Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Rutu 3:1-5

Rutu àti Boasi ní ilẹ̀ ìpakà

Ní ọjọ́ kan, Naomi, ìyá ọkọ Rutu wí fún un pé, “Ọmọbìnrin mi, ǹjẹ́ kò yẹ kí èmi bá ọ wá ilé ọkọ mìíràn, níbi tí wọn yóò ti le è máa tọ́jú rẹ? Wò ó, Boasi ọkùnrin nì tí ìwọ bá àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ ṣiṣẹ́, tí í ṣe ìbátan wa, yóò wá láti fẹ́ ọkà barle ní ilẹ̀ ìpakà rẹ̀ ní àṣálẹ́ yìí. Wẹ̀, kí o sì fi ìpara olóòórùn dídùn pa ara rẹ, kí o sì wọ aṣọ rẹ tí ó dára jùlọ, kí o sì lọ sí ilẹ̀ ìpakà tí ó gbé ń pa ọkà, ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí ó mọ̀ pé o wà níbẹ̀ títí tí yóò fi jẹ tí yóò sì mu tán. Rí í dájú pé o mọ ibi tí ó sùn sí, lẹ́yìn ìgbà tí ó bá ti sùn, lọ kí o ṣí aṣọ ìbora rẹ̀ níbi ẹsẹ̀ rẹ̀ sókè kí o sì sùn sí ibi ẹsẹ̀ náà. Òun yóò sì sọ ohun tí ìwọ yóò ṣe fún ọ.”

Rutu sì fèsì pé, “Gbogbo ohun tí ìwọ sọ fún mi ni èmi yóò ṣe.”

Rutu 4:13-17

Èyí ni ìran Dafidi

13 Báyìí ni Boasi ṣe mú Rutu, tí ó sì di aya rẹ̀. Nígbà náà ni ó wọlé tọ aya rẹ̀, Olúwa sì mú kí ó lóyún, ó sì bí ọmọ ọkùnrin kan. 14 Àwọn obìnrin sì wí fún Naomi pé, “Ìyìn ni fún Olúwa tí kò fi ọ sílẹ̀ ní òní yìí láìní ìbátan, Olùràpadà. Kí ọmọ náà di olókìkí ní Israẹli. 15 Yóò tún ayé rẹ ṣe, yóò sì dáàbò bò ọ́ ní ọjọ́ ogbó rẹ. Nítorí pé ìyàwó ọmọ rẹ, èyí tí ó sàn fún ọ ju ọmọkùnrin méje lọ, tí ó sì fẹ́ràn rẹ ni ó bí ọmọ yìí fún.”

16 Naomi sì gbé ọmọ náà lé orí ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì ń tọ́jú rẹ̀. 17 Àwọn obìnrin àdúgbò sì wí pé, “A bí ọmọkùnrin kan fún Naomi.” Wọ́n sì pe orúkọ rẹ̀ ní Obedi. Òun sì ni baba Jese tí í ṣe baba Dafidi.

Saamu 127

Orin fún ìgòkè. Ti Solomoni.

127 Bí kò ṣe pé Olúwa bá kọ́ ilé náà
    àwọn tí ń kọ́ ọ ń ṣiṣẹ́ lásán ni;
    bí kò ṣe pé Olúwa bá pa ìlú mọ́, olùṣọ́ jí lásán.
Asán ni fún ẹ̀yin ti ẹ dìde ní kùtùkùtù
    láti pẹ́ dùbúlẹ̀, láti jẹ oúnjẹ làálàá;
    bẹ́ẹ̀ ni ó ń fi ìre fún olùfẹ́ rẹ̀ lójú ọ̀run.

Kíyèsi i, àwọn ọmọ ni ìní Olúwa:
    ọmọ inú sì ni èrè rẹ̀.
Bí ọfà ti rí ní ọwọ́ alágbára,
    bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ èwe
Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí apó rẹ̀ kún fún wọn;
    ojú kì yóò tì wọ́n,
    ṣùgbọ́n wọn yóò ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá ní ẹnu-ọ̀nà.

Heberu 9:24-28

24 Nítorí Kristi kò wọ ibi mímọ́ tí a fi ọwọ́ ṣe lọ tí i ṣe àpẹẹrẹ ti òtítọ́; ṣùgbọ́n ó lọ sí ọ̀run pàápàá, nísinsin yìí láti farahàn ní iwájú Ọlọ́run fún wa: 25 Kì í sí i ṣe pé kí ó lè máa fi ara rẹ̀ rú ẹbọ nígbàkúgbà, bí olórí àlùfáà tí máa ń wọ inú ibi mímọ́ lọ lọ́dọọdún ti òun pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ ti kì í ṣe tirẹ̀; 26 bí bẹ́ẹ̀ bá ni òun ìbá tí máa jìyà nígbàkúgbà láti ìpìlẹ̀ ayé: Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ni ó fi ara hàn lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo lópin ayé láti mu ẹ̀ṣẹ̀ kúrò nípa ẹbọ ara rẹ̀. 27 Níwọ́n bí a sì ti fi lélẹ̀ fún gbogbo ènìyàn láti kú lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, ṣùgbọ́n lẹ́yìn èyí ìdájọ́: 28 Bẹ́ẹ̀ ni Kristi pẹ̀lú lẹ́yìn tí a ti fi rú ẹbọ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láti ru ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀, yóò farahàn ní ìgbà kejì láìsí ẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn tí n wo ọ̀nà rẹ̀ fún ìgbàlà.

Marku 12:38-44

38 (A)Ó sì wí fún wọn nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ pé, “Ẹ ṣọ́ra fun àwọn olùkọ́ òfin tí wọ́n fẹ́ láti máa wọ aṣọ gígùn káàkiri, tí wọ́n sì fẹ́ ìkíni ní ọjà, 39 àti ibùjókòó ọlá nínú Sinagọgu àti ipò ọlá níbi àsè. 40 Àwọn tí wọ́n jẹ ilé àwọn opó rún, tí wọ́n sì ń gbàdúrà gígùn fún àṣehàn, nítorí èyí, ìjìyà wọn yóò pọ̀ púpọ̀.”

Ọ̀rẹ́ opó

41 (B)Jesu jókòó ní òdìkejì kọjú sí àpótí ìṣúra: ó ń wo ìjọ ènìyàn ti ń sọ owó sínú àpótí ìṣúra, ọ̀pọ̀ àwọn ọlọ́rọ̀ sì sọ púpọ̀ sí i. 42 Ṣùgbọ́n obìnrin opó kan wà, ó sì fi ààbọ̀ owó idẹ méjì síbẹ̀, tí ì ṣe ìdá méjì owó-babà kan sínú rẹ̀.

43 Jesu pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó sọ fún wọn wí pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yin pé, tálákà opó yìí sọ sínú àpótí ìṣúra ju gbogbo àwọn ìyókù to sọ sínú rẹ lọ. 44 Nítorí pé, àwọn ìyókù mú nínú ọ̀pọ̀ ìní wọ́n, ṣùgbọ́n ní tirẹ̀, nínú àìní rẹ̀, ó sọ gbogbo ohun tí ó ní náà sílẹ̀ àní gbogbo ìní rẹ̀.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.