Book of Common Prayer
Fún adarí orin. Orin. Saamu.
66 Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Ọlọ́run, ẹ̀yin ilẹ̀ gbogbo!
2 Ẹ kọrin ọlá orúkọ rẹ̀;
Ẹ kọrin ìyìnsí i,
3 Ẹ wí fún Ọlọ́run “pé,
ìwọ ti ní ẹ̀rù tó nínú iṣẹ́ rẹ!
Nípa ọ̀pọ̀ agbára rẹ ni àwọn ọ̀tá
rẹ yóò fi sìn ọ́.
4 Gbogbo ayé ń wólẹ̀ fún ọ;
wọn ń kọrin ìyìn sí ọ,
wọ́n ń kọrin ìyìn sí orúkọ rẹ.” Sela.
5 Ẹ wá wo ohun tí Ọlọ́run ṣe,
Iṣẹ́ rẹ̀ ti ní ẹ̀rù tó sí àwọn ọmọ ènìyàn!
6 Ó yí Òkun padà sí ilẹ̀ gbígbẹ,
wọ́n fi ẹsẹ̀ rin inú omi kọjá,
níbẹ̀ ni àwa yọ̀ nínú rẹ̀.
7 Ó ń jẹ ọba títí láé nípa agbára rẹ̀,
ojú rẹ̀ ń wo orílẹ̀-èdè
kí àwọn ọlọ̀tẹ̀ má ṣe gbé ara wọn ga. Sela.
8 Ẹ yin Ọlọ́run wa, ẹ̀yin ènìyàn,
jẹ́ kí a mú ni gbọ́ ohùn ìyìn rẹ̀;
9 Ó ti dá ààbò bo ẹ̀mí wa,
kò sì jẹ́ kí ẹsẹ̀ wa kí ó yẹ̀
10 Nítorí ìwọ, Ọlọ́run, dán wa wò;
ìwọ dán wa bí a tí ń dán fàdákà wò.
11 Ìwọ mú wa wá sínú ẹ̀wọ̀n
o sì di ẹrù lé ẹ̀yìn wa
12 Ìwọ mú àwọn ènìyàn gún wá ní orí
àwa la iná àti omi kọjá
ṣùgbọ́n ìwọ mú wa dé ibi ọ̀pọ̀.
13 Èmi ó wá sí tẹmpili rẹ pẹ̀lú ọrẹ ẹbọ sísun,
kí n sì mú ẹ̀jẹ́ mi ṣẹ sí ọ
14 Ẹ̀jẹ́ tí ètè mi jẹ́, tí ẹnu mi sì sọ
nígbà tí mo wà nínú ìṣòro.
15 Èmi ó rú ẹbọ sísun ọlọ́ràá sí ọ,
àti ẹbọ ọ̀rá àgbò;
èmi ó rú akọ màlúù àti ewúrẹ́. Sela.
16 Ẹ wá gbọ́ gbogbo ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run;
ẹ jẹ́ kí n sọ ohun tí ó ṣe fún mi.
17 Mo fi ẹnu mi kígbe sókè sí i:
Ìyìn rẹ̀ wà ní ẹnu mi.
18 Bí èmi bá gba ẹ̀ṣẹ̀ ní àyà mi,
Olúwa kì yóò gbọ́ ohùn mi;
19 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run gbọ́ nítòótọ́
ó ti gbọ́ ohùn mi nínú àdúrà.
20 Ìyìn ni fún Ọlọ́run
ẹni tí kò kọ àdúrà mi
tàbí mú ìfẹ́ rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ mi!
Fún adarí orin. Pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn. Saamu. Orin.
67 Kí Ọlọ́run kí ó ṣàánú fún wa kí ó sì bùkún fún wa,
kí ó sì jẹ́ kí ojú rẹ̀ tàn yí wa ká,
2 kí ọ̀nà rẹ le di mí mọ̀ ní ayé,
ìgbàlà rẹ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè.
3 Kí àwọn ènìyàn kí ó yìn ọ́, Ọlọ́run;
kí gbogbo ènìyàn kí ó yìn ọ́!
4 Kí orílẹ̀-èdè kí ó yọ̀, kí ó sì kọrin fún ayọ̀,
nítorí ìwọ fi òdodo darí àwọn ènìyàn,
ìwọ sì jẹ ọba àwọn orílẹ̀-èdè ní ayé.
5 Kí àwọn ènìyàn kí ó yìn ọ́, Ọlọ́run;
kí gbogbo ènìyàn kí ó yìn ọ́. Sela.
6 Nígbà náà ní ilẹ̀ yóò mú ìkórè rẹ̀ wá, Ọlọ́run,
Ọlọ́run wa, yóò bùkún fún wa.
7 Ọlọ́run yóò bùkún fún wa,
àti gbogbo òpin ilẹ̀ ayé yóò sì máa bẹ̀rù rẹ̀.
Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi.
19 Àwọn ọ̀run ń sọ nípa ti ògo Ọlọ́run;
Àwọsánmọ̀ ń sọ nípa ti iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.
2 Wọ́n ń fọhùn ní ọjọ́ dé ọjọ́;
wọ́n ń fi ìmọ̀ hàn ní alẹ́ dé alẹ́.
3 Kò sí ohùn tàbí èdè
níbi tí a kò gbé gbọ́ ìró wọn
4 (A)Ohùn wọn jáde lọ sí gbogbo orílẹ̀ ayé,
ọ̀rọ̀ wọn títí dé òpin ilẹ̀ ayé.
Ó ti kọ́ àgọ́ fún oòrùn nínú àwọn ọ̀run.
5 Tí ó dàbí ọkọ ìyàwó tí ó ń jáde ti yàrá rẹ̀ wá,
òun yọ bí alágbára ọkùnrin tí ó ń sáré ìje.
6 Ìjáde lọ rẹ̀ ni láti òpin ọ̀run wá
àti àyíká rẹ̀ sì dé ìpínlẹ̀ rẹ̀;
kò sì sí ohun tí ó pamọ́ kúrò nínú oore rẹ̀.
7 Pípé ni òfin Olúwa,
ó ń yí ọkàn padà.
Ẹ̀rí Olúwa dánilójú,
ó sọ òpè di ọlọ́gbọ́n.
8 Ìlànà Olúwa tọ̀nà,
ó ń fi ayọ̀ fún ọkàn.
Àṣẹ Olúwa ni mímọ́,
ó ń fi ìmọ́lẹ̀ fún ojú.
9 Ìbẹ̀rù Olúwa mọ́,
ó ń faradà títí láéláé.
Ìdájọ́ Olúwa dájú
òdodo ni gbogbo wọn.
10 Wọn ṣọ̀wọ́n ju wúrà lọ,
ju wúrà tí o dára jùlọ,
wọ́n dùn ju oyin lọ,
àti ju afárá oyin lọ.
11 Nípa wọn ni a ti ṣí ìránṣẹ́ rẹ̀ létí;
nípa pípa wọ́n mọ́, èrè púpọ̀ ń bẹ.
12 Ta ni ó lè mọ àṣìṣe rẹ̀?
Dáríjì mí nínú àṣìṣe mi tí ó pamọ́.
13 Wẹ ìránṣẹ́ rẹ mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àmọ̀ọ́n-mọ̀-dá;
má ṣe jẹ kí wọn kí ó jẹ ọba lórí mi.
Nígbà náà ní èmi yóò dúró ṣinṣin,
èmi yóò sì ṣe aláìlẹ́bi kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ ńlá.
14 Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹnu mi àti àṣàrò ọkàn mi
kí ó jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà ní ojú rẹ,
Ìwọ Olúwa àpáta mi, àti Olùdáǹdè mi.
Fún adarí orin. Ti àwọn ọmọ Kora. Gẹ́gẹ́ bí ti alamoti. b Orin.
46 Ọlọ́run ni ààbò àti agbára wa
ó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ ní ìgbà ìpọ́njú.
2 Nítorí náà àwa kì yóò bẹ̀rù, bí a tilẹ̀ ṣí ayé ní ìdí,
tí òkè sì ṣubú sínú Òkun.
3 Tí omi rẹ̀ tilẹ̀ ń hó tí ó sì ń mì
tí àwọn òkè ńlá tilẹ̀ ń mì pẹ̀lú ọwọ́ agbára rẹ̀. Sela.
4 Odò ńlá kan wà tí ṣíṣàn rẹ̀ mú inú ìlú Ọlọ́run dùn,
ibi mímọ́, níbi ti Ọ̀gá-ògo ń gbé.
5 Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀, kò ní yẹ̀:
Ọlọ́run yóò ràn án lọ́wọ́ ní kùtùkùtù òwúrọ̀.
6 Àwọn orílẹ̀-èdè ń bínú, àwọn ilẹ̀ ọba ṣubú,
ó gbé ohun rẹ̀ sókè, ayé yọ̀.
7 Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun wà pẹ̀lú wa,
Ọlọ́run Jakọbu ni ààbò wa.
8 Ẹ wá wo iṣẹ́ Olúwa
irú ahoro tí ó ṣe ní ayé.
9 O mú ọ̀tẹ̀ tán de òpin ilẹ̀ ayé
ó ṣẹ́ ọrun, ó sì gé ọ̀kọ̀ sí méjì
ó fi kẹ̀kẹ́ ogun jóná
10 Ẹ dúró jẹ́ẹ́, kí ẹ sì mọ̀ pé èmi ní Ọlọ́run.
A ó gbé mi ga nínú àwọn orílẹ̀-èdè
A ó gbé mi ga ní ayé.
11 Ọlọ́run alágbára wà pẹ̀lú wa
Ọlọ́run Jakọbu sì ni ààbò wa.
20 Jakọbu sì ṣiṣẹ́ sin Labani fún ọdún méje láti fẹ́ Rakeli. Àwọn ọdún wọ̀nyí sì dàbí ọjọ́ díẹ̀ lára rẹ̀, nítorí ó fẹ́ràn rẹ̀.
21 Jakọbu sì wí fún Labani pé, “Mo ti parí àsìkò tí a jọ ṣe àdéhùn rẹ̀, nítorí náà fún mi ní aya mi, kí òun lè ṣe aya fún mi.”
22 Labani sì pe gbogbo ènìyàn ibẹ̀ jọ, ó sì ṣe àsè ìyàwó fún wọ́n. 23 Ṣùgbọ́n nígbà tí ó di òru, Labani mú Lea tọ Jakọbu lọ. Jakọbu sì bá a lòpọ̀. 24 Labani sì fi Silipa ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ obìnrin fún Lea gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́.
25 Sì kíyèsi, nígbà ti ilẹ̀ mọ́, Jakọbu rí i pé Lea ni! Ó sì wí fún Labani pé, “Èwo ni ìwọ ṣe sí mi yìí? Ṣe bí nítorí Rakeli ni mo ṣe ṣiṣẹ́ sìn ọ, èéṣe tí ìwọ tàn mi?”
26 Labani sì dáhùn pé, “Kò bá àṣà wa mu láti fi àbúrò fún ọkọ ṣáájú ẹ̀gbọ́n rẹ̀. 27 Mú sùúrù parí ọ̀sẹ̀ ìgbéyàwó yìí náà, nígbà náà ni èmi yóò fi àbúrò rẹ̀ fún ọ pẹ̀lú, bí ìwọ ó bá ṣiṣẹ́ sìn mi fún ọdún méje mìíràn.”
28 Jakọbu sì gbà láti sin Labani fún ọdún méje mìíràn. Labani sì fi Rakeli ọmọ rẹ̀ fún un bí aya. 29 Labani sì fi Biliha ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ obìnrin fún Rakeli bí ìránṣẹ́. 30 Jakọbu sì bá Rakeli náà lòpọ̀. Ó sì fẹ́ràn Rakeli ju Lea lọ, ó sì ṣiṣẹ́ sin Labani fún ọdún méje mìíràn.
Àwọn ọmọ Jakọbu
31 Nígbà tí Ọlọ́run sì ri pé, Jakọbu kò fẹ́ràn Lea, ó ṣí i ni inú ṣùgbọ́n Rakeli yàgàn. 32 Lea sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Reubeni, nítorí ó wí pé, “Nítorí Ọlọ́run ti mọ ìpọ́njú mi, dájúdájú, ọkọ mi yóò fẹ́ràn mi báyìí.”
33 Ó sì tún lóyún, ó bí ọmọkùnrin kan. Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Simeoni, wí pé “Nítorí tí Olúwa ti gbọ́ pé a kò fẹ́ràn mi, ó sì fi èyí fún mi pẹ̀lú.”
34 Ó sì tún lóyún, ó bí ọmọkùnrin kan, ó sì wí pé, “Nígbà yìí ni ọkọ mi yóò fi ara mọ́ mi, nítorí tí mo ti bí ọmọkùnrin mẹ́ta fún un,” nítorí náà ni ó ṣe pe orúkọ rẹ̀ ní Lefi.
35 Ó sì tún lóyún, ó sì tún jẹ́ pé ọmọkùnrin ni ó bí, ó sì wí pé, “Nígbà yìí ni èmi yóò yin Olúwa.” Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Juda. Ó sì dáwọ́ ọmọ bíbí dúró.
14 Ìwé nǹkan wọ̀nyí ni mo kọ sí ọ, mo sì ń retí àti tọ̀ ọ́ wá ní lọ́ọ́lọ́ọ́. 15 Ṣùgbọ́n bí mo bá pẹ́, kí ìwọ lè mọ̀ bí ó ti yẹ fún àwọn ènìyàn láti máa hùwà nínú ilé Ọlọ́run, tì í ṣe ìjọ Ọlọ́run alààyè, ọ̀wọ́n àti ìpìlẹ̀ òtítọ́. 16 Láìṣiyèméjì, títóbi ní ohun ìjìnlẹ̀ ìwà-bí-Ọlọ́run:
ẹni tí a fihàn nínú ara,
tí a dá láre nínú Ẹ̀mí,
ti àwọn angẹli rí,
tí a wàásù rẹ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè,
tí a gbàgbọ́ nínú ayé,
tí a sì gbà sókè sínú ògo.
Àwọn ẹ̀kọ́ fun Timotiu
4 Nísinsin yìí, èmi ń tẹnumọ́ ọ́ pé ní ìgbà ìkẹyìn àwọn mìíràn yóò kúrò nínú ìgbàgbọ́, wọn yóò máa fiyèsí àwọn ẹ̀mí tí ń tannijẹ, àti ẹ̀kọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù. 2 Nípa àgàbàgebè àwọn tí ń ṣèké, àwọn tí ọkàn tìkára wọn dàbí èyí tí a fi irin gbígbóná jó. 3 Àwọn tí ń dánilẹ́kun láti gbéyàwó tiwọn si ń pàṣẹ láti ka èèwọ̀ oúnjẹ ti Ọlọ́run ti dá fún ìtẹ́wọ́gbà pẹ̀lú ọpẹ́ àwọn onígbàgbọ́ àti àwọn ti ó mọ òtítọ́. 4 Nítorí gbogbo ohun ti Ọlọ́run dá ni ó dára, kò sí ọkàn tí ó yẹ kí a kọ̀, bí a bá fi ọpẹ́ gbà á. 5 Nítorí tí a fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti àdúrà yà sí mímọ́.
6 Bí ìwọ bá ń rán àwọn ará létí nǹkan wọ̀nyí, ìwọ ó jẹ́ ìránṣẹ́ rere ti Kristi Jesu, tí a fi ọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́ àti ẹ̀kọ́ rere bọ́, èyí ti ìwọ ti ń tẹ̀lé. 7 Ṣùgbọ́n kọ ọ̀rọ̀ asán àti ìtàn àwọn àgbà obìnrin, sì máa tọ́ ara rẹ sí ìwà-bí-Ọlọ́run. 8 Nítorí ṣíṣe eré-ìdárayá ni èrè fún ohun díẹ̀, ṣùgbọ́n ìwà-bí-Ọlọ́run ni èrè fún ohun gbogbo, ó ní ìlérí ti ìgbé ayé ìsinsin yìí àti ti èyí tí ń bọ̀. 9 Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ náà, ó sì yẹ fún ìtẹ́wọ́gbà gbogbo. 10 Nítorí fún èyí ni àwa ń ṣe làálàá tí a sì ń jìjàkadì, nítorí àwa ní ìrètí nínú Ọlọ́run alààyè, ẹni tí í ṣe Olùgbàlà gbogbo ènìyàn, pẹ̀lúpẹ̀lú ti àwọn ti ó gbàgbọ́.
23 Jesu wò ó bí ọkùnrin náà ti ń lọ. Ó yípadà, ó sì sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Àní, ohun ìṣòro ni fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọ́run!”
24 Ọ̀rọ̀ yìí ya àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ lẹ́nu. Jesu tún sọ fún wọn pé, “Ẹyin ọmọ yóò tí ṣòro tó fún àwọn tí ó ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ọrọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọ́run. 25 Ó rọrùn fún ìbákasẹ láti gba ojú abẹ́rẹ́ wọlé jù fún ọlọ́rọ̀ kan láti wọ ìjọba ọ̀run.”
26 Ẹnu túbọ̀ ya àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sí i. Wọ́n béèrè wí pé, “Tí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ta ni nínú ayé ni ó lè ní ìgbàlà?”
27 Jesu wò wọ́n, ó sì wí fún wọn pé, “Ènìyàn ní èyí kò ṣe é ṣe fún ṣùgbọ́n kì í ṣe fún Ọlọ́run, nítorí ohun gbogbo ni ṣíṣe fún Ọlọ́run.”
28 (A)Nígbà náà ni Peteru kọjú sí Jesu, ó wí pé, “Àwa ti fi ohun gbogbo sílẹ̀, a sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.”
29 Jesu dáhùn pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín pé, kò sí ẹnikẹ́ni tí ó fi ohunkóhun sílẹ̀ bí: ilé, tàbí àwọn arákùnrin, tàbí àwọn arábìnrin, tàbí ìyá, tàbí baba, tàbí àwọn ọmọ tàbí ohun ìní nítorí mi àti nítorí ìhìnrere, 30 (B)tí a kì yóò fún padà ní ọgọọgọ́rùn-ún àwọn ilé, tàbí arákùnrin, tàbí arábìnrin, tàbí ìyá, tàbí ọmọ, tàbí ilẹ̀, àti inúnibíni pẹ̀lú. Gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò jẹ́ tirẹ̀ ní ayé yìí àti pé ní ayé tó ń bọ̀ yóò ní ìyè àìnípẹ̀kun. 31 (C)Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ àwọn tí ó síwájú ni yóò di ẹni ìkẹyìn, àwọn tí ó sì kẹ́yìn yóò síwájú.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.