Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Saamu ti Dafidi. Nígbà ti ó sá fún ọmọ rẹ̀ Absalomu.
3 Olúwa, báwo ni àwọn ọ̀tá mi ṣe pọ̀ tó báyìí!
Báwo ni àwọn ti ó dìde sí mi ṣe pọ̀ tó!
2 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó ń sọ ní ti tèmi, pé
“Ọlọ́run kò nígbà á là.” Sela.
3 Ṣùgbọ́n ìwọ ni asà yí mi ká, Olúwa;
ìwọ fi ògo fún mi, ìwọ sì gbé orí mi sókè.
4 Olúwa ni mo kígbe sókè sí,
ó sì dá mi lóhùn láti orí òkè mímọ́ rẹ̀ wá. Sela.
5 Èmi dùbúlẹ̀, mo sì sùn;
mo sì tún padà jí, nítorí Olúwa ni ó ń gbé mi ró.
6 Èmi kì yóò bẹ̀rù ẹgbẹgbẹ̀rún ènìyàn
tí wọ́n rọ̀gbà yí mi ká.
7 Dìde, Olúwa!
Gbà mí, Ọlọ́run mi!
Lu gbogbo àwọn ọ̀tá mi ní àgbọ̀n;
kí o sì ká eyín àwọn ènìyàn búburú.
8 Láti ọ̀dọ̀ Olúwa ni ìgbàlà ti wá.
Kí ìbùkún rẹ wà lórí àwọn ènìyàn rẹ. Sela.
Àdúrà Solomoni fún ìyàsímímọ́
22 Solomoni sì dúró níwájú pẹpẹ Olúwa, níwájú gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli, ó sì na ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì sókè ọ̀run. 23 Ó sì wí pé:
“Olúwa Ọlọ́run Israẹli, kò sí Ọlọ́run tí ó dàbí rẹ lókè ọ̀run tàbí ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀ ìwọ tí ó pa májẹ̀mú àti àánú mọ́ pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ rẹ tí ń fi gbogbo ọkàn wọn rìn níwájú rẹ. 24 O sì ti pa ìlérí rẹ mọ́ fún ìránṣẹ́ rẹ Dafidi baba mi; pẹ̀lú ẹnu rẹ ni ìwọ ṣe ìlérí, o sì mú u ṣẹ pẹ̀lú ọwọ́ rẹ, bí ó ti rí lónìí.
25 “Ǹjẹ́ báyìí Olúwa Ọlọ́run Israẹli, bá ìránṣẹ́ rẹ̀ Dafidi baba mi pa ohun tí ìwọ ti ṣe ìlérí fún un mọ́ wí pé, ìwọ kì yóò kùnà láti ní ènìyàn kan láti jókòó níwájú mi lórí ìtẹ́ Israẹli, kìkì bí àwọn ọmọ rẹ bá lè kíyèsi ohun tí wọ́n ń ṣe láti máa rìn níwájú mi bí ìwọ ti rìn. 26 Ǹjẹ́ báyìí, Ọlọ́run Israẹli, jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ tí o ti ṣe ìlérí fún ìránṣẹ́ rẹ̀ Dafidi baba mi wá sí ìmúṣẹ.
27 “Ṣùgbọ́n nítòótọ́, Ọlọ́run yóò máa gbé ayé bí? Ọ̀run àti ọ̀run àwọn ọ̀run kò le gbà ọ́. Kí a má sọ pé ilé yìí tí mo kọ́ fún ọ! 28 Síbẹ̀ ṣe ìfetísílẹ̀ àdúrà ìránṣẹ́ rẹ àti ẹ̀bẹ̀ rẹ fún àánú, Olúwa Ọlọ́run mi. Gbọ́ ẹkún àti àdúrà tí ìránṣẹ́ rẹ̀ ń gbà níwájú rẹ lónìí. 29 Jẹ́ kí ojú rẹ ṣí sí ilé yìí ní òru àti ní ọ̀sán, ibí yìí tí ìwọ ti wí pé, orúkọ mi yóò wà níbẹ̀, nítorí ìwọ yóò gbọ́ àdúrà tí ìránṣẹ́ rẹ gbà sí ibí yìí. 30 Gbọ́ ẹ̀bẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ àti ti Israẹli, ènìyàn rẹ nígbà tí wọ́n bá gbàdúrà sí ibí yìí. Gbọ́ láti ọ̀run wá láti ibùgbé rẹ, àti nígbà tí o bá gbọ́, dáríjì.
9 (A)“Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn nǹkan wọ̀nyí bá bẹ̀rẹ̀ sí i ṣẹlẹ̀, ẹ kíyèsára! Nítorí ẹ̀yin yóò wà nínú ewu. Wọn yóò fà yín lọ ilé ẹjọ́ gbogbo. Wọn yóò fi ìyà jẹ yín nínú Sinagọgu wọn. Àwọn ènìyàn yóò fẹ̀sùn kàn yín níwájú àwọn baálẹ̀ àti níwájú àwọn ọba nítorí orúkọ mi, fún ẹ̀rí fún wọn. 10 Nítorí pé ẹ gbọdọ̀ kọ́kọ́ wàásù ìhìnrere náà fún gbogbo orílẹ̀-èdè kí òpin tó dé. 11 (B)Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n bá ń fà yín lọ, tí wọ́n bá sì ń fi yín lé wọn lọ́wọ́, ẹ má ṣe ṣàníyàn ṣáájú ohun tí ẹ ó sọ. Ṣùgbọ́n ohun tí bá fi fún yín ní wákàtí náà, òun ni kí ẹ̀yin kí ó wí. Nítorí kì í ṣe ẹ̀yin ni ó ń wí, bí kò ṣe Ẹ̀mí Mímọ́.
12 “Arákùnrin yóò máa fi ẹ̀sùn kan arákùnrin rẹ̀, tí yóò sì yọrí sí ikú. Baba yóò máa ṣe ikú pa ọmọ rẹ̀. Àwọn ọmọ yóò máa dìtẹ̀ sí òbí wọn. Àní, àwọn ọmọ pẹ̀lú yóò máa ṣe ikú pa òbí wọn. 13 (C)Àwọn ènìyàn yóò kórìíra yín nítorí tí ẹ jẹ́ tèmi. Ṣùgbọ́n ẹni tó bá fi ara da ìyà títí dé òpin tí kò sì kọ̀ mí sílẹ̀ òun ni yóò rí ìgbàlà.
14 (D)“Ṣùgbọ́n nígba tí ẹ̀yin bá rí ìríra ìsọdahoro, tí ó dúró níbí tí kò yẹ, tí a tí ẹnu wòlíì Daniẹli sọ, (ẹnikẹ́ni tí ó bá kà á ki í ó yé e) nígbà náà ni kí àwọn tí ń bẹ ni Judea sálọ sí orí òkè. 15 Kí ẹni ti ń bẹ lórí ilé má ṣe sọ̀kalẹ̀ lọ sínú ilé, bẹ́ẹ̀ ni kí ó má sì ṣe wọ inú rẹ̀, láti mú ohunkóhun jáde nínú ilé rẹ̀. 16 Kí ẹni tí ó wà lóko má ṣe padà sẹ́yìn láti wá mú aṣọ rẹ̀. 17 (E)Ègbé ní fún àwọn tí ó lóyún, àti fún obìnrin tí ń fún ọ́mọ lọ́mú ní ọjọ́ wọ̀nyí. 18 Kí ẹ sì máa gbàdúrà pé èyí ṣẹlẹ̀ ní àkókò òtútù. 19 Nítorí ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì yóò jẹ́ àkókò ìpọ́njú, irú èyí tí kò ì ṣẹlẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ ẹ̀dá Ọlọ́run. Irú rẹ̀ kò sì ni ṣẹlẹ̀ mọ́.
20 “Àfi tí Olúwa bá gé àkókò ìjìyà náà kúrú, ẹyọ ẹ̀mí kan ní ayé kì yóò là. Ṣùgbọ́n nítorí àwọn tí Ọlọ́run yàn, ni yóò ṣe dín àwọn ọjọ́ náà kù. 21 Nígbà náà, bí ẹnikẹ́ni bá sọ fún un yín pé, ‘Ẹ wò ó, Kristi wa níbi yìí!’ tàbí, sọ fún un yín pé, ‘Ẹ wò ó, ó wà lọ́hùn ún nì!’ Ẹ má ṣe gbà wọ́n gbọ́. 22 (F)Nítorí àwọn èké Kristi àti àwọn wòlíì èké ni yóò wá, wọn yóò sì fi iṣẹ́ ìyanu tí yóò tan ènìyàn jẹ hàn. Bí ó bá ṣe é ṣe, wọn yóò tan àwọn àyànfẹ́ pàápàá jẹ. 23 Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra. Mo ti kìlọ̀ fún un yín ṣáájú tó!
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.