Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Saamu ìyìn. Ti Dafidi.
145 Èmi yóò gbé ọ ga, Ọlọ́run ọba mi;
Èmi yóò yin orúkọ rẹ̀ láé àti láéláé
2 Ní ojoojúmọ́ èmi yóò yìn ọ́
èmi yóò sì pòkìkí orúkọ rẹ láé àti láéláé.
3 Títóbi ni Olúwa. Òun sì ni ó yẹ láti fi ìyìn fún púpọ̀púpọ̀:
kò sí ẹni tí ó lè wọn títóbi rẹ̀.
4 Ìran kan yóò máa yin iṣẹ́ rẹ dé ìran mìíràn;
wọn yóò máa sọ iṣẹ́ agbára rẹ
5 Wọn yóò máa sọ ìyìn ọláńlá rẹ tí ó lógo,
èmi yóò máa ṣe àṣàrò nínú iṣẹ́ ìyanu rẹ.
6 Wọn yóò sọ iṣẹ́ agbára rẹ tí ó ní ẹ̀rù
èmi yóò kéde iṣẹ́ ńlá rẹ̀.
7 Wọn yóò ṣe ìrántí ọ̀pọ̀lọpọ̀
ìwà rere rẹ àti orin ayọ̀ òdodo rẹ.
8 Olóore-ọ̀fẹ́ ni Olúwa àti aláàánú
ó lọ́ra láti bínú ó sì ní ìfẹ́ púpọ̀.
9 Olúwa dára sí ẹni gbogbo;
ó ní àánú lórí ohun gbogbo tí ó dá.
10 Gbogbo ohun tí ìwọ ti dá ni
yóò máa yìn ọ́ Olúwa;
àwọn ẹni mímọ́ yóò máa pòkìkí rẹ.
11 Wọn yóò sọ ògo ìjọba rẹ
wọn yóò sì sọ̀rọ̀ agbára rẹ,
12 Kí gbogbo ènìyàn le mọ iṣẹ́ agbára rẹ̀
àti ọláńlá ìjọba rẹ tí ó lógo.
13 Ìjọba rẹ ìjọba ayérayé ni,
àti ìjọba rẹ wà ní gbogbo ìrandíran.
14 Olúwa mú gbogbo àwọn tí ó ṣubú ró
ó sì gbé gbogbo àwọn tí ó tẹríba dìde.
15 Ojú gbogbo ènìyàn ń wò ọ́,
ó sì fún wọn ní oúnjẹ wọn ní àkókò tí ó yẹ
16 Ìwọ ṣí ọwọ́ rẹ
ìwọ sì tẹ́ ìfẹ́ gbogbo ohun alààyè lọ́rùn.
17 Olúwa jẹ́ olódodo ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀
àti ìfẹ́ rẹ̀ sí gbogbo ohun tí o dá.
18 Olúwa wà ní tòsí gbogbo àwọn tí ń ké pè é,
sí gbogbo ẹni tí ń ké pè é ní òtítọ́.
19 Ó mú ìfẹ́ àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ṣẹ;
ó gbọ́ igbe wọn, ó sì gbà wọ́n.
20 Olúwa dá gbogbo àwọn tí ó ní ìfẹ́ sẹ sí
ṣùgbọ́n gbogbo àwọn ẹni
búburú ní yóò parun.
21 Ẹnu mi yóò sọ̀rọ̀ ìyìn Olúwa.
Jẹ́ kí gbogbo ẹ̀dá yín orúkọ rẹ̀ mímọ́ láé àti láéláé.
Ògo ọjọ́ iwájú ti Sioni
54 (A)“Kọrin, ìwọ obìnrin àgàn,
ìwọ tí kò tí ì bímọ rí;
bú sí orin, ẹ hó fún ayọ̀,
ẹ̀yin tí kò tí ì rọbí rí;
nítorí pé púpọ̀ ni ọmọ àwọn obìnrin ìsọdahoro
ju ti ẹni tí ó ní ọkọ,”
ni Olúwa wí.
2 Fẹ ibi àgọ́ rẹ lójú sí i,
fẹ aṣọ àgọ́ rẹ kí ó gbòòrò sí i,
má ṣe dá a dúró;
sọ okùn rẹ di gígùn,
mú òpó rẹ lágbára sí i.
3 Nítorí ìwọ ó fẹ̀ sọ́tùn àti sí òsì;
ìrandíran rẹ yóò jogún àwọn orílẹ̀-èdè,
wọn yóò sì dó sí ahoro àwọn ìlú wọn.
4 “Má ṣe bẹ̀rù, ìtìjú kò ní ṣubú lù ọ́.
Má ṣe bẹ̀rù ìdójútì, a kì yóò kàn ọ́ lábùkù.
Ìwọ yóò gbàgbé ìtìjú ìgbà èwe e rẹ
Ìwọ kì yóò sì rántí ẹ̀gàn ìgba-opo rẹ mọ́.
5 Nítorí Ẹlẹ́dàá rẹ ni ọkọ rẹ
Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀
Ẹni Mímọ́ Israẹli ni Olùràpadà rẹ;
a sì ń pè é ní Ọlọ́run gbogbo ayé.
6 Olúwa yóò pè ọ́ padà
àfi bí ẹni pé obìnrin tí a kọ̀sílẹ̀
tí a sì bà lọ́kàn jẹ́
obìnrin tí a fẹ́ ní ọ̀dọ́,
tí a sì wá jákulẹ̀” ni Olúwa wí.
7 “Fún ìgbà díẹ̀ ni mo kọ̀ ọ́ sílẹ̀,
ṣùgbọ́n pẹ̀lú ọkàn ìyọ́nú èmi yóò
mú ọ padà wá.
8 Ní ríru ìbínú.
Mo fi ojú pamọ́ fún ọ fún ìṣẹ́jú kan,
ṣùgbọ́n pẹ̀lú àánú àìnípẹ̀kun
Èmi yóò ṣíjú àánú wò ọ́,”
ni Olúwa Olùdáǹdè rẹ wí.
Ẹ̀kọ́ nípa ìfẹ́
9 Kí ìfẹ́ kí ó wà ní àìṣẹ̀tàn. Ẹ máa takété sí ohun tí í ṣe búburú; ẹ fi ara mọ́ ohun tí í ṣe rere. 10 Ní ti ìfẹ́ ará, ẹ máa fi ìyọ́nú fẹ́ràn ara yín; ní ti ọlá, ẹ máa fi ẹnìkejì yín ṣáájú. 11 Ní ti iṣẹ́ ṣíṣe, ẹ má ṣe ọ̀lẹ; ẹ máa ní ìgbóná ọkàn; ẹ máa sìn Olúwa. 12 (A)Ẹ máa yọ̀ ni ìrètí; ẹ máa mú sùúrù nínú ìpọ́njú; ẹ máa dúró gbọingbọin nínú àdúrà. 13 Ẹ máa pèsè fún àìní àwọn ènìyàn mímọ́; ẹ fi ara yín fún àlejò ṣíṣe.
14 (B)Ẹ máa súre fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí yín; ẹ máa súre, ẹ má sì ṣépè. 15 Àwọn tí ń yọ̀, ẹ máa bá wọn yọ̀, àwọn tí ń sọkún, ẹ máa bá wọn sọkún. 16 (C)Ẹ máa wà ní inú kan náà sí ara yín. Ẹ má ṣe gbéraga, ṣùgbọ́n ẹ má tẹ̀lé àwọn onírẹ̀lẹ̀. Ẹ má ṣe jẹ́ ọlọ́gbọ́n ní ojú ara yín.
17 (D)Ẹ má ṣe fi búburú san búburú fún ẹnikẹ́ni. Ẹ má pèsè ohun tí ó tọ́ níwájú gbogbo ènìyàn. 18 (E)Bí ó bá sé é ṣe, bí ó ti wà ní ipa tiyín, ẹ má wà ní àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn. 19 (F)Olùfẹ́ mi ọ̀wọ́n, ẹ má ṣe gbẹ̀san ara yín, ṣùgbọ́n ẹ fi ààyè sílẹ̀ fún ìbínú Ọlọ́run; nítorí a ti kọ ọ́ pé, Olúwa wí pé, “Tèmi ni ẹ̀san, èmi ó gbẹ̀san.” 20 (G)Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀,
“Bí ebi bá ń pa ọ̀tá rẹ, fún un ní oúnjẹ;
bí òùngbẹ bá ń gbẹ ẹ́, fún un ní omi mu.
Ní ṣíṣe èyí, ìwọ ó kó ẹ̀yín iná lé e ní orí.”
21 Má ṣe jẹ́ kí búburú ṣẹ́gun rẹ, ṣùgbọ́n fi rere ṣẹ́gun búburú.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.