní sí wa,
    àti òtítọ́ Olúwa dúró láéláé.

Ẹ yin Olúwa!

Eksodu 17

Omi láti inú àpáta

17 (A)Gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli si gbéra láti jáde kúrò láti aginjù Sini wọ́n ń lọ láti ibi kan de ibi kan gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ. Wọ́n pàgọ́ sí Refidimu, ṣùgbọ́n kò sí omi fún àwọn ènìyàn láti mú. Àwọn ènìyàn sì sọ̀ fún Mose, wọ́n wí pé, “Fún wa ni omi mu.”

Mose dá wọn lóhùn wí pé, “Èéṣe ti ẹ̀yin fi ń bá mi jà? Èéṣe ti ẹ̀yin fi ń dán Olúwa wò?”

(B)Ṣùgbọ́n òǹgbẹ ń gbẹ àwọn ènìyàn, wọ́n sì ń kùn sí Mose, wọ́n wí pé, “Èéṣe tí ìwọ fi mú wa jáde kúrò ní Ejibiti láti mú kí òǹgbẹ pa àwa, àwọn ọmọ wa àti ohun ọ̀sìn wa ku fún òǹgbẹ.”

Nígbà náà ni Mose gbé ohùn rẹ̀ sókè sí Olúwa pé; “Kí ni kí èmi kí ó ṣe fún àwọn ènìyàn yìí? Wọ́n múra tan láti sọ mi ni òkúta.”

Olúwa sì dá Mose lóhùn pé, “Máa lọ síwájú àwọn ènìyàn, mú nínú àwọn àgbàgbà Israẹli pẹ̀lú rẹ, mú ọ̀pá tí ìwọ fi lu odò Naili lọ́wọ́ kí ó sì máa lọ. Èmi yóò dúró ni ibẹ̀ dè ọ ni orí àpáta ni Horebu. Ìwọ ó sì lu àpáta, omi yóò sì jáde nínú rẹ̀ fún àwọn ènìyàn láti mu.” Mose sì ṣe bẹ́ẹ̀ ni iwájú àwọn àgbàgbà Israẹli. Ó sì sọ orúkọ ibẹ̀ ni Massa (ìdánwò) àti Meriba (kíkùn) nítorí àwọn ọmọ Israẹli sọ̀, wọ́n sì dán Olúwa wò, wọ́n wí pé, “Ǹjẹ́ Olúwa ń bẹ láàrín wa tàbí kò sí?”

A ṣẹ́gun àwọn ará Ameleki

Àwọn ara Amaleki jáde, wọ́n sì dìde ogun sí àwọn ọmọ Israẹli ni Refidimu. Mose sì sọ fún Joṣua pé, “Yàn lára àwọn ọkùnrin fún wa, kí wọn ó sì jáde lọ bá àwọn ará Amaleki jà. Ní ọ̀la, èmi yóò dúró ni orí òkè pẹ̀lú ọ̀pá Ọlọ́run ní ọwọ́ mi.”

10 Joṣua ṣe bí Mose ti wí fún un, ó sì bá àwọn ará Amaleki jagun; nígbà tí Mose, Aaroni àti Huri lọ sí orí òkè náà. 11 Níwọ́n ìgbà tí Mose bá gbé apá rẹ̀ sókè, Israẹli n borí ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá sì rẹ apá rẹ̀ sílẹ̀, Amaleki a sì borí. 12 Ṣùgbọ́n apá ń ro Mose; Wọ́n mú òkúta, wọ́n sì fi sí abẹ́ rẹ̀, ó sì jókòó lé òkúta náà: Aaroni àti Huri sì mu ní apá rẹ̀, ọ̀kan ní apá ọ̀tún àti èkejì ni apá òsì; apá rẹ̀ méjèèjì sì dúró gangan títí di ìgbà ti oòrùn wọ. 13 Joṣua sì fi ojú idà ṣẹ́gun àwọn ará Amaleki.

14 (C)Olúwa sì sọ fun Mose pé. “Kọ èyí sì inú ìwé fún ìrántí, kí o sì sọ fún Joṣua pẹ̀lú; nítorí èmi yóò pa ìrántí Amaleki run pátápátá kúrò lábẹ́ ọ̀run.”

15 Mose sì tẹ́ pẹpẹ kan, ó sì sọ orúkọ pẹpẹ náà ní Olúwa ni àsíá mi (Jehofa-Nisi). 16 Ó wí pé, “A gbé ọwọ́ sókè sí ìtẹ́ Olúwa. Olúwa yóò bá Amaleki jagun láti ìran dé ìran.”

1 Peteru 4:7-19

Ṣùgbọ́n òpin ohun gbogbo kù sí dẹ̀dẹ̀; nítorí náà kí ẹ̀yin wà ní àìrékọjá, kí ẹ sì máa ṣọ́ra nínú àdúrà. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ẹ ní ìfẹ́ tí ó gbóná láàrín ara yín: nítorí ìfẹ́ ni ń bo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀. Ẹ máa ṣe ara yín ni àlejò láìsí ìkùnsínú. 10 Bí olúkúlùkù ti rí ẹ̀bùn gbà, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ máa ṣe ìpín fún ni rẹ̀ láàrín ara yín, bí ìríjú rere tí onírúurú oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run. 11 Bí ẹnikẹ́ni ba ń sọ̀rọ̀, kí o máa sọ bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, bí ẹnikẹ́ni bá ń ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́, kí ó ṣe é bí agbára tí Ọlọ́run fi fún un, kí a lè máa yin Ọlọ́run lógo ní ohun gbogbo nípa Jesu Kristi, ẹni tí ògo àti ìjọba wà fún láé àti láéláé. Àmín.

Jíjìyà fun jíjẹ́ onígbàgbọ́

12 Olùfẹ́, ẹ má ṣe ka ìdánwò gbígbóná ti ń bẹ láàrín yín láti dán yín wò bi ẹni pé ohun àjèjì ni ó dé bá yín: 13 Ṣùgbọ́n níwọ̀n bí ẹ̀yin tí jẹ́ alábápín ìyà Kristi, ẹ máa yọ̀, kí ẹ̀yin lè yọ ayọ̀ púpọ̀ nígbà tí a bá fi ògo rẹ̀ hàn. 14 (A)Bí a bá gàn yín nítorí orúkọ Kristi, ẹni ìbùkún ni yín: nítorí Ẹ̀mí Ògo àti ti Ọlọ́run bà lé yín. 15 Ṣùgbọ́n ẹ má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni nínú yín jìyà bí apànìyàn, tàbí bí olè, tàbí bí olùṣe búburú, tàbí bí ẹni tí ń tojú bọ̀ ọ̀ràn ẹlòmíràn. 16 Ṣùgbọ́n bí ó bá jìyà bí Kristiani kí ojú má ṣe tì í: ṣùgbọ́n kí ó kúkú yin Ọlọ́run lógo nítorí ti o orúkọ yìí. 17 Nítorí ti ìgbà náà dé, tí ìdájọ́ yóò bẹ̀rẹ̀ láti ilé Ọlọ́run wá: bí ó bá sì tètè tí ọ̀dọ̀ wa bẹ̀rẹ̀, ìgbẹ̀yìn àwọn tí kò gba ìhìnrere Ọlọ́run yó ha ti rí?

18 (B)“Bí ó bá ṣe pé agbára káká ni a fi gba olódodo là,
    níbo ni aláìwà-bí-Ọlọ́run àti ẹlẹ́ṣẹ̀ yóò yọjú sí?”

19 Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí àwọn tí ń jìyà gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Ọlọ́run ni ṣíṣe rere, fi ọkàn wọn lè Ẹlẹ́dàá olóòtítọ́ lọ́wọ́.

Johanu 16:16-33

16 (A)“Nígbà díẹ̀, ẹ̀yin kì ó sì rí mi: àti nígbà díẹ̀ si, ẹ ó sì rí mi, nítorí tí èmi ń lọ sọ́dọ̀ Baba.”

Ìbànújẹ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn yóò di ayọ̀

17 Nítorí náà díẹ̀ nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ń bá ara wọn sọ pé, “Kín ni èyí tí o wí fún wa yìí, nígbà díẹ̀, ẹ̀yin ó sì rí mi: àti nígbà díẹ̀ ẹ̀wẹ̀, ẹ̀yin kì yóò rí mi: àti, nítorí tí èmi ń lọ sọ́dọ̀ Baba?” 18 Nítorí náà wọ́n wí pé, kín ni, nígbà díẹ̀? Àwa kò mọ̀ ohun tí ó wí.

19 Jesu sá à ti mọ̀ pé, wọ́n ń fẹ́ láti bi òun léèrè, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ń bi ara yín léèrè ní ti èyí tí mo wí pé, nígbà díẹ̀, ẹ̀yin kì yóò sì rí mi: àti nígbà díẹ̀ si, ẹ̀yin ó sì rí mi? 20 (B)Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín pé, ẹ̀yin yóò máa sọkún ẹ ó sì máa pohùnréré ẹkún, ṣùgbọ́n àwọn aráyé yóò máa yọ̀: ṣùgbọ́n, ìbànújẹ́ yín yóò di ayọ̀. 21 (C)Nígbà tí obìnrin bá ń rọbí, a ní ìbìnújẹ́, nítorí tí wákàtí rẹ̀ dé: ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá ti bí ọmọ náà tán, òun kì í sì í rántí ìrora náà mọ́, fún ayọ̀ nítorí a bí ènìyàn sí ayé. 22 Nítorí náà ẹ̀yin ní ìbànújẹ́ nísinsin yìí: ṣùgbọ́n èmi ó tún rí yín, ọkàn yín yóò sì yọ̀, kò sì sí ẹni tí yóò gba ayọ̀ yín lọ́wọ́ yín. 23 Àti ní ọjọ́ náà ẹ̀yin kì ó bi mí lérè ohunkóhun. Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ohunkóhun tí ẹ̀yin bá béèrè lọ́wọ́ Baba ní orúkọ mi, òhun ó fi fún yín. 24 (D)Títí di ìsinsin yìí ẹ kò tí ì béèrè ohunkóhun ní orúkọ mi: ẹ béèrè, ẹ ó sì rí gbà, kí ayọ̀ yín kí ó lè kún.

25 (E)“Nǹkan wọ̀nyí ni mo fi òwe sọ fún yín: ṣùgbọ́n àkókò dé, nígbà tí èmi kì yóò fi òwe bá yín sọ̀rọ̀ mọ́, ṣùgbọ́n èmi ó sọ nípa ti Baba fún yín gbangba. 26 Ní ọjọ́ náà, ẹ̀yin ó béèrè ní orúkọ mi: èmi kò sì wí fún yín pé, èmi ó béèrè lọ́wọ́ Baba fún yín: 27 Nítorí tí Baba tìkára rẹ̀ fẹ́ràn yín, nítorí tí ẹ̀yin ti fẹ́ràn mi, ẹ sì ti gbàgbọ́ pé, lọ́dọ̀ Ọlọ́run ni èmi ti jáde wá. 28 Mo ti ọ̀dọ̀ Baba jáde wá, mo sì wá sí ayé: àti nísinsin yìí mo fi ayé sílẹ̀, mo sì lọ sọ́dọ̀ Baba.”

29 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wí fún un pé, “Wò ó, nígbà yìí ni ìwọ ń sọ̀rọ̀ gbangba, ìwọ kò sì sọ ohunkóhun ní òwe. 30 Nígbà yìí ni àwa mọ̀ pé, ìwọ mọ̀ ohun gbogbo, ìwọ kò ní kí a bi ọ́ léèrè: nípa èyí ni àwa gbàgbọ́ pé, lọ́dọ̀ Ọlọ́run ni ìwọ ti jáde wá.”

31 Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin gbàgbọ́ wàyí? 32 (F)Kíyèsi i, wákàtí ń bọ̀, àní ó dé tan nísinsin yìí, tí a ó fọ́n yín ká kiri, olúkúlùkù sí ilé rẹ̀; ẹ ó sì fi èmi nìkan sílẹ̀: ṣùgbọ́n kì yóò sì ṣe èmi nìkan, nítorí tí Baba ń bẹ pẹ̀lú mi.

33 (G)“Nǹkan wọ̀nyí ni mo ti sọ fún yín tẹ́lẹ̀, kí ẹ̀yin kí ó lè ní àlàáfíà nínú mi. Nínú ayé, ẹ̀yin ó ní ìpọ́njú; ṣùgbọ́n ẹ tújúká; mo ti ṣẹ́gun ayé.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.