Book of Common Prayer
Fún adarí orin. Ohun èlò orin olókùn. Ti Dafidi.
61 Gbọ́ ẹkún mi, Ọlọ́run;
Tẹ́tí sí àdúrà mi.
2 Láti òpin ayé wá ni èmi yóò pè ọ́,
mo pè nígbà àyà mi ń ṣàárẹ̀;
mú mi lọ sí ibi àpáta tí ó ga jù mí lọ.
3 Nítorí ìwọ ti jẹ́ ibi ààbò mi,
ilé ìṣọ́ agbára àwọn ọ̀tá.
4 Mo ń lépa láti máa gbé nínú àgọ́ rẹ títí láé
kí n sì rí ààbò níbi ìyẹ́ apá rẹ.
5 Nítorí ìwọ ti gbọ́ àwọn ẹ̀jẹ́ mi, Ọlọ́run;
Ìwọ ti fún mi ní ogún àwọn tí ó bẹ̀rù orúkọ rẹ.
6 Jẹ́ kí ẹ̀mí ọba kí ó gùn,
ọdún rẹ̀ fún ìrandíran.
7 Kí ó máa jẹ ọba níwájú Ọlọ́run títí láé;
pèsè àánú àti òtítọ́ rẹ tí yóò máa ṣe ìtọ́jú rẹ.
8 Nígbà náà ni èmi ó máa kọrin ìyìn sí orúkọ rẹ títí láé
kí n san ẹ̀jẹ́ mi ní ojoojúmọ́.
Fún adarí orin. Fun Jedutuni. Saamu Dafidi.
62 Nínú Ọlọ́run nìkan ni ọkàn mi ti rí ìsinmi;
ìgbàlà mi ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá.
2 Òun nìkan ní àpáta mi àti ìgbàlà mi;
Òun ni ààbò mi, a kì yóò sí mi ní ipò padà.
3 Ẹ̀yin ó ti máa kọ́lú ènìyàn kan pẹ́ tó?
Gbogbo yín ni ó fẹ́ pa á,
bí ògiri tí ó fẹ́ yẹ̀, àti bí ọgbà tí ń wó lọ?
4 Kìkì èrò wọn ni láti bì ṣubú
kúrò nínú ọlá rẹ̀;
inú wọn dùn sí irọ́.
Wọ́n ń fi ẹnu wọn súre,
ṣùgbọ́n wọ́n ń gégùn ún nínú ọkàn wọn. Sela.
5 Nínú Ọlọ́run nìkan ni ìsinmi wà, ìwọ Ọlọ́run mi.
Ìrètí mi wá láti ọ̀dọ̀ rẹ.
6 Òun nìkan ní àpáta àti ìgbàlà mi;
Òun ni ààbò mi, a kì yóò ṣí mi ní ipò.
7 Ìgbàlà mi àti ògo mi dúró nínú Ọlọ́run;
Òun ní àpáta ńlá mi, àti ààbò mi.
8 Gbẹ́kẹ̀lé ní gbogbo ìgbà, ẹ̀yin ènìyàn;
tú ọkàn rẹ jáde sí i,
nítorí Ọlọ́run ni ààbò wa.
9 Nítòótọ́, asán ni àwọn ọmọ ènìyàn, èké
sì ni àwọn olóyè, wọ́n gòkè nínú ìwọ̀n,
lápapọ̀ wọ́n jẹ́ èémí.
10 Má ṣe gbẹ́kẹ̀lé ìnilára,
tàbí gbéraga nínú olè jíjà,
nítòótọ́ bí ọrọ̀ rẹ̀ ń pọ̀ sí i,
má ṣe gbẹ́kẹ̀ rẹ lé wọn.
11 Ọlọ́run ti sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kejì, ni mo
gbọ́ èyí pé, ti Ọlọ́run ni agbára
12 (A)Pẹ̀lúpẹ̀lú, Olúwa, tìrẹ ni àánú
nítorí tí ìwọ san án fún olúkúlùkù ènìyàn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀.
Fún adarí orin. Ti Dafidi. Saamu. Orin.
68 Kí Ọlọ́run kí ó dìde, kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ kí ó fọ́nká;
kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ kí ó sá níwájú rẹ̀.
2 Bí ìjì ti ń fẹ́ èéfín lọ,
kí ó fẹ́ wọn lọ;
bí ìda ti í yọ́ níwájú iná,
kí olùṣe búburú ṣègbé níwájú Ọlọ́run.
3 Ṣùgbọ́n kí inú olódodo kí ó dùn
kí ó sì kún fún ayọ̀ níwájú Ọlọ́run;
kí inú wọn kí ó dùn, kí ó sì kún fún ayọ̀.
4 Ẹ kọrin sí Ọlọ́run,
ẹ kọrin ìyìn sí i,
ẹ la ọ̀nà fún ẹni tí ń rékọjá ní aginjù.
Olúwa ni orúkọ rẹ̀, kí ẹ sì máa yọ̀ níwájú rẹ̀.
5 Baba àwọn aláìní baba àti onídàájọ́ àwọn opó ni Ọlọ́run ní ibùgbé
rẹ̀ mímọ́
6 Ọlọ́run gbé aláìlera
kalẹ̀ nínú ìdílé,
ó darí àwọn ẹlẹ́wọ̀n pẹ̀lú orin,
ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́tẹ̀ ní ń gbé nínú ilẹ̀ gbígbẹ.
7 Nígbà tí ìwọ bá jáde lónìí níwájú àwọn ènìyàn rẹ, Ọlọ́run,
tí ń kọjá lọ láàrín aginjù, Sela.
8 Ilẹ̀ mì títí,
àwọn ọ̀run ń rọ òjò jáde,
níwájú Ọlọ́run,
ẹni Sinai,
níwájú Ọlọ́run, Ọlọ́run Israẹli.
9 Ìwọ fún wa ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ òjò, Ọlọ́run;
ìwọ tu ilẹ̀ ìní rẹ̀ lára nígbà tí ó rẹ̀ ẹ́ tan.
10 Àwọn ènìyàn rẹ tẹ̀dó síbẹ̀
nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìní rẹ, Ọlọ́run, ìwọ pèsè fún àwọn aláìní.
11 Olúwa ti pàṣẹ ọ̀rọ̀,
púpọ̀ ní ogun àwọn ẹni tí ó ń ròyìn rẹ̀.
12 “Àwọn ọba àti àwọn ológun yára sálọ;
Obìnrin tí ó sì jókòó ni ilé ní ń pín ìkógun náà.
13 Nígbà tí ẹ̀yin dùbúlẹ̀ láàrín agbo ẹran,
nígbà náà ni ẹ̀yin ó dàbí ìyẹ́ àdàbà ti a bò ní fàdákà,
àti ìyẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú wúrà pupa.”
14 Nígbà tí Olódùmarè fọ́n àwọn ọba ká ní ilẹ̀ náà,
ó dàbí òjò dídi ní Salmoni.
15 Òkè Baṣani jẹ́ òkè Ọlọ́run;
òkè tí ó ní orí púpọ̀ ni òkè Baṣani.
16 Kí ló dé tí ẹ̀yin fi ń ṣe ìlara,
ẹ̀yin òkè wúwo, òkè tí Ọlọ́run ti fẹ́ láti jẹ ọba
níbi tí Ọlọ́run fúnrarẹ̀ yóò máa gbé títí láé?
17 Ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ni kẹ̀kẹ́ ogun Ọlọ́run
ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀rún;
Olúwa ń bẹ láàrín wọn, ní Sinai ni ibi mímọ́ rẹ̀.
18 Ìwọ ti gòkè sí ibi gíga
ìwọ ti di ìgbèkùn ní ìgbèkùn lọ;
ìwọ ti gba ẹ̀bùn fún ènìyàn:
nítòótọ́, fún àwọn ọlọ̀tẹ̀ pẹ̀lú,
Kí Olúwa Ọlọ́run lè máa bá wọn gbé.
19 Olùbùkún ni Olúwa,
Ọlọ́run Olùgbàlà wa,
ẹni tí ó ń fi ojoojúmọ́ gba ẹrù wa rù. Sela.
20 Ọlọ́run wa jẹ́ Ọlọ́run tó ń gbàlà
àti sí Olúwa Olódùmarè ni ó ń gbà wá lọ́wọ́ ikú.
21 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò tẹ orí àwọn ọ̀tá rẹ̀,
àti agbárí onírun àwọn tó ń tẹ̀síwájú nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn
22 Olúwa wí pé, “Èmi ó mú wọn wá láti Baṣani;
èmi ó mú wọn wá láti ibú omi Òkun,
23 Kí ẹsẹ̀ rẹ kí ó le pọ́n ní inú ẹ̀jẹ̀ àwọn ọ̀tá rẹ,
àti ahọ́n àwọn ajá rẹ ní ìpín tiwọn lára àwọn ọ̀tá rẹ.”
24 Wọ́n ti rí ìrìn rẹ, Ọlọ́run,
ìrìn Ọlọ́run mi àti ọba mi ní ibi mímọ́ rẹ̀.
25 Àwọn akọrin ní iwájú,
tí wọn ń lu ṣaworo
26 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa ní ẹgbẹgbẹ́;
àní fún Olúwa ẹ̀yin tí ó ti orísun Israẹli wá.
27 Níbẹ̀ ní ẹ̀yà kékeré Benjamini wà, tí ó ń darí wọn,
níbẹ̀ ni àwọn ọmọ-aládé Juda,
níbẹ̀ ni àwọn ọmọ-aládé Sebuluni àti tí Naftali.
28 Pàṣẹ agbára rẹ, Ọlọ́run;
fi agbára rẹ hàn wá, Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti ṣe ní ìṣáájú.
29 Nítorí tẹmpili rẹ ni Jerusalẹmu
àwọn ọba yóò mú ẹ̀bùn wá fún ọ.
30 Bá àwọn ẹranko búburú wí,
tí ń gbé láàrín eèsún
ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn akọ màlúù
pẹ̀lú àwọn ọmọ màlúù
títí olúkúlùkù yóò fi foríbalẹ̀ pẹ̀lú ìwọ̀n fàdákà:
tú àwọn ènìyàn tí ń ṣe inú dídùn sí ogun ká
31 Àwọn ọmọ-aládé yóò wá láti Ejibiti;
Etiopia yóò na ọwọ́ rẹ̀ sí Ọlọ́run.
32 Kọrin sí Ọlọ́run, ẹ̀yin ìjọba ayé,
kọrin ìyìn sí Olúwa, Sela.
33 Sí ẹni tí ń gun ọ̀run dé ọ̀run àtijọ́ lókè,
tó ń fọhùn rẹ̀, ohùn ńlá.
34 Kéde agbára Ọlọ́run,
ọláńlá rẹ̀ wà lórí Israẹli,
tí agbára rẹ̀ wà lójú ọ̀run.
35 Ìwọ ní ẹ̀rù, Ọlọ́run, ní ibi mímọ́ rẹ;
Ọlọ́run Israẹli fi agbára àti okun fún àwọn ènìyàn rẹ.
Olùbùkún ní Ọlọ́run!
20 Lẹ́yìn ti Aaroni ti parí ṣíṣe ètùtù ti ibi mímọ́ jùlọ, ti àgọ́ ìpàdé àti ti pẹpẹ: òun yóò sì mú ààyè ewúrẹ́ wá. 21 Aaroni yóò sì gbé ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì lé orí ààyè ewúrẹ́ náà, yóò sì jẹ́wọ́ gbogbo ìwà búburú àti ìṣọ̀tẹ̀ àwọn ara Israẹli lé e lórí: gbogbo ìrékọjá wọn àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn ni yóò sì gbé ka orí ewúrẹ́ náà. Yóò sì rán an lọ sí ijù láti ọwọ́ ẹni tí a yàn fún iṣẹ́ náà. 22 Ewúrẹ́ náà yóò sì ru gbogbo àìṣedéédéé wọn lọ sí ilẹ̀ tí ènìyàn kò gbé. Òun yóò sì jọ̀wọ́ ewúrẹ́ náà lọ́wọ́ lọ sínú ijù.
23 (A)Aaroni yóò sì padà wá sí ibi àgọ́ ìpàdé, yóò sì bọ́ aṣọ ọ̀gbọ̀ wọ̀n-ọn-nì sílẹ̀, tí ó wọ̀ nígbà tí ó lọ sí ibi mímọ́ jùlọ, yóò sì fi wọ́n sílẹ̀ níbẹ̀ 24 Yóò sì fi omi wẹ ara rẹ̀ ní ibi mímọ́ kan: yóò sì wọ aṣọ rẹ̀ yóò sì wá ṣí iwájú: yóò sì rú ẹbọ sísun ti ara rẹ̀ àti ẹbọ sísun ti àwọn ènìyàn láti ṣe ètùtù fún ara rẹ̀ àti fún àwọn ènìyàn: 25 Òun yóò sì sun ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà lórí pẹpẹ.
26 Ẹni tí ó tú ewúrẹ́ ìpààrọ̀ náà sílẹ̀ yóò sì fọ aṣọ rẹ̀: yóò sì wẹ ara rẹ̀ nínú omi: lẹ́yìn èyí ó lè wá sí ibùdó. 27 (B)Ọ̀dọ́ akọ màlúù àti ewúrẹ́ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ tí a ti mú ẹ̀jẹ̀ wọn wá sí ibi mímọ́ jùlọ ni kí a gbe jáde kúrò ní ibùdó. Awọ wọn ni a ó fi iná sun bákan náà. 28 Ẹni tí ó sun wọ́n yóò sì fọ aṣọ rẹ̀: yóò sì wẹ ara rẹ̀: lẹ́yìn èyí ni ó tó le wọ ibùdó.
29 (C)Èyí ni yóò jẹ́ ìlànà títí láé fún un yín: pé ní ọjọ́ kẹwàá oṣù keje ni ẹ gbọdọ̀ ṣẹ́ ara yín: kí ẹ má ṣe ṣe iṣẹ́ kankan, yálà onílé tàbí àlejò tí ó ń gbé pẹ̀lú yín. 30 Torí pé ní ọjọ́ yìí ni àlùfáà yóò ṣe ètùtù fún yín láti sọ yín di mímọ́: kí ẹ̀yin bá à le mọ́ níwájú Olúwa yín kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín gbogbo. 31 Ọjọ́ yìí yóò jẹ́ ọjọ́ ìsinmi pátápátá fún un yín: ẹ̀yin yóò sì ṣẹ́ ara yín: Èyí yóò sì jẹ́ ìlànà títí láé. 32 Àlùfáà náà tí a ti fi òróró yàn tí a sì ti sọ di mímọ́ láti máa ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ ní ilé ìsìn ní ipò baba rẹ̀: òun ni kí ó ṣe ètùtù: yóò sì wọ aṣọ funfun gbòò àní aṣọ mímọ́ náà: òun yóò sì ṣe ètùtù. 33 Yóò sì ṣe ètùtù fún àgọ́ ìpàdé àti fún pẹpẹ: yóò sì ṣe ètùtù fún àlùfáà àti fún gbogbo àgbájọpọ̀ àwọn ènìyàn náà.
34 “Èyí ni yóò jẹ́ ìlànà ayérayé fún yín: láti máa ṣe ètùtù fún àwọn ará Israẹli fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn lẹ́ẹ̀kan lọ́dún.”
Ó sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.
5 (A)Nísinsin yìí, ará, a kò nílò láti kọ ìwé sí i yín mọ́ nípa àkókò àti ìgbà, 2 (B)nítorí ẹ̀yin pàápàá mọ̀ wí pé ọjọ́ Olúwa yóò wá bí olè lóru. 3 (C)Ní àkókò gan an tí àwọn ènìyàn yóò máa wí pé, “Àlàáfíà àti ààbò,” nígbà náà ni ìparun òjijì yóò dé sórí wọn gẹ́gẹ́ bí ìrọbí obìnrin tí ó lóyún, wọn kò sí ni rí ibi ààbò láti sá sí.
4 (D)Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ará, kò sí nínú òkùnkùn nípa nǹkan wọ̀nyí tí ọjọ́ Olúwa yóò fi dé bá yín bí olè. 5 (E)Nítorí gbogbo yín ni ọmọ ìmọ́lẹ̀ àti ọmọ ọ̀sán gangan. Ẹ kì í ṣe tí òru tàbí tí òkùnkùn mọ́. 6 (F)Nítorí náà, ẹ kíyèsára yín kí ẹ má ṣe sùn bí àwọn ẹlòmíràn. Ẹ máa ṣọ́nà kí ẹ sì máa pa ara yín mọ́. 7 (G)Nítorí àwọn tí wọ́n ń sùn, a máa sùn ní òru, àwọn ẹni tí ń mu àmupara, a máa mú un ní òru. 8 (H)Ṣùgbọ́n àwa jẹ́ ti ìmọ́lẹ̀, ẹ jẹ́ kí a pa ara wa mọ́, ní gbígbé ìgbàgbọ́ wọ̀ àti ìfẹ́ bí ìgbàyà ni òru àti ìrètí ìgbàlà bí àṣíborí. 9 (I)Nítorí pé, Ọlọ́run kò yàn wa láti da ìbínú rẹ̀ gbígbóná sí orí wa, ṣùgbọ́n ó yàn láti gbà wá là nípasẹ̀ Olúwa wa, Jesu Kristi. 10 Jesu kú fún wa kí a lè ba à gbé títí láéláé. Èyí yóò rí bẹ́ẹ̀ yálà a sùn tàbí a wà láààyè pẹ̀lú rẹ̀. 11 Nítorí náà, ẹ máa gba ara yín níyànjú, kí ẹ sì máa gbé ara yín ró, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ń ṣe.
7 Ṣùgbọ́n nígbà ti ẹ̀yin bá ń gbàdúrà, ẹ má ṣe àtúnwí asán bí àwọn aláìkọlà, nítorí wọn rò pé a ó tìtorí ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ gbọ́ tiwọn. 8 Ẹ má ṣe dàbí i wọn, nítorí Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run mọ ohun tí ẹ ṣe aláìní, kí ẹ tilẹ̀ tó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.
9 (A)“Nítorí náà, báyìí ni kí ẹ ṣe máa gbàdúrà:
“ ‘Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run,
ọ̀wọ̀ fún orúkọ yín,
10 Kí ìjọba yín dé,
Ìfẹ́ tiyín ni kí a ṣe
ní ayé bí ti ọ̀run.
11 Ẹ fún wa ní oúnjẹ òòjọ́ wa lónìí
12 Ẹ dárí gbèsè wa jì wá,
Bí àwa ti ń dáríji àwọn ajigbèsè wa,
13 (B)Ẹ má ṣe fà wá sínú ìdánwò,
Ṣùgbọ́n ẹ gbà wá lọ́wọ́ ibi.
Nítorí ìjọba ni tiyín, àti agbára àti ògo, láéláé, Àmín.’
14 (C)Nítorí náà, bí ẹ̀yin bá dárí jí àwọn tó ṣẹ̀ yín, baba yín ọ̀run náà yóò dáríjì yín. 15 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá kọ̀ láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn jì wọ́n, baba yín kò ní í dárí ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.