Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 25:1-10

Ti Dafidi.

25 Olúwa,
    ìwọ ni mo gbé ọkàn mi sókè sí.

Ọlọ́run, èmi gbẹ́kẹ̀lé ọ;
    Má ṣe jẹ́ kí ojú ó tì mí
    Má ṣe jẹ́ kí àwọn ọ̀tá mi ó yọ̀ mí.
Ẹni tí ó dúró tì ọ́
    ojú kì yóò tì í,
àwọn tí ń ṣẹ̀ láìnídìí
    ni kí ojú kí ó tì.

Fi ọ̀nà rẹ hàn mí, Olúwa,
    kọ mi ní ipa tìrẹ;
ṣe amọ̀nà mi nínú òtítọ́ ọ̀ rẹ, kí o sì kọ́ mi,
    Nítorí ìwọ ni Ọlọ́run ìgbàlà mi;
    ìwọ ni mo dúró tì ní gbogbo ọjọ́.
Rántí, Olúwa àánú àti ìfẹ́ ẹ̀ rẹ̀ ńlá,
    torí pé wọ́n ti wà ní ìgbà àtijọ́
Má ṣe rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ìgbà èwe mi
    tàbí ìrékọjá mi;
gẹ́gẹ́ bí i ìfẹ́ ẹ rẹ̀ rántí mi
    nítorí tí ìwọ dára, Ìwọ! Olúwa.

Rere àti ẹni ìdúró ṣinṣin ní Olúwa:
    nítorí náà, ó kọ́ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ni ọ̀nà náà.
Ó ṣe amọ̀nà àwọn onírẹ̀lẹ̀ ni ohun tí ó dára,
    ó sì kọ́ àwọn onírẹ̀lẹ̀ ní ọ̀nà rẹ̀.
10 Gbogbo ipa ọ̀nà Olúwa ni ìfẹ́ àti òdodo tí ó dúró ṣinṣin,
    fún àwọn tí ó pa májẹ̀mú àti ẹ̀rí rẹ̀ mọ́.

Nehemiah 9:26-31

26 “Ṣùgbọ́n wọ́n ṣe àìgbọ́ràn, wọ́n sì ṣọ̀tẹ̀ sí ọ; wọ́n gbàgbé òfin rẹ. Wọ́n pa àwọn wòlíì rẹ, tí o fi gbà wọn ni ìyànjú pé kí wọn yí padà sí ọ; wọ́n sì se ọ̀rọ̀-òdì tí ó burú jàì. 27 Nítorí náà, ìwọ fi wọ́n lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́, àwọn tí ó ni wọ́n lára. Ṣùgbọ́n nígbà tí a ni wọ́n lára wọ́n kígbe sí ọ. Ìwọ gbọ́ wọn láti ọ̀run wá àti nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àánú rẹ, ìwọ fún wọn ní olùgbàlà, tí ó gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn.

28 “Ṣùgbọ́n bí wọ́n bá ti wà nínú ìsinmi, wọn a sì túnṣe búburú lójú rẹ. Nígbà náà ni ìwọ kọ̀ wọ́n sílẹ̀ ṣọ́wọ́ àwọn ọ̀tá kí wọ́n lè jẹ ọba lórí wọn. Nígbà tí wọ́n bá sì tún kígbe sí ọ, ìwọ a gbọ́ láti ọ̀run wá, àti nínú àánú rẹ ni ìwọ gbà láti ìgbà dé ìgbà.

29 “Ìwọ kìlọ̀ fún wọn láti padà sínú òfin rẹ, ṣùgbọ́n wọ́n hu ìwà ìgbéraga, wọ́n sì ṣe àìgbọ́ràn si àṣẹ rẹ. Wọ́n ṣẹ̀ sí ìlànà rẹ, nípa èyí tí ènìyàn yóò yè tí wọ́n bá pa wọ́n mọ́. Nínú agídí ọkàn wọ́n kọ ẹ̀yìn sí ọ, wọ́n jẹ́ olórí kunkun wọn kò sì fẹ́ gbọ́. 30 Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ni ìwọ fi ní sùúrù pẹ̀lú wọn. Nípa ẹ̀mí rẹ ni ìwọ kìlọ̀ fún wọn nípasẹ̀ àwọn wòlíì. Síbẹ̀ wọn kò fi etí sílẹ̀, nítorí náà ni ìwọ ṣe fi wọ́n lé àwọn aládùúgbò wọn lọ́wọ́. 31 Ṣùgbọ́n nínú ọ̀pọ̀ àánú rẹ, ìwọ kò mú òpin bá wọn tàbí kọ̀ wọ́n sílẹ̀, nítorí ìwọ ni Ọlọ́run olóore-ọ̀fẹ́ àti aláàánú.

Luku 21:20-24

20 (A)“Nígbà tí ẹ̀yin bá sì rí ti a fi ogun yí Jerusalẹmu ká, ẹ mọ̀ nígbà náà pé, ìsọdahoro rẹ̀ kù sí dẹ̀dẹ̀. 21 Nígbà náà ni kí àwọn tí ń bẹ ní Judea sálọ sórí òkè; àti àwọn tí ń bẹ láàrín rẹ̀ kí wọn jáde kúrò; kí àwọn tí ó sì ń bọ̀ ní ìgbèríko má ṣe wọ inú rẹ̀ wá. 22 Nítorí ọjọ́ ẹ̀san ni ọjọ́ wọ̀nyí, kì a lè mú ohun gbogbo tí a ti kọ̀wé rẹ̀ ṣẹ. 23 (B)Ṣùgbọ́n ègbé ni fún àwọn tí ó lóyún, àti àwọn tí ó fi ọyàn fún ọmọ mu ní ọjọ́ wọ̀nyí! Nítorí tí ìpọ́njú púpọ̀ yóò wà lórí ilẹ̀ àti ìbínú sí àwọn ènìyàn wọ̀nyí. 24 (C)Wọn ó sì ti ojú idà ṣubú, a ó sì dìwọ́n ní ìgbèkùn lọ sí orílẹ̀-èdè gbogbo; Jerusalẹmu yóò sì di ìtẹ̀mọ́lẹ̀ lẹ́sẹ̀ àwọn aláìkọlà, títí àkókò àwọn aláìkọlà yóò fi kún.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.