Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 106:1-12

106 (A)Yin Olúwa! Ẹ fi ìyìn fún
    Olúwa, nítorí tí ó ṣeun.

Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa nítorí tí ó ṣeun;
    Nítorí tí ìfẹ́ rẹ̀ dúró láéláé.

Ta ni ó lè ròyìn iṣẹ́ agbára Olúwa,
    ta ní lè sọ nípa ìyìn rẹ̀?
Ìbùkún ni fún àwọn tí ń pa ìdájọ́ mọ́?
    Ẹni tí n ṣe ohun tí ó tọ́.

Rántí mi, Olúwa,
    Nígbà tí o bá fi ojúrere rẹ hàn,
    wá sí ìhà mi nígbà tí ìwọ bá gbà wọ́n,
Kí èmi kí ó lè jẹ ìgbádùn àlàáfíà àwọn tí ìwọ ti yàn,
    kí èmi kí ó sì darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn,
    ìní rẹ láti jọ yìn ọ́ lógo.

Àwa ti dẹ́ṣẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wa ti ṣe,
    àwa ti ṣe ohun tí kò dá a,
    a sì ti hùwà búburú
Nígbà tí àwọn baba wa wà ní Ejibiti,
    iṣẹ́ ìyanu rẹ kò yé wọn,
wọn kò rántí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àánú rẹ,
    gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ṣọ̀tẹ̀ sí ọ níbi Òkun, àní níbi Òkun pupa
Ṣùgbọ́n o gbà wọ́n là nítorí orúkọ rẹ
    láti jẹ́ kí agbára ńlá rẹ di mí mọ̀
O bá Òkun pupa wí, ó sì gbẹ;
    o sì mú wọn la ìbú já bí aginjù
10 O gbà wọ́n là kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn
    láti ọwọ́ ọ̀tá ni o ti gbà wọ́n
11 Omi ya lu àwọn ọ̀tá wọn, bẹ́ẹ̀ ni
    kò sí èyí tí ó yè nínú wọn.
12 Nígbà náà wọn gba ìpinnu rẹ gbọ́
    wọ́n sì kọrin ìyìn rẹ.

Onidajọ 4:1-16

Debora

Lẹ́yìn ikú Ehudu, àwọn ènìyàn Israẹli sì tún ṣẹ̀, wọ́n ṣe ohun tí ó burú ní ojú Olúwa. Nítorí náà Olúwa jẹ́ kí Jabini, ọba àwọn Kenaani, ẹni tí ó jẹ ọba ní Hasori, ṣẹ́gun wọn. Orúkọ olórí ogun rẹ̀ ni Sisera ẹni tí ń gbé Haroseti-Hagoyimu. Nítorí tí ó ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún (900) kẹ̀kẹ́ ogun irin, ó sì ń pọ́n Israẹli lójú gidigidi fún ogún ọdún, Israẹli ké pe Olúwa fún ìrànlọ́wọ́.

Debora, wòlíì obìnrin, aya Lapidoti ni olórí àti aṣíwájú àwọn ará Israẹli ní àsìkò náà. Òun a máa jókòó ṣe ìdájọ́ ní abẹ́ igi ọ̀pẹ tí a sọ orúkọ rẹ̀ ní ọ̀pẹ Debora láàrín Rama àti Beteli ní ilẹ̀ òkè Efraimu, àwọn ará Israẹli a sì máa wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti yanjú èdè-àìyedè tí wọ́n bá ní sí ara wọn, tàbí láti gbọ́ ohùn Olúwa láti ẹnu rẹ̀. Ní ọjọ́ kan, ó ránṣẹ́ pe Baraki ọmọ Abinoamu, ẹni tí ń gbé ní Kedeṣi ní ilẹ̀ Naftali, ó sì wí fún un pé, “Olúwa, Ọlọ́run Israẹli pa á ní àṣẹ fún un pé: ‘Kí ó kó ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá àwọn akọni ọkùnrin jọ láti ẹ̀yà Naftali àti ẹ̀yà Sebuluni bí ẹgbẹ́ ogun, kí o sì síwájú wọn lọ sí òkè Tabori. Èmi yóò sì fa Sisera olórí ogun Jabini, pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ ogun rẹ àti àwọn ogun rẹ, sí odò Kiṣoni èmi yóò sì fi lé ọ lọ́wọ́ ìwọ yóò sì ṣẹ́gun wọn níbẹ̀.’ ”

Baraki sì dá a lóhùn pé, “Èmi yóò lọ tí ìwọ ó bá bá mi lọ, ṣùgbọ́n tí ìwọ kì yóò bá bá mi lọ, èmi kì yóò lọ.”

Debora dá a lóhùn pé, “ó dára, èmi yóò bá ọ lọ. Ṣùgbọ́n ọlá ìṣẹ́gun tí o ń lọ yìí kò ní jẹ́ tìrẹ, nítorí Olúwa yóò fi Sisera lé obìnrin lọ́wọ́” Báyìí Debora bá Baraki lọ sí Kedeṣi. 10 Nígbà tí Baraki pe ẹ̀yà Sebuluni àti ẹ̀yà Naftali sí Kedeṣi ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá akíkanjú ọkùnrin ogun tẹ̀lé e, Debora pẹ̀lú bá wọn lọ.

11 Ǹjẹ́ Heberi ọmọ Keni, ti ya ara rẹ́ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọmọ Keni, àní àwọn ọmọ Hobabu, àna Mose, ó sì pa àgọ́ rẹ̀ títí dé ibi igi óákù Saananimu, tí ó wà ni agbègbè Kedeṣi.

12 Nígbà tí a sọ fún Sisera pé Baraki ọmọ Abinoamu ti kó ogun jọ sí òkè Tabori, 13 Sisera kó gbogbo kẹ̀kẹ́ ogun irin rẹ̀ tí ṣe ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀run (900) àti gbogbo àwọn ènìyàn (ọmọ-ogun) tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, láti Haroseti tí àwọn orílẹ̀-èdè wá sí odò Kiṣoni.

14 Debora sì wí fún Baraki pé, “Lọ! Lónìí ni Olúwa fi Sisera lé ọ lọ́wọ́, Olúwa ti lọ síwájú rẹ.” Baraki sì síwájú, àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá sì tẹ̀lé e lẹ́yìn, wọ́n sì kọjá sí òkè Tabori. 15 Olúwa sì mú ìdàrúdàpọ̀ wá sí àárín ogun Sisera, Olúwa sì fi ojú idà ṣẹ́gun Sisera àti àwọn oníkẹ̀kẹ́ ogun àti ọmọ-ogun orí ilẹ̀ ní iwájú Baraki. Sisera sì sọ̀kalẹ̀ lórí kẹ̀kẹ́-ẹṣin rẹ̀ ó sì fi ẹsẹ̀ sálọ.

16 Baraki àti àwọn ogun rẹ̀ sì lé àwọn ọ̀tá náà, àwọn ọmọ-ogun orílẹ̀ àti àwọn kẹ̀kẹ́ ogun wọn títí dé Haroseti ti àwọn orílẹ̀-èdè, gbogbo ogun Sisera sì ti ojú idà ṣubú, kò sí ọ̀kan tí ó lè sálà tàbí tí ó wà láààyè.

Efesu 6:10-17

Ìhámọ́ra Ọlọ́run

10 Ní àkótán, ara mí, ẹ jẹ́ alágbára nínú Olúwa, àti nínú agbára ipá rẹ̀. 11 Ẹ gbé gbogbo ìhámọ́ra Ọlọ́run wọ̀, kí ẹ̀yin lè kọ ojú ìjà sí àrékérekè èṣù. 12 Nítorí pé kì í ṣe ẹ̀jẹ̀ àti ẹran-ara ní àwa ń bá jìjàkadì, ṣùgbọ́n àwọn ìjòyè, àwọn ọlọ́lá, àwọn aláṣẹ ìbí òkùnkùn ayé yìí, àti àwọn ẹ̀mí búburú ní ojú ọ̀run. 13 Nítorí náà, ẹ gbé gbogbo ìhámọ́ra Ọlọ́run wọ̀, kí ẹ̀yin lè dúró tiiri sí ọjọ́ ibi, nígbà tí ẹ̀yin bá sì ti ṣe ohun gbogbo tan kí ẹ sì dúró. 14 (A)Ẹ dúró nítorí náà lẹ́yìn tí ẹ fi àmùrè òtítọ́ dì ẹ̀gbẹ́ yin, tí ẹ sì ti di ìgbàyà òdodo mọ́ra. 15 (B)Tí ẹ sì ti fi ìmúra ìhìnrere àlàáfíà wọ ẹsẹ̀ yín ní bàtà. 16 Ní àfikún, ẹ mú apata ìgbàgbọ́, nípa èyí tí ẹ̀yin lè máa fi paná gbogbo ọfà iná ẹni ibi náà. 17 Kí ẹ sì mú àṣíborí ìgbàlà, àti idà ẹ̀mí, tí í ṣe ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.