Book of Common Prayer
Maskili ti Asafu.
78 Ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ gbọ́ ẹ̀kọ́ mi;
tẹ́tí rẹ sí ọ̀rọ̀ ẹnu mi.
2 (A)Èmi ó la ẹnu mi ní òwe,
èmi o sọ ohun ìkọ̀kọ̀, ohun ti ọjọ́ pípẹ́;
3 Ohun tí a ti gbọ́ tí a sì ti mọ̀,
ohun tí àwọn baba wa ti sọ fún wa.
4 Àwa kì yóò pa wọ́n mọ́
kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọmọ,
ní fífi ìyìn Olúwa, àti ipa rẹ̀
àti iṣẹ́ ìyanu tó ti ṣe hàn
fún ìran tí ń bọ̀.
5 Ó gbé ẹ̀rí kalẹ̀ ní Jakọbu
o sì fìdí àṣẹ múlẹ̀ ní Israẹli,
èyí tí ó pàṣẹ fún àwọn baba ńlá wa
láti kọ́ àwọn ọmọ wọn,
6 Nítorí náà, àwọn ìran tí ń bọ̀ yóò mọ̀ wọ́n
bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ tí a kò tí ì bí
tí yóò dìde tí wọn yóò sọ fún àwọn ọmọ wọn
7 Nígbà náà ni wọ́n ò fi ìgbẹ́kẹ̀lé wọn sínú Ọlọ́run
wọn kò sì ní gbàgbé iṣẹ́ Ọlọ́run
ṣùgbọ́n wọn ó pa àṣẹ rẹ̀ mọ́.
8 Kí wọn kí ó má ṣe dàbí àwọn baba ńlá wọn,
ìran alágídí àti ọlọ́tẹ̀,
ìran tí ọkàn wọn kò ṣọ òtítọ́ si olóore,
àti ẹ̀mí ẹni tí kò bá Ọlọ́run dúró ṣinṣin.
9 Àwọn ọkùnrin Efraimu, tí ó há mọ́ ọ tí wọ́n mú ọrun,
wọ́n yípadà ní ọjọ́ ogun
10 Wọn kò pa májẹ̀mú Ọlọ́run mọ́
wọn sì kọ̀ láti máa gbé nínú òfin rẹ̀
11 Wọ́n gbàgbé ohun tí ó ti ṣe,
àwọn ìyanu tí ó ti fihàn wọ́n.
12 Ó ṣe ìyanu níwájú àwọn baba wọn ní ilẹ̀ Ejibiti, ní agbègbè Ṣoani.
13 Ó pín Òkun ní yà, ó sì mú wọn kọjá
Ó mù kí omi naà dúró bi odi gíga.
14 Ní ọ̀sán, ó fi ìkùùkuu àwọsánmọ̀ ṣe amọ̀nà wọn
àti ní gbogbo òru pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ iná.
15 Ó sán àpáta ní aginjù
ó sì fún wọn ní omi mímu lọ́pọ̀lọpọ̀
bí ẹni pé láti inú ibú wá.
16 Ó mú ìṣàn omi jáde láti inú àpáta
omi ṣíṣàn sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí odò.
17 Wọ́n sì tún tẹ̀síwájú láti dẹ́ṣẹ̀ sí i
ní ìṣọ̀tẹ̀ sí Ọ̀gá-ògo ní aginjù.
18 Wọ́n mọ̀ ọ́n mọ̀ dán Ọlọ́run wò
nípa bíbéèrè fún oúnjẹ tí wọn bẹ̀bẹ̀ fún
19 Wọ́n sọ̀rọ̀-òdì sí Ọlọ́run, wí pé
“Ọlọ́run ha lè tẹ́ tábìlì ní aginjù?
20 Nígbà tí ó lu àpáta, omi tú jáde,
odò sì sàn lọ́pọ̀lọpọ̀
ṣùgbọ́n òun ha lè fún wa lóúnjẹ
ó ha le pèsè ẹran fún àwọn ènìyàn rẹ̀”
21 Nígbà tí Olúwa gbọ́ wọn, ó bínú gidigidi;
iná rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ sí Jakọbu,
ìbínú rẹ̀ sì rú sí Israẹli,
22 Nítorí wọn kò gba Ọlọ́run gbọ́,
wọn kò sì gbẹ́kẹ̀lé ìgbàlà rẹ̀.
23 Síbẹ̀ ó pàṣẹ fún ìràwọ̀ ojú ọ̀run,
ó sì ṣí ìlẹ̀kùn ọ̀run sílẹ̀;
24 (B)Ó rọ manna fún àwọn ènìyàn láti jẹ,
ó fún wọn ní ọkà láti ọ̀run.
25 Àwọn ènìyàn jẹ oúnjẹ àwọn angẹli;
Ó fún wọn ní oúnjẹ ní àjẹyó,
26 Ó mú afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn láti ọ̀run wá
ó mú afẹ́fẹ́ gúúsù wá nípa agbára rẹ̀.
27 Ó rọ òjò ẹran sílẹ̀ sórí wọn bí erùpẹ̀ ilẹ̀,
àti ẹyẹ abìyẹ́ gẹ́gẹ́ bí iyanrìn etí Òkun
28 Ó jẹ́ kí wọn jáde ní ibùdó wọn,
yíká àgọ́ wọn.
29 Wọ́n jẹ, wọ́n sì yó jọjọ
nítorí ó ti fún wọn ní ohun tí wọn fìtara bẹ̀bẹ̀ fún
30 Ṣùgbọ́n wọn kò kúrò nínú oúnjẹ tí wọn fìtara bẹ̀bẹ̀ fún,
nígbà tí oúnjẹ wọn sì wà ní ẹnu wọn,
31 Ìbínú Ọlọ́run dìde sí wọn
ó pa àwọn tí ó jùlọ nínú wọn,
ó sì lu àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin Israẹli bolẹ̀.
32 Nínú gbogbo ìwọ̀nyí, wọ́n ń dẹ́ṣẹ̀ síwájú;
nínú gbogbo iṣẹ́ ìyanu rẹ̀, wọ́n kò gbàgbọ́
33 O fi òpin sí ayé wọn nínú asán
àti ọdún wọn nínú ìpayà.
34 Nígbàkígbà tí Ọlọ́run bá pa wọ́n,
wọn yóò wá a kiri;
wọn yóò fi ìtara yípadà sí i.
35 Wọ́n rántí pé Ọlọ́run ní àpáta wọn;
wí pé Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo jùlọ ni olùràpadà àpáta wọn
36 Ṣùgbọ́n nígbà náà ni wọ́n yóò pọ́n ọn pẹ̀lú ẹnu wọ́n
wọ́n fi ahọ́n wọ́n purọ́ fún un;
37 (C)Ọkàn wọn kò sòtítọ́ sí i,
wọn kò jẹ́ olódodo sí májẹ̀mú rẹ̀.
38 Síbẹ̀ ó ṣàánú;
ó dárí àìṣedéédéé wọn jì
òun kò sì pa wọ́n run
nígbà púpọ̀ ló ń yí ìbínú rẹ̀ padà
kò sì ru ìbínú rẹ̀ sókè
39 Ó rántí pé ẹlẹ́ran ara ni wọ́n,
afẹ́fẹ́ tó ń kọjá tí kò lè padà.
40 Nígbà gbogbo ní wọn ń ṣọ̀tẹ̀ sí i ní aginjù
wọn mú un bínú nínú ilẹ̀ tí ó di ahoro!
41 Síwájú àti síwájú wọ́n dán Ọlọ́run wò;
wọ́n mú ẹni mímọ́ Israẹli bínú.
42 Wọ́n kò rántí agbára rẹ̀:
ní ọjọ́ tí ó rà wọ́n padà lọ́wọ́ àwọn aninilára,
43 Ní ọjọ́ tí ó fi iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ hàn ní Ejibiti,
àti iṣẹ́ ààmì rẹ̀ ni ẹkùn Ṣoani
44 Ó sọ omi wọn di ẹ̀jẹ̀;
wọn kò lè mu láti odò wọn.
45 Ó rán ọ̀wọ́ eṣinṣin láti pa wọ́n run,
àti ọ̀pọ̀lọ́ tí ó bá wọn jẹun.
46 Ó fi ọkà wọn fún láńtata,
àwọn ìre oko wọn fún eṣú.
47 Ó fi yìnyín ba àjàrà wọn jẹ́
ó bá èso sikamore wọn jẹ́.
48 Ó fi ohun ọ̀sìn wọn fún yìnyín,
agbo ẹran wọn fún mọ̀nàmọ́ná.
49 Ó mú kíkorò ìbínú rẹ̀ wá sí wọn lára,
ìrunú àti ìkáàánú, àti ìpọ́njú,
nípa rírán angẹli apanirun sí wọn.
50 Ó pèsè ipa fún ìbínú rẹ̀,
òun kò gbà wọ́n lọ́wọ́ ikú,
ṣùgbọ́n ó fi ẹ̀mí wọ́n fún àjàkálẹ̀-ààrùn.
51 Ó kọlu àwọn àkọ́bí ọmọ ọkùnrin Ejibiti
Olórí agbára wọn nínú àgọ́ Hamu
52 Ṣùgbọ́n ó mú àwọn ènìyàn rẹ̀ jáde bí ọ̀wọ́ ẹran;
ó ṣọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí àgùntàn nínú aginjù.
53 Ó dáàbò bò wọ́n dáradára, nítorí náà ni ẹ̀rù kò ṣe bà wọ́n
ṣùgbọ́n Òkun padé mọ́ àwọn ọ̀tá wọn.
54 Bákan náà ni ó mú wọn wá sí etí ilẹ̀ mímọ́ rẹ̀
òkè tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ ti gbà
55 Ó lé kèfèrí jáde níwájú wọn
ó sì fi títa okùn pín ilẹ̀ náà fún wọn gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìní;
ó mú àwọn ẹ̀yà Israẹli jókòó ní ilẹ̀ wọn.
56 Ṣùgbọ́n wọn dán Ọlọ́run wò
wọn sì ṣọ̀tẹ̀ sí Ọ̀gá-ògo;
wọn kò pa àṣẹ rẹ̀ mọ́.
57 Ṣùgbọ́n wọ́n yípadà,
wọn jẹ́ aláìṣòdodo gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wọn
wọ́n sì pẹ̀yìndà sí apákan bí ọrun ẹ̀tàn.
58 Wọ́n bí i nínú pẹ̀lú ibi gíga wọn;
wọn rú owú rẹ̀ sókè nípa òrìṣà wọn
59 Nígbà tí Ọlọ́run gbọ́ wọn,
inú bí i gidigidi;
ó kọ Israẹli pátápátá.
60 Ó kọ àgọ́ Ṣilo sílẹ̀,
àgọ́ tí ó ti gbé kalẹ̀ láàrín àwọn ènìyàn.
61 Ó rán àpótí ẹ̀rí, agbára rẹ̀ lọ sí ìgbèkùn,
dídán ògo rẹ̀ lọ sí ọwọ́ àwọn ọ̀tá.
62 Ó fi àwọn ènìyàn rẹ̀ lé idà lọ́wọ́,
ó sì bínú sí àwọn ohun ìní rẹ̀.
63 Iná run àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin wọn,
àwọn ọmọbìnrin wọn kò sì ní orin ìgbéyàwó:
64 A fi àlùfáà wọn fún idà,
àwọn opó wọn kò sì le è sọkún.
65 Olúwa sì jí gẹ́gẹ́ bí ẹni ojú oorun,
gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin ti i jí kúrò nínú ìraníyè ọtí.
66 Ó kọlu àwọn ọ̀tá rẹ̀ padà;
ó fi wọn sínú ìtìjú ayérayé.
67 Nígbà náà ni ó kọ́ àgọ́ Josẹfu,
kò sì yan ẹ̀yà Efraimu;
68 Ṣùgbọ́n ó yan ẹ̀yà Juda,
òkè Sioni, èyí tí ó fẹ́ràn.
69 Ó kọ́ ibi mímọ́ rẹ̀, ibi gíga,
gẹ́gẹ́ bí ayé tí ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ títí láé.
70 Ó yan Dafidi ìránṣẹ́ rẹ̀
ó mú láti inú àwọn agbo ẹran;
71 Ó mú un jáde nínú ìtọ́jú àgùntàn
láti jẹ́ olùṣọ́-àgùntàn àwọn ènìyàn rẹ̀ Jakọbu
àti Israẹli ogún un rẹ̀.
72 Dafidi sì ṣọ́ wọn pẹ̀lú òtítọ́ inú ọkàn;
pẹ̀lú ọwọ́ òye ni ó fi darí wọn.
Isaaki àti Abimeleki
26 Ìyàn kan sì mú ní ilẹ̀ náà, yàtọ̀ fún èyí tí ó mú ní ìgbà ayé Abrahamu, Isaaki sì lọ sọ́dọ̀ Abimeleki ọba àwọn Filistini ni Gerari. 2 Olúwa sì fi ara han Isaaki, ó sì wí pé, “Má ṣe sọ̀kalẹ̀ lọ sí Ejibiti: Jókòó ní ilẹ̀ tí èmi ó fún ọ. 3 (A)Máa ṣe àtìpó ní ilẹ̀ yìí fún ìgbà díẹ̀, èmi ó sì wà pẹ̀lú rẹ, Èmi yóò sì bùkún fún ọ. Nítorí ìwọ àti irú-ọmọ rẹ ni èmi yóò fi gbogbo àwọn ilẹ̀ wọ̀nyí fún, èmi yóò sì fi ìdí ìbúra tí mo ṣe fún Abrahamu baba rẹ múlẹ̀. 4 Èmi yóò sọ ìran rẹ di púpọ̀ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, èmi yóò sì fi gbogbo ilẹ̀ yìí fún irú àwọn ọmọ rẹ, àti nípasẹ̀ irú-ọmọ rẹ ni a ó bùkún fún gbogbo orílẹ̀-èdè ayé, 5 nítorí tí Abrahamu gba ohùn mi gbọ́, ó sì pa gbogbo ìkìlọ̀, àṣẹ, ìlànà àti òfin mi mọ́.” 6 Nítorí náà Isaaki jókòó ní Gerari.
12 Ní ọdún náà, Isaaki gbin ohun ọ̀gbìn sí ilẹ̀ náà, ó sì kórè rẹ̀ ní ìlọ́po ọgọ́ọ̀rún ni ọdún kan náà, nítorí Ọlọ́run bùkún un. 13 Ọkùnrin náà sì di ọlọ́rọ̀ púpọ̀, ọrọ̀ rẹ̀ sì ń pọ̀ si, títí ó fi di ènìyàn ńlá. 14 Ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹran ọ̀sìn àti agbo ẹran àti àwọn ìránṣẹ́ tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn Filistini ń ṣe ìlara rẹ̀. 15 Nítorí náà àwọn ará Filistini ru erùpẹ̀ di gbogbo kànga tí àwọn ìránṣẹ́ Abrahamu baba rẹ̀ ti gbẹ́.
16 Nígbà náà ni Abimeleki wí fún Isaaki pé, “Jáde kúrò ní ilẹ̀ wa, nítorí tí ìwọ ti di alágbára púpọ̀ jù wá lọ.”
17 Isaaki sì ṣí kúrò níbẹ̀, ó sì pàgọ́ sí Àfonífojì Gerari ó sì ń gbé ibẹ̀. 18 Isaaki sì ṣe àtúngbẹ́ àwọn kànga tí Abrahamu baba rẹ̀ ti gbẹ́ nígbà ayé rẹ̀, èyí tí àwọn Filistini ti dí lẹ́yìn ikú Abrahamu baba rẹ̀, ó sì fún wọn lórúkọ tí baba rẹ̀ ti sọ wọ́n tẹ́lẹ̀.
19 Àwọn ìránṣẹ́ Isaaki sì gbẹ́ kànga ní àfonífojì náà, wọ́n kan ìsun omi níbẹ̀. 20 Ṣùgbọ́n àwọn darandaran Gerari ń bá àwọn darandaran Isaaki jà sí kànga náà pé àwọn ni àwọn ni í. Nítorí náà ni ó fi pe orúkọ kànga náà ní Eseki, nítorí pé wọ́n bá a jà sí kànga náà. 21 Àwọn ìránṣẹ́ Isaaki tún gbẹ́ kànga mìíràn, wọ́n sì tún jà nítorí rẹ̀ pẹ̀lú, ó sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Sitna (kànga àtakò). 22 Ó sì tún kúrò níbẹ̀, ó sì gbẹ́ kànga mìíràn, wọn kò sì jásí èyí rárá, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Rehoboti, ó wí pé, “Nísinsin yìí, Olúwa ti fi ààyè gbà wá, a ó sì gbilẹ̀ si ní ilẹ̀ náà.”
23 Láti ibẹ̀, ó kúrò lọ sí Beerṣeba 24 Ní òru ọjọ́ tí ó dé ibẹ̀, Olúwa sì fi ara hàn án, ó sì wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run Abrahamu baba rẹ: Má ṣe bẹ̀rù nítorí èmi wà pẹ̀lú rẹ, èmi yóò sì bùsi fún ọ, èmi yóò sì sọ iye ìran rẹ di púpọ̀, nítorí Abrahamu ìránṣẹ́ mi.”
25 Isaaki sì kọ́ pẹpẹ kan síbẹ̀, ó sì pe orúkọ Olúwa. Níbẹ̀ ni ó pàgọ́ rẹ̀ sí, àwọn ìránṣẹ́ rẹ sì gbẹ́ kànga kan níbẹ̀.
26 (A)Nígbà náà ni Abimeleki tọ̀ ọ́ wá láti Gerari, àti Ahussati, olùdámọ̀ràn rẹ̀ àti Fikoli, olórí ogun rẹ̀. 27 Isaaki sì bi wọ́n léèrè pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin tọ̀ mí wá, níwọ̀n ìgbà tí ẹ̀yin kórìíra mi tí ẹ sì lé mi jáde kúrò lọ́dọ̀ yín?”
28 Wọ́n dáhùn pé, “A rí i dájú pé Olúwa wà pẹ̀lú rẹ, nítorí náà ni a fi rò ó wí pé, ó yẹ kí májẹ̀mú kí o wà láàrín àwa àti ìwọ. Jẹ́ kí a ṣe àdéhùn 29 pé ìwọ kì yóò ṣe wá ní ibi, bí àwa pẹ̀lú kò ti ṣe ọ́ ní aburú, tí a sì ń ṣe ọ́ dáradára, tí a sì rán ọ jáde ní àlàáfíà láìṣe ọ́ ní ibi, kíyèsi Olúwa sì ti bùkún fún ọ.”
30 Isaaki sì ṣe àsè fún wọn, wọn sì jẹ, wọ́n sì mu. 31 Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì wọn búra fún ara wọn. Isaaki sì rán wọn lọ, wọ́n sì lọ ní àlàáfíà.
32 Ní ọjọ́ náà gan an ni àwọn ìránṣẹ́ Isaaki wá sọ fún un pé àwọn ti kan omi ní kànga kan tí àwọn gbẹ́. 33 (B)Ó sì pe orúkọ kànga náà ní Ṣiba (kànga májẹ̀mú), títí di òní olónìí, orúkọ ìlú náà ni Beerṣeba.
17 Ẹ máa gbọ́ ti àwọn tí ń ṣe olórí yín, kí ẹ sì máa tẹríba fún wọ́n: Nítorí wọn ń ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ nítorí ọkàn yín, bí àwọn ti yóò ṣe ìṣirò, kí wọn lè fi ayọ̀ ṣe èyí, kì í ṣe pẹ̀lú ìbànújẹ́, nítorí èyí yìí yóò jẹ àìlérè fún yín.
18 Ẹ máa gbàdúrà fún wa: nítorí àwa gbàgbọ́ pé àwa ni ẹ̀rí ọkàn rere, a sì ń fẹ́ láti máa hùwà títọ́ nínú ohun gbogbo. 19 Ṣùgbọ́n èmi ń bẹ̀ yín gidigidi sí i láti máa ṣe èyí, kí a ba lè tètè fi mi fún yín padà.
20 (A)Ǹjẹ́ Ọlọ́run àlàáfíà, ẹni tí o tún mu olùṣọ́-àgùntàn ńlá ti àwọn àgùntàn, ti inú òkú wá, nípa ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú ayérayé, àní Olúwa wa Jesu. 21 Kí ó mú yín pé nínú iṣẹ́ rere gbogbo láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀, kí ó máa ṣiṣẹ́ ohun tí i ṣe ìtẹ́wọ́gbà níwájú rẹ̀ nínú yín nípasẹ̀ Jesu Kristi; ẹni tí ògo wà fún láé àti láéláé. Àmín.
22 Èmi sì ń bẹ̀ yín ará, ẹ gbà ọ̀rọ̀ ìyànjú mi; nítorí ìwé kúkúrú ni mo kọ sí yín.
23 Ẹ mọ pé a sá titu Timotiu arákùnrin wa sílẹ̀; bí ó ba tètè dé, èmí pẹ̀lú rẹ̀ yóò rí yín, àti gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́.
24 Ẹ ki gbogbo àwọn tí ń ṣe olórí yín, àti gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́.
Àwọn tí o ti Itali wá ki yín.
25 Kí oore-ọ̀fẹ́ wà pẹ̀lú gbogbo yín.
53 Wọ́n sì lọ olúkúlùkù sí ilé rẹ̀. 8 1 Jesu sì lọ sí orí òkè olifi.
2 Ó sì tún padà wá sí tẹmpili ní kùtùkùtù òwúrọ̀, gbogbo ènìyàn sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀; ó sì jókòó, ó ń kọ́ wọn. 3 Àwọn akọ̀wé àti àwọn Farisi sì mú obìnrin kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀, tí a mú nínú ṣíṣe panṣágà; wọ́n sì mú un dúró láàrín. 4 Wọ́n sì wí fún un pé, “Olùkọ́, a mú obìnrin yìí nínú ìṣe panṣágà, 5 Ǹjẹ́ nínú òfin, Mose pàṣẹ fún wa láti sọ irú àwọn obìnrin bẹ́ẹ̀ ní òkúta, ṣùgbọ́n ìwọ ha ti wí?” 6 Èyí ni wọ́n wí, láti dán án wò, kí wọn ba à lè rí ẹ̀sùn kan kà sí i lọ́rùn.
Ṣùgbọ́n Jesu bẹ̀rẹ̀ sílẹ̀, ó sì ń fi ìka rẹ̀ kọ̀wé ní ilẹ̀. 7 Nígbà tí wọ́n ń bi í léèrè lemọ́lemọ́, ó gbe orí rẹ sókè, ó sì wí fún wọn pé, “Jẹ́ kí ẹni tí ó wà láìní ẹ̀ṣẹ̀ nínú yín kọ́kọ́ sọ òkúta lù ú.” 8 Ó sì tún bẹ̀rẹ̀ sílẹ̀, ó ń kọ̀wé ní ilẹ̀.
9 Nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, (tí ẹ̀rí ọkàn wọn sì dá wọn lẹ́bi) wọ́n sì jáde lọ lọ́kọ̀ọ̀kan, bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn àgbà títí dé àwọn tí ó kẹ́yìn; a sì fi Jesu nìkan sílẹ̀, àti obìnrin náà láàrín, níbi tí ó wà. 10 Jesu sì dìde, ó sì wí fún un pé, “Obìnrin yìí, àwọn (olùfisùn rẹ) dà? Kò sí ẹnìkan tí ó dá ọ lẹ́bi?”
11 Ó wí pé, “Kò sí ẹnìkan, Olúwa.”
Jesu wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ ni èmi náà kò dá ọ lẹ́bi: máa lọ, láti ìgbà yìí lọ, má dẹ́ṣẹ̀ mọ́.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.