Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Jeremiah 33:14-16

14 “ ‘Àwọn ọjọ́ náà ń bọ̀,’ ni Olúwa wí, ‘tí èmi ó mú ìlérí rere tí mo ṣe fún ilé Israẹli àti ilé Juda ṣẹ.

15 (A)‘Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì àti ní àkókò náà,
    Èmi ó gbé olódodo dìde láti ẹ̀ka Dafidi.
    Yóò ṣe ìdájọ́ àti ohun tí ó tọ́ ní ilẹ̀ náà.
16 Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, Juda yóò di ẹni ìgbàlà.
    Jerusalẹmu yóò sì máa gbé láìséwu
Orúkọ yìí ni a ó máa pè é
    Olúwa wa olódodo.’

Saamu 25:1-10

Ti Dafidi.

25 Olúwa,
    ìwọ ni mo gbé ọkàn mi sókè sí.

Ọlọ́run, èmi gbẹ́kẹ̀lé ọ;
    Má ṣe jẹ́ kí ojú ó tì mí
    Má ṣe jẹ́ kí àwọn ọ̀tá mi ó yọ̀ mí.
Ẹni tí ó dúró tì ọ́
    ojú kì yóò tì í,
àwọn tí ń ṣẹ̀ láìnídìí
    ni kí ojú kí ó tì.

Fi ọ̀nà rẹ hàn mí, Olúwa,
    kọ mi ní ipa tìrẹ;
ṣe amọ̀nà mi nínú òtítọ́ ọ̀ rẹ, kí o sì kọ́ mi,
    Nítorí ìwọ ni Ọlọ́run ìgbàlà mi;
    ìwọ ni mo dúró tì ní gbogbo ọjọ́.
Rántí, Olúwa àánú àti ìfẹ́ ẹ̀ rẹ̀ ńlá,
    torí pé wọ́n ti wà ní ìgbà àtijọ́
Má ṣe rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ìgbà èwe mi
    tàbí ìrékọjá mi;
gẹ́gẹ́ bí i ìfẹ́ ẹ rẹ̀ rántí mi
    nítorí tí ìwọ dára, Ìwọ! Olúwa.

Rere àti ẹni ìdúró ṣinṣin ní Olúwa:
    nítorí náà, ó kọ́ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ni ọ̀nà náà.
Ó ṣe amọ̀nà àwọn onírẹ̀lẹ̀ ni ohun tí ó dára,
    ó sì kọ́ àwọn onírẹ̀lẹ̀ ní ọ̀nà rẹ̀.
10 Gbogbo ipa ọ̀nà Olúwa ni ìfẹ́ àti òdodo tí ó dúró ṣinṣin,
    fún àwọn tí ó pa májẹ̀mú àti ẹ̀rí rẹ̀ mọ́.

1 Tẹsalonika 3:9-13

Kò ṣe é ṣe fún wa láti dá ọpẹ́ tán lọ́wọ́ Ọlọ́run nítorí ayọ̀ àti ìfẹ́ tí ó máa ń kún ọkàn wa nípa àdúrà wa fún un yín. 10 Nítorí pé àwa ń gbàdúrà fún un yín lọ̀sán-án àti lóru. Èyí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe àtúnṣe ibi tí ìgbàgbọ́ yín bá kù sí.

11 À ń gbàdúrà wí pé, kí ó wu Ọlọ́run pàápàá àti Olúwa wa Jesu Kristi láti rán wa padà sí ọ̀dọ̀ yín lẹ́ẹ̀kan sí í. 12 A sì béèrè pé, kí Ọlọ́run ràn yín lọ́wọ́ tó bẹ́ẹ̀ tí ìfẹ́ yín yóò fi gbòòrò tí yóò sì sàn kan olúkúlùkù yín. Èyí yóò jẹ́ àpẹẹrẹ gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ àwa náà ṣe sàn kan ẹ̀yin náà. 13 (A)Kí ó lè fi ọkàn yín balẹ̀ ní àìlábùkù nínú ìwà mímọ́ níwájú Ọlọ́run àti Baba wa. Nígbà náà, ẹ ó ní ìgboyà láti dúró níwájú rẹ̀ láìṣẹ̀, ní ọjọ́ tí Olúwa wa Jesu Kristi yóò padà wá pẹ̀lú àwọn tí ó jẹ́ tirẹ̀.

Luku 21:25-36

25 (A)(B) “Ààmì yóò sì wà ní oorun, àti ní òṣùpá, àti ní ìràwọ̀; àti lórí ilẹ̀ ayé ìdààmú fún àwọn orílẹ̀-èdè nínú ìpayà híhó Òkun àti ìgbì omi. 26 Àyà àwọn ènìyàn yóò máa já fún ìbẹ̀rù, àti ìrètí nǹkan wọ̀nyí tí ń bọ̀ sórí ayé: nítorí àwọn agbára ọ̀run ni a ó mì tìtì. 27 (C)Nígbà náà ni wọn ó sì rí Ọmọ ènìyàn tí yóò máa bọ̀ wá nínú àwọsánmọ̀ pẹ̀lú agbára àti ògo ńlá. 28 (D)Ṣùgbọ́n nígbà tí nǹkan wọ̀nyí bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ, ǹjẹ́ kí ẹ wo òkè, kí ẹ sì gbé orí yín sókè; nítorí ìdáǹdè yín kù sí dẹ̀dẹ̀.”

29 (E)Ó sì pa òwe kan fún wọn pé, “Ẹ kíyèsi igi ọ̀pọ̀tọ́, àti sí gbogbo igi; 30 Nígbà tí wọ́n bá rúwé, ẹ̀yin rí i, ẹ sì mọ̀ fúnra ara yín pé, ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn kù fẹ́ẹ́rẹ́. 31 Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ̀yin, nígbà tí ẹ̀yin bá rí nǹkan wọ̀nyí tí o ṣẹ, kí ẹ̀yin mọ̀ pé, ìjọba Ọlọ́run kù sí dẹ̀dẹ̀.

32 (F)“Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ìran yìí kì yóò rékọjá, títí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò fi ṣẹ. 33 (G)Ọ̀run àti ayé yóò rékọjá: ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ mi kì yóò rékọjá.

34 (H)“Ṣùgbọ́n ẹ máa kíyèsára yín, kí ọkàn yín má ṣe kún fún wọ̀bìà, àti fún ọtí àmupara, àti fún àníyàn ayé yìí, tí ọjọ́ náà yóò sì fi dé bá yín lójijì bí ìkẹ́kùn. 35 Nítorí bẹ́ẹ̀ ni yóò dé bá gbogbo àwọn tí ń gbé orí gbogbo ilẹ̀ ayé. 36 (I)Ǹjẹ́ kì ẹ máa ṣọ́nà, kí ẹ sì máa gbàdúrà nígbà gbogbo, kí ẹ ba à lè la gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí yóò ṣẹlẹ̀, kí ẹ sì lè dúró níwájú Ọmọ Ènìyàn.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.