Book of Common Prayer
Orin fún ìgòkè. Ti Dafidi.
131 Olúwa àyà mi kò gbéga,
bẹ́ẹ̀ ni ojú mi kò gbé sókè:
bẹ́ẹ̀ ni èmi kò fi ọwọ́ mi lé ọ̀ràn ńlá,
tàbí lé ohun tí ó ga jù mí lọ
2 Nítòótọ́ èmi mú ọkàn mi sinmi,
mo sì mú un dákẹ́ jẹ́ẹ́,
bí ọmọ tí a ti ọwọ́ ìyá rẹ̀ gbà ní ẹnu ọmú:
ọkàn mi rí gẹ́gẹ́ bí ọmọ tí a já ní ẹnu ọmú.
3 Israẹli, ìwọ ní ìrètí ní ti Olúwa
láti ìsinsin yìí lọ àti láéláé.
Orin fún ìgòkè.
132 Olúwa, rántí Dafidi
nínú gbogbo ìpọ́njú rẹ̀.
2 Ẹni tí ó ti búra fún Olúwa,
tí ó sì ṣe ìlérí fún Alágbára Jakọbu pé.
3 Nítòótọ́, èmi kì yóò wọ inú àgọ́ ilé mi lọ,
bẹ́ẹ̀ èmi kì yóò gun orí àkéte mi:
4 Èmi kì yóò fi oorun fún ojú mi,
tàbí òògbé fún ìpéǹpéjú mi,
5 Títí èmi ó fi rí ibi fún Olúwa,
ibùjókòó fún Alágbára Jakọbu.
6 Kíyèsi i, àwa gbúròó rẹ̀ ni Efrata:
àwa rí i nínú oko ẹgàn náà.
7 Àwa ó lọ sínú àgọ́ rẹ̀:
àwa ó máa sìn níbi àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀
8 Olúwa, dìde sí ibi ìsinmi rẹ:
ìwọ, àti àpótí agbára rẹ.
9 Kí a fi òdodo wọ àwọn àlùfáà rẹ:
kí àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ kí ó máa hó fún ayọ̀.
10 Nítorí tí Dafidi ìránṣẹ́ rẹ̀
Má ṣe yí ojú ẹni òróró rẹ padà.
11 (A)Olúwa ti búra nítòótọ́ fún Dafidi:
Òun kì yóò yípadà kúrò nínú rẹ̀,
nínú irú-ọmọ inú rẹ ni èmi ó gbé kalẹ̀ sí orí ìtẹ́ rẹ.
12 Bí àwọn ọmọ rẹ̀ yóò bá pa májẹ̀mú mi mọ́
àti ẹ̀rí mi tí èmi yóò kọ́ wọn,
àwọn ọmọ wọn pẹ̀lú yóò jókòó lórí ìtẹ́ rẹ láéláé.
13 Nítorí tí Olúwa ti yan Sioni:
ó ti fẹ́ ẹ fún ibùjókòó rẹ̀.
14 Èyí ni ibi ìsinmi mi láéláé:
níhìn-ín ni èmi yóò máa gbé:
nítorí tí mo fẹ́ ẹ.
15 Èmi yóò bùkún oúnjẹ rẹ̀ púpọ̀púpọ̀:
èmi yóò fi oúnjẹ tẹ́ àwọn tálákà rẹ̀ lọ́rùn.
16 Èmi yóò sì fi ìgbàlà wọ àwọn àlùfáà rẹ̀:
àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ yóò máa hó fún ayọ̀.
17 Níbẹ̀ ni èmi yóò gbé mú ìwo Dafidi yọ̀,
èmi ti ṣe ìlànà fìtílà kan fún ẹni òróró mi.
18 Àwọn ọ̀tá rẹ̀ ni èmi yóò fi ìtìjú wọ̀:
ṣùgbọ́n lára òun tìkára rẹ̀ ni adé yóò máa gbilẹ̀.
Orin fún ìgòkè. Ti Dafidi
133 Kíyèsi, ó ti dára ó sì ti dùn tó fún
àwọn ará láti máa jùmọ̀ gbé ní ìrẹ́pọ̀.
2 Ó dàbí òróró ìkunra iyebíye ní orí,
tí ó sàn dé irùngbọ̀n, àní irùngbọ̀n Aaroni:
tí ó sì sàn sí etí aṣọ sórí rẹ̀;
3 Bí ìrì Hermoni
tí o sàn sórí òkè Sioni.
Nítorí níbẹ̀ ní Olúwa gbé pàṣẹ ìbùkún,
àní ìyè láéláé.
Orin ìgòkè.
134 Ẹ kíyèsi i, ẹ fi ìbùkún fún Olúwa,
gbogbo ẹ̀yin ìránṣẹ́ Olúwa,
tí ó dúró ní ilé Olúwa ní òru.
2 Ẹ gbé ọwọ́ yín sókè sí ibi mímọ́,
kí ẹ sì fi ìbùkún fún Olúwa.
3 Olúwa tí ó dá ọ̀run òun ayé,
kí ó bùsi i fún ọ láti Sioni wá.
135 Ẹ yin Olúwa.
Ẹ yin orúkọ Olúwa;
ẹ yìn ín, ẹ̀yin ìránṣẹ́ Olúwa.
2 Ẹ̀yin tí ń dúró ní ilé Olúwa,
nínú àgbàlá ilé Ọlọ́run wa.
3 Ẹ yin Olúwa: nítorí tí Olúwa ṣeun;
ẹ kọrin ìyìn sí orúkọ rẹ̀; nítorí tí ó dùn.
4 Nítorí tí Olúwa ti yan Jakọbu fún ara rẹ̀;
àní Israẹli fún ìṣúra ààyò rẹ̀.
5 Nítorí tí èmi mọ̀ pé Olúwa tóbi,
àti pé Olúwa jù gbogbo òrìṣà lọ.
6 Olúwa ṣe ohunkóhun tí ó wù ú,
ní ọ̀run àti ní ayé,
ní Òkun àti ní ọ̀gbun gbogbo.
7 Ó mú ìkùùkuu gòkè láti òpin ilẹ̀ wá:
ó dá mọ̀nàmọ́ná fún òjò:
ó ń mú afẹ́fẹ́ ti inú ilẹ̀ ìṣúra rẹ̀ wá.
8 Ẹni tí ó kọlu àwọn àkọ́bí Ejibiti,
àti ti ènìyàn àti ti ẹranko.
9 Ẹni tí ó rán iṣẹ́ ààmì àti iṣẹ́ ìyanu sí àárín rẹ̀, ìwọ Ejibiti,
sí ara Farao àti sí ara àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ gbogbo.
10 Ẹni tí ó kọlu àwọn orílẹ̀-èdè púpọ̀,
tí ó sì pa àwọn alágbára ọba.
11 Sihoni, ọba àwọn ará Amori, àti Ogu,
ọba Baṣani, àti gbogbo ìjọba Kenaani:
12 Ó sì fi ilẹ̀ wọn fún ni ní ìní,
ìní fún Israẹli, ènìyàn rẹ̀.
13 Olúwa orúkọ rẹ dúró láéláé;
ìrántí rẹ Olúwa, láti ìrandíran.
14 (B)Nítorí tí Olúwa yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀,
yóò sì ṣe ìyọ́nú sí àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀.
15 Fàdákà òun wúrà ni èrè àwọn aláìkọlà,
iṣẹ́ ọwọ́ ènìyàn ni.
16 Wọ́n ní ẹnu, ṣùgbọ́n wọn kò le sọ̀rọ̀;
wọ́n ní ojú, ṣùgbọ́n wọn kò fi ríran.
17 Wọ́n ní etí, ṣùgbọ́n wọn kò fi gbọ́rọ̀;
bẹ́ẹ̀ ni kò si èémí kan ní ẹnu wọn
18 Àwọn tí ń ṣe wọ́n dàbí wọn:
gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni olúkúlùkù ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé wọn.
19 Ẹ̀yin ara ilé Israẹli, ẹ fi ìbùkún fún Olúwa,
ẹ̀yin ará ilé Aaroni, fi ìbùkún fún Olúwa.
20 Ẹ̀yin ará ilé Lefi, fi ìbùkún fún Olúwa;
ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù Olúwa, fi ìbùkún fún Olúwa.
21 Olùbùkún ni Olúwa, láti Sioni wá,
tí ń gbé Jerusalẹmu.
Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
Ìkìlọ̀ nítorí àwọn aṣẹ́wó
7 Ọmọ mi, pa ọ̀rọ̀ mi mọ́,
sì fi àwọn òfin mi pamọ́ sínú ọkàn rẹ.
2 Pa òfin mi mọ́, ìwọ yóò sì yè
tọ́jú ẹ̀kọ́ mi bí ẹyinlójú rẹ
3 Kọ wọ́n sí ọwọ́ òsì rẹ, má ṣe fi jẹun
kọ wọ́n sí inú wàláà àyà rẹ.
4 Wí fún ọgbọ́n pé, “Ìwọ ni arábìnrin mi,”
sì pe òye ní ìbátan rẹ;
5 Wọn yóò pa ó mọ́ kúrò lọ́wọ́ obìnrin alágbèrè,
kúrò lọ́wọ́ àjèjì obìnrin àti ọ̀rọ̀ ìtànjẹ rẹ̀.
6 Ní ojú fèrèsé ilé è mi
mo wo ìta láti ojú fèrèsé.
7 Mo rí i láàrín àwọn aláìmọ̀kan
mo sì kíyèsi láàrín àwọn ọ̀dọ́kùnrin,
ọ̀dọ́ kan tí ó ṣe aláìgbọ́n.
8 Ó ń lọ ní pópónà ní tòsí i ilé alágbèrè obìnrin náà,
ó ń rìn lọ sí ọ̀nà ilé e rẹ̀
9 Ní ìrọ̀lẹ́ bí oòrùn ṣe ń wọ̀,
bí òkùnkùn ṣe ń bo ni lára.
10 Bẹ́ẹ̀ ni obìnrin kan jáde wá láti pàdé rẹ̀,
ó múra bí panṣágà pẹ̀lú ètè búburú.
11 (Ó jẹ́ aláriwo àti alágídí,
ìdí rẹ̀ kì í jókòó nílé;
12 bí ó ti ń já níhìn-ín ní ó ń já lọ́hùn ún
gbogbo orígun ni ó ti ń ba ní ibùba.)
13 Ó dìímú, ó sì fẹnukò ó ní ẹnu
pẹ̀lú ojú díndín ó wí pé:
14 “Mo ní ọrẹ àlàáfíà ní ilé;
lónìí ni mo san ẹ̀jẹ́ mi.
15 Nítorí náà ni n o ṣe jáde wá pàdé è rẹ;
mo wá ọ káàkiri mo sì ti rí ọ!
16 Mo ti tẹ́ ibùsùn mi
pẹ̀lú aṣọ aláràbarà láti ilẹ̀ Ejibiti.
17 Mo ti fi nǹkan olóòórùn dídùn sí ibùsùn mi
bí i òjìá, aloe àti kinamoni.
18 Wá, jẹ́ kí a lo ìfẹ́ papọ̀ ní kíkún títí di àárọ̀;
jẹ́ kí a gbádùn ara wa pẹ̀lú ìfẹ́!
19 Ọkọ ọ̀ mi ò sí nílé;
ó ti lọ sí ìrìnàjò jíjìn.
20 Ó mú owó púpọ̀ lọ́wọ́
kò sì ní darí dé kí ó tó di ọ̀sán.”
21 Pẹ̀lú ọ̀rọ̀ dídùn ó sì í lọ́nà;
ó tàn án jẹ pẹ̀lú ẹnu dídùn.
22 Òun sì tọ̀ ọ́ lọ lẹsẹ̀ kan náà,
bí i màlúù tí ń lọ sí ibùpa,
tàbí bí (aṣiwèrè) àgbọ̀nrín tí ń lọ sí ibi ọgbọ́n ìfabà kọ́.
23 Títí tí ọ̀kọ̀ fi gún un ní ẹ̀dọ̀,
bí ẹyẹ ṣe ń fẹ́ wọ inú okùn,
láìmọ̀ pé yóò gba ẹ̀mí òun.
24 Nítorí náà báyìí ẹ̀yin ọmọ mi, tẹ́tí sí mi
fọkàn sí nǹkan tí mo sọ.
25 Má ṣe jẹ́ kí ọkàn rẹ kí ó yà sí ọ̀nà rẹ̀,
tàbí kí ó rìn lọ sí ipa ọ̀nà rẹ̀.
26 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn tí ó ti fà lulẹ̀
Ogunlọ́gọ̀ àwọn alágbára ni ó ti pa.
27 Ilé e rẹ̀ ni ọ̀nà tààrà sí isà òkú,
tí ó lọ tààrà sí àgbàlá ikú.
Àwọn àfiyèsí ìparí
13 (A)Nǹkan wọ̀nyí ni mo kọ̀wé rẹ̀ sí yín, àní sí ẹ̀yin tí ó gba orúkọ Ọmọ Ọlọ́run gbọ́; kí ẹ̀yin lè mọ̀ pé ẹ̀yin ní ìyè àìnípẹ̀kun, àní fún ẹ̀yin tí ó gba orúkọ Ọmọ Ọlọ́run gbọ́. 14 (B)Èyí sì ni ìgboyà tí àwa ní níwájú rẹ̀, pé bí àwa bá béèrè ohunkóhun gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀, ó ń gbọ́ tí wa; 15 Bí àwa bá sì mọ̀ pé ó ń gbọ́ tí wa, ohunkóhun tí àwa bá béèrè, àwa mọ̀ pé àwa rí ìbéèrè tí àwa ti béèrè lọ́dọ̀ rẹ̀ gbà.
16 Bí ẹnikẹ́ni bá rí arákùnrin rẹ̀ tí ń dẹ́ṣẹ̀ tí kì í ṣe sí ikú, òun yóò béèrè, Ọlọ́run yóò sì fún un ni ìyè, àní, fún àwọn tí ń dẹ́ṣẹ̀ tí kì í ṣe sí ikú. Ẹ̀ṣẹ̀ kan ń bẹ sì ikú: èmi kò wí pé ki òun gbàdúrà fún èyí. 17 Gbogbo àìṣòdodo ni ẹ̀ṣẹ̀: ẹ̀ṣẹ̀ kan ń bẹ tí kì í ṣe sí ikú.
18 (C)Àwa mọ̀ pé ẹnikẹ́ni tí a bí nípa ti Ọlọ́run kì í dẹ́ṣẹ̀: ṣùgbọ́n ẹni tí a bí nípa tí Ọlọ́run a pa ara rẹ̀ mọ́, ẹni búburú kò ní lè fọwọ́ kàn án. 19 Àwa mọ̀ pé tí Ọlọ́run ni wá, àti gbogbo ayé ni ó wà lábẹ́ agbára ẹni búburú náà. 20 (D)Àwa sì mọ̀ pé Ọmọ Ọlọ́run dé, ó sì tí fi òye fún wa, kí àwa lè mọ ẹni tí í ṣe òtítọ́, àwa sì ń bẹ nínú ẹni tí í ṣe òtítọ́, àní, nínú Ọmọ rẹ̀, Jesu Kristi. Èyí ni Ọlọ́run òtítọ́, àti ìyè àìnípẹ̀kun.
21 Ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ pa ara yín mọ́ kúrò nínú òrìṣà.
55 (A)Àjọ ìrékọjá àwọn Júù sì súnmọ́ etílé: ọ̀pọ̀lọpọ̀ láti ìgbèríko sì gòkè lọ sí Jerusalẹmu ṣáájú ìrékọjá, láti ya ara wọn sí mímọ́. 56 (B)Nígbà náà ni wọ́n ń wá Jesu, wọ́n sì ń bá ara wọn sọ̀, bí wọ́n ti dúró ní tẹmpili, wí pé, “kín ni ẹyin ti rò ó sí pé kì yóò wá sí àjọ?” 57 Ǹjẹ́ àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisi ti pàṣẹ pé bí ẹnìkan bá mọ ibi tí ó gbé wà, kí ó fi í hàn, kí wọn ba à lè mú un.
A fi ààmì òróró yàn Jesu ni Betani
12 (C)Nítorí náà, nígbà tí àjọ ìrékọjá ku ọjọ́ mẹ́fà, Jesu wá sí Betani, níbi tí Lasaru wà, ẹni tí ó ti kú, tí Jesu jí dìde kúrò nínú òkú. 2 Wọ́n sì ṣe àsè alẹ́ fún un níbẹ̀: Marta sì ń ṣe ìránṣẹ́: ṣùgbọ́n Lasaru Jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn tí ó jókòó níbi tábìlì rẹ̀. 3 Nígbà náà ni Maria mú òróró ìkunra nadi, òṣùwọ̀n lítà kan, àìlábùlà, olówó iyebíye, ó sì ń fi kun Jesu ní ẹsẹ̀, ó sì ń fi irun orí rẹ̀ nu ẹsẹ̀ rẹ̀ nù. Ilé sì kún fún òórùn ìkunra náà.
4 (D)Nígbà náà ni ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, Judasi Iskariotu, ọmọ Simoni ẹni tí yóò fi í hàn, wí pé, 5 “Èéṣe tí a kò ta òróró ìkunra yìí ní ọ̀ọ́dúnrún owó idẹ kí a sì fi fún àwọn tálákà?” 6 (E)Ṣùgbọ́n ó wí èyí, kì í ṣe nítorí tí ó náání àwọn tálákà; ṣùgbọ́n nítorí tí ó jẹ́ olè, òun ni ó ni àpò, a sì máa jí ohun tí a fi sínú rẹ̀ láti fi ran ara rẹ lọ́wọ́.
7 (F)Nígbà náà ni Jesu wí pé, “Ẹ fi í sílẹ̀, ó ṣe é sílẹ̀ de ọjọ́ ìsìnkú mi. 8 Nígbà gbogbo ni ẹ̀yin sá à ní tálákà pẹ̀lú yín; ṣùgbọ́n èmi ni ẹ kò ní nígbà gbogbo.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.