Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 126

Orin fún ìgòkè.

126 Nígbà tí Olúwa mú ìkólọ Sioni padà,
    àwa dàbí ẹni tí ó ń lá àlá.
Nígbà náà ni ẹnu wa kún fún ẹ̀rín,
    àti ahọ́n wa kọ orin;
nígbà náà ni wọ́n wí nínú àwọn kèfèrí pé,
    Olúwa ṣe ohun ńlá fún wọn.
Olúwa ṣe ohun ńlá fún wa;
    nítorí náà àwa ń yọ̀.

Olúwa mú ìkólọ wa padà,
    bí ìṣàn omi ní gúúsù.
Àwọn tí ń fi omijé fún irúgbìn
    yóò fi ayọ̀ ka.
Ẹni tí ń fi ẹkún rìn lọ,
    tí ó sì gbé irúgbìn lọ́wọ́,
lóòtítọ́, yóò fi ayọ̀ padà wá,
    yóò sì ru ìtí rẹ̀.

Isaiah 19:18-25

18 Ní ọjọ́ náà ìlú márùn-ún ní ilẹ̀ Ejibiti yóò sọ èdè àwọn ará Kenaani, wọn yóò sì búra àtìlẹ́yìn fún Olúwa àwọn ọmọ-ogun. Ọ̀kan nínú wọn ni a ó sì máa pè ní ìlú ìparun.

19 Ní ọjọ́ náà pẹpẹ kan yóò wà fún Olúwa ní àárín gbùngbùn Ejibiti, àti ọ̀wọ́n kan fún Olúwa ní etí bodè rẹ̀. 20 Yóò sì jẹ́ ààmì àti ẹ̀rí sí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ní ilẹ̀ Ejibiti. Nígbà tí wọ́n bá ké pe Olúwa nítorí àwọn aninilára wọn, yóò rán olùgbàlà àti olùgbèjà kan sí wọn tí yóò sì gbà wọ́n sílẹ̀. 21 Báyìí ni Olúwa yóò sọ ara rẹ̀ di mí mọ̀ fún àwọn ará Ejibiti àti ní ọjọ́ náà ni wọn yóò gba Olúwa gbọ́. Wọn yóò sìn ín pẹ̀lú ẹbọ ọrẹ ìyẹ̀fun, wọn yóò jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Olúwa wọn yóò sì mú un ṣẹ. 22 Olúwa yóò fi àjàkálẹ̀-ààrùn kan bá Ejibiti jà; yóò bá wọn jà yóò sì tún wò wọ́n sàn. Wọn yóò yípadà sí Olúwa, Òun yóò sì gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wọn yóò sì wò wọ́n sàn.

23 Ní ọjọ́ náà òpópónà kan yóò wá láti Ejibiti lọ sí Asiria. Àwọn ará Asiria yóò lọ sí Ejibiti àti àwọn ará Ejibiti lọ sí Asiria. Àwọn ará Ejibiti àti ará Asiria yóò jọ́sìn papọ̀. 24 Ní ọjọ́ náà Israẹli yóò di ẹ̀kẹta pẹ̀lú Ejibiti àti Asiria, àní orísun ìbùkún ní ilẹ̀ ayé. 25 Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò bùkún wọn yóò wí pé, “Ìbùkún ni fún Ejibiti ènìyàn mi, Asiria iṣẹ́ ọwọ́ mi, àti Israẹli ìní mi.”

2 Peteru 1:2-15

Kí oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà máa bí sí i fún yín nínú ìmọ̀ Ọlọ́run àti ti Jesu Olúwa wa.

Mímú kí ìpè àti yíyàn ẹni dájú

Bí agbára rẹ̀ bí Ọlọ́run ti fún wa ní ohun gbogbo tí a nílò fún ṣe ti ìyè àti ti ìwà-bí-Ọlọ́run, nípa ìmọ̀ ẹni tí ó pè wá nípa Ògo àti ìṣeun rẹ̀. Nípa èyí tí ó fi àwọn ìlérí rẹ̀ tí ó tóbi púpọ̀ tí ó ṣe iyebíye fún wa: pé nípa ìwọ̀nyí ni kí ẹ̀yin lè di alábápín nínú àbùdá ti Ọlọ́run, nígbà tí ẹ̀yin bá ti yọ kúrò nínú ìbàjẹ́ tí ó ń bẹ nínú ayé nípa ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́.

Àti nítorí ìdí èyí, ẹ máa ṣe àìsimi gbogbo, ẹ fi ìwà rere kún ìgbàgbọ́, àti ìmọ̀ kún ìwà rere; àti àìrékọjá kún ìmọ̀; àti sùúrù kún àìrékọjá; àti ìwà-bí-Ọlọ́run kún sùúrù. Àti ìfẹ́ ọmọnìkejì kún ìwà-bí-Ọlọ́run; àti ìfẹ́ni kún ìfẹ́ ọmọnìkejì. Nítorí bí ẹ̀yin bá ní nǹkan wọ̀nyí tí wọ́n bá sì pọ̀, wọn kì yóò jẹ́ kí ẹ ṣe ọ̀lẹ tàbí aláìléso nínú ìmọ̀ Olúwa wa Jesu Kristi. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ṣe aláìní nǹkan wọ̀nyí, kò lè ríran ní òkèèrè, ó fọjú, ó sì ti gbàgbé pé a ti wẹ òun nù kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ àtijọ́.

10 Nítorí náà, ará ẹ túbọ̀ máa ṣe àìsimi láti sọ ìpè àti yíyàn yín di dájúdájú: nítorí bí ẹ̀yin bá ń ṣe nǹkan wọ̀nyí, ẹ̀yin kì yóò ṣubú. 11 Nítorí báyìí ni a ó pèsè fún yín lọ́pọ̀lọpọ̀ láti wọ ìjọba àìnípẹ̀kun ti Olúwa àti Olùgbàlà wa Jesu Kristi.

Àsọtẹ́lẹ̀ ti ọrọ̀ Ọlọ́run

12 Nítorí náà, èmi ó máa rán yin létí àwọn nǹkan wọ̀nyí nígbà gbogbo, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀yin ti mọ̀ wọ́n, tí ẹsẹ̀ yín sì múlẹ̀ nínú òtítọ́ tí ẹ ní báyìí. 13 Èmi sì rò pé ó tọ́ láti máa mú wọn wá sí ìrántí yín, níwọ̀n ìgbà tí èmí ba ń bẹ nínú àgọ́ ara yìí. 14 Bí èmi ti mọ̀ pé, bíbọ́ àgọ́ ara mi yìí sílẹ̀ kù sí dẹ̀dẹ̀, àní, bí Olúwa wa Jesu Kristi ti fihàn mí. 15 Èmi ó sì máa ṣaápọn pẹ̀lú, kí ẹ̀yin lè máa rántí nǹkan wọ̀nyí nígbà gbogbo lẹ́yìn ikú mi.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.