Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 148

148 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

Ẹ fi ìyìn fún Olúwa láti ọ̀run wá,
    Ẹ fi ìyìn fún un níbi gíga.
Ẹ fi ìyìn fún un,
    gbogbo ẹ̀yin angẹli rẹ̀
Ẹ fi ìyìn fún un,
    gbogbo ẹ̀yin ọmọ-ogun rẹ̀
Ẹ fi ìyìn fún un,
    oòrùn àti òṣùpá
Ẹ fi ìyìn fún un,
    gbogbo ẹ̀yin ìràwọ̀ ìmọ́lẹ̀.
Ẹ fi ìyìn fún un,
    ẹ̀yin ọ̀run àti àwọn ọ̀run gíga
    àti ẹ̀yin omi tí ń bẹ ní òkè ọ̀run.

Ẹ jẹ́ kí wọn kí ó yin orúkọ Olúwa
    nítorí ó pàṣẹ a sì dá wọn
Ó fi ìdí wọn múlẹ̀ láé àti láéláé
    ó sì ti ṣe ìlànà kan tí kì yóò já.

Ẹ yin Olúwa láti ilẹ̀ ayé wá
    ẹ̀yin ẹ̀dá inú Òkun títóbi
    àti ẹ̀yin ibú Òkun
Mọ̀nàmọ́ná àti òjò yìnyín
    ìdí omi àti àwọn ìkùùkuu,
    ìjì líle tí ń mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ;
Òkè ńlá àti gbogbo òkè kéékèèkéé,
    igi eléso àti gbogbo igi kedari,
10 Àwọn ẹranko ńlá àti ẹran ọ̀sìn
    gbogbo ohun afàyàfà àti àwọn ẹyẹ abìyẹ́:
11 Àwọn ọba ayé àti ènìyàn ayé gbogbo
    àwọn ọmọ-aládé àti gbogbo àwọn onídàájọ́ ayé,
12 Ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin
    àwọn arúgbó àti àwọn ọmọdé.

13 Ẹ jẹ́ kí wọn kí ó yin orúkọ Olúwa
    nítorí orúkọ rẹ̀ nìkan ni ó ní ọlá
    ògo rẹ̀ kọjá ayé àti ọ̀run
14 Ó sì gbé ìwo kan sókè fún àwọn ènìyàn rẹ̀,
    ìyìn fún gbogbo ènìyàn mímọ́ rẹ̀ àní fún àwọn ọmọ Israẹli,
    àwọn ènìyàn tí ó súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀.

Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

Isaiah 54:1-13

Ògo ọjọ́ iwájú ti Sioni

54 (A)“Kọrin, ìwọ obìnrin àgàn,
    ìwọ tí kò tí ì bímọ rí;
bú sí orin, ẹ hó fún ayọ̀,
    ẹ̀yin tí kò tí ì rọbí rí;
nítorí pé púpọ̀ ni ọmọ àwọn obìnrin ìsọdahoro
    ju ti ẹni tí ó ní ọkọ,”
    ni Olúwa wí.
Fẹ ibi àgọ́ rẹ lójú sí i,
    fẹ aṣọ àgọ́ rẹ kí ó gbòòrò sí i,
má ṣe dá a dúró;
    sọ okùn rẹ di gígùn,
    mú òpó rẹ lágbára sí i.
Nítorí ìwọ ó fẹ̀ sọ́tùn àti sí òsì;
    ìrandíran rẹ yóò jogún àwọn orílẹ̀-èdè,
    wọn yóò sì dó sí ahoro àwọn ìlú wọn.

“Má ṣe bẹ̀rù, ìtìjú kò ní ṣubú lù ọ́.
    Má ṣe bẹ̀rù ìdójútì, a kì yóò kàn ọ́ lábùkù.
Ìwọ yóò gbàgbé ìtìjú ìgbà èwe e rẹ
    Ìwọ kì yóò sì rántí ẹ̀gàn ìgba-opo rẹ mọ́.
Nítorí Ẹlẹ́dàá rẹ ni ọkọ rẹ
    Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀
Ẹni Mímọ́ Israẹli ni Olùràpadà rẹ;
    a sì ń pè é ní Ọlọ́run gbogbo ayé.
Olúwa yóò pè ọ́ padà
    àfi bí ẹni pé obìnrin tí a kọ̀sílẹ̀
tí a sì bà lọ́kàn jẹ́
    obìnrin tí a fẹ́ ní ọ̀dọ́,
    tí a sì wá jákulẹ̀” ni Olúwa wí.
“Fún ìgbà díẹ̀ ni mo kọ̀ ọ́ sílẹ̀,
    ṣùgbọ́n pẹ̀lú ọkàn ìyọ́nú èmi yóò
    mú ọ padà wá.
Ní ríru ìbínú.
    Mo fi ojú pamọ́ fún ọ fún ìṣẹ́jú kan,
ṣùgbọ́n pẹ̀lú àánú àìnípẹ̀kun
    Èmi yóò ṣíjú àánú wò ọ́,”
    ni Olúwa Olùdáǹdè rẹ wí.

“Sí mi, èyí dàbí i àwọn ọjọ́ Noa,
    nígbà tí mo búra pé àwọn omi
Noa kì yóò tún bo ilẹ̀ ayé mọ́.
    Bẹ́ẹ̀ ni nísinsin yìí mo ti búra láti má ṣe bínú sí ọ,
    bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò bá ọ wí mọ́.
10 Bí a tilẹ̀ mi àwọn òkè ńlá
    tí a sì ṣí àwọn òkè kékeré nídìí,
Síbẹ̀síbẹ̀ ìfẹ́ àìkùnà mi fún ọ kì yóò yẹ̀ láéláé
    tàbí májẹ̀mú àlàáfíà ni a ó mú kúrò,”
    ni Olúwa, ẹni tí ó ṣíjú àánú wò ọ́ wí.

11 (B)Ìwọ ìlú tí a pọ́n lójú, tí ìjì ń gbá kiri
    tí a kò sì tù nínú,
Èmi yóò fi òkúta Tikuosi kọ́ ọ
    àti ìpìlẹ̀ rẹ pẹ̀lú safire.
12 Èmi yóò fi iyùn ṣe odi rẹ,
    àwọn ẹnu-ọ̀nà ni a ó fi ohun èlò dáradára fún,
    àti àwọn ògiri rẹ pẹ̀lú òkúta iyebíye.
13 (C)Gbogbo ọ̀dọ́mọkùnrin rẹ ni Olúwa yóò kọ́,
    àlàáfíà àwọn ọmọ rẹ yóò jẹ́ ńlá àti púpọ̀.

Ìfihàn 21:1-7

Jerusalẹmu tuntun

21 (A)Mo sì rí ọ̀run tuntun kan àti ayé tuntun kan: nítorí pé ọ̀run ti ìṣáájú àti ayé ìṣáájú ti kọjá lọ; Òkun kò sì ṣí mọ́. (B)Mo sì rí ìlú mímọ́, Jerusalẹmu tuntun ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, tí a ti múra sílẹ̀ bí ìyàwó tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ fún ọkọ rẹ̀. (C)Mo sì gbọ́ ohùn ńlá kan láti orí ìtẹ́ náà wá, ń wí pé, “Kíyèsi i, àgọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú àwọn ènìyàn, òun ó sì máa bá wọn gbé, wọn ó sì máa jẹ́ ènìyàn rẹ̀, àti Ọlọ́run tìkára rẹ̀ yóò wà pẹ̀lú wọn, yóò sì máa jẹ́ Ọlọ́run wọn. (D)Ọlọ́run yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ni ojú wọn; kì yóò sì ṣí ikú mọ́, tàbí ọ̀fọ̀, tàbí ẹkún, bẹ́ẹ̀ ni kí yóò sí ìrora mọ́: nítorí pé ohun àtijọ́ tí kọjá lọ.”

(E)Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ náà, sì wí pé, “Kíyèsi i, mo sọ ohun gbogbo di ọ̀tun!” Ó sì wí fún mi pé, “Kọ̀wé rẹ̀: Nítorí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí òdodo àti òtítọ́ ni wọ́n.”

(F)Ó sì wí fún mi pé, “Ó parí. Èmi ni Alfa àti Omega, ìpilẹ̀ṣẹ̀ àti òpin. Èmi ó sì fi omi fún ẹni tí òùngbẹ ń gbẹ láti inú orísun omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́. (G)Ẹni tí ó ba ṣẹ́gun ni yóò jogún nǹkan wọ̀nyí; èmi ó sì máa jẹ́ Ọlọ́run rẹ̀, òun ó sì máa jẹ ọmọ mi.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.