Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Ọ̀rọ̀ Olúwa dúró títí láé
89 Ọ̀rọ̀ rẹ, Olúwa, títí láé ni;
ó dúró ṣinṣin ní ọ̀run
90 Òtítọ́ rẹ̀ ń lọ dé gbogbo ìran dé ìran;
ìwọ ti dá ayé, ó sì dúró ṣinṣin.
91 Òfin rẹ dúró di òní
nítorí ohun gbogbo ń sìn ọ́.
92 Bí òfin rẹ̀ kò bá jẹ́ dídùn inú mi,
èmi ìbá ti ṣègbé nínú ìpọ́njú mi.
93 Èmi kì yóò gbàgbé ẹ̀kọ́ rẹ láé,
nítorí nípa wọn ni ìwọ ti pa ayé mi mọ́
94 Gbà mí, nítorí èmi jẹ́ tìrẹ
èmi ti wá ẹ̀kọ́ rẹ.
95 Àwọn ẹni búburú dúró láti pa mí run,
ṣùgbọ́n èmi yóò kíyèsi ẹ̀rí rẹ.
96 Sí ohun pípé gbogbo èmi ti rí òpin;
ṣùgbọ́n àṣẹ rẹ aláìlópin ni.
11 Nígbà tí Mikaiah ọmọ Gemariah ọmọ Ṣafani gbọ́ gbogbo àkọsílẹ̀ ọ̀rọ̀ Olúwa láti inú ìwé náà; 12 Ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilé ọba sínú yàrá akọ̀wé; níbi tí gbogbo àwọn ìjòyè gbé jókòó sí: Eliṣama akọ̀wé, Delaiah ọmọ Ṣemaiah, Elnatani ọmọ Akbori, Gemariah ọmọ Ṣafani àti Sedekiah ọmọ Hananiah àti gbogbo àwọn ìjòyè. 13 Lẹ́yìn tí Mikaiah sọ gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀n-ọn-nì tí o ti gbọ́ fún wọn, nígbà tí Baruku kà láti inú ìwé kíkà náà ní etí àwọn ènìyàn. 14 Gbogbo àwọn ìjòyè sì rán Jehudu ọmọ Netaniah ọmọ Ṣelemiah ọmọ Kuṣi sí Baruku wí pé, mú ìwé kíká náà ní ọwọ́ rẹ láti inú èyí tí ìwọ kà ní etí àwọn ènìyàn; kí o si wá. Nígbà náà ni Baruku ọmọ Neriah wá sí ọ̀dọ̀ wọn pẹ̀lú ìwé kíká ní ọwọ́ rẹ̀. 15 Wọ́n sì wí fún pé, “Jókòó, jọ̀wọ́ kà á sí etí wa!”
Nígbà náà ni Baruku sì kà á ní etí wọn. 16 Nígbà tí wọ́n sì gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ náà tan; wọ́n ń wo ara wọn lójú pẹ̀lú ẹ̀rù. Wọ́n sì wí fún Baruku pé, “Àwa gbọdọ̀ jábọ̀ gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún ọba.” 17 Wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ Baruku pé, “Sọ fún wa báwo ni o ṣe kọ gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí? Ṣé Jeremiah ló sọ wọ́n?”
18 Baruku sì dá wọn lóhùn wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, láti ẹnu rẹ̀ ni, ó sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ báyìí fún mi, èmi sì fi tàdáwà kọ wọ́n sínú ìwé náà.”
19 Nígbà náà ni àwọn ìjòyè sọ fún Baruku wí pé, “Lọ fi ara rẹ pamọ́ àti Jeremiah, má sì ṣe jẹ́ kí ẹnìkan mọ ibi tí ẹ̀yin wà.”
20 Lẹ́yìn tí wọ́n fi ìwé kíká náà pamọ́ sí iyàrá Eliṣama akọ̀wé, wọ́n sì wọlé tọ ọba lọ nínú àgbàlá, wọ́n sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ náà ní etí ọba. 21 Ọba sì rán Jehudu láti lọ mú ìwé kíká náà wá, Jehudu sì mu jáde láti inú iyàrá Eliṣama akọ̀wé. Ó sì ka ìwé náà ní etí ọba àti ní etí gbogbo àwọn ìjòyè tí ó dúró ti ọba. 22 Ó sì jẹ́ ìgbà òtútù nínú oṣù kẹsànán, ọba sì jókòó ní ẹ̀bá iná ààrò, iná náà sì ń jó ní iwájú rẹ̀. 23 Nígbà tí Jehudu ka ojú ìwé mẹ́ta sí mẹ́rin nínú ìwé náà, ọba fi ọ̀bẹ gé ìwé, ó sì sọ sínú iná tí ó wà nínú ìdáná, títí tí gbogbo ìwé kíká náà fi jóná tán. 24 Síbẹ̀, ọba àti gbogbo àwọn ẹ̀mẹwàá rẹ̀ tí wọ́n gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí kò bẹ̀rù; wọn kò sì fa aṣọ wọn yá. 25 Elnatani, Delaiah àti Gemariah sì bẹ ọba kí ó má ṣe fi ìwé kíká náà jóná, ṣùgbọ́n ọba kọ̀ láti gbọ́ tiwọn. 26 Dípò èyí ọba pàṣẹ fún Jerahmeeli ọmọ Hameleki, Seraiah ọmọ Asrieli àti Ṣelemiah ọmọ Abdeeli láti mú Baruku akọ̀wé àti Jeremiah wòlíì ṣùgbọ́n Ọlọ́run fi wọ́n pamọ́.
Ayọ̀ Paulu
2 (A)Ẹ gbà wá tọkàntọkàn; a kò fi ibi ṣe ẹnikẹ́ni, a kò ba ẹnikẹ́ni jẹ́, a kò rẹ́ ẹnikẹ́ni jẹ. 3 (B)Èmi kò sọ èyí láti dá a yín lẹ́bi; nítorí mo tí wí ṣáájú pé, ẹ̀yin wà nínú ọkàn wa kí a lè jùmọ̀ kú, àti kí a lè jùmọ̀ wà láààyè. 4 Mo ní ìgboyà ńlá láti bá yín sọ̀rọ̀; ìṣògo mí lórí yín pọ̀; mo kún fún ìtùnú, mo sì ń yọ̀ rékọjá nínú gbogbo ìpọ́njú wa.
5 (C)Nítorí pé nígbà tí àwa tilẹ̀ dé Makedonia, ara wá kò balẹ̀, ṣùgbọ́n a ń pọ́n wá lójú níhà gbogbo, ìjà ń bẹ lóde, ẹ̀rù ń bẹ nínú. 6 (D)Ṣùgbọ́n ẹni tí ń tu àwọn onírẹ̀lẹ̀ nínú, àní Ọlọ́run, ó tù wá nínú nípa dídé tí Titu dé; 7 Kì í sì i ṣe nípa dídé rẹ̀ nìkan ṣùgbọ́n nípa ìtùnú náà pẹ̀lú tí ẹ ti tù ú nínú, nígbà tí ó ròyìn fún wa ìfẹ́ àtọkànwá yín, ìbànújẹ́ yín, àti ìtara yín fún mi; bẹ́ẹ̀ ní mo sì túbọ̀ yọ̀.
8 (E)Nítorí pé, bí mo tilẹ̀ ba inú yín jẹ́ nípa ìwé tí mo kọ èmi kò kábámọ̀ mọ́, bí mo tilẹ̀ ti kábámọ̀ tẹ́lẹ̀ rí; nítorí tí mo wòye pé ìwé mi mú yín banújẹ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé fún ìgbà díẹ̀. 9 Èmi yọ̀ nísinsin yìí, kì í ṣe nítorí tí a mú inú yín bàjẹ́, ṣùgbọ́n nítorí tí a mú inú yín bàjẹ́ sí ìrònúpìwàdà: nítorí ti a mú inú yín bàjẹ́ bí ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run, kí ẹ̀yin má ṣe ti ipasẹ̀ wa pàdánù ní ohunkóhun. 10 Nítorí pé ìbànújẹ́ ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run a máa ṣiṣẹ́ ìrònúpìwàdà sí ìgbàlà tí kì í mú àbámọ̀ wá: ṣùgbọ́n ìbànújẹ́ ti ayé a máa ṣiṣẹ́ ikú. 11 Kíyèsi i, nítorí ohun kan náà yìí tí a mú yin banújẹ́ fún bí ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run, irú ìmúraṣíṣẹ́ tí ó mú jáde nínú yín, wíwẹ ara yín mọ́ ńkọ́, ìbànújẹ́ ńkọ́, ìpayà ńkọ́, ìfojúṣọ́nà ńkọ́, ìtara ńkọ́, ìjẹ́ni-níyà ńkọ́. Nínú ohun ààmì kọ̀ọ̀kan yìí ni ẹ̀yin ti fi ara yín hàn bí aláìlẹ́bi nínú ọ̀ràn náà. 12 (F)Nítorí náà, bí mo tilẹ̀ tí kọ̀wé sí yín, èmi kò kọ ọ́ nítorí ẹni tí ó ṣe ohun búburú náà tàbí nítorí ẹni ti a fi ohun búburú náà ṣe, ṣùgbọ́n kí àníyàn yín nítorí wá lè farahàn níwájú Ọlọ́run.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.