Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 105

105 (A)Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, ké pe orúkọ rẹ̀:
    Jẹ́ kí a mọ ohun tí ó ṣe láàrín àwọn orílẹ̀-èdè;
Kọrin sí i, kọrin ìyìn sí i;
    sọ ti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ gbogbo.
Ṣògo nínú orúkọ mímọ́ rẹ̀:
    Jẹ́ kí ọkàn àwọn tí ń wá Olúwa kí ó yọ̀.
Olúwa àti ipá rẹ̀;
    wa ojú rẹ̀ nígbà gbogbo.

Rántí àwọn ìyanu tí ó ti ṣe,
    ìyanu rẹ̀, àti ìdájọ́ tí ó sọ,
Ẹ̀yin ìran Abrahamu ìránṣẹ́ rẹ̀,
    ẹ̀yin ọmọkùnrin Jakọbu, àyànfẹ́ rẹ̀.
Òun ni Olúwa Ọlọ́run wa:
    ìdájọ́ rẹ̀ wà ní gbogbo ayé.

(B)Ó rántí májẹ̀mú rẹ̀ láéláé,
    ọ̀rọ̀ tí ó pàṣẹ, fún ẹgbẹgbẹ̀rún ìran,
májẹ̀mú tí ó dá pẹ̀lú Abrahamu,
    ìbúra tí ó ṣe pẹ̀lú fún Isaaki.
10 Ó ṣe ìdánilójú u rẹ̀ fún Jakọbu gẹ́gẹ́ bí àṣẹ
    sí Israẹli, gẹ́gẹ́ bi májẹ̀mú ayérayé:
11 “Fún ìwọ ni èmi ó fún ní ilẹ̀ Kenaani
    gẹ́gẹ́ bí ìpín tí ìwọ ó jogún.”

12 Nígbà tí wọn kéré níye,
    wọ́n kéré jọjọ, àti àwọn àjèjì níbẹ̀
13 wọ́n rìn kiri láti orílẹ̀-èdè sí orílẹ̀-èdè,
    láti ìjọba kan sí èkejì.
14 Kò gba ẹnikẹ́ni láààyè láti pọ́n wọn lójú;
    ó fi ọba bú nítorí tiwọn:
15 “Má ṣe fọwọ́ kan ẹni ààmì òróró mi, má sì ṣe wòlíì mi níbi.”

16 Ó pe ìyàn sórí ilẹ̀ náà
    ó sì pa gbogbo ìpèsè oúnjẹ wọn run;
17 Ó sì rán ọkùnrin kan síwájú wọn
    Josẹfu tí a tà gẹ́gẹ́ bí ẹrú.
18 Wọn fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ bọ ẹsẹ̀ rẹ̀
    a gbé ọrùn rẹ̀ sínú irin
19 Títí ọ̀rọ̀ tí ó sọtẹ́lẹ̀ fi ṣẹ
    títí ọ̀rọ̀ Olúwa fi dá a láre.
20 Ọba ránṣẹ́ lọ tú u sílẹ̀
    àwọn aláṣẹ ènìyàn tú u sílẹ̀
21 Ó fi jẹ olúwa lórí ilẹ̀ rẹ̀
    aláṣẹ lórí ohun gbogbo tí ó ní,
22 Gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀, kí ó máa
    ṣe àkóso àwọn ọmọ-aládé
    kí ó sì kọ́ àwọn àgbàgbà rẹ̀ ní ọgbọ́n.

23 Israẹli wá sí Ejibiti;
    Jakọbu sì ṣe àtìpó ní ilé Hamu.
24 Olúwa, sì mú àwọn ọmọ rẹ̀ bí sí i
    ó sì mú wọn lágbára jù
    àwọn ọ̀tá wọn lọ
25 Ó yí wọn lọ́kàn padà láti kórìíra àwọn ènìyàn
    láti ṣe àrékérekè sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.
26 Ó rán Mose ìránṣẹ́ rẹ̀
    àti Aaroni tí ó ti yàn
27 Wọ́n ń ṣe iṣẹ́ ìyanu láàrín wọn
    ó ṣe iṣẹ́ ìyanu ní Hamu.
28 Ó rán òkùnkùn, o sì mú ilẹ̀ ṣú
    wọn kò sì sọ̀rọ̀-òdì sí ọ̀rọ̀ rẹ̀.
29 Ó sọ omi wọn di ẹ̀jẹ̀,
    ó pa ẹja wọn.
30 Ilẹ̀ mú ọ̀pọ̀lọ́ jáde wá,
    èyí tí ó lọ sí ìyẹ̀wù àwọn ọba wọn.
31 Ó sọ̀rọ̀, onírúurú eṣinṣin sì dìde,
    ó sì hu kantíkantí ní ilẹ̀ wọn
32 Ó sọ òjò di yìnyín,
    àti ọ̀wọ́-iná ní ilẹ̀ wọn;
33 Ó lu àjàrà wọn àti igi ọ̀pọ̀tọ́ wọn
    ó sì dá igi orílẹ̀-èdè wọn.
34 Ó sọ̀rọ̀, eṣú sì dé,
    àti kòkòrò ní àìníye,
35 Wọn sì jẹ gbogbo ewé ilẹ̀ wọn,
    wọ́n sì jẹ èso ilẹ̀ wọn run
36 Nígbà náà, ó kọlu gbogbo àwọn ilẹ̀ wọn,
    ààyò gbogbo ipá wọn.
37 Ó mú Israẹli jáde
    ti òun ti fàdákà àti wúrà,
    nínú ẹ̀yà rẹ̀ kò sí aláìlera kan.
38 Inú Ejibiti dùn nígbà tí wọn ń lọ,
    nítorí ẹ̀rù àwọn Israẹli ń bá wọ́n.

39 Ó ta àwọsánmọ̀ fún ìbòrí,
    àti iná láti fún wọn ní ìmọ́lẹ̀ lálẹ́
40 Wọn béèrè, ó sì mú ẹyẹ àparò wá,
    ó sì fi oúnjẹ ọ̀run tẹ́ wọn lọ́rùn.
41 Ó sì la àpáta, ó sì mú omi jáde;
    gẹ́gẹ́ bí odò tí ń sàn níbi gbígbẹ.

42 Nítorí ó rántí ìlérí mímọ́ rẹ̀
    àti Abrahamu ìránṣẹ́ rẹ̀.
43 Ó sì fi ayọ̀ mú àwọn ènìyàn rẹ̀ jáde
    pẹ̀lú ayọ̀ ní ó yan àyànfẹ́ rẹ̀
44 Ó fún wọn ní ilẹ̀ ìní náà,
    wọ́n sì jogún iṣẹ́ àwọn ènìyàn náà,
45 Kí wọn kí ó lè máa pa àṣẹ rẹ̀ mọ́
    kí wọn kí ó lè kíyèsi òfin rẹ̀.

Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

Eksodu 24

Ìfimúlẹ̀ májẹ̀mú

24 Ní ìgbà náà ni Olúwa sọ fún Mose pé, “Gòkè tọ Olúwa wá, ìwọ àti Aaroni, Nadabu àti Abihu àti àádọ́rin (70) àwọn àgbàgbà Israẹli. Ẹ̀yin kì ó sìn ni òkèèrè réré. Ṣùgbọ́n Mose nìkan ṣoṣo ni yóò súnmọ́ Olúwa; àwọn tókù kò gbọdọ̀ súnmọ́ tòsí ibẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ènìyàn kò gbọdọ̀ gòkè wá pẹ̀lú rẹ̀.”

Nígbà ti Mose lọ láti sọ fún àwọn ènìyàn, gbogbo ọ̀rọ̀ àti òfin Olúwa, wọ́n wí ní ohùn kan pé, “Gbogbo ohun ti Olúwa wí ni àwa yóò ṣe.” Nígbà náà ni Mose kọ gbogbo ohun tí Olúwa sọ sílẹ̀.

Ó dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ó sì mọ pẹpẹ ni ẹsẹ̀ òkè náà. Ó ṣe ọ̀wọ́n òkúta méjìlá. Èyí ti ó dúró fún àwọn ẹ̀yà Israẹli méjìlá. Nígbà náà ni ó rán àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin Israẹli, wọ́n sì rú ẹbọ sísun, wọ́n fi ọ̀dọ́ màlúù rú ẹbọ àlàáfíà si Olúwa. Mose bu ìlàjì ẹ̀jẹ̀ ẹran sínú abọ́, ó sì fi ìlàjì tókù wọn ara pẹpẹ. Nígbà náà ni ó sì mú ìwé májẹ̀mú, ó sì kà á sí àwọn ènìyàn. Wọ́n dáhùn pé, “Àwa yóò ṣe gbogbo ohun tí Olúwa wí: Àwa yóò sì gbọ́rọ̀.”

(A)Nígbà náà ni Mose gbé ẹ̀jẹ̀, ó sì wọn sí àwọn ènìyàn náà lára pé, “Èyí ni ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú tí Ọlọ́run ti ṣe pẹ̀lú yín ni ìbámu pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí.”

Mose àti Aaroni, Nadabu àti Abihu àti àádọ́rin àwọn àgbàgbà Israẹli gòkè lọ. 10 Wọ́n sì rí Ọlọ́run Israẹli. Ní abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀ ni ohun kan bí i pèpéle ti a fi òkúta safire ṣe wà. Èyí ti ó mọ́ nigínnigín bí àwọ̀ sánmọ̀ fúnrarẹ̀. 11 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run kò gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè sí àwọn àgbàgbà Israẹli wọ̀nyí; wọ́n ri Ọlọ́run, wọ́n jẹ, wọ́n sì mu.

12 (B)Olúwa sì sọ fún Mose pé, “Gòkè wá sí ọ̀dọ̀ mi, kí o sì dúró níhìn-ín. Èmi yóò sì fún ọ ní wàláà òkúta pẹ̀lú òfin àti ìlànà tí mo ti kọ sílẹ̀ fún ìtọ́sọ́nà wọn.”

13 Nígbà náà ni Mose jáde lọ pẹ̀lú Joṣua arákùnrin rẹ̀. Mose lọ sí orí òkè Ọlọ́run. 14 Ó sì wí fún àwọn àgbàgbà pé, Ẹ dúró dè wá níhìn-ín yìí, títí àwa yóò fi tún padà tọ̀ yín wá, sì kíyèsi i, Aaroni àti Huri ń bẹ pẹ̀lú yín, bí ẹnìkan bá ni ọ̀ràn kan, kí ó tọ̀ wọ́n lọ.

15 Nígbà tí Mose gun orí òkè lọ, ìkùùkuu bo orí òkè náà. 16 Ògo Olúwa sì wà ní orí òkè Sinai. Ìkùùkuu bo orí òkè náà fún ọjọ́ mẹ́fà, ni ọjọ́ keje ni Olúwa kọ sí Mose láti inú ìkùùkuu náà wá. 17 Ni ojú àwọn ọmọ Israẹli ògo Olúwa náà dàbí iná ajónirun ni orí òkè. 18 Nígbà náà ni Mose wọ inú ìkùùkuu náà bí ó ti ń lọ ní orí òkè. Ó sì wà ni orí òkè náà ni ogójì ọ̀sán àti ogójì òru.

Kolose 2:8-23

Ẹ rí dájú pé ẹnikẹ́ni kò mú yin ní ìgbèkùn pẹ̀lú ẹ̀kọ́ àròsọ àti ìmọ̀ ẹ̀tàn, èyí tí ó gbára lé ìlànà ti ènìyàn àti àgbékalẹ̀ àwọn ẹ̀mí ayé yìí tí ó yàtọ̀ sí ti Kristi.

Nítorí nínú Kristi ni ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìwàláàyè Ọlọ́run gbé ní ara, 10 (A)ẹ̀yin sì ní ohun gbogbo ní kíkún nínú Kristi, ẹni tí i ṣe orí fún gbogbo agbára àti àṣẹ. 11 Nínú ẹni tí a kò fi ìkọlà tí a fi ọwọ́ kọ kọ yín ní ilà, ni bíbọ ara ẹ̀ṣẹ̀ sílẹ̀, nínú ìkọlà Kristi. 12 Bí a ti sin yín pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ nínú ìtẹ̀bọmi, tí a sì ti jí yín dìde pẹ̀lú rẹ̀ nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ yín nínú agbára Ọlọ́run, ẹni tí ó jí dìde kúrò nínú òkú.

13 Àti ẹ̀yin, ẹni tí ó ti kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín àti àìkọlà ará yín, mo ní, ẹ̀yin ni ó sì ti sọ di ààyè pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀, ó sì ti dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín; 14 Ó sì ti pa ìwé májẹ̀mú nì rẹ́, tí ó lòdì sí wa, tí a kọ nínú òfin, èyí tí o lòdì sí wa: òun ni ó sì ti mú kúrò lójú ọ̀nà, ó sì kàn án mọ àgbélébùú. 15 (B)Ó sì ti gba agbára kúrò lọ́wọ́ àwọn ìjọba ẹ̀mí búburú àti àwọn alágbára gbogbo, ó sì ti dójútì wọn ní gbangba, bí ó ti ń yọ̀ fún ìṣẹ́gun lórí wọn.

16 (C)Nítorí náà ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ṣe ìdájọ́ yín ní ti jíjẹ, tàbí ní ti mímu, tàbí ní ti ọjọ́ àsè, tàbí oṣù tuntun, àti ọjọ́ ìsinmi: 17 (D)Àwọn tí í ṣe òjìji ohun tí ń bọ̀; ṣùgbọ́n ní ti òtítọ́, nínú Kristi ni àti mu wọn ṣẹ. 18 Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tí ó ní inú dídùn nínú ìrẹ̀lẹ̀ èké àti bíbọ àwọn angẹli lọ́ èrè yín gbà lọ́wọ́ yín, ẹni tí ń dúró lórí nǹkan wọ̀n-ọn-nì tí ó ti rí, tí ó ń ṣe féfé asán nípa èrò ti ọkàn ara rẹ̀. 19 (E)Wọn ti sọ ìdàpọ̀ wọn pẹ̀lú ẹni tí i ṣe orí nu, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí a ń ti ipa oríkèé àti iṣan pèsè fún gbogbo ara, ti a sì ń so ó ṣọ̀kan pọ̀, tí ó sì ń dàgbà nípa ìmísí Ọlọ́run.

20 (F)Bí ẹ̀yin bá ti kú pẹ̀lú Kristi si àwọn agbára ìlànà ayé yìí, kín ló dé tí ẹ̀yin ń tẹríba fún òfin bí ẹni pé ẹ̀yin wà nínú ayé, 21 Má ṣe dìímú, má ṣe tọ́ ọ wò, má ṣe fi ọwọ́ bà á, 22 (G)Gbogbo èyí tí yóò ti ipa lílo run, gẹ́gẹ́ bí òfin àti ẹ̀kọ́ ènìyàn? 23 Àwọn nǹkan tí ó ní àfarawé ọgbọ́n nítòótọ́, nípasẹ̀ àdábọwọ́ ìsìn, àti ìrẹ̀lẹ̀, àti ìpọ́nra-ẹni-lójú, ṣùgbọ́n tí kò ni èrè láti di ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara ku.

Matiu 4:12-17

Jesu bẹ̀rẹ̀ sí wàásù

12 (A)Nígbà tí Jesu gbọ́ wí pé a ti fi Johanu sínú túbú ó padà sí Galili. 13 (B)Ó kúrò ní Nasareti, ó sì lọ í gbé Kapernaumu, èyí tí ó wà létí Òkun Sebuluni àti Naftali. 14 Kí èyí tí a ti sọtẹ́lẹ̀ láti ẹnu wòlíì Isaiah lè ṣẹ pé:

15 (C)“ìwọ Sebuluni àti ilẹ̀ Naftali
    ọ̀nà tó lọ sí Òkun, ní ọ̀nà Jordani,
    Galili ti àwọn kèfèrí.
16 Àwọn ènìyàn tí ń gbé ni òkùnkùn
    tí ri ìmọ́lẹ̀ ńlá,
àti àwọn tó ń gbé nínú ilẹ̀ òjijì ikú
    ni ìmọ́lẹ̀ tan fún.”

17 (D)Láti ìgbà náà lọ ni Jesu ti bẹ̀rẹ̀ sí wàásù: “Ẹ ronúpìwàdà, nítorí tí ìjọba ọ̀run kù sí dẹ̀dẹ̀.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.