Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 75-76

Fún adarí orin. Tí ohùn “Má ṣe parun.” Saamu ti Asafu. Orin.

75 A fi ìyìn fún ọ, Ọlọ́run,
    a yìn ọ́, nítorí orúkọ rẹ súnmọ́ tòsí;
    àwọn ènìyàn ń sọ ti ìyanu rẹ.

Ìwọ wí pé, “Mo yan àkókò ìyàsọ́tọ̀;
    Èmi ni ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ òdodo.
Nígbà tí ayé àti àwọn ènìyàn ibẹ̀ wárìrì,
    Èmi ni mo di òpó rẹ̀ mú ṣinṣin.
Èmí wí fún àwọn agbéraga pé
    Ẹ má ṣe gbéraga mọ́;
àti sí ènìyàn búburú;
    Ẹ má ṣe gbé ìwo yín sókè.
Ẹ má ṣe gbe ìwo yín sókè sí ọ̀run;
    ẹ má ṣe sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọrùn líle.”

Nítorí ìgbéga kò ti ìlà-oòrùn wá
    tàbí ní ìwọ̀-oòrùn,
    bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe láti gúúsù wá.
Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ni olùdájọ́;
    Ó ń rẹ ẹnìkan sílẹ̀, ó sì ń gbé ẹlòmíràn ga.
Ní ọwọ́ Olúwa ni ago kan wà,
    ọtí wáìnì náà sì pọ́n, ó kún fún àdàlú,
ó fún ọtí àdàlú tí a pò mọ́ òórùn dídùn tí ó tú jáde,
    àwọn ènìyàn búburú ayé gbogbo mú u pátápátá.

Ṣùgbọ́n èmi, ó máa ròyìn rẹ títí láé;
    Èmi ó kọrin ìyìn sí Ọlọ́run Jakọbu.
10 Èmi ó gé ìwo gbogbo ènìyàn búburú,
    Ṣùgbọ́n ìwo àwọn olódodo ni a ó gbéga.

Fún adarí orin. Pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn. Saamu ti Asafu. Orin.

76 Ní Juda ni a mọ Ọlọ́run;
    orúkọ rẹ̀ sì lágbára ní Israẹli
Àgọ́ rẹ̀ wà ní Salẹmu,
    ibùgbé rẹ̀ ni Sioni.
Níbẹ̀ ni ó ṣẹ́ ọfà,
    asà àti àwọn idà, ohun ìjà ogun. Sela.

Ìwọ ni ògo àti ọlá
    Ju òkè ńlá ìkógun wọ̀nyí lọ.
A kó àwọn alágídí ọkàn ní ìkógun
    wọ́n sun oorun ìgbẹ̀yìn wọn;
kò sí ọ̀kan nínú àwọn akọni
    tó lè gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè.
Ní ìfibú rẹ, Ọlọ́run Jakọbu,
    àwọn ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ ogun sì dùbúlẹ̀ síbẹ̀.

Ìwọ nìkan ni ó yẹ kí a bẹ̀rù.
    Ta ló lé dúró níwájú rẹ, nígbà tí ìwọ bá ń bínú?
Ìwọ ń ṣe ìdájọ́ láti ọ̀run,
    ilé ayé bẹ̀rù, ó sì dúró jẹ́ẹ́:
Nígbà tí, ìwọ Ọlọ́run,
    bá dìde láti ṣe ìdájọ́,
láti gba àwọn ẹni ìnilára ilẹ̀ náà. Sela.
10 Lóòótọ́, ìbínú rẹ sí àwọn ènìyàn ń mú ìyìn wá fún ọ,
    ẹni tí ó yọ nínú ìbínú rẹ ní a dá nígbà tí ìwọ bá fi ìbínú ìyókù di ara rẹ ni àmùrè.

11 Jẹ́ ẹ̀jẹ́ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ kí o sì mú un ṣẹ;
    kí gbogbo àwọn tí ó yí i ká
    mú ẹ̀bùn wá fún ẹni tí ó tọ́ láti bẹ̀rù.
12 Ó ké ẹ̀mí àwọn aládé kúrò;
    àwọn ọba ayé sì ń bẹ̀rù rẹ̀.

Saamu 23

Saamu ti Dafidi.

23 Olúwa ni Olùṣọ́ èmi àgùntàn rẹ̀, èmi kì yóò ṣe aláìní.
    (A)Ó mú mi dùbúlẹ̀ sí ibi pápá oko tútù
Ó mú mi lọ sí ibi omi dídákẹ́ rọ́rọ́;
    Ó mú ọkàn mi padà bọ̀ sípò
Ó mú mi lọ sí ọ̀nà òdodo
    nítorí orúkọ rẹ̀.
Bí mo tilẹ̀ ń rìn
    Láàrín àfonífojì òjìji ikú,
èmi kì yóò bẹ̀rù ibi kan;
    nítorí ìwọ wà pẹ̀lú mi;
ọ̀gọ rẹ àti ọ̀pá à rẹ
    wọ́n ń tù mí nínú.

Ìwọ tẹ́ tábìlì oúnjẹ sílẹ̀ níwájú mi
    ní ojú àwọn ọ̀tá à mi;
ìwọ ta òróró sí mi ní orí;
    ago mí sì kún àkúnwọ́sílẹ̀.
Nítòótọ́, ìre àti àánú ni yóò máa tọ̀ mí lẹ́yìn
    ní ọjọ́ ayé è mi gbogbo,
èmi yóò sì máa gbé inú ilé Olúwa
    títí láéláé.

Saamu 27

Ti Dafidi.

27 Olúwa ni ìmọ́lẹ̀ mi àti ìgbàlà mi;
    ta ni èmi yóò bẹ̀rù?
Olúwa ni ibi ìsádi ẹ̀mí mi,
    ẹ̀rù ta ni yóò bà mí?

Nígbà tí àwọn ènìyàn búburú kọjú ìjà sí mi
    láti jẹ ẹran-ara mi,
àní àwọn ọ̀tá mi àti àwọn abínúkú mi,
    wọn yóò kọsẹ̀, wọn yóò sì ṣubú.
Bí ọmọ-ogun tilẹ̀ yí mi ká tí wọ́n sì dìde sí mi,
    ọkàn mi kì yóò bẹ̀rù;
bí ogun tilẹ̀ dìde sí mi,
    nínú èyí ni ọkàn mi yóò le.

Ohun kan ni mo béèrè lọ́dọ̀ Olúwa,
    òhun ni èmi yóò máa wá kiri:
kí èmi kí ó le wà ní ilé Olúwa
    ní ọjọ́ ayé mi gbogbo,
kí èmi: kí ó le kíyèsi ẹwà Olúwa,
    kí èmi kí ó sì máa wà ní tẹmpili rẹ̀.
Nítorí pé ní ìgbà ìpọ́njú
    òun yóò pa mí mọ́ nínú àgọ́ rẹ̀;
níbi ìkọ̀kọ̀ àgọ́ rẹ̀ ni òun yóò pa mí mọ́;
    yóò sì gbé mi sókè lórí àpáta.

Ní ìsinsin yìí, a ti gbé orí mi sókè
    ga ju ti àwọn ọ̀tá mi lọ tí ó yí mí ká;
èmi yóò rú ẹbọ nínú àgọ́ rẹ, ẹbọ ariwo àti ti ayọ̀;
    èmi yóò kọrin àní orin dídùn sí Olúwa.

Gbọ́ ohùn mi nígbà tí ẹ̀mí bá à ń pè, Háà! Olúwa,
    ṣe àánú fún mi kí o sì dá mi lóhùn;
“Wá,” ọkàn mi wí pé, “wá ojú u rẹ̀.”
    Ojú rẹ, Olúwa, ni èmí ń wá.
Má ṣe fi ojú rẹ pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ mi,
    má ṣe fi ìbínú sá ìránṣẹ́ rẹ tì;
    ìwọ tí o ti jẹ́ olùrànlọ́wọ́ mi,
Má ṣe fi mí sílẹ̀, má sì ṣe kọ̀ mí,
    háà! Ọlọ́run ìgbàlà mi.
10 Bí ìyá àti baba bá kọ̀ mí sílẹ̀,
    Olúwa yóò tẹ́wọ́ gbà mí.
11 Kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ, Olúwa,
    kí o sì sìn mi lọ sí ọ̀nà tí ó tẹ́jú
    nítorí àwọn ọ̀tá mi.
12 Má ṣe fi mí lé ìfẹ́ àwọn ọ̀tá mi lọ́wọ́,
    nítorí àwọn ẹlẹ́rìí èké ti dìde sí mi,
    wọ́n sì mí ìmí ìkà.

13 Èmi ní ìgbàgbọ́ pé,
    èmi yóò rí ìre Olúwa
    ní ilẹ̀ alààyè.
14 Dúró de Olúwa;
    kí ó jẹ alágbára, kí o sì mú ọkàn le
    àní dúró de Olúwa.

Gẹnẹsisi 24:28-38

28 Ọmọbìnrin náà sì sáré, ó sì lọ sọ ohun gbogbo wọ̀nyí fún àwọn ará ilé ìyá rẹ̀. 29 Rebeka ní arákùnrin tí ń jẹ́ Labani; Labani sì sáré lọ bá ọkùnrin náà ní etí odò. 30 Bí ó sì ti rí òrùka imú àti ẹ̀gbà ní ọwọ́ arábìnrin rẹ̀ tí ó sì tún gbọ́ ohun tí Rebeka sọ pé ọkùnrin náà sọ fún òun, ó jáde lọ bá ọkùnrin náà, ó sì bá a, ó dúró ti ìbákasẹ wọ̀n-ọn-nì ní ẹ̀bá ìsun omi. 31 Ó wí fún ọkùnrin náà pé, “Wá, ìwọ ẹni ìbùkún Olúwa, Èéṣe tí o dúró sí ìta níhìn-ín? Mo ti pèsè ààyè sílẹ̀ fún ọ àti ààyè fún àwọn ìbákasẹ rẹ.”

32 Ọkùnrin náà sì bá Labani lọ ilé, ó sì tú ẹrù orí ìbákasẹ rẹ̀ sílẹ̀, ó sì fún wọn ni koríko àti oúnjẹ. Ó sì bu omi fún ọkùnrin náà àti àwọn arákùnrin rẹ̀ láti wẹ ẹsẹ̀ wọn. 33 Wọ́n sì gbé oúnjẹ síwájú rẹ̀, ṣùgbọ́n, ó wí pé, “Èmi kò ní jẹun àyàfi bí mo bá sọ ohun tí mo ní í sọ.”

Labani sì wí pé, “Kò burú, sọ ọ́.”

34 Nítorí náà, ó wí pé, “ìránṣẹ́ Abrahamu ni èmi. 35 Olúwa sì ti bùkún olúwa mi gidigidi. Ó sì ti di ọlọ́rọ̀, Ó sì ti fún un ní àgùntàn, màlúù, àti fàdákà àti wúrà, ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin àti ìbákasẹ àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. 36 Sara aya olúwa mi sì ti bí ọmọkùnrin kan fún un, ní ìgbà ogbó rẹ̀, olúwa mi sì ti fún ọmọ náà ní ohun gbogbo tí ó ní. 37 Olúwa mi sì ti mú mi búra wí pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ fẹ́ aya fún ọmọ mi, láàrín àwọn ọmọbìnrin Kenaani, ní ilẹ̀ ibi tí èmi ń gbé, 38 Ṣùgbọ́n lọ sí ìdílé baba mi láàrín àwọn ìbátan mi kí o sì fẹ́ aya fún ọmọ mi.’

Gẹnẹsisi 24:49-51

49 Ǹjẹ́ nísinsin yìí bí ẹ̀yin yóò bá fi inú rere àti òtítọ́ bá olúwa mi lò, ẹ sọ fún mi, bí bẹ́ẹ̀ sì kọ́, ẹ sọ fún mi, kí ń le è mọ ọ̀nà tí èmi yóò yà sí.”

50 Labani àti Betueli sì dáhùn pé, “Lọ́dọ̀ Olúwa ni èyí ti wá, nítorí náà àwa kò le sọ rere tàbí búburú fún ọ. 51 Rebeka nìyí, mú un kí ó máa lọ, kí ó sì di aya ọmọ olúwa à rẹ, bí Olúwa ti fẹ́.”

Heberu 12:12-29

12 (A)Nítorí náà, ẹ na ọwọ́ tí ó rọ, àti eékún àìlera; 13 (B)“Kí ẹ sì ṣe ipa ọ̀nà tí ó tọ́ fún ẹsẹ̀ yin,” kí èyí tí ó rọ má bá a kúrò lórí ike ṣùgbọ́n kí a kúkú wò ó sàn.

Ìkìlọ̀ lòdì sí kíkọ Ọlọ́run

14 Ẹ máa lépa àlàáfíà pẹ̀lú ènìyàn gbogbo, àti ìwà mímọ́, láìsí èyí yìí kò sí ẹni tí yóò rí Olúwa: 15 (C)Ẹ máa kíyèsára kí ẹnikẹ́ni má ṣe kùnà oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run; kí “gbòǹgbò ìkorò” kan máa ba hù sókè kí ó sì yọ yín lẹ́nu, ọ̀pọ̀lọpọ̀ a sì ti ipa rẹ̀ di àìmọ́. 16 (D)Kí o má bá à si àgbèrè kan tàbí aláìwà-bí-Ọlọ́run bi Esau, ẹni tí o tìtorí òkèlè oúnjẹ kan ta ogún ìbí rẹ̀. 17 (E)Nítorí ẹ̀yin mọ pé lẹ́yìn náà, nígbà tí ó fẹ́ láti jogún ìbùkún náà, a kọ̀ ọ́, nítorí kò ri ààyè ìrònúpìwàdà, bí o tilẹ̀ jẹ́ pé ó fi omijé wa a gidigidi.

18 (F)Nítorí ẹ̀yin kò wá òkè tí a lè fi ọwọ́ kàn, àti ti iná ti ń jó, àti ti ìṣúdudu àti òkùnkùn, àti ìjì. 19 Àti ìró ìpè, àti ohùn ọ̀rọ̀, èyí tí àwọn tí o gbọ́ bẹ̀bẹ̀ pé, kí a má ṣe sọ ọ̀rọ̀ sí i fún wọn mọ́: 20 (G)Nítorí pé wọn kò lè gba ohun tí ó paláṣẹ, “Bí o tilẹ̀ jẹ ẹranko ni ó fi ara kan òkè náà, a ó sọ ọ́ ni òkúta.” 21 (H)Ìran náà sì lẹ́rù to bẹ́ẹ̀ tí Mose wí pé, “Ẹ̀rù ba mi gidigidi mo sì wárìrì.”

22 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin wá sí òkè Sioni, àti sí ìlú Ọlọ́run alààyè, ti Jerusalẹmu ti ọ̀run, àti si ẹgbẹ́ àwọn angẹli àìníye, 23 Si àjọ ńlá tí ìjọ àkọ́bí tí a ti kọ orúkọ wọn ni ọ̀run, àti sọ́dọ̀ Ọlọ́run onídàájọ́ gbogbo ènìyàn, àti sọ́dọ̀ àwọn ẹ̀mí olóòtítọ́ ènìyàn tí a ṣe ni àṣepé, o 24 (I)Àti sọ́dọ̀ Jesu alárinà májẹ̀mú tuntun, àti si ibi ẹ̀jẹ̀ ìbùwọ́n ni, ti ń sọ̀rọ̀ ohun tí ó dára ju ti Abeli lọ.

25 (J)Kíyèsi i, kí ẹ má ṣe kọ̀ ẹni tí ń kìlọ̀. Nítorí bí àwọn wọ̀nyí kò bá bọ́ nígbà tí wọn kọ̀ ẹni ti ń kìlọ̀ ni ayé, mélòó mélòó ni àwa kì yóò bọ́, bí àwa ba pẹ̀hìndà sí ẹni tí ń kìlọ̀ láti ọ̀run wá: 26 (K)Ohùn ẹni tí ó mi ayé nígbà náà: ṣùgbọ́n nísinsin yìí o ti ṣe ìlérí, wí pé, “Lẹ́ẹ̀kan sí i èmi ki yóò mi kìkì ayé nìkan, ṣùgbọ́n ọ̀run pẹ̀lú.” 27 Àti ọ̀rọ̀ yìí, “Lẹ́ẹ̀kan sí i,” ìtumọ̀ rẹ̀ ni, mímú àwọn ohun wọ̀nyí ti a ń mì kúrò, bí ohun tí a ti dá, kí àwọn ohun tí a kò lè mì lè wà síbẹ̀.

28 Nítorí náà bí àwa tí ń gbà ilẹ̀ ọba ti a kò lè mì, ẹ jẹ́ kí a dá ọpẹ́ nípa èyí ti a fi lè máa sin Ọlọ́run ni ìtẹ́wọ́gbà pẹ̀lú ọ̀wọ̀ àti ìbẹ̀rù rẹ̀. 29 (L)Nítorí pé, “Ọlọ́run wa, iná ti ń jó ni run ni.”

Johanu 7:14-36

Jesu kọ́ àwọn ènìyàn

14 Nígbà tí àjọ dé àárín; Jesu gòkè lọ sí tẹmpili ó sì ń kọ́ni. 15 Ẹnu sì ya àwọn Júù, wọ́n wí pé, “Ọkùnrin yìí ti ṣe mọ ìwé, nígbà tí kò kọ́ ẹ̀kọ́?”

16 Jesu dáhùn, ó sì wí pé, “Ẹ̀kọ́ mi kì í ṣe tèmi, bí kò ṣe ti ẹni tí ó rán mi. 17 Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀ yóò mọ̀ ní ti ẹ̀kọ́ náà, bí ìbá ṣe ti Ọlọ́run, tàbí bí èmi bá sọ ti ara mi. 18 Ẹni tí ń sọ ti ara rẹ̀ ń wá ògo ara rẹ̀: ṣùgbọ́n ẹni tí ń wá ògo ẹni tí ó rán an, òun ni olóòtítọ́, kò sì sí àìṣòdodo nínú rẹ̀. 19 (A)Mose kò ha fi òfin fún yín, kò sí ẹnikẹ́ni nínú yín tí ó pa òfin náà mọ́? Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń wá ọ̀nà láti pa mí?”

20 (B)Ìjọ ènìyàn dáhùn, wọ́n sì wí pé, “Ìwọ ní ẹ̀mí èṣù: Ta ni ń wá ọ̀nà láti pa ọ́?”

21 (C)Jesu dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Kìkì iṣẹ́ ààmì kan ni mo ṣe, ẹnu sì ya gbogbo yín. 22 (D)Síbẹ̀, nítorí pé Mose fi ìkọlà fún yín (kò tilẹ̀ kúkú wá láti ọ̀dọ̀ Mose bí kò ṣe láti ọ̀dọ̀ àwọn baba ńlá yín); nítorí náà ẹ sì ń kọ ènìyàn ní ilà ní ọjọ́ ìsinmi. 23 (E)Bí ènìyàn bá ń gba ìkọlà ní ọjọ́ ìsinmi, kí a má ba à rú òfin Mose, ẹ ha ti ṣe ń bínú sí mi, nítorí mo mú ènìyàn kan láradá ní ọjọ́ ìsinmi? 24 (F)Ẹ má ṣe ìdájọ́ nípa ti ara, ṣùgbọ́n ẹ máa ṣe ìdájọ́ òdodo.”

Ṣé Jesu ni Kristi?

25 Nígbà náà ni àwọn kan nínú àwọn ará Jerusalẹmu wí pé, “ẹni tí wọ́n ń wá ọ̀nà láti pa kọ́ yìí? 26 Sì wò ó, ó ń sọ̀rọ̀ ní gbangba, wọn kò sì wí nǹkan kan sí i. Àwọn olórí ha mọ̀ nítòótọ́ pé, èyí ni Kristi náà? 27 (G)Ṣùgbọ́n àwa mọ ibi tí ọkùnrin yí gbé ti wá: ṣùgbọ́n nígbà tí Kristi bá dé, kò sí ẹni tí yóò mọ ibi tí ó gbé ti wá.”

28 (H)Nígbà náà ni Jesu kígbe ní tẹmpili bí ó ti ń kọ́ni, wí pé, “Ẹ̀yin mọ̀ mí, ẹ sì mọ ibi tí mo ti wá: èmi kò sì wá fún ara mi, ṣùgbọ́n olóòtítọ́ ni ẹni tí ó rán mi, ẹni tí ẹ̀yin kò mọ̀. 29 (I)Ṣùgbọ́n èmi mọ̀ ọ́n: nítorí pé lọ́dọ̀ rẹ̀ ni mo ti wá, òun ni ó rán mi.”

30 (J)Nítorí náà wọ́n ń wá ọ̀nà à ti mú un: ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan tí ó gbé ọwọ́ lé e, nítorí tí wákàtí rẹ̀ kò tí ì dé. 31 (K)Ọ̀pọ̀ nínú ìjọ ènìyàn sì gbà á gbọ́, wọ́n sì wí pé, “Nígbà tí Kristi náà bá dé, yóò ha ṣe iṣẹ́ ààmì jù wọ̀nyí, tí ọkùnrin yìí ti ṣe lọ?”

32 Àwọn Farisi gbọ́ pé, ìjọ ènìyàn ń sọ nǹkan wọ̀nyí lábẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀; àwọn Farisi àti àwọn olórí àlùfáà sì rán àwọn oníṣẹ́ lọ láti mú un.

33 (L)Nítorí náà Jesu wí fún wọn pé, “Níwọ́n ìgbà díẹ̀ ni èmi yóò wà pẹ̀lú yín, èmi yóò lọ sí ọ̀dọ̀ ẹni tí ó rán mi. 34 Ẹ̀yin yóò wá mi, ẹ̀yin kì yóò sì rí mi: àti ibi tí èmi bá wà, ẹ̀yin kì yóò le wà.”

35 (M)Nítorí náà ni àwọn Júù ń bá ara wọn sọ pé, “Níbo ni ọkùnrin yìí yóò gbé lọ tí àwa kì yóò fi rí i? Yóò ha lọ sí àárín àwọn Helleni tí wọ́n fọ́n káàkiri, kí ó sì máa kọ́ àwọn Helleni bí. 36 Ọ̀rọ̀ kín ni èyí tí ó sọ yìí, ẹ̀yin yóò wá mi, ẹ kì yóò sì rí mi, àti ibi tí èmi bá wà ẹ̀yin kì yóò le wà?”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.