Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 78

Maskili ti Asafu.

78 Ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ gbọ́ ẹ̀kọ́ mi;
    tẹ́tí rẹ sí ọ̀rọ̀ ẹnu mi.
(A)Èmi ó la ẹnu mi ní òwe,
    èmi o sọ ohun ìkọ̀kọ̀, ohun ti ọjọ́ pípẹ́;
Ohun tí a ti gbọ́ tí a sì ti mọ̀,
    ohun tí àwọn baba wa ti sọ fún wa.
Àwa kì yóò pa wọ́n mọ́
    kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọmọ,
ní fífi ìyìn Olúwa, àti ipa rẹ̀
    àti iṣẹ́ ìyanu tó ti ṣe hàn
fún ìran tí ń bọ̀.
Ó gbé ẹ̀rí kalẹ̀ ní Jakọbu
    o sì fìdí àṣẹ múlẹ̀ ní Israẹli,
èyí tí ó pàṣẹ fún àwọn baba ńlá wa
    láti kọ́ àwọn ọmọ wọn,
Nítorí náà, àwọn ìran tí ń bọ̀ yóò mọ̀ wọ́n
    bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ tí a kò tí ì bí
    tí yóò dìde tí wọn yóò sọ fún àwọn ọmọ wọn
Nígbà náà ni wọ́n ò fi ìgbẹ́kẹ̀lé wọn sínú Ọlọ́run
    wọn kò sì ní gbàgbé iṣẹ́ Ọlọ́run
    ṣùgbọ́n wọn ó pa àṣẹ rẹ̀ mọ́.
Kí wọn kí ó má ṣe dàbí àwọn baba ńlá wọn,
    ìran alágídí àti ọlọ́tẹ̀,
    ìran tí ọkàn wọn kò ṣọ òtítọ́ si olóore,
    àti ẹ̀mí ẹni tí kò bá Ọlọ́run dúró ṣinṣin.

Àwọn ọkùnrin Efraimu, tí ó há mọ́ ọ tí wọ́n mú ọrun,
    wọ́n yípadà ní ọjọ́ ogun
10 Wọn kò pa májẹ̀mú Ọlọ́run mọ́
    wọn sì kọ̀ láti máa gbé nínú òfin rẹ̀
11 Wọ́n gbàgbé ohun tí ó ti ṣe,
    àwọn ìyanu tí ó ti fihàn wọ́n.
12 Ó ṣe ìyanu níwájú àwọn baba wọn ní ilẹ̀ Ejibiti, ní agbègbè Ṣoani.
13 Ó pín Òkun ní yà, ó sì mú wọn kọjá
    Ó mù kí omi naà dúró bi odi gíga.
14 Ní ọ̀sán, ó fi ìkùùkuu àwọsánmọ̀ ṣe amọ̀nà wọn
    àti ní gbogbo òru pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ iná.
15 Ó sán àpáta ní aginjù
    ó sì fún wọn ní omi mímu lọ́pọ̀lọpọ̀
    bí ẹni pé láti inú ibú wá.
16 Ó mú ìṣàn omi jáde láti inú àpáta
    omi ṣíṣàn sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí odò.

17 Wọ́n sì tún tẹ̀síwájú láti dẹ́ṣẹ̀ sí i
    ní ìṣọ̀tẹ̀ sí Ọ̀gá-ògo ní aginjù.
18 Wọ́n mọ̀ ọ́n mọ̀ dán Ọlọ́run wò
    nípa bíbéèrè fún oúnjẹ tí wọn bẹ̀bẹ̀ fún
19 Wọ́n sọ̀rọ̀-òdì sí Ọlọ́run, wí pé
    “Ọlọ́run ha lè tẹ́ tábìlì ní aginjù?
20 Nígbà tí ó lu àpáta, omi tú jáde,
    odò sì sàn lọ́pọ̀lọpọ̀
ṣùgbọ́n òun ha lè fún wa lóúnjẹ
    ó ha le pèsè ẹran fún àwọn ènìyàn rẹ̀”
21 Nígbà tí Olúwa gbọ́ wọn, ó bínú gidigidi;
iná rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ sí Jakọbu,
ìbínú rẹ̀ sì rú sí Israẹli,
22 Nítorí wọn kò gba Ọlọ́run gbọ́,
    wọn kò sì gbẹ́kẹ̀lé ìgbàlà rẹ̀.
23 Síbẹ̀ ó pàṣẹ fún ìràwọ̀ ojú ọ̀run,
    ó sì ṣí ìlẹ̀kùn ọ̀run sílẹ̀;
24 (B)Ó rọ manna fún àwọn ènìyàn láti jẹ,
    ó fún wọn ní ọkà láti ọ̀run.
25 Àwọn ènìyàn jẹ oúnjẹ àwọn angẹli;
    Ó fún wọn ní oúnjẹ ní àjẹyó,
26 Ó mú afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn láti ọ̀run wá
    ó mú afẹ́fẹ́ gúúsù wá nípa agbára rẹ̀.
27 Ó rọ òjò ẹran sílẹ̀ sórí wọn bí erùpẹ̀ ilẹ̀,
    àti ẹyẹ abìyẹ́ gẹ́gẹ́ bí iyanrìn etí Òkun
28 Ó jẹ́ kí wọn jáde ní ibùdó wọn,
    yíká àgọ́ wọn.
29 Wọ́n jẹ, wọ́n sì yó jọjọ
    nítorí ó ti fún wọn ní ohun tí wọn fìtara bẹ̀bẹ̀ fún
30 Ṣùgbọ́n wọn kò kúrò nínú oúnjẹ tí wọn fìtara bẹ̀bẹ̀ fún,
    nígbà tí oúnjẹ wọn sì wà ní ẹnu wọn,
31 Ìbínú Ọlọ́run dìde sí wọn
    ó pa àwọn tí ó jùlọ nínú wọn,
    ó sì lu àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin Israẹli bolẹ̀.

32 Nínú gbogbo ìwọ̀nyí, wọ́n ń dẹ́ṣẹ̀ síwájú;
    nínú gbogbo iṣẹ́ ìyanu rẹ̀, wọ́n kò gbàgbọ́
33 O fi òpin sí ayé wọn nínú asán
    àti ọdún wọn nínú ìpayà.
34 Nígbàkígbà tí Ọlọ́run bá pa wọ́n,
    wọn yóò wá a kiri;
    wọn yóò fi ìtara yípadà sí i.
35 Wọ́n rántí pé Ọlọ́run ní àpáta wọn;
    wí pé Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo jùlọ ni olùràpadà àpáta wọn
36 Ṣùgbọ́n nígbà náà ni wọ́n yóò pọ́n ọn pẹ̀lú ẹnu wọ́n
    wọ́n fi ahọ́n wọ́n purọ́ fún un;
37 (C)Ọkàn wọn kò sòtítọ́ sí i,
    wọn kò jẹ́ olódodo sí májẹ̀mú rẹ̀.
38 Síbẹ̀ ó ṣàánú;
    ó dárí àìṣedéédéé wọn jì
òun kò sì pa wọ́n run
    nígbà púpọ̀ ló ń yí ìbínú rẹ̀ padà
kò sì ru ìbínú rẹ̀ sókè
39 Ó rántí pé ẹlẹ́ran ara ni wọ́n,
    afẹ́fẹ́ tó ń kọjá tí kò lè padà.

40 Nígbà gbogbo ní wọn ń ṣọ̀tẹ̀ sí i ní aginjù
    wọn mú un bínú nínú ilẹ̀ tí ó di ahoro!
41 Síwájú àti síwájú wọ́n dán Ọlọ́run wò;
    wọ́n mú ẹni mímọ́ Israẹli bínú.
42 Wọ́n kò rántí agbára rẹ̀:
    ní ọjọ́ tí ó rà wọ́n padà lọ́wọ́ àwọn aninilára,
43 Ní ọjọ́ tí ó fi iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ hàn ní Ejibiti,
    àti iṣẹ́ ààmì rẹ̀ ni ẹkùn Ṣoani
44 Ó sọ omi wọn di ẹ̀jẹ̀;
    wọn kò lè mu láti odò wọn.
45 Ó rán ọ̀wọ́ eṣinṣin láti pa wọ́n run,
    àti ọ̀pọ̀lọ́ tí ó bá wọn jẹun.
46 Ó fi ọkà wọn fún láńtata,
    àwọn ìre oko wọn fún eṣú.
47 Ó fi yìnyín ba àjàrà wọn jẹ́
    ó bá èso sikamore wọn jẹ́.
48 Ó fi ohun ọ̀sìn wọn fún yìnyín,
    agbo ẹran wọn fún mọ̀nàmọ́ná.
49 Ó mú kíkorò ìbínú rẹ̀ wá sí wọn lára,
    ìrunú àti ìkáàánú, àti ìpọ́njú,
    nípa rírán angẹli apanirun sí wọn.
50 Ó pèsè ipa fún ìbínú rẹ̀,
    òun kò gbà wọ́n lọ́wọ́ ikú,
    ṣùgbọ́n ó fi ẹ̀mí wọ́n fún àjàkálẹ̀-ààrùn.
51 Ó kọlu àwọn àkọ́bí ọmọ ọkùnrin Ejibiti
    Olórí agbára wọn nínú àgọ́ Hamu
52 Ṣùgbọ́n ó mú àwọn ènìyàn rẹ̀ jáde bí ọ̀wọ́ ẹran;
    ó ṣọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí àgùntàn nínú aginjù.
53 Ó dáàbò bò wọ́n dáradára, nítorí náà ni ẹ̀rù kò ṣe bà wọ́n
    ṣùgbọ́n Òkun padé mọ́ àwọn ọ̀tá wọn.
54 Bákan náà ni ó mú wọn wá sí etí ilẹ̀ mímọ́ rẹ̀
    òkè tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ ti gbà
55 Ó lé kèfèrí jáde níwájú wọn
    ó sì fi títa okùn pín ilẹ̀ náà fún wọn gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìní;
    ó mú àwọn ẹ̀yà Israẹli jókòó ní ilẹ̀ wọn.

56 Ṣùgbọ́n wọn dán Ọlọ́run wò
    wọn sì ṣọ̀tẹ̀ sí Ọ̀gá-ògo;
    wọn kò pa àṣẹ rẹ̀ mọ́.
57 Ṣùgbọ́n wọ́n yípadà,
    wọn jẹ́ aláìṣòdodo gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wọn
wọ́n sì pẹ̀yìndà sí apákan bí ọrun ẹ̀tàn.
58 Wọ́n bí i nínú pẹ̀lú ibi gíga wọn;
    wọn rú owú rẹ̀ sókè nípa òrìṣà wọn
59 Nígbà tí Ọlọ́run gbọ́ wọn,
    inú bí i gidigidi;
ó kọ Israẹli pátápátá.
60 Ó kọ àgọ́ Ṣilo sílẹ̀,
    àgọ́ tí ó ti gbé kalẹ̀ láàrín àwọn ènìyàn.
61 Ó rán àpótí ẹ̀rí, agbára rẹ̀ lọ sí ìgbèkùn,
    dídán ògo rẹ̀ lọ sí ọwọ́ àwọn ọ̀tá.
62 Ó fi àwọn ènìyàn rẹ̀ lé idà lọ́wọ́,
    ó sì bínú sí àwọn ohun ìní rẹ̀.
63 Iná run àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin wọn,
    àwọn ọmọbìnrin wọn kò sì ní orin ìgbéyàwó:
64 A fi àlùfáà wọn fún idà,
    àwọn opó wọn kò sì le è sọkún.

65 Olúwa sì jí gẹ́gẹ́ bí ẹni ojú oorun,
    gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin ti i jí kúrò nínú ìraníyè ọtí.
66 Ó kọlu àwọn ọ̀tá rẹ̀ padà;
    ó fi wọn sínú ìtìjú ayérayé.
67 Nígbà náà ni ó kọ́ àgọ́ Josẹfu,
    kò sì yan ẹ̀yà Efraimu;
68 Ṣùgbọ́n ó yan ẹ̀yà Juda,
    òkè Sioni, èyí tí ó fẹ́ràn.
69 Ó kọ́ ibi mímọ́ rẹ̀, ibi gíga,
    gẹ́gẹ́ bí ayé tí ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ títí láé.
70 Ó yan Dafidi ìránṣẹ́ rẹ̀
    ó mú láti inú àwọn agbo ẹran;
71 Ó mú un jáde nínú ìtọ́jú àgùntàn
    láti jẹ́ olùṣọ́-àgùntàn àwọn ènìyàn rẹ̀ Jakọbu
    àti Israẹli ogún un rẹ̀.
72 Dafidi sì ṣọ́ wọn pẹ̀lú òtítọ́ inú ọkàn;
    pẹ̀lú ọwọ́ òye ni ó fi darí wọn.

Lefitiku 26:1-20

Èrè ìgbọ́ràn

26 (A)‘Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ mọ ère òrìṣà, tàbí kí ẹ̀yin gbe ère kalẹ̀ tàbí kí ẹ̀yin gbẹ́ ère òkúta: kí ẹ̀yin má sì gbẹ́ òkúta tí ẹ̀yin yóò gbé kalẹ̀ láti sìn. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.

(B)“ ‘Ẹ pa ọjọ́ ìsinmi mi mọ́ kí ẹ̀yin sì bọ̀wọ̀ fún ibi mímọ́ mi: Èmi ni Olúwa.

(C)“ ‘Bí ẹ̀yin bá tẹ̀lé àṣẹ mi, tí ẹ̀yin sì ṣọ́ra láti pa òfin mi mọ́. Èmi yóò rọ̀jò fún yín ní àkókò rẹ̀, kí ilẹ̀ yín le mú èso rẹ̀ jáde bí ó tí yẹ kí àwọn igi eléso yín so èso. Èrè oko yín yóò pọ̀ dé bi pé ẹ ó máa pa ọkà títí di àsìkò ìkórè igi eléso, ẹ̀yin yóò sì máa gbé ní ilẹ̀ yín láìléwu.

“ ‘Èmi yóò fún yín ní àlàáfíà ní ilẹ̀ yín, ẹ̀yin yóò sì sùn láìsí ìbẹ̀rù ẹnikẹ́ni. Èmi yóò mú kí gbogbo ẹranko búburú kúrò ní ilẹ̀ náà: bẹ́ẹ̀ ni idà kì yóò la ilẹ̀ yín já. Ẹ̀yin yóò lé àwọn ọ̀tá yín: wọn yóò sì tipa idà kú. Àwọn márùn-ún péré nínú yín yóò máa ṣẹ́gun ọgọ́rùn-ún ènìyàn: Àwọn ọgọ́rùn-ún yóò sì máa ṣẹ́gun ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá: Àwọn ọ̀tá yín yóò tipa idà kú níwájú yín.

“ ‘Èmi yóò fi ojúrere wò yín: Èmi yóò mú kí ẹ bí sí i, èmi yóò jẹ́ kí ẹ pọ̀ sí i: Èmi yóò sì pa májẹ̀mú mi mọ́ pẹ̀lú yín. 10 Àwọn èrè oko yín yóò pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ẹ̀yin ó máa jẹ èrè ọdún tí ó kọjá, ẹ̀yin ó sì kó wọn jáde: kí ẹ̀yin lè rí ààyè kó tuntun sí. 11 (D)Èmi yóò kọ́ àgọ́ mímọ́ mi sí àárín yín. Èmi kò sì ní kórìíra yín. 12 Èmi yóò wà pẹ̀lú yín: Èmi yóò máa jẹ́ Ọlọ́run yín: Ẹ̀yin yóò sì máa jẹ́ ènìyàn mi. 13 Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín tí ó mú yín jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti: kí ẹ̀yin má ba à jẹ́ ẹrú fún wọn mọ́. Mo sì já ìdè àjàgà yín: mo sì mú kí ẹ̀yin máa rìn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí a gbé lórí sókè.

Ìjìyà fún àìgbọ́ràn

14 (E)“ ‘Bí ẹ̀yin kò bá fetí sí mi tí ẹ̀yin kò sì ṣe gbogbo òfin wọ̀nyí. 15 Bí ẹ̀yin bá kọ àṣẹ mi tí ẹ̀yin sì kórìíra òfin mi, tí ẹ̀yin sì kùnà láti pa ìlànà mi mọ́, nípa èyí tí ẹ̀yin ti ṣẹ̀ sí májẹ̀mú mi. 16 Èmi yóò ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí sí yín: Èmi yóò mú ìpayà òjijì bá yín: àwọn ààrùn afiniṣòfò, àti ibà afọ́nilójú, tí í pa ni díẹ̀díẹ̀. Ẹ̀yin yóò gbin èso ilẹ̀ yín lásán: nítorí pé àwọn ọ̀tá yín ni yóò jẹ gbogbo ohun tí ẹ̀yin ti gbìn. 17 Èmi yóò dojúkọ yín títí tí ẹ̀yin ó fi di ẹni ìkọlù; àwọn tí ó kórìíra yín ni yóò sì ṣe àkóso lórí yín. Ìbẹ̀rù yóò mú yín dé bi pé ẹ̀yin yóò máa sá káàkiri nígbà tí ẹnikẹ́ni kò lé yín.

18 “ ‘Bí ẹ̀yin kò bá wá gbọ́ tèmi lẹ́yìn gbogbo èyí: Èmi yóò fi kún ìyà yín ní ìlọ́po méje nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín. 19 Èmi yóò fọ́ agbára ìgbéraga yín: ojú ọ̀run yóò le koko bí irin: ilẹ̀ yóò sì le bí idẹ (òjò kò ní rọ̀: ilẹ̀ yín yóò sì le). 20 Ẹ ó máa lo agbára yín lásán torí pé ilẹ̀ yín kì yóò so èso, bẹ́ẹ̀ ni àwọn igi yín kì yóò so èso pẹ̀lú.

1 Timotiu 2:1-6

Àwọn ẹ̀kọ́ lórí ìsìn

Nítorí náà mo gbà yín níyànjú ṣáájú ohun gbogbo, pé kí a máa bẹ̀bẹ̀, kí a máa gbàdúrà, kí a máa ṣìpẹ̀, àti kí a máa dúpẹ́ nítorí gbogbo ènìyàn. Fún àwọn ọba, àti gbogbo àwọn tí ó wà ni ipò àṣẹ, kí a lè máa lo ayé wa ní àlàáfíà àti ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ pẹ̀lú nínú gbogbo ìwà-bí-Ọlọ́run àti ìwà mímọ́. Nítorí èyí dára, ó sì ṣe ìtẹ́wọ́gbà níwájú Ọlọ́run Olùgbàlà wa; Ẹni tí ó fẹ́ kí gbogbo ènìyàn ní ìgbàlà kí wọ́n sì wá sínú ìmọ̀ òtítọ́. Nítorí Ọlọ́run kan ní ń bẹ, onílàjà kan pẹ̀lú láàrín Ọlọ́run àti ènìyàn, àní Kristi Jesu ọkùnrin náà. Ẹni ti ó fi ara rẹ̀ ṣe ìràpadà fún gbogbo ènìyàn—ẹ̀rí tí a fi fún ni ní àkókò tó yẹ.

Matiu 13:18-23

18 (A)“Nítorí náà, ẹ fi etí sí ohun tí òwe afúnrúgbìn túmọ̀ sí: 19 Nígbà tí ẹnikẹ́ni bá gbọ́ ọ̀rọ̀ nípa ìjọba ọ̀run ṣùgbọ́n tí kò yé e, lẹ́yìn náà èṣù á wá, a sì gba èyí tí a fún sí ọkàn rẹ̀ kúrò. Èyí ni irúgbìn ti a fún sí ẹ̀bá ọ̀nà. 20 Ẹni tí ó sì gba irúgbìn tí ó bọ́ sí ilẹ̀ orí àpáta, ni ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, lọ́gán, ó sì fi ayọ̀ gba ọ̀rọ̀ náà. 21 Ṣùgbọ́n nítorí kò ní gbòǹgbò, ó wà fún ìgbà díẹ̀; nígbà tí wàhálà àti inúnibíni bá dìde nítorí ọ̀rọ̀ náà ní ojú kan náà yóò sì kọsẹ̀. 22 Ẹni tí ó si gba irúgbìn tí ó bọ́ sí àárín ẹ̀gún ni ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, ṣùgbọ́n àwọn àníyàn ayé yìí, ìtànjẹ, ọrọ̀ sì fún ọ̀rọ̀ náà pa, ọ̀rọ̀ náà kò so èso nínú rẹ̀. 23 Ṣùgbọ́n ẹni tí ó gba irúgbìn tí ó bọ́ sí orí ilẹ̀ rere ni ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, tí ó sì yé e; òun sì so èso òmíràn ọgọ́rọ̀ọ̀rùn, òmíràn ọgọ́tọ̀ọ̀ta, òmíràn ọgbọọgbọ̀n.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.