Add parallel Print Page Options

“Ọmọ ènìyàn, kọ ojú rẹ sí ìhà Jerusalẹmu, kí o sì wàásù lòdì sí ibi mímọ́. Sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí ilẹ̀ Israẹli. Kí ó sì sọ fún un pe: ‘Èyí yìí ni Olúwa wí: Èmi lòdì sí ọ. Èmi yóò fa idà mi yọ kúrò nínú àkọ̀ rẹ̀, Èmi yóò sì ké olódodo àti ènìyàn búburú kúrò ni àárín yín. Nítorí pé, èmi yóò ké olódodo àti olùṣe búburú kúrò, idà mi yóò jáde láti inú àkọ̀ rẹ̀ lòdì sí gbogbo ènìyàn láti gúúsù títí dé àríwá. Nígbà náà gbogbo ènìyàn yóò mọ̀ pé èmi Olúwa ti yọ idà mi kúrò nínú àkọ̀ rẹ̀; kì yóò sì padà sínú rẹ̀ mọ́.’

“Nítorí náà, mí ìmí ẹ̀dùn ìwọ ọmọ ènìyàn! Mí ìmí ẹ̀dùn pẹ̀lú ọkàn ìbànújẹ́ àti ẹ̀dùn ọkàn kíkorò ní iwájú wọn.

Read full chapter

Ìdásílẹ̀ àwọn ẹrú

12 (A)Bí Heberu ara yín kan, yálà ọkùnrin tàbí obìnrin bá ta ara rẹ̀ fún ọ, tí ó sì sìn ọ́ fún ọdún mẹ́fà. Ní ọdún keje, jẹ́ kí ó di òmìnira. 13 Nígbà tí ó bá dá a sílẹ̀ má ṣe jẹ́ kí ó lọ lọ́wọ́ òfo. 14 Fi tọkàntọkàn fún un láti inú agbo ewúrẹ́ rẹ, ilẹ̀ ìpakà rẹ, àti ibi ìfúntí rẹ. Fún un gẹ́gẹ́ bí Olúwa Ọlọ́run rẹ ti bùkún fún ọ tó. 15 Ẹ rántí pé ẹ ti fi ìgbà kan jẹ́ ẹrú ní Ejibiti, Olúwa Ọlọ́run yín sì rà yín padà, ìdí nìyí tí mo fi pa àṣẹ yìí fún un yín lónìí.

16 Ṣùgbọ́n bí ìránṣẹ́ rẹ bá sọ fún ọ pé, “Èmi kò fẹ́ fi ọ́ sílẹ̀” nítorí pé ó fẹ́ràn ìwọ àti ìdílé rẹ, tí ó sì tẹ́ ọ lọ́rùn, 17 kí ìwọ kí ó mú ìlu kan lu etí rẹ̀ mọ́ ara ìlẹ̀kùn, yóò sì di ẹrú rẹ láéláé. Bẹ́ẹ̀ náà ni kí o ṣe sí ìránṣẹ́ ẹrúbìnrin rẹ.

18 Má ṣe kà á sí ohun ìnira láti dá ẹrú rẹ sílẹ̀, nítorí ìsìnrú rẹ̀ fún ọ, ní ọdún mẹ́fà náà tó ìlọ́po méjì iṣẹ́ alágbàṣe, Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò bùkún fún ọ nínú gbogbo ìdáwọ́lé rẹ.

Read full chapter