Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 140

Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi.

140 Olúwa, gbà mi lọ́wọ́ ọkùnrin búburú u nì,
    yọ mí lọ́wọ́ ọkùnrin ìkà a nì;
Ẹni tí ń ro ìwà búburú ní inú wọn;
    nígbà gbogbo ni wọ́n ń rú ìjà sókè sí mi.
Wọ́n ti pọ́n ahọ́n wọn bí ejò,
    oró paramọ́lẹ̀ ń bẹ ní abẹ́ ètè wọn.

Olúwa, pa mí mọ́ kúrò lọ́wọ́ àwọn ènìyàn búburú;
    yọ mí kúrò lọ́wọ́ ọkùnrin ìkà a nì
    ẹni tí ó ti pinnu rẹ̀ láti bi ìrìn mi ṣubú
Àwọn agbéraga ti dẹkùn sílẹ̀ fún mi àti okùn:
    wọ́n ti na àwọ̀n lẹ́bàá ọ̀nà;
    wọ́n ti kẹ́kùn sílẹ̀ fún mi.

Èmi wí fún Olúwa pé ìwọ ni Ọlọ́run mi;
    Olúwa, gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi.
Olúwa Olódùmarè, agbára ìgbàlà mi,
    ìwọ ni ó bo orí mi mọ́lẹ̀ ní ọjọ́ ìjà.
Olúwa, máa ṣe fi ìfẹ́ ènìyàn búburú fún un;
    Má ṣe kún ọgbọ́n búburú rẹ̀ lọ́wọ́;
    kí wọn kí ó máa ba à gbé ara wọn ga. Sela.

Bí ó ṣe ti orí àwọn tí ó yí mi káàkiri ni,
    jẹ́ kí ète ìka ara wọn kí ó bò wọ́n mọ́lẹ̀.
10 A ó da ẹ̀yin iná sí wọn lára:
    Òun yóò wọ́ wọn lọ sínú iná,
sínú ọ̀gbun omi jíjìn,
    kí wọn kí ó má ba à le dìde mọ́.
11 Má ṣe jẹ́ kí aláhọ́n búburú fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ ní ayé;
    ibi ni yóò máa dọdẹ ọkùnrin ìkà nì láti bì í ṣubú.

12 Èmi mọ̀ pé, Olúwa yóò mú ọ̀nà olùpọ́njú dúró,
    yóò sì ṣe ẹ̀tọ́ fún àwọn tálákà
13 Nítòótọ́ àwọn olódodo yóò
    máa fi ọpẹ́ fún orúkọ rẹ;
    àwọn ẹni dídúró ṣinṣin yóò máa gbé iwájú rẹ.

Saamu 142

Maskili ti Dafidi. Nígbà tí ó wà nínú ihò òkúta. Àdúrà.

142 Èmi kígbe sókè sí Olúwa;
    Èmi gbé ohùn mi sókè sí Olúwa fún àánú.
Èmi tú àròyé mí sílẹ̀ níwájú rẹ̀,
    bẹ́ẹ̀ ní èmi fi iṣẹ́ mi hàn níwájú rẹ̀.

Nígbà tí ẹ̀mí mi ṣàárẹ̀ nínú mi,
    ìwọ ni ẹni tí ó mọ ọ̀nà mi.
Ní ipa ọ̀nà tí èmi ń rìn
    ènìyàn ti dẹ okùn fún mi ní ìkọ̀kọ̀
Wo ọwọ́ ọ̀tún mi kí ó sì rì i
    kò sí ẹni tí ó ṣe àníyàn mi
èmi kò ní ààbò;
    kò sí ẹni tí ó náání ọkàn mi.

Èmi kígbe sí ọ, Olúwa:
    èmi wí pé, “ìwọ ni ààbò mi,
    ìpín mi ní ilẹ̀ alààyè.”

Fi etí sí igbe mi,
    nítorí tí èmi wà nínú àìnírètí
gbà mí lọ́wọ́ àwọn tí ń lépa mi,
    nítorí wọ́n lágbára jù mí lọ
Mú ọkàn mi jáde kúrò nínú túbú,
    kí èmi lè máa yin orúkọ rẹ.
Nígbà náà ni àwọn olódodo yóò yí mi káàkiri
    nítorí ìwọ yóò fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ba mi ṣe.

Saamu 141

Saamu ti Dafidi.

141 Olúwa, èmi ké pè ọ́; yára wá sí ọ̀dọ̀ mi.
    Gbọ́ ohùn mi, nígbà tí mo bá ń ké pè ọ́.
Jẹ́ kí àdúrà mi ó wá sí iwájú rẹ bí ẹbọ tùràrí
    àti ìgbé ọwọ́ mi si òkè rí bí ẹbọ àṣálẹ́.

Fi ẹ̀ṣọ́ ṣọ́ ẹnu mi, Olúwa:
    kí o sì máa pa ìlẹ̀kùn ètè mi mọ́.
Má ṣe jẹ́ kí ọkàn mi fà sí ohun tí ń ṣe ibi,
    Láti máa bá àwọn tí ń ṣiṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ búburú
    má sì ṣe jẹ́ kí èmi jẹ àdídùn wọn.

Jẹ́ kí olódodo lù mí: ìṣeun ni ó jẹ́:
    jẹ́ kí ó bá mi wí, ó jẹ́ òróró ní orí mi.
    Tí kì yóò fọ́ mi ní orí.

Síbẹ̀ àdúrà mi wá láìsí ìṣe àwọn olùṣe búburú
    A ó ju àwọn alákòóso sílẹ̀ láti bẹ̀bẹ̀ òkúta,
    àwọn ẹni búburú yóò kọ pé àwọn ọ̀rọ̀ mi dùn.
Wọn yóò wí pé, “Bí ẹni tí ó la aporo sórí ilẹ̀,
    bẹ́ẹ̀ ni egungun wa tànkálẹ̀ ní ẹnu isà òkú.”

Ṣùgbọ́n ojú mi ń bẹ lára rẹ, Olúwa Olódùmarè;
    nínú rẹ̀ ni èmi ti rí ààbò, má ṣe fà mi fún ikú.
Pa mí mọ́ kúrò nínú okùn tí wọn ti dẹ sílẹ̀ fún mi,
    kúrò nínú ìkẹ́kùn àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.
10 Jẹ́ kí àwọn ẹni búburú ṣubú sínú àwọ̀n ara wọn,
    nígbà tí èmi bá kọjá lọ láìléwu.

Saamu 143

Saamu ti Dafidi.

143 Olúwa gbọ́ àdúrà mi,
    fetísí igbe mi fún àánú;
    nínú òtítọ́ àti òdodo rẹ, wá fún ìrànlọ́wọ́ mi
(A)Má ṣe mú ìránṣẹ́ rẹ wá sí ìdájọ́,
    nítorí kò sí ẹnìkan tí ó wà láààyè
    tí ó ṣe òdodo níwájú rẹ.
Ọ̀tá ń lépa mi,
    ó fún mi pamọ́ ilẹ̀;
ó mú mi gbé nínú òkùnkùn
    bí àwọn tí ó ti kú ti pẹ́.
Nítorí náà ẹ̀mí mi ṣe rẹ̀wẹ̀sì nínú mi;
    ọkàn mi nínú mi ṣì pòruurù.
Èmi rántí ọjọ́ tí ó ti pẹ́;
    èmi ń ṣe àṣàrò lórí gbogbo iṣẹ́ rẹ
    mo sì ṣe àkíyèsí ohun tí ọwọ́ rẹ ti ṣe.
Èmi na ọwọ́ mi jáde sí ọ:
    òǹgbẹ rẹ gbẹ ọkàn mi bí i ìyàngbẹ ilẹ̀. Sela.

Dá mi lóhùn kánkán, Olúwa;
    ó rẹ ẹ̀mí mi tán.
Má ṣe pa ojú rẹ mọ́ kúrò lára mi
    kí èmi má ba à dàbí àwọn tí ó lọ sínú ihò
Mú mi gbọ́ ìṣeun ìfẹ́ rẹ ní òwúrọ̀:
    nítorí ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀lé.
Fi ọ̀nà tí èmi i bá rìn hàn mí,
    nítorí èmi gbé ọkàn mi sókè sí ọ.
Gbà mí kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi, Olúwa,
    nítorí èmi fi ara mi pamọ́ sínú rẹ.
10 Kọ́ mi láti ṣe ìfẹ́ rẹ,
    nítorí ìwọ ni Ọlọ́run mi
jẹ́ kí ẹ̀mí rẹ dídára
    darí mi sí ilẹ̀ tí ó tẹ́jú.

11 Nítorí orúkọ rẹ, Olúwa, sọ mi di ààyè;
    nínú òdodo rẹ, mú ọkàn mi jáde nínú wàhálà.
12 Nínú ìfẹ́ rẹ tí kì í kùnà, ké àwọn ọ̀tá mi kúrò,
    run gbogbo àwọn tí ń ni ọkàn mi lára,
    nítorí pé èmi ni ìránṣẹ́ rẹ.

Òwe 8:1-21

Ọgbọ́n n fi ìpè síta

(A)Ǹjẹ́ ọgbọ́n kò ha ń kígbe síta?
    Òye kò ha ń gbé ohùn rẹ sókè?
Ní ibi gíga ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà
    ní ìkóríta, ní ó dúró;
Ní ẹgbẹ́ ibodè tí ó wọ ìlú,
    ní ẹnu ibodè ni ó ń kígbe sókè:
Sí i yín ẹ̀yin ènìyàn, ní mo ń kígbe pè;
    Mo gbé ohun mi sókè sí gbogbo ènìyàn,
Ẹ̀yin aláìmọ̀kan, ẹ kọ́gbọ́n;
    ẹ̀yin aṣiwèrè, ẹ gba òye.
Ẹ gbọ́, nítorí tí èmi ó sọ̀rọ̀ ohun iyebíye;
    Èmí ṣí ètè mi láti sọ ohun tí ó tọ́,
Ẹnu mi ń sọ ohun tí í ṣe òtítọ́,
    nítorí ètè mi kórìíra ibi.
Gbogbo ọ̀rọ̀ ẹnu mi ni ó tọ́,
    kò sí èyí tí ó jẹ́ ẹ̀tàn tàbí àyídáyidà níbẹ̀
Fún olóye gbogbo rẹ̀ ni ó tọ̀nà;
    wọ́n jẹ́ aláìlẹ́gàn fún gbogbo ẹni tí ó ní ìmọ̀.
10 Yan ẹ̀kọ́ mi dípò fàdákà,
    ìmọ̀ dípò o wúrà àṣàyàn,
11 Nítorí ọgbọ́n ṣe iyebíye jù iyùn lọ,
    kò sí ohun tí ọkàn rẹ̀ fẹ́ tí a sì le fiwé e.

12 “Èmi, ọgbọ́n ń gbé pẹ̀lú òye;
    mo ní ìmọ̀ àti ọgbọ́n-inú.
13 Ìbẹ̀rù Olúwa ni ìkórìíra ibi
    mo kórìíra ìgbéraga àti agídí,
    ìwà ibi àti ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn.
14 Ìmọ̀ràn àti ọgbọ́n tí ó yè kooro jẹ́ tèmi
    mo ní òye àti agbára.
15 Nípasẹ̀ mi ni ọba ń ṣàkóso
    tí àwọn aláṣẹ sì ń ṣe òfin tí ó dára
16 Nípasẹ̀ mi àwọn ọmọ-aládé ń ṣàkóso
    àti gbogbo ọlọ́lá tí ń ṣàkóso ilẹ̀ ayé.
17 Mo fẹ́ràn àwọn tí ó fẹ́ràn mi
    àwọn tí ó sì wá mi rí mi.
18 Lọ́dọ̀ mi ni ọrọ̀ àti ọlá wà
    ọrọ̀ tí í tọ́jọ́ àti ìgbéga rere.
19 Èso mi dára ju wúrà dáradára lọ;
    ohun tí mò ń mú wá ju àṣàyàn fàdákà lọ.
20 Mò ń rìn ní ọ̀nà òdodo,
    ní ojú ọ̀nà òtítọ́,
21 Mò ń fi ọrọ̀ fún gbogbo àwọn tí ó fẹ́ràn mi
    mo sì ń mú kí ilé ìṣúra wọn kún.

Filemoni

Ìkíni

Èmi Paulu, ẹni tí a fi sẹ́wọ̀n nítorí pé ó ń wàásù ìhìnrere Jesu Kristi àti Timotiu arákùnrin wa.

Sí Filemoni ọ̀rẹ́ wa ọ̀wọ́n àti alábáṣiṣẹ́ wa, sí Affia arábìnrin wa, sí Arkippu ẹni tó jẹ́ jagunjagun fún àgbélébùú náà àti sí ìjọ àwọn Kristiani tí ó ń pàdé nínú ilé rẹ:

(A)Oore-Ọ̀fẹ́ fún un yín àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa àti Jesu Kristi.

Ọpẹ́ àti Àdúrà

(B)Èmi máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nígbà tí mo bá rántí rẹ nínú àdúrà mi, nítorí mo ń gbọ́ nípa ìgbàgbọ́ rẹ nínú Jesu Olúwa àti nípa ìfẹ́ rẹ sí àwọn ènìyàn mímọ́. Èmi ń gbàdúrà pé, bí ìwọ ti ń ṣe alábápín nínú ìgbàgbọ́ rẹ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, pé kí ìgbàgbọ́ náà lè mú ọkàn wọn dúró gbọingbọin, gẹ́gẹ́ bí wọn ti rí àwọn ọ̀rọ̀ ohun rere tí ó ń bẹ nínú ayé rẹ, èyí tí ó ti ọ̀dọ̀ Kristi wá. Ìfẹ́ rẹ ti fún mi ní ayọ̀ púpọ̀ àti ìgboyà, nítorí ìwọ, arákùnrin ti tu ọkàn àwọn ènìyàn mímọ́ lára.

Paulu bẹ̀bẹ̀ fún Onesimu

Nítorí náà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé nínú Kristi mo ní ìgboyà púpọ̀ láti pàṣẹ ohun ti ó yẹ kí ó ṣe fún ọ, Síbẹ̀ nítorí ìfẹ́ èmí kúkú bẹ̀ ọ́. Èmi gẹ́gẹ́ bí Paulu, arúgbó, àti nísinsin yìí òǹdè Jesu Kristi. 10 (C)Èmí bẹ̀ ọ́ nítorí ọmọ mi Onesimu, ẹni tí ó di ọmọ nígbà tí mo wà nínú ìdè. 11 Nígbà kan rí, kò wúlò fún ọ, ṣùgbọ́n ní báyìí, ó ti wúlò fún ọ àti fún èmi pàápàá.

12 Èmi rán an nísinsin yìí, àní ẹni ọkàn mi padà sí ọ̀dọ̀ rẹ. 13 Èmi ìbá fẹ́ láti dá a dúró sọ́dọ̀ mi níhìn-ín, kí ó ba à dípò rẹ láti máa ràn mí lọ́wọ́ nígbà tí mo wà nínú ìdè nítorí ìhìnrere 14 ṣùgbọ́n èmi kò fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀ rárá láìgba ìyọ̀ǹda ní ọwọ́ rẹ, kí oore tí ìwọ bá ṣe má ba à jẹ́ ìfipámúniṣe bí kò ṣe ìfìfẹ́ṣe. 15 Bóyá ìdí rẹ̀ tí òun fi yẹra kúrò lọ́dọ̀ rẹ fún ìgbà díẹ̀ ni pé kí ìwọ kí ó lè gbà á padà sọ́dọ̀ títí láé; 16 Kì í wá ṣe bí ẹrú mọ́, ṣùgbọ́n bí ẹni ti ó sàn ju ẹrú lọ, gẹ́gẹ́ bí arákùnrin. Ó ṣọ̀wọ́n fún mi jọjọ, ṣùgbọ́n ó ṣọ̀wọ́n fún ọ jù nípa ti ara àti gẹ́gẹ́ bí arákùnrin nínú Olúwa.

17 Nítorí náà bí ìwọ bá kà mí sí ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, tẹ́wọ́ gbà á bí ìwọ yóò ti tẹ́wọ́ gbà mí. 18 Bí ó bá ti ṣe ọ́ ní ibi kan tàbí jẹ ọ́ ní gbèsè ohun kan, kà á sí mi lọ́rùn. 19 Èmi Paulu, ni mo fi ọwọ́ ara mi kọ ìwé yìí; èmi yóò san án padà láì tilẹ̀ ní í sọ nípa pé ìwọ pàápàá jẹ mi ní gbèsè ara rẹ. 20 Èmi ń fẹ́, arákùnrin, pé kí èmi kí ó lè ni àǹfààní kan láti ọ̀dọ̀ rẹ nínú Olúwa; fi ayọ̀ rẹ kún ọkàn mi nínú Kristi. 21 Ìgbẹ́kẹ̀lé ti mo ní pé ìwọ yóò gbọ́rọ̀, ni mo fi kọ ìwé yìí ránṣẹ́ sí ọ. Mo mọ̀ dájú pé ìwọ yóò ṣe ju bí mo ti béèrè lọ.

22 Ó ku ohun kan: Ṣe ìtọ́jú iyàrá àlejò rẹ sílẹ̀ fún mi, nítorí mo ní ìgbàgbọ́ pé a óò tú mi sílẹ̀ fún yín ní ìdáhùn sí àdúrà yín.

23 Epafira, òǹdè ẹlẹgbẹ́ mi nínú Kristi Jesu kí ọ. 24 (D)Marku kí ọ pẹ̀lú Aristarku, Dema àti Luku, àwọn alábáṣiṣẹ́ mi.

25 Kí oore-ọ̀fẹ́ Jesu Kristi Olúwa wa wà pẹ̀lú ẹ̀mí yín.

Johanu 12:9-19

Nítorí náà, ìjọ ènìyàn nínú àwọn Júù ni ó mọ̀ pé ó wà níbẹ̀; wọ́n sì wá, kì í ṣe nítorí Jesu nìkan, ṣùgbọ́n kí wọn lè rí Lasaru pẹ̀lú, ẹni tí ó ti jí dìde kúrò nínú òkú. 10 (A)Ṣùgbọ́n àwọn olórí àlùfáà gbìmọ̀ kí wọn lè pa Lasaru pẹ̀lú; 11 Nítorí pé nípasẹ̀ rẹ̀ ni ọ̀pọ̀ nínú àwọn Júù jáde lọ, wọ́n sì gbà Jesu gbọ́.

Jesu gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọ Jerusalẹmu

12 (B)Ní ọjọ́ kejì nígbà tí ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ó wá sí àjọ gbọ́ pé, Jesu ń bọ̀ wá sí Jerusalẹmu. 13 (C)Wọ́n mú imọ̀ ọ̀pẹ, wọ́n sì jáde lọ pàdé rẹ̀, wọ́n sì ń kígbe pé,

“Hosana!”

“Olùbùkún ni ẹni tí ń bọ̀ wá ní orúkọ Olúwa!”

“Olùbùkún ni ọba Israẹli!”

14 Nígbà tí Jesu sì rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan, ó gùn ún; gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé pé,

15 (D)“Má bẹ̀rù, ọmọbìnrin Sioni;
    Wò ó, ọba rẹ ń bọ̀ wá,
    o jókòó lórí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.”

16 (E)Nǹkan wọ̀nyí kò tètè yé àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀: ṣùgbọ́n nígbà tí a ṣe Jesu lógo, nígbà náà ni wọ́n rántí pé, a kọ̀wé nǹkan wọ̀nyí nípa rẹ̀ sí i.

17 Nítorí náà, ìjọ ènìyàn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ nígbà tí o pé Lasaru jáde nínú ibojì rẹ̀, tí ó sì jí i dìde kúrò nínú òkú, jẹ́rìí sí i. 18 Nítorí èyí ni ìjọ ènìyàn sì ṣe lọ pàdé rẹ̀, nítorí tí wọ́n gbọ́ pé ó ti ṣe iṣẹ́ ààmì yìí. 19 Nítorí náà àwọn Farisi wí fún ara wọn pé, “Ẹ kíyèsi bí ẹ kò ti lè borí ní ohunkóhun? Ẹ wo bí gbogbo ayé ti ń wọ́ tọ̀ ọ́!”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.