Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 147:12-20

12 Yin Olúwa, ìwọ Jerusalẹmu
    yin Ọlọ́run rẹ, ìwọ Sioni.

13 Nítorí tí ó ti mú ọ̀pá ìdábùú ibodè rẹ̀ lágbára;
    Òun sì ti bùkún fún àwọn ọmọ rẹ̀ nínú rẹ
14 Òun jẹ́ kí àlàáfíà wà ní àwọn ẹnu ibodè rẹ̀
    òun sì fi jéró dáradára tẹ́ ọ lọ́rùn.

15 Òun sì rán àṣẹ rẹ̀ sí ayé
    ọ̀rọ̀ rẹ̀ sáré tete.
16 Ó fi yìnyín fún ni bi irun àgùntàn
    ó sì fọ́n ìrì dídì ká bí eérú
17 Ó rọ òjò yìnyín rẹ̀ bí òkúta wẹ́wẹ́
    ta ni ó lè dúró níwájú òtútù rẹ̀
18 Ó rán ọ̀rọ̀ rẹ̀ jáde ó sì mú wọn yọ̀
    ó mú kí afẹ́fẹ́ rẹ̀ fẹ́
    ó sì mú odò rẹ̀ sàn.

19 Ó sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ di mí mọ̀ fún Jakọbu
    àwọn òfin àti ìlànà rẹ̀ fún Israẹli
20 Òun kó tí ṣe irú èyí sí orílẹ̀-èdè kan rí, Bí ó ṣe ti ìdájọ́ rẹ̀
    wọn ko mọ òfin rẹ̀.

Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

Òwe 1:1-7

Èròǹgbà àti kókó-ọ̀rọ̀

Àwọn òwe ti Solomoni, ọmọ Dafidi, ọba Israẹli.

Láti le ní ọgbọ́n àti ẹ̀kọ́,
    Láti ní òye àwọn ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀.
Láti gba ẹ̀kọ́ ọgbọ́n, òdodo,
    àti ìdájọ́, àti àìṣègbè;
láti fi òye fún onírẹ̀lẹ̀,
    ìmọ̀ àti ìṣọ́ra fún àwọn èwe.
Jẹ́ kí ọlọ́gbọ́n tẹ́tí kí ó sì ní ìmọ̀ kún ìmọ̀,
    sì jẹ́ kí ẹni òye gba ìtọ́sọ́nà.
Láti mọ ìtumọ̀ òwe àti ìtán-dòwe,
    àwọn ọ̀rọ̀ àti àlọ́ àwọn ọlọ́gbọ́n.

Ìbẹ̀rù Olúwa ni ìbẹ̀rẹ̀ ìmọ̀,
    ṣùgbọ́n aláìgbọ́n kẹ́gàn ọgbọ́n àti ẹ̀kọ́.

Jakọbu 3:13-18

Oríṣìí ọgbọ́n méjì

13 Ta ni ó gbọ́n tí ó sì ní ìmọ̀ nínú yín? Ẹ jẹ́ kí ó fi iṣẹ́ rẹ̀ hàn nípa ìwà rere, nípa ìwà tútù ti ọgbọ́n. 14 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá ní owú kíkorò àti ìjà ní ọkàn yín, ẹ má ṣe ṣe féfé, ẹ má sì ṣèké sí òtítọ́. 15 Ọgbọ́n yìí kì í ṣe èyí tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, ṣùgbọ́n ti ayé ni, ti ara ni, ti ẹ̀mí èṣù ni. 16 Nítorí níbi tí owú òun ìjà bá gbé wà, níbẹ̀ ni rúdurùdu àti iṣẹ́ búburú gbogbo wà.

17 Ṣùgbọ́n ọgbọ́n tí ó ti òkè wá jẹ́ mímọ́ ní àkọ́kọ́, ti àlàáfíà, àti ti ìrẹ̀lẹ̀, kì í sì í ṣòro láti bẹ̀, ó kún fún àánú àti fún èso rere, kì í ṣe ojúsàájú, a sì máa sọ òtítọ́. 18 Àwọn tí ó ń ṣiṣẹ́ àlàáfíà a sì máa gbin èso àlàáfíà ní àlàáfíà.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.