Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
14 Kọrin, ìwọ ọmọbìnrin Sioni,
kígbe sókè, ìwọ Israẹli!
Fi gbogbo ọkàn yọ̀, kí inú rẹ kí ó sì dùn,
ìwọ ọmọbìnrin Jerusalẹmu.
15 Olúwa ti mú ìdájọ́ rẹ wọ̀n-ọn-nì
kúrò, ó sì ti ti àwọn ọ̀tá rẹ padà sẹ́yìn.
Olúwa, ọba Israẹli wà pẹ̀lú rẹ,
Ìwọ kì yóò sì bẹ̀rù ibi kan mọ́.
16 Ní ọjọ́ náà, wọn yóò sọ fún Jerusalẹmu pé,
“Má ṣe bẹ̀rù Sioni;
má sì ṣe jẹ́ kí ọwọ́ rẹ kí ó dẹ̀.
17 Olúwa Ọlọ́run rẹ wà pẹ̀lú rẹ,
Ó ní agbára láti gbà ọ là.
Yóò yọ̀ ni orí rẹ fún ayọ̀;
Yóò tún ọ ṣe nínú ìfẹ́ rẹ̀,
Yóò sì fi orin yọ̀ ní orí rẹ.”
18 “Èmi ó kó àwọn tí ó ń banújẹ́ fún àjọ̀dún tí a yàn jọ,
àwọn tí ó jẹ́ tirẹ̀;
àwọn tí ẹ̀gàn rẹ̀ jásí ẹ̀rù.
19 Ní àkókò náà
ni èmi yóò dojúkọ àwọn
tí ń ni yín lára,
èmi yóò gba àtiro là,
èmi yóò sì ṣa àwọn tí ó ti fọ́nká jọ,
èmi yóò fi ìyìn àti ọlá fún wọn ní
gbogbo ilẹ̀ tí a bá ti dójútì wọ́n.
20 Ní àkókò náà ni èmi yóò ṣà yín jọ;
Nígbà náà ni èmi yóò mú un yín padà wá sílé.
Èmi yóò fi ọlá àti ìyìn fún un yín
láàrín gbogbo ènìyàn àgbáyé,
nígbà tí èmi yóò yí ìgbèkùn yín
padà bọ sípò ní ojú ara yín,”
ni Olúwa wí.
2 Nítòótọ́ Ọlọ́run ni ìgbàlà mi,
èmi yóò gbẹ́kẹ̀lé e èmi kì yóò bẹ̀rù.
Olúwa, Olúwa náà ni agbára à mi àti orin ìn mi,
òun ti di ìgbàlà mi.”
3 Pẹ̀lú ayọ̀ ni ìwọ yóò máa pọn omi
láti inú kànga ìgbàlà.
4 Ní ọjọ́ náà, ìwọ yóò wí pé:
“Fi ọpẹ́ fún Olúwa, ké pe orúkọ rẹ̀,
Jẹ́ kí ó di mí mọ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè,
ohun tí ó ti ṣe
kí o sì kéde pé a ti gbé
orúkọ rẹ̀ ga.
5 Kọ orin sí Olúwa, nítorí ó ti ṣe ohun tí ó lógo,
jẹ́ kí èyí di mí mọ̀ fún gbogbo ayé.
6 Kígbe sókè kí o sì kọrin fún ayọ̀, ẹ̀yin ènìyàn Sioni,
nítorí títóbi ni ẹni mímọ́ kan ṣoṣo
ti Israẹli láàrín yín.”
4 Ẹ máa yọ̀ nínú Olúwa nígbà gbogbo: mo sì tún wí pé. Ẹ máa yọ̀. 5 Ẹ jẹ́ ki ìpamọ́ra yín di mímọ́ fún gbogbo ènìyàn, Olúwa ń bẹ nítòsí. 6 (A)Ẹ má ṣe ṣe àníyàn ohunkóhun; ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo, nípa àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́, ẹ máa fi ìbéèrè yín hàn fún Ọlọ́run. 7 Àti àlàáfíà Ọlọ́run, tí ó ju ìmòye gbogbo lọ, yóò pa ọkàn àti èrò yín mọ nínú Kristi Jesu.
7 (A)Nígbà náà ni ó wí fún ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn tí ó wá láti ṣe ìtẹ̀bọmi lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Ẹ̀yin ìran paramọ́lẹ̀, ta ni ó kìlọ̀ fún un yín láti sá kúrò nínú ìbínú tí ń bọ̀? 8 (B)Nítorí náà kí ẹ̀yin kí ó so èso tí ó yẹ fún ìrònúpìwàdà, kí ẹ má sì ṣe sí í wí nínú ara yín pé, ‘Àwa ní Abrahamu ní baba.’ Kí èmi kí ó wí fún un yín, Ọlọ́run lè gbé ọmọ dìde fún Abrahamu nínú òkúta wọ̀nyí. 9 (C)Àti nísinsin yìí pẹ̀lú, a fi àáké lé gbòǹgbò igi náà: gbogbo igi tí kò bá so èso rere, a óò ge lulẹ̀, a sì wọ jù sínú iná.”
10 Àwọn ènìyàn sì ń bi í pé, “Kí ni kí àwa kí ó ṣe?”
11 Ó dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Ẹni tí ó bá ní ẹ̀wù méjì, kí ó fi ọ̀kan fún ẹni tí kò ní; ẹni tí ó bá sì ní oúnjẹ, kí ó ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú.”
12 Àwọn agbowó òde sì tọ̀ ọ́ wá láti ṣe ìtẹ̀bọmi lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì bi í pé, “Olùkọ́, kí ni àwa ó ha ṣe?”
13 Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe fi agbára gbà jù bí a ti rán yín lọ mọ́.”
14 Àwọn ọmọ-ogun sì béèrè lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Àti àwa, kí ni àwa ó ṣe?”
Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe hùwà ipá sí ẹnikẹ́ni, kí ẹ má sì ṣe ka ẹ̀sùn èké sí ẹnikẹ́ni; kí òwò ọ̀yà yín tó yín.”
15 (D)Bí àwọn ènìyàn sì ti ń retí, tí gbogbo wọn sì ń rò nínú ara wọn nítorí Johanu, bí òun ni Kristi tàbí òun kọ́; 16 (E)Johanu dáhùn ó sì wí fún gbogbo wọn pé, “Lóòótọ́ ni èmi ń fi omi bamitiisi yín; ṣùgbọ́n ẹni tí ó lágbára jù mí lọ ń bọ̀, okùn bàtà ẹsẹ̀ ẹni tí èmi kò tó tú: òun ni yóò fi Ẹ̀mí Mímọ́ àti iná bamitiisi yín: 17 Ẹni tí àtẹ rẹ̀ ń bẹ ní ọwọ́ rẹ̀, láti gbá ilẹ̀ ìpakà rẹ̀ mọ́ tó tó, kí ó sì kó alikama rẹ̀ sínú àká; ṣùgbọ́n ìyàngbò ni yóò fi iná àjóòkú sun.” 18 Johanu lo oríṣìíríṣìí ọ̀rọ̀ púpọ̀ láti gba àwọn ènìyàn níyànjú àti láti wàásù ìhìnrere fún wọn.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.