Add parallel Print Page Options

21 (A)Nítorí náà ó tún wí fún wọn pé, “Èmi ń lọ, ẹ̀yin yóò sì wá mi, ẹ ó sì kú nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín: ibi tí èmi gbé ń lọ, ẹ̀yin kì yóò lè wá.”

Read full chapter

35 (A)Nígbà náà ni Jesu wí fún wọn pé, “Nígbà díẹ̀ sí i ni ìmọ́lẹ̀ wà láàrín yín, ẹ máa rìn nígbà tí ẹ̀yin ní ìmọ́lẹ̀, kí òkùnkùn má ṣe bá yín: ẹni tí ó bá sì ń rìn ní òkùnkùn kò mọ ibi òun ń lọ.

Read full chapter

33 (A)“Ẹ̀yin ọmọ mi, nígbà díẹ̀ sí i ni èmi wà pẹ̀lú yín. Ẹ̀yin yóò wá mi: àti gẹ́gẹ́ bí mo ti wí fún àwọn Júù pé, Níbi tí èmi gbé ń lọ, ẹ̀yin kì yóò le wà; bẹ́ẹ̀ ni mo sì wí fún yín nísinsin yìí.

Read full chapter

19 (A)Nígbà díẹ̀ sí i, ayé kì yóò rí mi mọ́; ṣùgbọ́n ẹ̀yin yóò rí mi: nítorí tí èmi wà láààyè, ẹ̀yin yóò wà láààyè pẹ̀lú.

Read full chapter

16 (A)“Nígbà díẹ̀, ẹ̀yin kì ó sì rí mi: àti nígbà díẹ̀ si, ẹ ó sì rí mi, nítorí tí èmi ń lọ sọ́dọ̀ Baba.”

Ìbànújẹ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn yóò di ayọ̀

17 Nítorí náà díẹ̀ nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ń bá ara wọn sọ pé, “Kín ni èyí tí o wí fún wa yìí, nígbà díẹ̀, ẹ̀yin ó sì rí mi: àti nígbà díẹ̀ ẹ̀wẹ̀, ẹ̀yin kì yóò rí mi: àti, nítorí tí èmi ń lọ sọ́dọ̀ Baba?” 18 Nítorí náà wọ́n wí pé, kín ni, nígbà díẹ̀? Àwa kò mọ̀ ohun tí ó wí.

19 Jesu sá à ti mọ̀ pé, wọ́n ń fẹ́ láti bi òun léèrè, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ń bi ara yín léèrè ní ti èyí tí mo wí pé, nígbà díẹ̀, ẹ̀yin kì yóò sì rí mi: àti nígbà díẹ̀ si, ẹ̀yin ó sì rí mi?

Read full chapter