Book of Common Prayer
Fún adarí orin. Ti Dafidi. Ẹ̀bẹ̀.
70 (A)Yára, Ọlọ́run, láti gbà mí là,
Olúwa, wá kánkán láti ràn mí lọ́wọ́.
2 Kí àwọn tí ń wá ọkàn mi
kí a dójútì wọ́n, kí wọn sì dààmú;
kí àwọn tó ń wá ìparun mi
yí ẹ̀yìn padà nínú ìtìjú.
3 Kí a pa wọ́n ní ẹ̀yìn dà fún èrè
ìtìjú àwọn tí ń wí pé, “Háà! Háà!”
4 Ṣùgbọ́n kí àwọn tí ó ń wá ọ ó máa yọ̀
kí inú wọn kí ó sì máa dùn nípa rẹ,
kí àwọn tí ó ń fẹ́ ìgbàlà rẹ máa wí pé,
“Jẹ́ kí a gbé Ọlọ́run ga!”
5 Ṣùgbọ́n mo jẹ́ òtòṣì àti aláìní;
wa kánkán sí ọ̀dọ̀ mi, Ọlọ́run.
Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ àti olùdáǹdè mi;
Olúwa, má ṣe dúró pẹ́.
71 Nínú rẹ, Olúwa, ni mo ní ààbò;
Má ṣe jẹ́ kí ojú kí ó tì mí.
2 Gbà mí kí o sì tú mi sílẹ̀ nínú òdodo rẹ;
dẹ etí rẹ sí mi, kí o sì gbà mí.
3 Jẹ́ àpáta ààbò mi,
níbi tí èmi lè máa lọ,
pa àṣẹ láti gbà mí,
nítorí ìwọ ni àpáta àti odi agbára mi.
4 Gbà mí, Ọlọ́run mi, lọ́wọ́ àwọn olùṣe búburú,
ní ọwọ́ aláìṣòdodo àti ìkà ọkùnrin.
5 Nítorí ìwọ jẹ́ ìrètí mi, Olúwa Olódùmarè,
ìwọ ni ìgbẹ́kẹ̀lé mi láti ìgbà èwe.
6 Mo gbẹ́kẹ̀lé ọ láti ìgbà ìbí mi;
Ìwọ mú mi jáde láti inú ìyá mi wá
èmi ó máa yìn ọ́ títí láé.
7 Mo di ààmì fún ọ̀pọ̀ ènìyàn,
ṣùgbọ́n ìwọ ni ààbò mi tí ó lágbára.
8 Ìyìn rẹ̀ kún ẹnu mi,
ó ń sọ ti ọlá rẹ ní ọjọ́ gbogbo.
9 Má ṣe ta mí nù ní ọjọ́ ogbó mi
Má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀ nígbà tí kò sí okun mọ́
10 Nítorí àwọn ọ̀tá mi ń sọ̀rọ̀-òdì sí mi,
àwọn tí wọn dúró láti pa mí gbìmọ̀ pọ̀.
11 Wọ́n wí pé, “Ọlọ́run ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀;
lépa rẹ̀ kí ẹ sì mu,
nítorí kò sí ẹni tí yóò gbà á.”
12 Má ṣe jìnnà sí mi, Ọlọ́run;
wa kánkán, Ọlọ́run mi, láti ràn mí lọ́wọ́.
13 Jẹ́ kí wọn kí ó dààmú,
kí a sì run àwọn tí ń ṣe ọ̀tá ọkàn mi
kí a sì fi ẹ̀gàn àti àbùkù
bo àwọn tí ń wá ìpalára mi.
14 Ṣùgbọ́n ní tèmi, ìgbà gbogbo ní ìrètí mi;
èmi ó yìn ọ́ síwájú àti síwájú sí i.
15 Ẹnu mi yóò sọ nípa ti òdodo rẹ,
ti ìgbàlà rẹ, ni gbogbo ọjọ́,
lóòtítọ́, èmi kò mọ iye rẹ̀.
16 Èmi ó wá láti wá kéde agbára,
Olúwa Olódùmarè;
èmi ó kéde òdodo rẹ̀ nìkan.
17 Láti ìgbà èwe, Ọlọ́run ni ìwọ ti kọ́ mi
títí di òní ni mo ń sọ ti iṣẹ́ ìyanu rẹ.
18 Pẹ̀lúpẹ̀lú, nígbà tí èmi di arúgbó tán tí mo sì hewú,
Má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀, Ọlọ́run mi,
títí èmi ó fi ipá rẹ han ìran tí ń bọ̀,
àti agbára rẹ fún gbogbo àwọn tí ń bọ̀ lẹ́yìn.
19 Ọlọ́run, òdodo rẹ dé ọ̀run,
ìwọ tí o ti ṣe ohun ńlá
Ta ni ó dàbí rẹ, Ọlọ́run?
20 Pẹ̀lúpẹ̀lú ìwọ ti mú mi rí ìdààmú, tí ó pọ̀ tí ó sì korò,
ìwọ yóò tún sọ ayé mi jí
ìwọ yóò sì tún mú mi sọ sókè
láti ọ̀gbun ilẹ̀ wá.
Ìwọ yóò sọ ọlá mi di púpọ̀
21 Ìwọ yóò fi kún ọwọ́ mi
ìwọ yóò tù mí nínú ní ha gbogbo.
22 Èmi yóò fi dùùrù mi yìn
fún òtítọ́ rẹ, Ọlọ́run mi;
èmi ó kọrin ìyìn sí ọ pẹ̀lú dùùrù
ìwọ ẹni mímọ́ Israẹli.
23 Ètè mi yóò kígbe fún ìyìn
nígbà tí mo bá kọrin ìyìn sí ọ:
èmi, ẹni tí o rà padà.
24 Ahọ́n mi yóò sọ ti òdodo rẹ ní gbogbo ọjọ́,
fún àwọn tí ó fẹ́ pa mí lára,
a sì dójúti àwọn tí ń wá ìdààmú mi.
Maskili ti Asafu.
74 Ọlọ́run, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ wá sílẹ̀ títí láé?
Èéṣe tí ìbínú rẹ̀ fi dìde sí àwọn àgùntàn pápá rẹ?
2 Rántí àwọn ènìyàn tí ìwọ ti rà nígbà àtijọ́,
ẹ̀yà ilẹ̀ ìní rẹ, tí ìwọ ti rà padà
Òkè Sioni, níbi tí ìwọ ń gbé.
3 Yí ẹsẹ̀ rẹ padà sí ìparun ayérayé wọn,
gbogbo ìparun yìí tí ọ̀tá ti mú wá sí ibi mímọ́.
4 Àwọn ọ̀tá rẹ ń bú ramúramù
láàrín ènìyàn rẹ,
wọ́n ń gbé àsíá wọn sókè fún ààmì;
5 Wọ́n ń rí bí ọkùnrin tí ó gbé àáké rẹ̀ sókè
láti gé igi igbó dídí.
6 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, iṣẹ́ ọnà fínfín,
ni wọ́n fi àáké wó lulẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀kan náà.
7 Wọ́n sun ibi mímọ́ rẹ lulẹ̀
wọ́n ba ibùgbé orúkọ rẹ jẹ́
8 Wọ́n wí ní ọkàn wọn. “Àwa ó run wọ́n pátápátá!”
Wọ́n sun gbogbo ibi ìjọ́sìn Ọlọ́run ní ilẹ̀ náà.
9 A kò fún wa ní ààmì iṣẹ́ ìyanu kankan;
kò sí wòlíì kankan
ẹnìkankan wa kò mọ ìgbà tí eléyìí yóò dà.
10 Àwọn ọ̀tá yóò ti kùn sí ọ pẹ́ tó, Ọlọ́run?
Àwọn ọ̀tá yóò ha ba orúkọ rẹ jẹ́ títí láé?
11 Èéṣe tí ìwọ fi dá ọwọ́ rẹ dúró, ọwọ́ ọ̀tún rẹ?
Mú un kúrò nínú ìṣẹ́po aṣọ rẹ kí o sì run wọ́n!
12 Ṣùgbọ́n ìwọ Ọlọ́run ni ọba mi láti ìgbà pípẹ́;
Ó mú ìgbàlà wá sórí ilẹ̀ ayé.
13 Ìwọ ni ó la Òkun sílẹ̀ nípa agbára rẹ;
Ìwọ fọ́ orí ẹ̀mí búburú nínú omi
14 Ìwọ fọ́ orí Lefitani túútúú, o sì fi ṣe oúnjẹ fun àwọn ẹ̀dá tí ń gbé inú ijù
Tìrẹ ni ọ̀sán, tìrẹ sì ni alẹ́ pẹ̀lú;
ìwọ fi ìdí oòrùn àti òṣùpá lélẹ̀.
15 Ìwọ ya orísun omi àti ìṣàn omi;
Ìwọ mú kí odò tó ń sàn gbẹ
16 Tìrẹ ni ọ̀sán, tìrẹ ni òru pẹ̀lú;
ìwọ yà oòrùn àti òṣùpá.
17 Ìwọ pààlà etí ayé;
Ìwọ dá ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn àti ìgbà òtútù.
18 Rántí bí àwọn ọ̀tá ń kẹ́gàn rẹ, Olúwa
bí àwọn aṣiwèrè ènìyàn ti ń ba orúkọ rẹ jẹ́.
19 Má ṣe fi ẹ̀mí àdàbà rẹ fún ẹranko igbó búburú;
Má ṣe gbàgbé ẹ̀mí àwọn ènìyàn rẹ tí a ń pọ́n lójú títí láé.
20 Bojú wo májẹ̀mú rẹ,
nítorí ibi òkùnkùn ayé kún fún ibùgbé ìkà.
21 Má ṣe jẹ́ kí àwọn aninilára padà sẹ́yìn nínú ìtìjú
jẹ́ kí àwọn aláìní àti tálákà yin orúkọ rẹ.
22 Dìde, Ọlọ́run, gba ẹjọ́ ara rẹ rò;
rántí bí àwọn aṣiwèrè ti ń kẹ́gàn rẹ ní gbogbo ọjọ́.
23 Má ṣe gbàgbé ohùn àwọn ọ̀tá rẹ,
bíbú àwọn ọ̀tá rẹ, tí ó ń pọ̀ sí i nígbà gbogbo.
26 (A)“ ‘Ẹ má ṣe jẹ ẹrankẹ́ran pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀.
“ ‘Ẹ kò gbọdọ̀ lọ sí ọ̀dọ̀ yẹ̀míwò tàbí oṣó.
27 (B)“ ‘Ẹ má ṣe dá òṣù sí àárín orí yín (fífá irun ẹ̀gbẹ́ orí, tí a ó sì dá irun àárín orí sí) tàbí kí ẹ ré orí irùngbọ̀n yín bí àwọn aláìkọlà ti ń ṣe.
28 “ ‘Ẹ má ṣe tìtorí òkú, gé ibi kankan nínú ẹ̀yà ara yín, Ẹ kò sì gbọdọ̀ sín gbẹ́rẹ́ kankan. Èmi ni Olúwa.
29 (C)“ ‘Ẹ má ṣe ba ọmọbìnrin yín jẹ́ láti sọ ọ́ di panṣágà, kí ilẹ̀ yín má ba à di ti àgbèrè, kí ó sì kún fún ìwà búburú.
30 (D)“ ‘Ẹ gbọdọ̀ máa pa ìsinmi mi mọ́ kí ẹ sì fi ọ̀wọ̀ fún ibi mímọ́ mi, Èmi ni Olúwa.
31 (E)“ ‘Ẹ má ṣe tọ abókùúsọ̀rọ̀ tàbí àwọn àjẹ́ lọ, ẹ kò gbọdọ̀ tọ̀ wọ́n lẹ́yìn láti jẹ́ kí wọ́n sọ yín di aláìmọ́. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.
32 “ ‘Fi ọ̀wọ̀ fún ọjọ́ orí arúgbó kí ẹ sì bu ọlá fún àwọn àgbàlagbà. Ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run yín: Èmi ni Olúwa.
33 (F)“ ‘Nígbà tí àjèjì kan bá ń gbé pẹ̀lú yín ní ilẹ̀ yín, ẹ má ṣe ṣe é ní ibi 34 kí àjèjì tí ń gbé pẹ̀lú yín dàbí onílé láàrín yín kí ẹ sì fẹ́ràn rẹ̀ bí i ara yín, torí pé ẹ̀yin ti jẹ́ àjèjì ní ilẹ̀ Ejibiti rí. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.
35 (G)“ ‘Ẹ má ṣe lo òṣùwọ̀n èké, nígbà tí ẹ bá ń díwọ̀n yálà nípa òṣùwọ̀n ọ̀pá, òṣùwọ̀n ìwúwo tàbí òṣùwọ̀n onínú. 36 Ẹ jẹ́ olódodo pẹ̀lú àwọn òṣùwọ̀n yín òṣùwọ̀n ìtẹ̀wọ̀n, òṣùwọ̀n wíwúwo, òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun àti òṣùwọ̀n nǹkan olómi yín ní láti jẹ́ èyí tí kò ní èrú nínú. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín tí ó mú yín jáde láti ilẹ̀ Ejibiti.
37 “ ‘Ẹ ó sì máa pa gbogbo àṣẹ àti òfin mi mọ́, ẹ ó sì máa ṣe wọ́n. Èmi ni Olúwa.’ ”
1 (A)Paulu, Sila àti Timotiu,
Sí ìjọ Tẹsalonika, nínú Ọlọ́run Baba wa àti Jesu Kristi Olúwa:
2 (B)Oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà fún yín láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run baba àti Jesu Kristi Olúwa.
Àdúrà àti ìdúpẹ́
3 (C)Ó yẹ kí a máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nígbà gbogbo nítorí yín, ará, àní gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ, nítorí pé ìgbàgbọ́ yín ń dàgbà gidigidi, àti ìfẹ́ olúkúlùkù yín sí ara yín ń di púpọ̀. 4 Nítorí náà, àwa tìkára wa ń fi yín ṣògo nínú ìjọ Ọlọ́run, nítorí sùúrù àti ìgbàgbọ́ yín nínú gbogbo inúnibíni àti wàhálà yín tí ẹ̀yin náà ń fi ara dà.
5 Àwọn nǹkan wọ̀nyí jẹ́ ẹ̀rí pé òdodo ni ìdájọ́ Ọlọ́run àti pé nítorí èyí ni a ó kà yín yẹ fún ìjọba Ọlọ́run, nítorí èyí tí ẹ̀yin pẹ̀lú ṣe ń jìyà. 6 Olódodo ni Ọlọ́run: Òun yóò pọ́n àwọn tí ń pọ́n yín lójú, lójú, 7 Òun yóò sì fi ìtura fún ẹ̀yin tí a ti pọ́n lójú àti fún àwa náà pẹ̀lú. Èyí yóò sì ṣe nígbà ìfarahàn Jesu Olúwa láti ọ̀run wá fún wá nínú ọwọ́ iná pẹ̀lú àwọn angẹli alágbára. 8 (D)Òun yóò fi ìyà jẹ àwọn tí kò mọ Ọlọ́run àti àwọn tí ń ṣe àìgbọ́ràn sí ìhìnrere Jesu Olúwa wa. 9 A ó fi ìparun àìnípẹ̀kun jẹ wọ́n ní yà, a ó sì ṣe wọn mọ̀ kúrò níwájú Olúwa àti inú ògo agbára rẹ̀ 10 Ní ọjọ́ tí yóò jẹ́ ẹni tí a ó yìn lógo nínú àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ àti ẹni àwòyanu ní àárín gbogbo àwọn tí ó ti gbàgbọ́. Èyí kò yọ yín sílẹ̀, nítorí ẹ ti gba ẹ̀rí tí a jẹ́ sí yín gbọ́.
11 (E)Nítorí èyí, àwa pẹ̀lú ń gbàdúrà fún un yín nígbà gbogbo, pé kí Ọlọ́run wa kí ó lè kà yín yẹ fún ìpè rẹ̀, àti pé nípa agbára rẹ̀, òun yóò mú gbogbo èrò rere yín ṣẹ àti gbogbo ohun tí ìgbàgbọ́ bá rú jáde. 12 Wọ̀nyí ni àdúrà wa, kí orúkọ Jesu Olúwa wa lè di yíyìn lógo nínú yín àti ẹ̀yin nínú rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run àti ti Jesu Kristi Olúwa.
Ẹ má ṣe àníyàn
25 (A)“Nítorí náà, mo wí fún yín, ẹ má ṣe ṣe àníyàn nípa ẹ̀mí yín, ohun tí ẹ ó jẹ àti èyí tí ẹ ó mu; tàbí nípa ara yín, ohun tí ẹ ó wọ̀. Ṣé ẹ̀mí kò ha ṣe pàtàkì ju oúnjẹ lọ tàbí ara ni kò ha ṣe pàtàkì ju aṣọ lọ? 26 Ẹ wo àwọn ẹyẹ ojú ọrun; wọn kì í gbìn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í kórè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í kójọ sínú àká, síbẹ̀ Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run ń bọ́ wọn. Ẹ̀yin kò ha níye lórí jù wọ́n lọ bí? 27 Ta ni nínú gbogbo yín nípa àníyàn ṣíṣe ti ó lè fi ìṣẹ́jú kan kún ọjọ́ ayé rẹ̀?
28 “Kí ni ìdí ti ẹ fi ń ṣe àníyàn ní ti aṣọ? Ẹ wo bí àwọn lílì tí ń bẹ ní igbó ti ń dàgbà. Wọn kì í ṣiṣẹ́ bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í rànwú. 29 Bẹ́ẹ̀ ni mo wí fún yín pé, a kò ṣe Solomoni lọ́ṣọ̀ọ́ nínú gbogbo ògo rẹ̀ tó ọ̀kan nínú àwọn nǹkan wọ̀nyí. 30 Ǹjẹ́ bí Ọlọ́run bá wọ koríko igbó ní aṣọ bẹ́ẹ̀, èyí tí ó wà níhìn-ín lónìí ti a sì gbà sínú iná lọ́la, kò ha ṣe ni ṣe yín lọ́ṣọ̀ọ́ tó bẹ́ẹ̀ àti jù bẹ́ẹ̀ lọ, ẹ̀yin tí ìgbàgbọ́ yín kéré? 31 Nítorí náà, ẹ má ṣe ṣe àníyàn kí ẹ sì máa wí pé, ‘Kí ni àwa yóò jẹ?’ Tàbí ‘Kí ni àwa yóò mu?’ Tàbí ‘Irú aṣọ wo ni àwa yóò wọ̀?’ 32 Nítorí àwọn kèfèrí ń fi ìwọra wá àwọn nǹkan wọ̀nyí bẹ́ẹ̀ ni Baba yín ní ọ̀run mọ̀ dájúdájú pé ẹ ní ìlò àwọn nǹkan wọ̀nyí. 33 Ṣùgbọ́n, ẹ kọ́kọ́ wá ìjọba Ọlọ́run ná àti òdodo rẹ̀, yóò sì fi gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí kún un fún yín pẹ̀lú. 34 Nítorí náà, ẹ má ṣe àníyàn ọ̀la, ọ̀la ni yóò ṣe àníyàn ara rẹ̀. Wàhálà ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ti tó fún un.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.