Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
5 Ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ rẹ, ìwọ Olúwa, ó ga dé ọ̀run,
òtítọ́ ọ̀ rẹ ga dé àwọsánmọ̀.
6 Òdodo rẹ dàbí àwọn òkè Ọlọ́run,
àwọn ìdájọ́ rẹ dàbí ibú ńlá;
ìwọ gba ẹranko àti ènìyàn là, Olúwa.
7 Báwo ni ìṣeun ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ rẹ ti tó! Ọlọ́run!
Kí gbogbo ọmọ ènìyàn le sá sí abẹ́ òjìji ìyẹ́ rẹ.
8 Àsè ilé rẹ yóò tẹ́ wọn lọ́rùn gidigidi;
ìwọ yóò sì mú wọn mu nínú odò inú dídùn rẹ.
9 Nítorí pé pẹ̀lú rẹ ni orísun ìyè wà:
nínú ìmọ́lẹ̀ rẹ ni àwa yóò rí ìmọ́lẹ̀.
10 Mú ìṣeun ìfẹ́ ẹ̀ rẹ sí àwọn tí ó mọ̀ ọ́n
àti ìgbàlà rẹ sí àwọn tí ó ní ìdúró ṣinṣin ọkàn!
4 “Tí ìwọ yóò bá yí padà, Ìwọ Israẹli,
padà tọ̀ mí wá,”
ni Olúwa wí.
“Tí ìwọ yóò bá sì mú ìríra rẹ kúrò níwájú mi,
ìwọ kí ó sì rìn kiri.
2 Tí ó bá jẹ́ lóòtítọ́ àti òdodo ni ìwọ búra.
Nítòótọ́ bí Olúwa ti wà láààyè,
nígbà náà ni orílẹ̀-èdè yóò di alábùkún fún nípasẹ̀ rẹ,
àti nínú rẹ̀ ni wọn yóò ṣògo.”
3 Èyí ni ohun tí Olúwa wí fún àwọn ènìyàn Juda àti Jerusalẹmu.
“Hú gbogbo ilẹ̀ tí ẹ kò lò rí,
kí o má sì ṣe gbìn sáàrín ẹ̀gún.”
4 Kọ ara rẹ ní ilà sí Olúwa
kọ ọkàn rẹ ní ilà
ẹ̀yin ènìyàn Juda àti gbogbo ènìyàn Jerusalẹmu,
bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ìbínú mi yóò ru jáde yóò sì jó bí iná,
nítorí ibi tí o ti ṣe
kì yóò sí ẹni tí yóò pa á.
Jesu àti Beelsebulu
14 (A)(B) Ó sì ń lé ẹ̀mí èṣù kan jáde, tí ó sì yadi. Nígbà tí ẹ̀mí èṣù náà jáde, odi sọ̀rọ̀; ẹnu sì ya ìjọ ènìyàn. 15 Ṣùgbọ́n àwọn ẹlòmíràn nínú wọn wí pé, “Nípa Beelsebulu olórí àwọn ẹ̀mí èṣù ni ó fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde.” 16 (C)Àwọn ẹlòmíràn sì ń dán an wò, wọ́n ń fẹ́ ààmì lọ́dọ̀ rẹ̀ láti ọ̀run wá.
17 Ṣùgbọ́n òun mọ èrò inú wọn, ó wí fún wọn pé, “Gbogbo ìjọba tí ó ya ara rẹ̀ ní ipá, ni a ń sọ di ahoro; ilé tí ó sì ya ara rẹ̀ nípá yóò wó. 18 Bí Satani ba yapa sí ara rẹ̀, ìjọba rẹ̀ yóò ha ṣe dúró? Nítorí ẹ̀yin wí pé, nípa Beelsebulu ni èmi fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde. 19 Bí ó ba ṣe pé nípa Beelsebulu ni èmi fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, nípa ta ni àwọn ọmọ yín fi ń lé wọn jáde, nítorí náà àwọn ni yóò ṣe onídàájọ́ yín. 20 Ṣùgbọ́n bí ó bá ṣe pé nípa ìka ọwọ́ Ọlọ́run ni èmi fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, ǹjẹ́ ìjọba Ọlọ́run dé bá yín tán.
21 “Nígbà tí alágbára ọkùnrin tí ó ni ìhámọ́ra bá ń ṣọ́ ààfin rẹ̀, ẹrù rẹ̀ yóò wà ní àlàáfíà. 22 Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹni tí ó ní agbára jù ú bá kọlù ú, tí ó sì ṣẹ́gun rẹ̀ a gba gbogbo ìhámọ́ra rẹ̀ tí ó gbẹ́kẹ̀lé lọ́wọ́ rẹ̀, a sì pín ìkógun rẹ̀.
23 (D)“Ẹni tí kò bá wà pẹ̀lú mi, ó lòdì sí mi: ẹni tí kò bá sì bá mi kójọpọ̀, ó fọ́nká.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.