Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 3

Saamu ti Dafidi. Nígbà ti ó sá fún ọmọ rẹ̀ Absalomu.

Olúwa, báwo ni àwọn ọ̀tá mi ṣe pọ̀ tó báyìí!
    Báwo ni àwọn ti ó dìde sí mi ṣe pọ̀ tó!
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó ń sọ ní ti tèmi, pé
    “Ọlọ́run kò nígbà á là.” Sela.

Ṣùgbọ́n ìwọ ni asà yí mi ká, Olúwa;
    ìwọ fi ògo fún mi, ìwọ sì gbé orí mi sókè.
Olúwa ni mo kígbe sókè sí,
    ó sì dá mi lóhùn láti orí òkè mímọ́ rẹ̀ wá. Sela.

Èmi dùbúlẹ̀, mo sì sùn;
    mo sì tún padà jí, nítorí Olúwa ni ó ń gbé mi ró.
Èmi kì yóò bẹ̀rù ẹgbẹgbẹ̀rún ènìyàn
    tí wọ́n rọ̀gbà yí mi ká.

Dìde, Olúwa!
    Gbà mí, Ọlọ́run mi!
Lu gbogbo àwọn ọ̀tá mi ní àgbọ̀n;
    kí o sì ká eyín àwọn ènìyàn búburú.

Láti ọ̀dọ̀ Olúwa ni ìgbàlà ti wá.
    Kí ìbùkún rẹ wà lórí àwọn ènìyàn rẹ. Sela.

Deuteronomi 26:5-10

Nígbà náà ni ìwọ yóò sọ ní iwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ pé, “Baba mi jẹ́ alárìnkiri ará Aramu, ó sì sọ̀kalẹ̀ wá sí Ejibiti pẹ̀lú ènìyàn díẹ̀, ó sì ń gbé níbẹ̀, ó sì wá di orílẹ̀-èdè olókìkí, alágbára, tí ó kún fún ọ̀pọ̀ ènìyàn. Ṣùgbọ́n àwọn ará Ejibiti ṣe àìdára sí wa, wọ́n jẹ wá ní yà, wọ́n fún wa ní iṣẹ́ líle ṣe. Nígbà náà ni a kégbe pe Olúwa Ọlọ́run àwọn baba wa, Olúwa sì gbọ́ ohùn wa, ó sì rí ìrora, làálàá àti ìnira wa. Nígbà náà ni Olúwa mú wa jáde wá láti Ejibiti pẹ̀lú ọwọ́ agbára àti apá nínà, pẹ̀lú ẹ̀rù ńlá àti iṣẹ́ ààmì àti iṣẹ́ ìyanu. Ó mú wa wá síbí, ó sì fún wa ní ilẹ̀ yìí, ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin; 10 àti pé ní báyìí, mo mú àkọ́so ilẹ̀ tí ìwọ Olúwa ti fún mi wá.” Ìwọ yóò gbé agbọ̀n náà síwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ, kí o sì wólẹ̀ níwájú u rẹ̀.

Heberu 10:32-39

32 Ṣùgbọ́n ẹ rántí ọjọ́ ìṣáájú nínú èyí tí, nígbà tí a ti sí yin lójú, ẹ fi ara da wàhálà ńlá ti ìjìyà; 33 lápákan, nígbà tí a sọ yín di ìran wíwò nípa ẹ̀gàn àti ìpọ́njú; àti lápákan, nígbà tí ẹ̀yin di ẹgbẹ́ àwọn tí a ṣe bẹ́ẹ̀ si. 34 Nítorí ẹ̀yin bá àwọn tí ó wà nínú ìdè kẹ́dùn, ẹ sì fi ayọ̀ gba ìkólọ ẹrù yin, nítorí ẹ̀yin mọ nínú ara yin pé, ẹ ni ọrọ̀ tí ó wà títí, tí ó sì dára jù bẹ́ẹ̀ lọ. 35 Nítorí náà ẹ má ṣe gbé ìgboyà yín sọnù, èyí ti o ni èrè ńlá.

36 Nítorí ẹ̀yin kò le ṣe aláìní sùúrù, nítorí ìgbà tí ẹ̀yin bá ti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run tan kí ẹ̀yin le gba ìlérí náà. 37 (A)Nítorí,

“Ni ìwọ̀n ìgbà díẹ̀ sí i,
    ẹni náà ti ń bọ̀ yóò dé,
    kí yóò sì jáfara.

38 Ṣùgbọ́n,

“Olódodo ni yóò yè nípa ìgbàgbọ́.
    Ṣùgbọ́n bí o ba fàsẹ́yìn,
    ọkàn mi kò ní inú dídùn sí i.”

39 Ṣùgbọ́n àwa kò sí nínú àwọn tí ń fàsẹ́yìn sínú ègbé; bí kò ṣe nínú àwọn tí o gbàgbọ́ sí ìgbàlà ọkàn.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.